Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JÍ! No. 1 2017 | Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Ọ̀dọ́ Tó Ní Ìdààmú Ọkàn

Ìròyìn fi hàn pé àwọn ọ̀dọ́ tó ń ní ìdààmú ọkàn ti wá ń pọ̀ kọjá wẹ́rẹwẹ̀rẹ báyìí.

Kí la lè ṣe nípa ìṣòro yìí?

Ìtẹ̀jáde Jí! yìí jíròrò àwọn ohun tó lè ran àwọn ọ̀dọ́ tó ní ìdààmú ọkàn lọ́wọ́, ó sì tún sọ ohun tí àwọn òbí wọn lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́, kí wọ́n sì tù wọ́n nínú.

 

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Ọ̀dọ́ Tó Ní Ìdààmú Ọkàn

Àpilẹ̀kọ yìí sọ ohun tó máa ń fà ìdààmú ọkàn àti bá a ṣe lè mọ̀ pé òun ló ń ṣe ẹnì kan. Wo ohun tí àwọn òbí àtàwọn mí ì lè ṣe.

Ẹ̀rín Músẹ́—Ẹ̀bùn Tó O Lè Fúnni

Tí ọ̀rẹ́ rẹ tàbí àjèjì kan bá rẹ́rìn-ín sí ẹ, ó dájú pé wàá rẹ́rìn-ín sí i pa dà, torí pé ó máa ń mára tuni.

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Ìṣẹ́yún

Ọ̀kẹ́ àìmọye oyún làwọn èèyàn ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣẹ́ dànù lọ́dọọdún. Ṣé ohun tó bá wù ẹ́ lo lè ṣe sí oyún inú rẹ?

“Irú Ìfẹ́ Yìí Wú Wa Lórí Gan-an Ni”

Lọ́jọ́ Saturday, April 25, 2015, ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára kan ṣọṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè Nepal. Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi hàn pé Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ máa fìfẹ́ hàn

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ

Bó O Ṣe Lè Mọyì Ẹnì Kejì Rẹ

Tí ọkọ àti ìyàwó bá ń sapá láti kíyè sí àwọn ànímọ́ tó dáa tí ẹnì kejí wọn ní, àjọgbé wọn máa tura. Báwo lo ṣe lè jẹ́ ẹni tó máa ń fi ìmọrírì hàn?

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Kòkòrò Saharan Silver

Ọ̀kan lára àwọn kòkòrò tó lè farada ooru gbígbóná ni kòkòrò yìí. Báwo ló ṣe ń ṣe é?

Àwọn Nǹkan Míì Tó Wà Lórí Ìkànnì

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Borí Àníyàn?

Àwọn ohun mẹ́fà tó máa jẹ́ kí àníyàn ràn ẹ́ lọ́wọ́ tí kò sì ní pa ẹ́ lára.

Ṣé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Ṣèrànwọ́ Nígbà Àjálù?

Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, wo bá a ṣe ń ran àwọn ará wa lọ́wọ́, títí kan àwọn míì tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà.