Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ỌMỌ TÍTỌ́

Bó O Ṣe Lè Máa Bá Ọmọ Rẹ Tó Ti Ń Bàlágà Sọ̀rọ̀

Bó O Ṣe Lè Máa Bá Ọmọ Rẹ Tó Ti Ń Bàlágà Sọ̀rọ̀

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRÒ

Nígbà tí ọmọ rẹ ṣì kéré, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ohun tí kì í sọ fún ọ. Àmọ́ ní báyìí tó ti ń bàlágà, agbára káká lo fi ń mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. Tó o bá ń bá a sọ̀rọ̀, ó lè jẹ́ pé imú ló máa fi dáhùn tàbí kó tiẹ̀ máa bá ẹ jiyàn títí tọ́rọ̀ náà fi máa bí ẹ nínú tá á sì wá di wàhálà.

O lè mọ bó o ṣe máa bá ọmọ rẹ tó ti ń bàlágà sọ̀rọ̀ láìjẹ́ pẹ́ ẹ̀ ń bára yín fa ọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n, jẹ́ ká kọ́kọ́ wo nǹkan méjì tó lè fa ìṣòro.

OHUN TÓ FÀ Á

Wọ́n ń fẹ́ òmìnira. A kì í fi ọjọ́ kan ṣoṣo bọ́ ọmọ tó rù sanra, torí náà, kì í ṣe ọjọ́ kan ni ọmọ máa ń dàgbà di ẹni tó tójú bọ́. Bí ọmọ náà ṣe ń dàgbà, kò ní fẹ́ kó o máa ṣe gbogbo nǹkan fún òun mọ́. Òun náà á fẹ́ máa ṣe àwọn ìpinnu kan fúnra rẹ̀. Òótọ́ ni pé àwọn ọmọ kan máa ń fẹ́ kí àwọn òbí fún wọn lómìnira ju bí wọ́n ṣe lẹ́tọ̀ọ́ sí i lọ. Àmọ́, àwọn òbí míì kì í fẹ́ fún àwọn ọmọ wọn lómìnira tó bó ṣe yẹ. Èyí sì sábà máa ń dá wàhálà sílẹ̀ láàárín àwọn òbí àtàwọn ọmọ tó ṣẹ̀ ń bàlágà. Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] kan tó ń jẹ́ Brad * sọ pé: “Gbogbo nǹkan tí mo bá ń ṣe pátá làwọn òbí mi máa ń fẹ́ mọ̀ ṣáá. Tí mo bá fi lè pé ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] pẹ́nrẹ́n, tí wọn ò sì fún mi lómìnira tó bí mo ṣe fẹ́, ṣe ni màá kúrò nílé fún wọn!”

Ìrònú wọn ti ń jinlẹ̀ sí i. Àwọn ọmọdé kì í fi bẹ́ẹ̀ ro ọ̀rọ̀ jinlẹ̀, àmọ́ àwọn ọmọ tó ti ń bàlágà máa ń ro ọ̀rọ̀ kọjá ohun tó kàn ṣẹlẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ríro ọ̀rọ̀ jinlẹ̀ máa ń jẹ́ káwọn ọ̀dọ́ lè ṣe ìpinnu lọ́nà tó mọ́yán lórí. Bí àpẹẹrẹ: Lójú ọmọ kékeré kan, tí ìyá rẹ̀ bá pín ẹja fún òun àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ́gbọọgba, ìyá yẹn ti ṣe ohun tó tọ́ nìyẹn. Àmọ́ àwọn ọ̀dọ́ tún máa ń ronú ju bẹ́ẹ̀ lọ. Lójú tiwọn, téèyàn bá pín nǹkan lọ́gbọọgba, kò fìgbà gbogbo túmọ̀ sí pé onítọ̀hún ti ṣe ohun tó tọ́. Irú àròjinlẹ̀ yìí máa ń mú kí oríṣiríṣi ọ̀rọ̀ máa jà gùdù lọ́kàn àwọn ọmọ tó ti ń bàlágà. Ó sì tún lè fa ìṣòrò láàárín ìwọ àti ọmọ rẹ.

 OHUN TÓ O LÈ ṢE

Nígbàkigbà tó bá ṣeé ṣe, ẹ jọ máa sọ̀rọ̀ bí ọ̀rẹ́. Má ṣe dúró dìgbà tẹ́ ẹ bá dìídì pera yín jókòó kẹ́ ẹ tó jọ sọ̀rọ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn òbí kan ti rí i pé ó máa ń rọrùn fún àwọn ọmọ wọn tó ti ń bàlágà láti sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn tí wọ́n bá jọ ń ṣiṣẹ́ ilé tàbí tí wọ́n bá jọ wà nínú mọ́tò. Wọ́n máa ń sọ tinú wọn tí wọ́n bá wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn òbí wọn ju tí wọ́n bá ń wojú wọn ní tààràtà lọ.—Ìlànà Bíbélì: Diutarónómì 6:6, 7.

Má ṣe sọ̀rọ̀ jù. Kì í ṣe gbogbo ọ̀rọ̀ ni wàá máa bá ọmọ rẹ fà títí tó fi máa di wàhálà. Kàkà bẹ́ẹ̀, sọ̀rọ̀ níwọ̀n kó o sì dánu dúró. Bópẹ́ bóyá, ohun tó o sọ fún ọmọ rẹ ṣì máa pa dà wá yé e nígbà tó bá ń ronú lórí ohun tó o bá a sọ. Ṣáà ti ní sùúrù fún un.—Ìlànà Bíbélì: Òwe 1:1-4.

Máa fetí sílẹ̀, má ṣe máa rin kinkin. Fetí sílẹ̀ dáadáa sí ohun tí ọmọ rẹ bá ń sọ, má ṣe já lu ọ̀rọ̀ rẹ̀, ìyẹn á jẹ́ kó o lè mọ bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an lọ́kàn rẹ̀. Tó o bá ń dá a lóhùn, á dáa kó o fọgbọ́n ṣe é. Torí tó o bá ń rin kinkin jù, ọmọ rẹ á máa fi ìyẹn kẹ́wọ́ láti ṣàìgbọràn. Ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa bí òbí àti ọmọ tó ti ń bàlágà ṣe lè di ọ̀rẹ́ ara wọn, ìyẹn ìwé Staying Connected to Your Teenager, sọ pé: “Ìgbà tí òbí bá ń rin kinkin gan-an làwọn ọmọ máa ń ṣojú ayé. Tí wọ́n bá wà lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn, wọ́n á máa ṣe ohun tí òbí fẹ́, àmọ́ tinú wọn ni wọ́n máa ṣe tí kò bá sí àwọn òbí wọn níbẹ̀.”—Ìlànà Bíbélì: Fílípì 4:5.

Máa ní sùúrù. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Kari sọ pé: “Tọ́rọ̀ èmi àti mọ́mì mi ò bá ti yéra, ṣe ni wọ́n máa bínú sí mi. Ìyẹn máa ń mú kínú bí èmi náà, àwa méjèèjì á wá bẹ̀rẹ̀ sí í bára wa jiyàn.” Dípò tí wàá fi bínú, sọ̀rọ̀ lọ́nà tí ọmọ rẹ á fi mọ̀ pé “o mọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára òun.” Bí àpẹẹrẹ, dípò kó o sọ pé, “Má yọ ara ẹ lẹ́nu nítorí ọ̀rọ̀ yẹn jàre!” o lè sọ pé, “Èmi náà mọ bọ́rọ̀ yìí ṣe rí lára ẹ.”—Ìlànà Bíbélì: Òwe 10:19.

Máa tọ́ ọ sọ́nà, má ṣe pàṣẹ fún un. A lè fi àròjinlẹ̀ tí ọmọ rẹ bẹ̀rẹ̀ sí í ní wé òdòdó tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà tó sì nílò àbójútó. Torí náà, tí ọmọ rẹ ò bá mọ ohun tó máa ṣe lórí ọ̀rọ̀ kan, jẹ́ kó fúnra ẹ̀ ronú lórí ohun tó máa ṣe kó sì ṣèpinnu fúnra rẹ̀. Tẹ́ ẹ bá jọ ń jíròrò ọ̀rọ̀ náà, ní sùúrù fún un kí òun fúnra rẹ̀ lè sọ ohun tó fẹ́ ṣe láti yanjú ìṣòro náà. Lẹ́yìn náà, tẹ́ ẹ bá ti jọ sọ̀rọ̀ nípa oríṣiríṣi ọ̀nà tó lè gbà yanjú ìṣòro náà, o lè sọ fún un pé: “Díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó o lè ṣe la ti jọ sọ yẹn. Mo fẹ́ kó o tún lọ ronú lórí ọ̀rọ̀ yìí dáadáa láàárín ọjọ́ kan sí méjì, lẹ́yìn náà kó o jẹ́ ká tún jọ sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà tó wù ẹ́ pé kó o gbà yanjú ìṣòro yìí àti ìdí tó o fi rò pé ọ̀nà tó o fẹ́ gbà yanjú ẹ̀ yẹn ló dáa jù.”—Ìlànà Bíbélì: Hébérù 5:14.

^ ìpínrọ̀ 7 A ti yí àwọn orúkọ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.