Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Ise Ti Irun Imu Ologbo N Se

Ise Ti Irun Imu Ologbo N Se

ÀWỌN ológbò tí à ń sìn nílé sábà máa ń ṣọdẹ lálẹ́. Irun imú wọn máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó wà nítòsí wọn, kí ọwọ́ wọn sì tẹ ohun tí wọ́n ń ṣọdẹ rẹ̀, pàápàá lọ́wọ́ alẹ́.

Rò ó wò ná: Ńṣe ni irun imú ológbò lẹ̀ mọ́ ẹran ara tó ní àwọn iṣan tó pọ̀. Àwọn iṣan yìí máa ń yára mọ nǹkan lára, kódà kó jẹ́ pé ńṣe ni afẹ́fẹ́ kàn rọra fẹ́ yẹ́ẹ́. Fún ìdí yìí, ológbò lè mọ ohun tó wà láyìíká rẹ̀ láìjẹ́ pé ó rí nǹkan ọ̀hún. Èyí sì wúlò gan-an nínú òkùnkùn.

Níwọ̀n bí irun imú yìí ti máa ń tètè mọ nǹkan lára, àwọn ológbò máa ń lò ó láti mọ ibi tí ohun kan, tàbí ẹran tí wọ́n fẹ́ pa wà àti bó ṣe ń rìn lọ. Irun imú yìí tún máa ń jẹ́ kí àwọn ológbò mọ bí nǹkan ṣe fẹ̀ tó kí wọ́n tó gba àárín rẹ̀ kọjá. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica gbà pé “díẹ̀ la ṣì mọ̀ lára gbogbo iṣẹ́ tí irun imú ológbò lè ṣe, àmọ́, ohun tá a mọ̀ ni pé téèyàn bá gé irun imú náà kúrò, ológbò kò ní lè ṣe nǹkan kan láàárín àkókò díẹ̀ lẹ́yìn náà.”

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ń ṣe àwọn rọ́bọ́ọ̀tì tó ní ẹ̀rọ kan tí wọ́n ń pè ní e-whiskers. Ẹ̀rọ yìí máa ń ṣiṣẹ́ bí irun imú ológbò, ó sì máa jẹ́ kí rọ́bọ́ọ̀tì náà lè gba àwọn ibi pàlàpálá kọjá. Onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ali Javey, tó ń ṣiṣẹ́ ní Yunifásítì California ní ìlú Berkeley sọ pé ẹ̀rọ tí wọ́n pè ní e-whiskers yìí, “gbọ́dọ̀ ní onírúurú ètò ìṣiṣẹ́ kọ̀ǹpútà. Ètò ìṣiṣẹ́ kọ̀ǹpútà yìí máa jẹ́ èyí tó lè bá àwọn ẹ̀rọ rọ́bọ́ọ̀tì tó lágbára gan-an ṣíṣẹ. Ìyẹn àwọn rọ́bọ́ọ̀tì tí èèyàn lè bá sọ̀rọ̀ táá sì máa ṣe bí nǹkan ẹlẹ́mìí.”

Kí lèrò rẹ? Ṣé ẹfolúṣọ̀n ló mú kí irun imú ológbò máa ṣiṣẹ́ lọ́nà yìí? Àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?