Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Olódodo Yóò Máa Yọ̀ Nínú Jèhófà’

‘Olódodo Yóò Máa Yọ̀ Nínú Jèhófà’

ARÁBÌNRIN DIANA ti lé lẹ́ni ọgọ́rin (80) ọdún. Ọkọ rẹ̀ ní àìsàn tó máa ń mú kí arúgbó ṣarán, ó sì wà nílé ìtọ́jú àwọn arúgbó fún ọdún mélòó kan títí tó fi kú. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ọmọkùnrin ẹ̀ méjì kú, òun fúnra rẹ̀ sì ní àrùn jẹjẹrẹ ọmú. Síbẹ̀ gbogbo ìgbà táwọn ará ìjọ bá rí Diana ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí lóde ẹ̀rí, ṣe ni inú rẹ̀ máa ń dùn.

Alábòójútó arìnrìn-àjò ni John, ohun tó lé ní ọdún mẹ́tàlélógójì (43) ló lò lẹ́nu iṣẹ́ yìí, ó sì gbádùn iṣẹ́ náà gan-an. Àmọ́, ó fi iṣẹ́ náà sílẹ̀ kó lè lọ tọ́jú mọ̀lẹ́bí rẹ̀ kan tó ń ṣàìsàn, ó sì ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ kan. Táwọn tó mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀ bá rí i láwọn àpéjọ wa, wọ́n máa ń sọ pé ìṣarasíhùwà ẹ̀ kò yàtọ̀ rárá torí pé gbogbo ìgbà ni inú rẹ̀ máa ń dùn.

Kí ló mú kí inú Diana àti John máa dùn láìka ìṣòro wọn sí? Báwo lẹnì kan tó ní ẹ̀dùn ọkàn, tó sì tún ń ṣàìsàn ṣe lè máa láyọ̀? Tẹ́nì kan ò bá ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan tó ní tẹ́lẹ̀ mọ́, kí lá jẹ́ kó máa láyọ̀? Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tó ń fúnni láyọ̀, ó ní: “Olódodo yóò sì máa yọ̀ nínú Jèhófà.” (Sm. 64:10) Òótọ́ pọ́ńbélé ni ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ, àmọ́ ká lè lóye ọ̀rọ̀ yìí dáadáa, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun tó lè fúnni láyọ̀ tó máa wà pẹ́ títí àti ohun tí kò lè fúnni nírú ayọ̀ bẹ́ẹ̀.

AYỌ̀ TÓ LÈ MÁ WÀ PẸ́ TÍTÍ

Àwọn nǹkan kan wà tó máa ń fúnni láyọ̀. Bí àpẹẹrẹ, inú ọkùnrin àti obìnrin tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn máa ń dùn gan-an lọ́jọ́ ìgbéyàwó wọn. Bákan náà, tẹ́nì kan bá bímọ tàbí tó láwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan, inú rẹ̀ máa dùn gan-an. Kò sí àní-àní pé àwọn nǹkan yìí máa ń fúnni láyọ̀ torí pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà ni wọ́n. Jèhófà ló dá ìdílé sílẹ̀, òun ló mú kó ṣeé ṣe fún wa láti máa bímọ, òun náà ló sì ń fún wa láwọn iṣẹ́ tá à ń ṣe nínú ìjọ.​—Jẹ́n. 2:​18, 22; Sm. 127:3; 1 Tím. 3:1.

Àmọ́ nígbà míì, àwọn nǹkan yìí kì í fúnni láyọ̀ tó máa ń wà pẹ́ títí. Ọkọ tàbí aya ẹnì kan lè kú tàbí kó di aláìṣòótọ́. (Ìsík. 24:18; Hós. 3:1) Àwọn ọmọ kan máa ń ya aláìgbọràn, kódà wọ́n lè kọtí ikún sí òfin Ọlọ́run débi tí wọ́n á fi yọ wọ́n lẹ́gbẹ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọmọ wòlíì Sámúẹ́lì ṣe ohun tó lòdì sí ìfẹ́ Jèhófà. Òmíì ni wàhálà tó ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé Dáfídì torí pé ó ṣe àgbèrè. (1 Sám. 8:​1-3; 2 Sám. 12:11) Irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ń fa ẹ̀dùn ọkàn tó lágbára, ó sì dájú pé wọn kì í jẹ́ kéèyàn láyọ̀.

Bákan náà, a lè ní àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan lónìí, àmọ́ ká má ní wọn mọ́ tó bá dọ̀la. Ó lè gba pé ká fi iṣẹ́ náà sílẹ̀ torí àìlera, ojúṣe ìdílé tàbí kó jẹ́ torí àwọn ìyípadà tó ń wáyé nínú ètò Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ àwọn tó nírú ìrírí yìí sọ pé ó dun àwọn torí pé àwọn gbádùn iṣẹ́ náà gan-an.

