Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kókó Iwájú Ìwé

Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Ọ̀dọ́ Tó Ní Ìdààmú Ọkàn

Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Ọ̀dọ́ Tó Ní Ìdààmú Ọkàn

ANNA * sọ pé: “Tí mo bá ní ìdààmú ọkàn, ńṣe ni gbogbo nǹkan máa ń tojú sú mi, nǹkan kan ò sì ní wù mí ṣe, kódà kó jẹ́ àwọn nǹkan tí mo nífẹ̀ẹ́ sí tẹ́lẹ̀. Ńṣe láá kàn máa ṣe mí bíi kí n máa sùn. Ó tún máa ń ṣe mí bíi pé àwọn èèyàn ò nífẹ̀ẹ́ mi, pé mi ò jámọ́ nǹkan kan àti pé mò ń fi tèmi ni àwọn míì lára.”

Julia sọ pé: “Mo máa ń ronú pé kí n pa ara mi. Lóòótọ́, kì í ṣe pé ó wù mí kí ń kú. Mò kàn ń wá ohun tó máa gbé ìdààmú ọkàn mi kúrò ni. Ẹni tó láájò èèyàn ni mí, àmọ́ nígbà tí mo bá ní ìdààmú ọkàn, mi ò kì í ronú nípa àwọn ẹlòmíì.”

Anna àti Julia ṣẹ̀ṣẹ̀ lé lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá ni nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìdààmú ọkàn. Ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan làwọn ọ̀dọ́ míì máa ń nírú ìṣòro yìí, àmọ́ ọ̀rọ̀ ti Anna àti Julia kò rí bẹ́ẹ̀, lemọ́lemọ́ ni wọ́n máa ń ní ìdààmú ọkàn, nígbà míì, ó máa ń gba ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ tàbí ọ̀pọ̀ oṣù kó tó lọ. Anna sọ pé: “Ńṣe ló dà bí ìgbà téèyàn há sínú ihò tó ṣókùnkùn biribiri, tí kò sì sọ́nà àtijáde. Á wá máa ṣe ẹ́ bíi pé orí ẹ fẹ́ dàrú.”

Kì í ṣe Anna àti Julia nìkan ló máa ń nírú ìṣòro yìí. Ó jọ pé àwọn ọ̀dọ́ tó ń ní ìdààmú ọkàn ti wá ń pọ̀ kọjá àfẹnusọ báyìí. Àjọ Ìlera Àgbáyé tiẹ̀ sọ pé ìdààmú ọkàn ni “olórí ohun tó máa ń fa àìlera fún àwọn ọ̀dọ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọdún 10 sí 19, ó sì tún máa ń sọ àwọn míì di aláàbọ̀ ara.”

Àwọn àmì tó fi hàn pé ẹnì kan ní ìdààmú ọkàn lè bẹ̀rẹ̀ sí í hàn lára ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà. Díẹ̀ lára àwọn àmì náà ni pé ó lè máa sùn jù tàbí kó má sùn tó, oúnjẹ lè má lọ lẹ́nu rẹ̀, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í sanra tàbí kó máa rù. Ẹ̀rù lè máa bà á, nǹkan lè máa sú u, ó sì lè máa bànújẹ́ tàbí kó máa ro ara rẹ̀ pin. Bákàn náà, ó lè máa yẹra fáwọn èèyàn, kó máa gbàgbé nǹkan tàbí kí ọkàn rẹ̀ má pa pọ̀, ó lè máa ronú pé kóhun pa ara òun tàbí kó tiẹ̀ gbìyànjú láti para ẹ̀, ó sì lè láwọn àìsàn míì tí kò ṣeé ṣàlàyé. Táwọn onímọ̀ nípa ọpọlọ bá fura pé ìdààmú ọkàn ló ń ṣe ẹnì kan, wọ́n sábà máa ń wá àwọn àmì àrùn tí kò lọ láàárín ọ̀sẹ̀ kan, tí kì í sì í jẹ́ kẹ́ni náà lè ṣàwọn ohun tó yẹ ní ṣíṣe lójoojúmọ́.

