Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ TÓ DÁ LÓRÍ ÀKÒRÍ Ẹ̀YÌN ÌWÉ

Bó O Ṣe Lè Kọ́ Ọmọ Rẹ Níwà Ọmọlúwàbí Lóde Òní

Bó O Ṣe Lè Kọ́ Ọmọ Rẹ Níwà Ọmọlúwàbí Lóde Òní

OJOOJÚMỌ́ la máa ń láǹfààní láti ṣoore fáwọn èèyàn. Àmọ́ ó ṣeni láàánú pé ayé ti di ayé ọ̀dájú, àwọn èèyàn ò sì mọ̀ ju tara wọn nìkan lọ mọ́. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ibi téèyàn bá dé láyé ló ti máa rí ìwàkiwà yìí. Àwọn èèyàn máa ń rẹ́ àwọn ẹlòmíì jẹ bó ṣe wù wọ́n. Wọ́n máa ń wa ọkọ̀ níwàkuwà. Ọ̀rọ̀ àlùfààṣá ló kún ẹnu wọn. Ìbínú fùfù sì ti gbòde kan.

Ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan ti ń wọnú ọ̀pọ̀ ìdílé pàápàá. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tọkọtaya kan máa ń kọra wọn sílẹ̀ torí wọ́n rò pé ọkọ tàbí aya wọn ò ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ fún wọn. Àwọn òbí kan sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ọmọ wọn níwà burúkú yìí láìmọ̀. Lọ́nà wo? Wọ́n ń kẹ́ àwọn ọmọ wọn lákẹ̀ẹ́bàjẹ́. Gbogbo ohun tọ́mọ bá ṣáà ti fẹ́ ni wọ́n máa ń ṣe fún un. Wọn kì í sì í fẹ́ bá ọmọ wí.

Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ òbí ṣì máa ń kọ́ àwọn ọmọ wọn láti máa gba tàwọn ẹlòmíì rò, kí wọ́n má kàn máa ro tara wọn nìkan ṣáá. Àǹfààní tó wà nínú ohun tí wọ́n ń ṣe yìí kò lóǹkà. Àwọn ọmọ tó bá níwà ọmọlúwàbí sábà máa ń ní ọ̀rẹ́ tí wọ́n jọ máa bá ara wọn kalẹ́. Wọ́n máa ń ní ìtẹ́lọ́rùn. Ìyẹn ò sì yà wá lẹ́nu torí Bíbélì sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.

Tó o bá jẹ́ òbí, báwo lo ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ rẹ kí wọ́n lè níwà ọmọlúwàbí kí wọ́n sì máa ní ayọ̀ téèyàn máa ń ní tó bá ń hùwà rere? Kí lo lè ṣe tí ìwà ìbàjẹ́ tó ti gbòde kan lóde òní kò fi ní kó èèràn ran àwọn ọmọ rẹ? Jẹ́ ká wo nǹkan mẹ́ta tó lè sọ ọmọ di onímọtara-ẹni-nìkan àti ohun tó o lè ṣe káwọn nǹkan yìí má bàa ṣàkóbá fún ọmọ rẹ.

1 Tó O Bá Ń Yìn Wọ́n Jù

Ìṣòro tó wà níbẹ̀. Àwọn tó ń ṣèwádìí sọ ohun kan tó ń kọni lóminú pé: Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ máa ń ro ara wọn ju bó ṣe yẹ lọ. Wọ́n máa ń retí pé dandan ni kọ́wọ́ àwọn tẹ nǹkan ńláńlá láìjẹ́ pé àwọ́n kọ́kọ́ ṣe àwọn ohun tó yẹ. Àwọn kan lára wọn máa ń retí pé táwọn bá ti dé ibi iṣẹ́ kan, kò ní pẹ́ rárá tí wọ́n á fi gbé àwọn ga lẹ́nu iṣẹ́, kódà táwọn ò bá tiẹ̀ mọṣẹ́ ọ̀hún dunjú. Àwọn míì gbà pé àwọn ṣe pàtàkì gan-an, torí náà, àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún àwọn. Bí wọ́n bá wá rí i pé àwọn èèyàn ò fún àwọn lóhun tí àwọ́n fẹ́, ìbànújẹ́ á wá sorí wọn kodò.

Ohun tó fà á. Bí wọ́n ṣe tọ́ àwọn kan dàgbà ló máa ń jẹ́ kí wọ́n máa ro ara wọn ju bó ṣe yẹ lọ. Bí àpẹẹrẹ, àwọn òbí kan ti jẹ́ kí ẹ̀mí ìgbéraga tó kún inú ayé òde òní kó sí wọn lórí. Wọ́n ń mú kó dà bíi pé kò burú téèyàn bá nírú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀. Wọ́n gbà pé tó o bá fẹ́ yin ọmọ, àfi kó o yìn ín kọjá bó ṣe yẹ. Àti pé tó o bá bá ọmọ wí, ìbànújẹ́ lò ń kó bá ọmọ yẹn. Lóde òní tí ìgbéraga sì ti wá gbòde kan, àwọn èèyàn gbà pé òbí tó bá ń bá ọmọ wí kò ṣe dáadáa torí pé kò fẹ́ kí ọmọ náà ka ara rẹ̀ sí pàtàkì nìyẹn. Ohun tí wọ́n ń sọ fáwọn òbí lóde òní ni pé wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ọmọ wọn banú jẹ́ rárá.

Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ àwọn bàbá àtàwọn ìyá fi máa ń yin àwọn ọmọ wọn ju bó ṣe yẹ lọ, kódà nígbà tọ́mọ wọn ò bá tiẹ̀ ṣe nǹkan tó fi yẹ kí wọ́n gbóríyìn fún un pàápàá. Wọ́n máa ń ṣàjọyọ̀ àṣeyọrí tọ́mọ wọn bá ṣe, ì báà tiẹ̀ jẹ́ ohun tí kò tó nǹkan. Tọ́mọ náà bá sì ṣe ohun tó yẹ kí wọ́n fi bá a wí, ṣe ni wọ́n á gbójú fò ó dá, ì báà tiẹ̀ jẹ́ lórí nǹkan pàtàkì pàápàá. Irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ gbà pé, táwọn bá ń yin ọmọ dáadáa, táwọn sì ń gbójú fo àwọn àṣìṣe rẹ̀, ọmọ náà kò ní máa rò pé òun kò já mọ́ nǹkan kan. Táwọn bá ń múnú ọmọ náà dùn nígbà gbogbo, ìyẹn ṣe pàtàkì ju káwọn kọ́ ọ ní ohun tó lè máa múnú ẹ̀ dùn títí lọ.

Ohun tí Bíbélì sọ. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé kò sóhun tó burú nínú kéèyàn yin ẹnì kan nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. (Mátíù 25:19-21) Àmọ́ téèyàn bá kàn ń yin ọmọ torí kórí rẹ̀ lè máa wú, ó lè mú kí ọmọ náà máa ka ara rẹ̀ sí pàtàkì ju bó ṣe yẹ lọ. Bíbélì sọ pé: “Nítorí bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun jẹ́ nǹkan kan nígbà tí kò jẹ́ nǹkan kan, ó ń tan èrò inú ara rẹ̀ jẹ.” (Gálátíà 6:3) Torí náà, Bíbélì sọ fún àwọn òbí pé: “Má ṣe fa ọwọ́ ìbáwí sẹ́yìn kúrò lára ọmọdé, nítorí pé bí ìwọ bá fi pàṣán nà án, òun kì yóò kú.” *Òwe 23:13, Bibeli Mímọ́.

Ohun tó o lè ṣe. Rí i dájú pé ò ń bá ọmọ rẹ wí nígbàkigbà tí ìbáwí bá tọ́ sí i, kó o sì tún máa yìn ín nígbà tó o bá rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀. Má kàn máa gbóríyìn fún ọmọ nítorí pé o fẹ́ mú kí orí rẹ̀ wú. Torí ìyẹn lè ṣàkóbá fún un. Ìwé Generation Me, tó dá lórí bí àwọn èèyàn òde òní ṣe ka ara wọn sí pàtàkì jù, sọ pé: “Téèyàn bá ń kẹ́kọ̀ọ́, tó sì ń sapá láti sunwọ̀n sí i nínú àwọn ohun tó mọ̀ ọ́n ṣe, ìyẹn ló máa jẹ́ kó lè dá ara rẹ̀ lójú lọ́nà tó nítumọ̀, kì í ṣe pé kí wọ́n kàn máa pọ́n ọn lé ní gbogbo ìgbà ṣáá.”

“Má ṣe ro ara [rẹ] jù bí ó ti yẹ lọ. Ṣugbọn kí olukuluku ronú láti máa ṣe jẹ́jẹ́.”—Róòmù 12:3, Ìròhìn Ayọ̀

2 Tó O Bá Ń Dáàbò Bò Wọ́n Jù

Ìṣòro tó wà níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ni wọn ò fi bẹ́ẹ̀ mọ ohun tí wọ́n lè ṣe sáwọn ìṣòrò tí wọ́n ń ní lẹ́nu iṣẹ́ náà. Ìrẹ̀wẹ̀sì máa ń bá wọn tẹ́nì kan bá sọ ibi tí wọ́n kù sí lẹ́nu iṣẹ́ náà fún wọn. Àwọn kan kì í ní ìtẹ́lọ́rùn, iṣẹ́ olówó gọbọi ni wọ́n máa ń wá. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìwé kan tó dá lórí àwọn ọ̀dọ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà, Dókítà Joseph Allen sọ̀rọ̀ nípa ọ̀dọ́ kan tí òun fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò lára àwọn tó ń wáṣẹ́. Ó ní ọ̀dọ̀ náà sọ pé: “Ó dà bíi pé àwọn nǹkan kan wà tó máa ń sú èèyàn nípa iṣẹ́ yìí, èmi ò fẹ́ nǹkan tó máa sú mi o.” Dókítà náà wá sọ pé: “Ó jọ pé pẹ̀lú bó ṣe dàgbà tó yẹn, kò mọ̀ pé gbogbo iṣẹ́ ló máa ń ní ìṣòro tiẹ̀. Ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún [23] ló sì pera rẹ̀ o!”

Ohun tó fà á. Lóde òní, ọ̀pọ̀ àwọn òbí máa ń dáàbò bo àwọn ọmọ wọn ju bó ṣe yẹ lọ. Wọn kì í fẹ́ káwọn ọmọ wọn yanjú ìṣòro kankan fúnra wọn. Bí àpẹẹrẹ, kí lo máa ń ṣe bí ọmọ rẹ bá fìdí rẹmi níléèwé? Ṣé o kì í lọ bá olùkọ́ rẹ̀ pé kó fi kún máàkì tó gbà? Bí ọmọ rẹ bá ṣẹ̀, tí olùkọ́ sì bá a wí ńkọ́? Ṣé o kì í lọ bá olùkọ́ jà lọ́jọ́ kejì? Àbí tí àfẹ́sọ́nà ọmọ rẹ bá já a jù sílẹ̀? Ṣé ẹni yẹn nìwọ náà máa ń di gbogbo ẹ̀bi rù?

Òótọ́ ni pé kò yẹ kéèyàn fi ọmọ rẹ̀ sílẹ̀ fúnyà jẹ. Àmọ́ tó o bá ń dáàbò bò wọ́n ju bó ṣe yẹ lọ, kò ní jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọn ṣe lè yanjú àwọn ìṣòro kan fúnra wọn. Àtubọ̀tán rẹ̀ kì í dáa, ó lè mú kí wọ́n gbà pé àṣegbé ni gbogbo ohun táwọn bá ṣe. Ìwé Positive Discipline for Teenagers, tó dá lórí báwọn òbí ṣe lè tọ́ ọmọ tó ti ń bàlágà, sọ pé: “Dípò kírú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ kọ́ bí wọ́n ṣe lè yanjú àwọn ìṣòro tàbí ìjákulẹ̀ tí wọ́n bá ní, kí wọ́n sì fi ṣàríkọ́gbọ́n, ṣe ni wọ́n máa ń dẹni tó jọra wọn lójú. Wọ́n á sì máa wo ara wọn bí ẹni tó yẹ kí gbogbo èèyàn títí kan àwọn òbí wọn máa gbé gẹ̀gẹ̀.”

Ohun tí Bíbélì sọ. Èèyàn ò lè ṣe kó má níṣòro láyé yìí. Bíbélì pàápàá tiẹ̀ sọ pé, ‘ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo èèyàn.’ (Oníwàásù 9:11) Títí kan àwọn èèyàn rere pàápàá. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fara da oríṣiríṣi ìṣòro lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀. Síbẹ̀, ó kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn ìṣòro tó ní yẹn! Ó sọ pé: “Mo ti kẹ́kọ̀ọ́, nínú àwọn ipò yòówù tí mo bá wà, láti máa ní ẹ̀mí ohun-moní-tómi. . . . mo ti kọ́ àṣírí bí a ti ń jẹ àjẹyó àti bí a ti ń wà nínú ebi, bí a ti ń ní ọ̀pọ̀ yanturu àti bí a ti ń jẹ́ aláìní.”— Fílípì 4:11, 12.

Ohun tó o lè ṣe. Ronú nípa bí òye àwọn ọmọ rẹ ṣe mọ, kó o wá tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì tó sọ pé: “Olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ti ara rẹ̀.” (Gálátíà 6:5) Bí ọmọ rẹ bá ṣẹ̀ tí olùkọ́ sì bá a wí, ó lè jẹ́ ohun tó máa dáa jù ni pé kí ìwọ náà tún bá a wí, kó o sì ní kó lọ bẹ olùkọ́ rẹ̀. Bó bá sì jẹ́ pé ṣe lọmọ rẹ̀ fìdí rẹmi níléèwé, ṣe ni kó o sọ fún un pé kó túbọ̀ múra sí ẹ̀kọ́ rẹ̀. Bí àfẹ́sọ́nà ọmọ rẹ bá já a jù sílẹ̀, ṣe ni kó o tù ú nínú. Tára bá tù ú, kó o wá ní kó ronú lórí ẹ̀kọ́ tó rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i. Bí àwọn ọmọ bá mọ bí wọ́n ṣe lè yanjú àwọn ìṣòro fúnra wọn, tí wọ́n sì ń fi ohun tó bá ṣẹlẹ̀ sí wọn ṣàríkọ́gbọ́n, ó máa sọ wọ́n dọkùnrin, ìyẹn á sì lè jẹ́ kí wọ́n dá ara wọn lójú bó ṣe yẹ. Àmọ́ wọn ò ní lè ṣe gbogbo nǹkan yìí, tí o kò bá jẹ́ kí wọ́n kọ́ bí wọn ṣe lè yanjú àwọn ìṣòrò kan fúnra wọn.

“Kí olukuluku yẹ iṣẹ́ ara rẹ̀ wò, nígbà náà yóò lè ṣògo lórí iṣẹ́ tirẹ̀.”—Gálátíà 6:4, Ìròhìn Ayọ̀

3 Tó O Bá Ń Kẹ́ Wọn Jù

Ìṣòro tó wà níbẹ̀. Nínú ìwádìí tí àwọn kan ṣe láàárín àwọn ọ̀dọ́, ẹni mẹ́jọ nínú mẹ́wàá wọn ló sọ pé báwọn ọ̀dọ́ ṣe fẹ́ di olówó ni wọ́n ń lé lóde òní. Wọ́n ní ìyẹn jẹ àwọn lógún ju bí wọ́n ṣe lè ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ lọ. Àmọ́ téèyàn bá fẹ́ dọlọ́rọ̀, kì í ní ìtẹ́lọ́rùn. Kódà, ìwádìí fi hàn pé àwọn tó ń lé bí wọ́n ṣe máa kó dúkìá jọ kì í fi bẹ́ẹ̀ láyọ̀, ìbànújẹ́ máa ń sorí wọn kodò kẹ́yìn ni. Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ wọn ni onírúurú àìsàn máa ń gbé dè títí kan ìdààmú ọkàn.

Ohun tó fà á. Láti kékeré làwọn òbí kan ti máa ń gbin ìfẹ́ fún ọ̀pọ̀ dúkìá sọ́kàn àwọn ọmọ wọn. Ìwé The Narcissism Epidemic, tó dá lórí bí ìwà ìjọra ẹni lójú ṣe ń pọ̀ sí i, sọ pé: “Àwọn òbí máa ń fẹ́ múnú àwọn ọmọ wọn dùn. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi máa ń ra nǹkan fún wọn ṣáá, nǹkan táwọn ọmọ sì ń fẹ́ nìyẹn. Àmọ́ kì í pẹ́ rárá tó fi máa ń mọ́ àwọn ọmọ lára débi pé wọ́n á máa béèrè pé kí wọ́n tún rà sí i fáwọn.”

Ó ṣe tán, inú àwọn tó ń polówó ọjà máa ń dùn láti kó àwọn èèyàn nífà. Pàápàá àwọn èèyàn tí kò nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Wọ́n máa ń jẹ́ káwọn èèyàn máa ronú pé ohun tó tún dáa ju èyí tó wà lọ́wọ́ wọn ló yẹ kí wọ́n ní, pé ohun tí wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ sí nìyẹn. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ni èrò yìí sì ti wọ̀ lọ́kàn. Wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ sọ ara wọn di onígbèsè. Torí pé wọn ò lówó, wọ́n á wá ra ohun tí wọ́n rò pé àwọn lẹ́tọ̀ọ́ sí yẹn láwìn.

Ohun tí Bíbélì sọ. Bíbélì pàápàá jẹ́rìí sí i pé owó wúlò láàyè tiẹ̀. (Oníwàásù 7:12) Àmọ́, ó tún kìlọ̀ fún wa pé “ìfẹ́ owó ni orísun ìwà búburú gbogbo.” Ó tún wá sọ pé ìfẹ́ owó ti mú kí àwọn kan “fa ìbànújẹ́ púpọ̀ fún ara wọn.” (1 Tímótì 6:10, Bíbélì Mímọ́) Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká má ṣe máa lé bá a ṣe fẹ́ kó ohun ìní tara jọ, àmọ́ ká jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun tá a bá ní tẹ́ wa lọ́rùn.—1 Tímótì 6:7, 8.

“Àwọn tí ó pinnu láti di ọlọ́rọ̀ máa ń ṣubú sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ ìfẹ́-ọkàn tí í ṣe ti òpònú, tí ó sì ń ṣeni lọ́ṣẹ́.”—1 Tímótì 6:9

Ohun tó o lè ṣe. Kí ìwọ òbí náà yẹ ara rẹ wò bóyá o nífẹ̀ẹ́ owó àti ohun ìní ju bó ṣe yẹ lọ. Àwọn nǹkan tó bá ṣe pàtàkì jù ni kó o máa fi sípò àkọ́kọ́, kó o sì kọ́ àwọn ọmọ rẹ láti máa ṣe bákan náà. Ìwé The Narcissism Epidemic tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ lẹ́ẹ̀kan yẹn tún sọ pé: “Àwọn òbí àtàwọn ọmọ lè jọ sọ̀rọ̀ kí wọ́n sì jọ wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè bí, ‘Ìgbà wo ló dáa jù ká máa ra nǹkan? Àsìkò wo ni kò yẹ ká lọ rà á?’ ‘Báwo ni ọjà náà ṣe gbówó lórí sí?’ ‘Ǹjẹ́ mo kàn máa ń ra nǹkan torí pé àwọn ẹlòmíì rò pé ó yẹ kí n rà á?’”

Ẹ má kàn máa ra nǹkan fún ọmọ yín torí kó lè gbàgbé ọ̀rọ̀ àná, ohun tó bá ṣẹlẹ̀ ni kẹ́ ẹ jọ sọ ní ìtùnbí-ìnùbí. Ìwé kan tí wọ́n pè ní The Price of Privilege sọ pé: “Téèyàn bá kàn ń ra nǹkan fún ẹlòmíì torí kó má bàa bínú mọ́, ìyẹn ò ní kọ́rọ̀ náà yanjú. Èèyàn gbọ́dọ̀ ro àròjinlẹ̀ kó sì lo ìfòyemọ̀ láti yanjú ìṣòro. Ríra bàtà tàbí báàgì fún ẹnì kan kọ́ ló yẹ ká máa fi yanjú ìṣòro.”

^ ìpínrọ̀ 11 Ohun tí Bíbélì ń sọ kò túmọ̀ sí pé kí àwọn òbí máa lu ọmọ wọn nílùkulù tàbí kí wọ́n bà wọ́n nínú jẹ́ o. (Éfésù 4:29, 31; 6:4) Torí kí wọ́n lè kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ ló ṣe ní kí wọ́n máa bá wọn wí, kò túmọ̀ sí pé kí àwọn òbí máa kanra mọ́ àwọn ọmọ wọn.