Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌFỌ̀RỌ̀WÁNILẸ́NUWÒ | PAOLA CHIOZZI

Onímọ̀ Sáyẹ́ǹsì Kan Ṣàlàyé Ohun Tó Gbà Gbọ́

Onímọ̀ Sáyẹ́ǹsì Kan Ṣàlàyé Ohun Tó Gbà Gbọ́

Ó lé ní ogún [20] ọdún tí Ọ̀mọ̀wé Paola Chiozzi fi ṣiṣẹ́ ní Yunifásítì tó wà nílùú Ferrara, lórílẹ̀-èdè Ítálì gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ sáyẹ́ǹsì. Àwọn tó ṣe ìwé yìí fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu rẹ̀ nípa iṣẹ́ tó ń ṣe àti ohun tó gbà gbọ́.

Ẹ jọ̀ọ́, ẹ sọ díẹ̀ nípa ara yín fún wa.

Iṣẹ́ bàtà ni bàbá mi ń ṣe, àgbẹ̀ sì ni ìyá mi. Àmọ́, láti kékeré ni mo ti pinnu pé mo fẹ́ di onímọ̀ sáyẹ́ǹsì. Ìdí ni pé àwòyanu ni mo máa ń wo àwọn òdòdó olóòórùn dídùn, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àtàwọn kòkòrò tó wà láyìíká mi. Mo máa ń rò ó lọ́kàn mi pé, ó ní láti jẹ́ pé ẹnì kan tí ọgbọ́n rẹ̀ ta yọ tàwa èèyàn ló dá wọn.

Ìyẹn ni pé àtilẹ̀wá lẹ ti gbà pé Ẹlẹ́dàá wà, àbí?

Rárá o. Láti kékeré ni mo ti máa ń ṣiyèméjì pé bóyá ni Ọlọ́run wà. Ohun tó sì fà á ni pé àrùn ọkàn ṣàdédé pa bàbá mi, ìyẹn sì kọ mí lóminú gan-an. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í bi ara mi pé, ‘Kí ló fà á tí Ọlọ́run tó dá àwọn nǹkan mèremère wọ̀nyí ṣe ń jẹ́ kí ìyà máa jẹ wá ká sì máa kú?’

Ǹjẹ́ ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tẹ́ ẹ ní ti jẹ́ kẹ́ ẹ rí ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn?

Mi ò tètè rí ìdáhùn tí mò ń wá. Ìgbà tí mo di onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, mo bẹ̀rẹ̀ sí í wádìí nípa bí àwọn sẹ́ẹ̀lì inú ara wa ṣe máa ń pààrọ̀ ara wọn nígbà tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn bá kú. Èyí yàtọ̀ sí bí àìsàn ṣe ń pa àwọn sẹ́ẹ̀lì tó sì ń mú kí ara wú tàbí kó dégbò. Ọdún bíi mélòó kan sẹ́yìn làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀ pé báwọn sẹ́ẹ̀lì yìí ṣe máa ń pààrọ̀ ara wọn dára fún ìlera wa, bẹ́ẹ̀ sì rèé àwọn nǹkan yẹn ti wà tipẹ́.

Ẹ sọ pé báwọn sẹ́ẹ̀lì ṣe ń pààrọ̀ ara wọn dára fún ìlera wa. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀?

Ṣẹ́ ẹ rí i, àwọn sẹ́ẹ̀lì tíntìntín tó wà nínú ara wa kò lóǹkà. Gbogbo wọn ló gbọ́dọ̀ kú káwọn míì sì rọ́pò wọn. Àwọn sẹ́ẹ̀lì kan máa ń pẹ́ nínú ara ju àwọn míì lọ. Àwọn kan kì í lò ju ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan lọ. Àwọn míì sì máa ń lo ọdún bíi mélòó kan kí wọn tó pààrọ̀ ara wọn. Torí náà, ọ̀nà táwọn sẹ́ẹ̀lì inú àgọ́ ara wa gbà ń pààrọ̀ ara wọn gbọ́dọ̀ wà létòlétò gan-an. Wọ́n gbọ́dọ̀ pààrọ̀ ara wọn nígbà tó yẹ, ká lè ní ìlera tó péye.

Kí ló lè ṣẹlẹ̀ táwọn sẹ́ẹ̀lì yìí ò bá pààrọ̀ ara wọn bó ṣe yẹ?

Ìwádìí jẹ́ ká mọ̀ pé táwọn sẹ́ẹ̀lì yìí ò bá kú nígbà tó yẹ, kí òmíràn sì rọ́pò wọn, ó lè fa àrùn tó máa ń mú kí oríkèé ara máa roni (ìyẹn rheumatoid arthritis) tàbí àrùn jẹjẹrẹ (ìyẹn cancer). Tó bá sì jẹ́ pé ṣe làwọn sẹ́ẹ̀lì ara yìí kú láìtọ́jọ́, ó lè fa àrùn tó máa ń mú kí apá àti ẹsẹ̀ àtàwọn iṣan ara máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ (ìyẹn Parkinson’s disease) tàbí àrùn tó máa ń jẹ́ kéèyàn gbàgbé nǹkan, kéèyàn má lè sọ̀rọ̀ tàbí kéèyàn má tiẹ̀ mọ nǹkan kan mọ́ (ìyẹn Alzheimer’s disease). Àmọ́, ìwádìí tí mò ń ṣe tún jẹ mọ́ bá a ṣe lè tọ́jú àwọn àrùn yìí.

Ipa wo wá ni ìmọ̀ tẹ́ ẹ ní nípa àwọn sẹ́ẹ̀lì yìí ti ní lórí yín?

Ká sòótọ́, àwọn àwárí tí mo ṣe yìí ti mú kí ń ṣe kàyéfì gan an. Bí àwọn sẹ́ẹ̀lì yìí ṣe wà létòlétò tí wọ́n sì ń pààrọ̀ ara wọn bó ṣe yẹ fi hàn pé ẹni tó ṣe wọ́n síbẹ̀ fẹ́ kí ara wa jí pépé. Ṣùgbọ́n ìbéèrè tó ṣì ń jà gùdù lọ́kàn mi ni pé: “Kí ló fà á tá a fi ń jìyà tá a sì ń kú?” Mo wá ìdáhùn ẹ̀ tì.

Àmọ́ ẹ gbà pé ẹnì kan ló ṣètò báwọn sẹ́ẹ̀lì yẹn ṣe ń pààrọ̀ ara wọn, àbí?

Bẹ́ẹ̀ ni. Ọ̀nà táwọn sẹ́ẹ̀lì yẹn gbà ń pààrọ̀ ara wọn díjú gan-an, ó sì kàmàmà, iṣẹ́ àrà yìí fi hàn pé ẹnì kan tí ọgbọ́n rẹ̀ fakíki ló pilẹ̀ rẹ̀ bẹ́ẹ̀. Mo gbà pé iṣẹ́ Ọlọ́run ni. Irinṣẹ́ kan tó lágbára tí wọ́n fi ń wo nǹkan tíntìntín ni mo fi ṣàyẹ̀wò àwọn ètò kan nínú ara tó ń mú kí àwọn sẹ́ẹ̀lì yìí lè máa pààrọ̀ ara wọn. Àwọn ètò yìí lágbára débi pé, láàárín ìṣẹ́jú àáyá mélòó kan, wọ́n lè pa àwọn sẹ́ẹ̀lì tó bá yẹ kó kú. Pabanbarì rẹ̀ wá ni pé àwọn sẹ́ẹ̀lì yẹn fúnra wọn máa ń lọ́wọ́ nínú ikú ara wọn tí àkókò bá tó. Àgbàyanu ńlá gbáà ni ètò báwọn sẹ́ẹ̀lì ṣe ń pààrọ̀ ara wọn yìí.

Mo gbà pé ó ṣeé ṣe láti wà láàyè títí láé torí pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo sẹ́ẹ̀lì inú ara wa ló máa ń pààrọ̀ ara wọn déédéé

Báwo lẹ ṣe wá rí ìdáhùn sí ìbéèrè tẹ́ ẹ ní nípa Ọlọ́run àti ìdí táwa èèyàn fi ń jìyà?

Mo rántí pé lọ́dún 1991, àwọn ọmọkùnrin méjì kan tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà wàásù dé ilé mi, mo wá bi wọ́n pé kí nìdí tá a fi ń kú? Wọ́n fi Bíbélì dá mi lóhùn pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) Wọ́n tún fi yé mi pé ọkùnrin tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá ì bá ṣì wà láàyè, ká ní kò ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ohun tí wọ́n sọ yé mi, torí ìwádìí tí mo ṣe bá ọ̀rọ̀ yẹn mu. Ó túbọ̀ wá yé mi pé kì í ṣe pé Ọlọ́run fẹ́ ká máa kú. Mo gbà pé ó ṣeé ṣe láti wà láàyè títí láé torí pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo sẹ́ẹ̀lì inú ara wa ló máa ń pààrọ̀ ara wọn déédéé.

Kí ló jẹ́ kó dá yín lójú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì?

Ohun tí mo kọ́ nínú Bíbélì ni. Pàápàá ohun tó wà nínú ìwé Sáàmù 139:16 tó sọ pé: “Àní ojú rẹ rí ọlẹ̀ mi, inú ìwé rẹ sì ni gbogbo àwọn ẹ̀yà rẹ̀ wà ní àkọsílẹ̀.” Ẹ̀kọ́ sáyẹ́ǹsì tí mo kọ́ ti jẹ́ kí n mọ̀ pé àwọn ohun tín-tìn-tín kan wà tó para pọ̀ di sẹ́ẹ̀lì inú ara wa lóòótọ́. Ó yà mí lẹ́nu bí ẹni tó kọ Sáàmù yẹn ṣe mọ àwọn nǹkan yìí. Bí mo ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó túbọ̀ wá dá mi lójú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni lóòótọ́.

Báwo lẹ ṣe wá lóye àwọn ẹ̀kọ́ tí Bíbélì fi kọ́ni?

Ọkùnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan máa ń wá kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tó yá, mo wá mọ ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà. Mo tún kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nínú Bíbélì pé òun máa “gbé ikú mì títí láé.” (Aísáyà 25:8) Ó dá mi lójú pé kò lè ṣòro fún Ẹlẹ́dàá wa láti sọ àgọ́ ara wa tó dá lọ́nà ìyanu di pípé ká lè máa wà láàyè títí lọ gbére.

Ǹjẹ́ ẹ̀yin náà ti lo ìmọ̀ Bíbélì tẹ́ ẹ ní yìí láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́?

Àtìgbà tí mo ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́dún 1995 lèmi náà ti ń sọ ohun tí mo kọ́ nínú Bíbélì fáwọn ẹlòmíì. Bí àpẹẹrẹ, ìdààmú ọkàn bá obìnrin kan tá a jọ ń ṣiṣẹ́ nígbà tí àbúrò rẹ̀ pokùn so. Wọ́n sọ fún un ní ṣọ́ọ̀ṣì pé Ọlọ́run kì í dárí ji ẹni tó bá pokùn so. Àmọ́ mo ka ohun tí Bíbélì sọ nípa ìrètí àjíǹde fún un. (Jòhánù 5:28, 29) Ṣe lara tù ú pẹ̀sẹ̀, inú rẹ̀ sì dùn láti mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá wa bìkítà nípa wa. Bí mo ṣe ń jẹ́ káwọn tó wà nírú ipò bẹ́ẹ̀ mọ ohun tí Bíbélì sọ fi mí lọ́kàn balẹ̀, ó sì tẹ́ mi lọ́rùn fíìfíì ju ẹ̀kọ́ nípa ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì lọ!