ÀWỌN OHUN TÓ Ń FA ÌDÀÀMÚ ỌKÀN FÁWỌN Ọ̀DỌ́

Àjọ Ìlera Àgbàyé sọ pé “ohun tó sábà máa ń fa ìdààmú ọkàn ni ìṣòro tó jẹyọ látinú àjọṣe pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì, ìrònú àti ìwà, àti àìsàn ìdílé.” Díẹ̀ lára wọn rèé:

Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ara. Bíi ti Julia, ìdààmú ọkàn lè jẹ́ àìsàn ìdílé, tó fi hàn pé ó lè ti ara òbí wọ ara ọmọ tí á sì fa ìdàrúdàpọ̀ àwọn kẹ́míkà inú ọpọlọ. Àwọn nǹkan míì tó ṣeé ṣe kó fà á ni àìsàn ọkàn, àyípadà kẹ́míkà inú ara tó máa ń súnni ṣe nǹkan àti ìlòkulò oògùn. Ọ̀pọ̀ ló jẹ́ pé ìlòkulò oògùn tó ti di bárakú ló sọ wọ́n di ẹni tó ń ní ìdààmú ọkàn. *

Ìdààmú. Lóòótọ́, ó dáa kéèyàn làágùn díẹ̀, àmọ́ tí ìdààmú bá ti wọ̀ ọ́ tàbí tí wàhálà bá pọ̀ jù, ó lè mú kó rẹni tàbí kí ọkàn dàrú. Bí ọ̀dọ́ kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà bá kojú irú nǹkan bẹ́ẹ̀, ó lè fa ìdààmú ọkàn fún un. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tíì sí àlàyé tó ṣe tààràtà nípa ohun tó ń fa ìdààmú ọkàn gan-an. Síbẹ̀, díẹ̀ lára àwọn ohun tá a mẹ́nu bà ní ìbẹ̀rẹ̀ lè fà á.

Díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó ń fa ìdààmú ọkàn fún àwọn ọ̀dọ́ ni ìkọ̀sílẹ̀ tàbí ìpinyà àwọn òbí, ikú ẹnì kan tí wọ́n fẹ́ràn, ìfipá-báni-lòpọ̀, ìjàǹbá ọkọ̀, àìsàn, tàbí ìṣòro ìwé kíkà. Nǹkan míì tó tún máa ń fà á ni tí àwọn òbí bá ń retí pé kí ọmọ náà ṣe ju agbára rẹ̀ lọ, bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè ní ó gbọ́dọ̀ gba ipò kìíní nílé ìwé. Wọ́n tún lè máa halẹ̀ mọ́ ọn nílé ìwé, ọkàn ọmọ náà lè má balẹ̀ nipa bí ọjọ́ iwájú ṣe máa rí. Ọmọ náà sì lè ní òbí tí kì í dá sí ọmọ, bóyá torí pé òun gan-an ní ìdààmú ọkàn, ó sì lè jẹ́ òbí tó máa ń bínú sódì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Bí àwọn nǹkan yìí bá fa ìdààmú ọkàn fún ọ̀dọ́ kan, kí ló lè ṣe?

MÓJÚ TÓ ARA ÀTI ÈRÒ RẸ̀

Àwọn dọ́kítà sábà máa ń fún àwọn tí ìdààmú ọkàn wọn kò bá tíì le ní oògùn tàbí kí wọ́n dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ kí ara wọn lè kọ́fẹ pa dà. * Jésù Kristi sọ pé: “Àwọn tí wọ́n lókun kò nílò oníṣègùn, ṣùgbọ́n àwọn tí ń ṣàmódi nílò rẹ̀.” (Máàkù 2:17) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ara àti èrò wa jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀, àìsàn lè ṣákóbá fún wọn. Torí náà, ó lè gba pé ká ṣàtúnṣe sí ohun tá a ń ṣe lójoojúmọ́.

Tó o bá ní ìdààmú ọkàn, ṣe àwọn àtúnṣe tó bá yẹ sí àwọn nǹkan tó ò ń ṣe àti nǹkan tó ò ń rò. Bí àpẹẹre, máa jẹun tó dáa, sùn dáadáa, kó o sì máa ṣeré ìmárale déédéé. Tá a bá ń ṣeré ìmárale, àwọn kẹ́míkà kan máa ń tú jáde tó máa ń jẹ́ kí ara jí pépé, á fún wa lókun, àá sì tún lè sùn dáadáa. Tó bá ṣeé ṣe, gbìyànjú láti tètè mọ ohun tó máa ń fa ìdààmù ọkàn rẹ àti àwọn nǹkan tó o máa ń ṣe tó bá ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀, kó o sì ṣètò bó o ṣe máa kápá rẹ̀. O lè bá ẹni tó o fọkàn tán sọ̀rọ̀. Tó o bá túbò sún mọ́ àwọn ìbátan àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ, èyí lè jẹ́ kó o fara dà á tàbí kó dín ìdààmú ọkàn rẹ kù. Bíi ti Julia tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lókè, ìwọ náà lè kọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ àti ìmọ̀lára rẹ sílẹ̀. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, rí i pé ò ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ohun tó máa jẹ́ kó o wo ìgbésí ayé lọ́nà tó tọ́ gan-an nìyẹn. Jésù Kristi sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.”Mátíù 5:3.

Jẹ oúnjẹ tó dáa, máa ṣeré ìmárale, kó o sì máa sùn dáadáa

Wàá rí ìtùnú tó o bá ń ka Bíbélì

Anna àti Julia jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ Jésù yìí pé òótọ́ ni. Anna sọ pé: “Bí mo ṣe jẹ́ kí ọwọ́ mi dí nípa tẹ̀mí ti jẹ́ kí ń máa ronú nípa bí máa ṣe ran àwọn míì lọ́wọ́, kí n sì gbé ìṣòro mi sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Kì í fìgbà gbogbo rọrùn o, àmọ́ ayọ̀ púpọ̀ wà níbẹ̀.” Julia ní tiẹ̀ máa ń rí ìtùnú nígbà tó bá ń gbàdúrà, tó sì ń ka Bíbélì. Ó sọ pé: “Bí mo ṣe máa ń sọ tọkàn mi fún Ọlọ́run máa ń mára tù mí pẹ̀sẹ̀. Bíbélì sì ti jẹ́ kí ń rí i pé mo níye lórí lójú Ọlọ́run, ó sì nífẹ̀ẹ́ mi. Yàtọ̀ síyẹn, Bíbélì kíkà ti jẹ́ kí ń rí i pé ọ̀la ṣì ń bọ̀ wá dáa.”

Jèhófà Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá wa, torí náà ó mọ bí wọ́n ṣe tọ́ wa dàgbà, ohun tí ojú wa ti rí láyé, àti bí àwọn ànímọ́ tí wọ́n bí mọ́ wa ṣe máa ń nípa lórí ìrísí àti bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa. Torí náà, ó máa ń pèsè ìrànlọ́wọ́ àti ìtùnú tá a nílò nígbà táwọn èèyàn bá fìfẹ́ hàn sí wa. Yàtọ̀ síyẹn, àsìkò ńbọ̀ tí Ọlọ́run máa mú gbogbo àìsàn kúrò. Aísáyà 33:24 sọ pé: “Kò sì sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’”

Bẹ́ẹ̀ ni o, Bíbélì ṣèlérí pé Ọlọ́run máa “nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú [wa], ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.” (Ìṣípayá 21:4) Èyí mà tù wá nínú o! Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún aráyé, jọ̀wọ́, lọ sí ìkànnì wa, ìyẹn jw.org/yo. Wàá rí Bíbélì kà níbẹ̀, pẹ̀lú oríṣiríṣi àpilẹ̀kọ̀ tá a jíròrò, títí kan àlàyé lórí ìdààmù ọkàn.

^ ìpínrọ̀ 3 A ti yí àwọn orúkọ náà pa dà.

^ ìpínrọ̀ 10 Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn àìsàn, oògùn, oògùn olóró lè fa ìrẹ̀wẹ̀sì tàbí ìdààmú ọkàn fún elòmíì, tó sì gba kí wọ́n wá ojútùú lọ sọ́dọ̀ dọ́kítà tó mọ́ṣẹ́.

^ ìpínrọ̀ 14 Jí! kò sọ pé irú ìtọ́jú báyìí ni kí ẹ gbà.