Èyí jẹ́ ká rí i pé lóòótọ́ àwọn nǹkan bí ìgbéyàwó, ọmọ bíbí àti àǹfààní iṣẹ́ ìsìn lè fúnni láyọ̀, àmọ́ ayọ̀ náà lè má wà títí lọ. Ṣé nǹkan míì wà tó lè fúnni láyọ̀ tó máa wà pẹ́ títí láìka ìṣòro tàbí ìyípadà yòówù kó dé sí? Ó dájú pé ó wà torí pé Sámúẹ́lì, Dáfídì àtàwọn míì ṣì láyọ̀ láìka àwọn ìṣòro tí wọ́n kojú sí.

AYỌ̀ TÓ WÀ PẸ́ TÍTÍ

Jésù mọ ohun tó túmọ̀ sí pé kéèyàn ní ayọ̀ tòótọ́. Kó tó wá sáyé, ó gbádùn àwọn àǹfààní tó ní lọ́run. Bíbélì sọ pé, ‘inú rẹ̀ ń dùn níwájú Jèhófà ní gbogbo ìgbà.’ (Òwe 8:30) Àmọ́ nígbà tó wá sáyé, ó kojú ọ̀pọ̀ ìṣòro. Síbẹ̀, Jésù ń láyọ̀ bó ṣe ń ṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀. (Jòh. 4:34) Nígbà tó ń jẹ̀rora lórí òpó igi oró ńkọ́? Bíbélì sọ pé: “Nítorí ìdùnnú tí a gbé ka iwájú rẹ̀, ó fara da òpó igi oró.” (Héb. 12:2) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa nǹkan méjì tí Jésù sọ pé ó ń fúnni láyọ̀ tòótọ́.

Nígbà kan, Jésù rán àádọ́rin (70) ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jáde lọ wàásù. Nígbà tí wọ́n pa dà dé, inú wọn dùn gan-an torí pé wọ́n ṣe iṣẹ́ ìyanu, wọ́n tiẹ̀ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Àmọ́ Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe yọ̀ lórí èyí, pé a mú àwọn ẹ̀mí tẹrí ba fún yín, ṣùgbọ́n ẹ yọ̀ nítorí pé a ti ṣàkọọ́lẹ̀ orúkọ yín ní ọ̀run.” (Lúùkù 10:​1-9, 17, 20) Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé rírí ojú rere Jèhófà ṣe pàtàkì ju àǹfààní iṣẹ́ ìsìn èyíkéyìí téèyàn lè ní. Jèhófà máa rántí àwọn ọmọlẹ́yìn náà sí rere, ìyẹn sì lohun tó máa fún wọn láyọ̀ jù lọ.

Lọ́jọ́ kan tí Jésù ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Ó ya obìnrin Júù kan lẹ́nu nígbà tó rí bí Jésù ṣe ń kọ́ni, ó wá sọ pé ó dájú pé ìyá tó bí Jésù máa láyọ̀ gan-an. Àmọ́ Jésù sọ fún obìnrin náà pé: “Ó tì o, kàkà bẹ́ẹ̀, aláyọ̀ ni àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!” (Lúùkù 11:​27, 28) Àwọn òbí máa ń láyọ̀ tí ọmọ wọn bá jẹ́ àrídunnú. Síbẹ̀, ohun tó máa jẹ́ kéèyàn ní ayọ̀ tó wà pẹ́ títí ni kéèyàn ṣègbọràn sí Jèhófà, kó sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀.

Kò sí àní-àní pé a máa láyọ̀ tá a bá mọ̀ pé inú Jèhófà ń dùn sí wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyà kì í ṣomi ọbẹ̀, síbẹ̀ àá ṣì máa láyọ̀ bá a ṣe ń rántí pé à ń múnú Jèhófà dùn. Tá a bá fara da àwọn ìṣòro tá à ń kojú, ó dájú pé ayọ̀ wa máa pọ̀ sí i. (Róòmù 5:​3-5) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà máa ń fún àwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé e ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, ayọ̀ sì wà lára èso tí ẹ̀mí Jèhófà ń mú ká ní. (Gál. 5:22) Èyí jẹ́ ká túbọ̀ lóye ohun tó wà nínú Sáàmù 64:​10, tó sọ pé: “Olódodo yóò sì máa yọ̀ nínú Jèhófà.”

Kí ló mú kí John máa láyọ̀ láìka ìyípadà tó dé bá a sí?

Ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ká rí ìdí tí Diana àti John fi ń láyọ̀ láìka àwọn ìṣòro àti ìyípadà tó dé bá wọn sí. Diana sọ pé: “Jèhófà ni mo gbára lé, bí ọmọ kan ṣe máa ń gbára lé àwọn òbí rẹ̀.” Báwo ni Diana ṣe ń rí ọwọ́ Ọlọ́run láyé rẹ̀? Ó sọ pé: “Jèhófà bù kún mi, ó sì mú kí n máa fayọ̀ wàásù nígbà gbogbo.” John náà ń fìtara báṣẹ́ ìwàásù nìṣó lẹ́yìn tó fi iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò sílẹ̀. Ó wá sọ ohun tó ràn án lọ́wọ́, ó ní: “Nígbà tí ètò Ọlọ́run sọ mí di olùkọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ lọ́dún 1998, mo túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.” Ìyẹn sì ràn án lọ́wọ́ lẹ́yìn tó fiṣẹ́ arìnrìn-àjò sílẹ̀. Ó fi kún un pé: “Èmi àtìyàwó mi ti pinnu pé gbogbo ohun tí Jèhófà bá ní ká ṣe la máa ṣe, ìyẹn ni ò jẹ́ kí àyípadà yẹn nira jù fún wa. A ò kábàámọ̀ rárá.”

Ọ̀pọ̀ àwọn míì náà ti rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù 64:10. Bí àpẹẹrẹ, tọkọtaya kan ti sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fún ohun tó lé lọ́gbọ̀n (30) ọdún. Nígbà tó yá, ètò Ọlọ́run sọ wọ́n di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Wọ́n sọ pé: “Kò sí béèyàn ṣe máa pàdánù ohun tó nífẹ̀ẹ́ sí tí kò ní dùn ún,” wọ́n wá fi kún un pé: “Bópẹ́bóyá, èèyàn á gbé e kúrò lọ́kàn.” Níjọ tí wọ́n gbé wọn lọ, wọn ò fi nǹkan falẹ̀, kíá ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá ìjọ wọn lọ sóde ẹ̀rí. Tọkọtaya náà tún sọ pé: “A sọ àwọn ohun pàtó tá a fẹ́ fún Jèhófà, bí Jèhófà sì ṣe ń dáhùn àdúrà wa, ọkàn wa balẹ̀, a sì túbọ̀ ń láyọ̀. Kò pẹ́ tá a dé làwọn míì nínú ìjọ yẹn bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, a sì tún láwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì méjì tó ń tẹ̀ síwájú.”

AYỌ̀ TÓ MÁA WÀ TÍTÍ LÁÉ

Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, kì í ṣe gbogbo ìgbà ni inú èèyàn máa ń dùn, torí pé nígbà míì nǹkan lè dùn, ìgbà míì sì rèé, nǹkan lè má lọ bó ṣe yẹ. Síbẹ̀, ọ̀rọ̀ Jèhófà nínú Sáàmù 64:10 ń fi wá lọ́kàn balẹ̀. Ó jẹ́ ká mọ̀ pé a ṣì lè láyọ̀ tá ò bá bọ́hùn lójú ìrẹ̀wẹ̀sì àtàwọn ìyípadà tó lè dé bá wa. Ó ṣe tán Bíbélì sọ pé àwọn “olódodo,” ìyẹn àwọn tó bá jẹ́ olóòótọ́ lójú ìṣòro ‘yóò máa yọ̀ nínú Jèhófà.’ Yàtọ̀ síyẹn, à ń fayọ̀ retí ìlérí tí Jèhófà ṣe pé òun máa mú “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun” wá. Tó bá dìgbà yẹn, a máa di pípé, gbogbo èèyàn Jèhófà á máa ‘yọ ayọ̀ ńláǹlà, wọ́n á sì kún fún ìdùnnú títí láé’ torí àwọn nǹkan tí Jèhófà máa ṣe.​—Aísá. 65:​17, 18.

Ẹ fojú inú wo bí nǹkan ṣe máa rí nígbà yẹn, kò ní sí àìsàn kankan mọ́, koko lara wa máa le. Àwọn nǹkan tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn báni máa di ohun ìgbàgbé, kódà a ò ní rántí wọn mọ́. Bíbélì fi dá wa lójú pé “àwọn ohun àtijọ́ ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà” mọ́. Bákan náà, gbogbo àwọn èèyàn wa tó ti kú máa jíǹde, àá sì tún jọ wà pa pọ̀. Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn òbí lọ̀rọ̀ wọn máa dà bí àwọn òbí ọmọ ọlọ́dún méjìlá (12) tí Jésù jí dìde, Bíbélì sọ pé: “Wọn kò mọ ohun tí wọn ì bá ṣe, nítorí tí ayọ̀ náà pọ̀ jọjọ.” (Máàkù 5:42) Tó bá dìgbà yẹn, gbogbo èèyàn pátá máa di “olódodo” ní gbogbo ọ̀nà, títí ayé làá sì máa “yọ̀ nínú Jèhófà.”