Hósíà 3:1-5

  • Hósíà gba ìyàwó rẹ̀ alágbèrè pa dà (1-3)

  • Ísírẹ́lì máa pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà (4, 5)

3  Ìgbà náà ni Jèhófà sọ fún mi pé: “Lọ lẹ́ẹ̀kan sí i, nífẹ̀ẹ́ ìyàwó rẹ tí ọkùnrin míì ti fẹ́, tó sì ń ṣe àgbèrè,+ bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn Ísírẹ́lì+ bí wọ́n tilẹ̀ lọ sọ́dọ̀ àwọn ọlọ́run míì,+ tí wọ́n sì fẹ́ràn ìṣù àjàrà gbígbẹ.”*  Nítorí náà, mo rà á fún ara mi ní ẹyọ fàdákà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) àti ọkà bálì tó kún òṣùwọ̀n hómérì* kan àtààbọ̀.  Nígbà náà, mo sọ fún un pé: “Ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni wàá fi jẹ́ tèmi. O ò gbọ́dọ̀ ṣe ìṣekúṣe,* o ò sì gbọ́dọ̀ ní àṣepọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin míì, irú ìwà kan náà ni màá sì hù sí ọ.”*  Nítorí pé ìgbà pípẹ́* ni àwọn èèyàn Ísírẹ́lì yóò máa gbé láìní ọba + àti láìní olórí, láìrú ẹbọ àti láìní òpó, láìsí éfódì+ àti ère tẹ́ráfímù.*+  Lẹ́yìn náà, àwọn èèyàn Ísírẹ́lì máa pa dà wá, wọ́n á wá Jèhófà Ọlọ́run wọn+ àti Dáfídì ọba wọn,+ wọ́n á sì gbọ̀n jìnnìjìnnì wá sọ́dọ̀ Jèhófà àti sí oore rẹ̀ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ìyẹn, èyí tí wọ́n ń lò nínú ìjọsìn èké.
Hómérì kan jẹ́ òṣùwọ̀n tó gba Lítà 220. Wo Àfikún B14.
Tàbí “iṣẹ́ aṣẹ́wó.”
Tàbí “mi ò ní ní àṣepọ̀ pẹ̀lú rẹ.”
Ní Héb., “ọjọ́ púpọ̀.”
Tàbí “àwọn òrìṣà ìdílé; òrìṣà.”