Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kókó Iwájú Ìwé

Nje O Gba Pe Olorun Wa? To O Ba Gba Anfaani Wo Lo Maa Se E?

Nje O Gba Pe Olorun Wa? To O Ba Gba Anfaani Wo Lo Maa Se E?

Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé àwọn ò lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè nípa bóyá Ọlọ́run wà, àwọn míì ò sì ka ìbéèrè náà sí pàtàkì. Ọ̀gbẹ́ni Hervé, tó dàgbà sí orílẹ̀-èdè Faransé sọ pé: “Lóòótọ́, mi ò lè sọ bóyá Ọlọ́run wà tàbí kò sí, àmọ́ mi ò kì í ṣe ẹlẹ́sìn. Ní tèmi o, ohun tí mo gbà ni pé kéèyàn ṣáà ti fọgbọ́n lo ilé ayé. Ìyẹn ò sì ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú Ọlọ́run.”

Àwọn míì lè ní irú èrò tí John, tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní. Ó sọ pé: “Àwọn òbí mi kò gba Ọlọ́run gbọ́. Nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́, mi ò mọ̀ bóyá Ọlọ́run wà. Síbẹ̀, àwọn ìgbà míì wà tọ́rọ̀ náà máa ń ṣe mí ní kàyéfì.”

Ṣé ìwọ náà ti rò ó rí pé ǹjẹ́ Ọlọ́run wà? Tó bá sì wà, kí nìdí tó fi dá àwa èèyàn sáyé? Ó ṣeé ṣe kó o ti rí àwọn nǹkan kan tó o gbà pé kò ní ṣeé ṣe tí kò bá sí Ẹlẹ́dàá. Bí àpẹẹrẹ, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì fi hàn pé ẹnì kan ló dìídì ṣètò ayé yìí kí àwọn nǹkan abẹ̀mí lè máa gbénú rẹ̀. Bákan náà, ẹ̀rí fi hàn pé kò ṣeé ṣe kí nǹkan ẹlẹ́mìí jáde láti ara nǹkan aláìlẹ́mìí.—Wo àpótí náà, “ Àwọn Ẹ̀rí Tó Fi Hàn Pé Ẹlẹ́dàá Wà.”

Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ lórí bí àwọn ẹ̀rí tá a mẹ́nu bà lókè yìí ti ṣe pàtàkì tó. Ńṣe ni wọ́n dà bí àkọlé tó ń tọ́ka sí ohun iyebíye kan. Ó máa ṣe ẹ́ láǹfààní gan-an tó o bá rí àwọn ẹ̀rí tí kò ṣe é já ní koro tó fi hàn pé Ọlọ́run wà, tó o sì tún rí àwọn ìsọfúnni tó ṣe é gbára lé nípa rẹ̀. Àwọn àpẹẹrẹ mẹ́rin kan rèé.

1. ÌDÍ TÁ A FI WÀ LÁYÉ

Tó bá jẹ́ pé ó ní ìdí pàtàkì tá a fi wà láyé, a máa fẹ́ mọ ìdí náà àti bó ṣe kàn wá. Ó ṣe tán, tí Ọlọ́run bá wà, táwa ò sì mọ̀ pé ó wà, á jẹ́ pé òtítọ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ láyé àtọ̀run la ò mọ̀ yẹn.

Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo. (Ìṣípayá 4:11) Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, báwo lèyí ṣe lè jẹ́ kí ìgbésí ayé wa dùn? Jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀.

Nínú gbogbo ẹ̀dá tó wà láyé, àwa èèyàn yàtọ̀. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run dá wa ní àwòrán rẹ̀, ká lè fi ìwà jọ ọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Síwájú sí i, Bíbélì kọ́ wa pé àwa èèyàn lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. (Jákọ́bù 2:23) Kò sí ohun tó lè jẹ́ ká gbádùn ayé wa ju pé ká sún mọ́ Ẹlẹ́dàá wa lọ.

Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run? Àwọn ọ̀rẹ́ Ọlọ́run lè sọ ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn fún un. Ọlọ́run sì ṣèlérí pé òun máa gbọ́ tiwọn, òun sì máa ṣe ohun tí wọ́n fẹ́. (Sáàmù 91:15) Tá a bá jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, a máa mọ ohun tó jẹ́ èrò rẹ̀ nípa ọ̀pọ̀ nǹkan. Èyí sì máa jẹ́ ká rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè pàtàkì nípa ìgbésí ayé.

Tí Ọlọ́run bá wà, táwa ò sì mọ̀ pé ó wà, á jẹ́ pé òtítọ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ láyé àtọ̀run la ò mọ̀ yẹn

2. ÌBÀLẸ̀ ỌKÀN

Ó ṣòro fún àwọn kan láti gbà pé Ọlọ́run wà nítorí ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn kárí ayé. Wọ́n máa ń ronú pé, ‘Kí ló dé tí Ẹlẹ́dàá tó jẹ́ alágbára fi fàyè gba ìyà àti ìwà ibi?’

Ohun tí Bíbélì sọ lórí kókó yìí tù wá nínú, ó jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run kò ní in lọ́kàn pé kí ìyà máa jẹ àwa èèyàn. Kódà, Ọlọ́run kò dá àwa èèyàn pé ká máa kú. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7-9, 15-17) Ṣé kì í ṣe àsọdùn lásán lọ̀rọ̀ yìí? Rárá o. Tó bá jẹ́ pé Ẹlẹ́dàá tó lágbára wà tó sì nífẹ̀ẹ́ wa, kò sí àní-àní pé irú àwọn nǹkan tó dáa báyìí ló máa fẹ́ fún wa.

Kí ló wá fà á tí a fi wà nínú ìṣòro báyìí? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run dá àwa èèyàn láti pinnu ohun tá a fẹ́. A kì í ṣe ẹ̀rọ rọ́bọ́ọ̀tì, tí Ọlọ́run á máa tẹ̀ síbí tẹ̀ sọ́hùn-ún. Àmọ́, tọkọtaya àkọ́kọ́ tí gbogbo àwa èèyàn ṣẹ̀ wá látọ̀dọ̀ wọn ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, wọ́n sì ṣe ìfẹ́ inú ara wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6, 22-24) Ìyà àìgbọ́ràn wọn la wá ń jẹ báyìí.

Ọkàn wa máa balẹ̀ tá a bá mọ̀ pé ìyà tó ń jẹ wá kò sí lára ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fún àwa èèyàn nígbà tó ṣẹ̀dá wa. Àmọ́ gbogbo wa la fẹ́ kí ìyà tó ń jẹ wá dópin, kí ọjọ́ ọ̀la wa sì dùn bí oyin.

3. ÌRÈTÍ

Gbàrà tí àwọn èèyàn àkọ́kọ́ ti ṣọ̀tẹ̀ ni Ọlọ́run ti ṣe ìlérí pé òun ṣì máa ṣe ohun tí òun ní lọ́kàn fún wa. Torí pé òun ni Olódùmarè, kò sí ohun tó lè dí i lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó ní lọ́kàn. (Aísáyà 55:11) Láìpẹ́, Ọlọ́run máa mú gbogbo àjálù tí àìgbọ́ràn Ádámù àti Éfà ti dá sílẹ̀ kúrò, gbogbo nǹkan sì máa pa dà sí bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí nígbà tó dá ilẹ̀ ayé.

Àǹfààní wo ni èyí máa ṣe fún ẹ? Wo méjì péré lára ohun tí Bíbélì sọ pé Ọlọ́run máa ṣe lọ́jọ́ iwájú.

  • ALÁÀFÍÀ MÁA WÀ KÁRÍ AYÉ, ÌWÀ IBI Á SÌ DÓPIN. “Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́; Dájúdájú, ìwọ yóò sì fiyè sí ipò rẹ̀, òun kì yóò sì sí.  Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sáàmù 37:10, 11.

