Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Irú Ìfẹ́ Yìí Wú Wa Lórí Gan-an Ni”

“Irú Ìfẹ́ Yìí Wú Wa Lórí Gan-an Ni”

NÍ ỌJỌ́ Saturday, April 25, 2015, ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára kan ṣọṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè Nepal. Apá àríwá orílẹ̀-èdè India ni Nepal wà, òkè sì pọ̀ níbẹ̀. Nǹkan bí ọgọ́rin kìlómítà (80 km) sí àríwá ìlú Kathmandu tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè náà ni ìmìtìtì ilẹ̀ yẹn ti ṣọṣẹ́ jù lọ. Ó báni nínú jẹ́ pé nǹkan bí ẹgbẹ́rùn-ún mẹ́jọ ààbọ̀ [8,500] èèyàn ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ. Èyí ni àjálù tó tíì pààyàn jù lọ nínú ìtàn orílẹ̀-èdè Nepal. Ó lé ní ẹgbẹ̀rùn-ún lọ́nà ọgọ́rùn-ún márùn-ún [500,000] ilé tó bà jẹ́. Ẹgbẹ̀rún-ún méjì ó lé igba [2,200] àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló wà lórílẹ̀-èdè Nepal, àgbègbè yìí sì ni ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn ń gbé. Ó dùn wá pé obìnrin kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn ọmọ rẹ̀ méjì kú.

Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń jẹ́ Michelle sọ pé: “Ìpàdé Kristẹni ni ọ̀pọ̀ lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà nígbà tí àjálù náà wáyé. Ká ní kì í ṣe bẹ́ẹ̀ ni, àwọn tó máa kú ì bá pọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ.” Kí ló fàá tí àjálù náà ò fi kan àwọn tó wà nípàdé? Ọ̀nà tí wọ́n gbà kọ Gbọ̀ngàn Ìjọba, ìyẹn ilé ìpàdé wọn ló fàá.

“A TI WÁ MỌ ÀǸFÀÀNÍ Ẹ̀ BÁYÌÍ!”

Wọ́n máa ń kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Nepal lọ́nà tí ìmìtìtì ilẹ̀ kò fi ní lè ṣàkóbá fún un. Arákùnrin Man Bahadur, tó wà lára àwọn tó máa ń kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa sọ pé: “Àwọn èèyàn ti máa ń béèrè ìdí tá a fi ń ṣe ìpìlẹ̀ tó lágbára gan-an fún irú ilé kékeré bẹ́ẹ̀. A ti wá mọ àǹfààní ẹ̀ báyìí!” Lẹ́yìn ìmìtìtì ilẹ̀ yẹn, àwọn tó ń bójú tó iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Nepal yọ̀ǹda pé káwọn èèyàn forí pamọ́ sí àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ọkàn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn aládùúgbò wọn sì balẹ̀ níbẹ̀, láìka ti jìnnìjìnnì tó wà lára wọn nítorí ohun tó ṣẹlẹ̀ náà.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn ará àdúgbò forí pamọ́ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba

Àwọn alàgbà ìjọ bẹ̀rẹ̀ sí í wá àwọn ará ìjọ tí wọn ò tíì rí. Ẹlẹ́rìí kan tó ń jẹ́ Babita sọ pé: “Àwọn alàgbà náà fi àǹfààní àwọn ará ìjọ ṣáájú tara wọn. Irú ìfẹ́ yìí wú wa lórí gan-an ni.” Lọ́jọ́ kejì, àwọn arákùnrin mẹ́ta tó jẹ́ ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Nepal, àtàwọn arákùnrin tó máa ń ṣèbẹ̀wò sí àwọn ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, bẹ̀rẹ̀ sí í lọ láti ìjọ kan sí òmíràn kí wọ́n lè mọ ohun tí wọ́n nílò, kí wọ́n sì pèsè ìrànwọ́ fáwọn alàgbà tó wà lágbègbè yẹn.

Gary Breaux, láti oríléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó fara pa

Ọjọ́ mẹ́fà lẹ́yìn ìmìtìtì ilẹ̀ náà, Arákùnrin Gary Breaux pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ Ruby, láti oríléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà wá sí orílẹ̀-èdè Nepal. Arákùnrin Reuben tó jẹ́ ọ̀kan lára ìgbìmọ̀ tá a mẹ́nu bà lókè sọ pé: “Torí ìdàrúdàpọ̀ tó wà nílùú Kathmandu, àti pé ara àwọn èèyàn ò tíì balẹ̀, a ronú pé Arákùnrin Breaux kò ní lè wá. Àmọ́, ó pinnu pé òun máa débẹ̀, ó sì wá lóòótọ́! Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nílùú yẹn mọyì ìbẹ̀wò náà gan-an.”

‘A TI WÁ SÚN MỌ́RA GAN-AN JU TI TẸ́LẸ̀ LỌ’

Arákùnrin Silas, tó ń ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Nepal, sọ pé: “Gbàrà tá a ti tún ẹ̀rọ tẹ́lifóònù wa ṣe ni ìpè ti ń wọlé tọ̀sán tòru! Ọ̀pọ̀ àwọn tá a jọ jẹ́ Ẹlẹ́rìí kárí ayé ló ń ronú nípa wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ń sọ èdè tí a ò gbọ́, síbẹ̀ a rí i pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ wa, wọ́n sì ń hára gàgà láti ṣèrànwọ́.”

Àwọn Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ oníṣègùn láti ilẹ̀ Yúróòpù ń tọ́jú àwọn tó fara pa

Fún ọ̀pọ̀ ọjọ́ làwọn Ẹlẹ́rìí lágbègbè yẹn fi ń gbé oúnjẹ wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, kí wọ́n lè fún àwọn tó ṣaláìní. Láfikún sí i, a dá Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù sílẹ̀, onírúurú ohun èlò sì bẹ̀rẹ̀ sí í ya wọlé, ní pàtàkì láti Bangladesh, India àti Japan. Ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, àwọn Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ oníṣègùn dé láti ilẹ̀ Yúróòpù, wọ́n sì fi Gbọ̀ngàn Ìjọba kan ṣe ibùjókòó. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, wọ́n ń tọ́jú àwọn tó fara pa, wọ́n sì tún ń ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè borí ìbànújẹ́ náà.

Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Uttara sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ọ̀pọ̀ èèyàn, ó ní: “Ìmìtìtì ilẹ̀ yẹn lágbára gan-an, ó sì ń dẹ́rù bani. Àmọ́ lẹ́yìn náà, a wá túbọ̀ sún mọ́ àwọn ará wa ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.” Kò sí àní-àní pé ìmìtìtì ilẹ̀ náà kò mú kí ìfẹ́ táwọn èèyàn Jèhófà ní fún un àtàwọn ará wọn dín kù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló mú kí ìfẹ́ náà lágbára sí i.