  • ÀÌSÀN ÀTI IKÚ KÒ NÍ SÍ MỌ́. “Kò sì sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” (Aísáyà 33:24) “Òun yóò gbé ikú mì títí láé, dájúdájú, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò nu omijé kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn.”—Aísáyà 25:8.

Kí nìdí tó fi yẹ ká gbà pé òótọ́ ni àwọn ìlérí Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì? Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà lákọsílẹ̀ nínú Bíbélì ló ti ṣẹ táwọn èèyàn sì jẹ́rìí sí i. Lóòótọ́, a ní ìrètí pé ọlà ń bọ̀ wá dáa, àmọ́ ìyẹn kò mú ìyà tó ń jẹ wá báyìí kúrò. Nǹkan míì wo ni Ọlọ́run tún ṣe láti ràn wá lọ́wọ́?

4. ÌTỌ́SỌ́NÀ TÁ Á JẸ́ KÁ FARA DA ÌṢÒRO KÁ SÌ ṢE ÌPINNU TÓ TỌ́

Ọlọ́run ń fún wa ní ìmọ̀ràn tó máa jẹ́ ká lè fara da ìṣòro, tá á sì jẹ́ ká lè ṣe ìpinnu tó tọ́. Àwọn ìpinnu kan kò fi bẹ́ẹ̀ le, àwọn míì sì wà tó máa ṣòro ṣe, tó jẹ́ pé òun la ó máa bá yí ní gbogbo ọjọ́ ayé wa. Kò sí èèyàn kankan tó lè fún wa ní ọgbọ́n tó máa wúlò bí ọgbọ́n tí Ẹlẹ́dàá wa bá fún wa. Torí pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa, ó máa ń mọ àwọn nǹkan tí kò tíì ṣẹlẹ̀. Torí náà, ó mọ ohun tó máa ṣe wá láǹfààní jù lọ.

Èrò Jèhófà Ọlọ́run ló wà nínú Bíbélì, ẹ̀mí mímọ́ ló sì fi darí àwọn èèyàn tó kọ́ ọ. Bíbélì sọ pé: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn.”—Aísáyà 48:17, 18.

Agbára Ọlọ́run kò ní ààlà, ó sì ṣe tán láti lo agbára rẹ̀ nítorí tiwa. Bíbélì sọ pé Ọlọ́run dà bíi bàbá onífẹ̀ẹ́ tó fẹ́ ràn wá lọ́wọ́. Ó sọ pé: “Baba tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!” (Lúùkù 11:13) Agbára tí Ọlọ́run ń fúnni yìí máa ń tọ́ni sọ́nà, ó sì máa ń fúnni lókun.

Báwo lo ṣe lè rí irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run? Bíbélì dáhùn pé: ‘Ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó wà àti pé òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.’ (Hébérù 11:6) Kó lè dá ẹ lójú pé Ọlọ́run wà lóòótọ́, ìwọ fúnra rẹ gbọ́dọ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run wà.

ṢÉ WÀÁ ṢÈWÁDÌÍ FÚNRA RẸ?

Ó máa ń gba àkókò kéèyàn tó lè mọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run, àmọ́ kò sí àní-àní pé ó máa ṣe ẹ́ láǹfààní. Ọ̀gbẹ́ni kan tó ń jẹ́ Xiujin Xiao, tí wọ́n bí lórílẹ̀-èdè Ṣáínà, tó sì ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, sọ pé: “Mo gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́, àmọ́ ó wù mí láti mọ ohun tó wà nínú Bíbélì. Torí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ní ọdún tí mo lò kẹ́yìn ní kọ́lẹ́ẹ̀jì, ọwọ́ mi dí gan-an débi pé mí ò ráyè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ́. Èyí ò jẹ́ kí inú mi dùn. Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa dà, ayọ̀ mi wá kún.”

Ṣé wàá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá wa? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o wá àyè láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀.