Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ o Mọ̀?

Ǹjẹ́ o Mọ̀?

Ǹjẹ́ o Mọ̀?

(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí, a sì kọ àwọn ìdáhùn náà ní kíkún sí ojú ìwé 16. Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìtẹ̀jáde “Insight on the Scriptures,” tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.)

1. Nínú aginjù, ọ̀rọ̀ wo ló tọ́ka sí ibùgbé Mósè àti sí àgọ́ ìjọsìn mímọ́? (Ẹ́kísódù 33:7; 39:40)

2. Ibo ni tẹ́ńpìlì Átẹ́mísì, èyí tí wọ́n kà sí ọ̀kan lára àwọn ìyanu méje ayé ìgbàanì wà? (Ìṣe 19:26, 27)

3. Kí ni orúkọ oyè òṣìṣẹ́ Bábílónì tó kéré sí ti baálẹ̀? (Dáníẹ́lì 2:48)

4. Lábẹ́ Òfin Mósè, ìpín wo ni wọ́n gbọ́dọ̀ fún àwọn ọmọ Léfì, kì sí nìdí rẹ̀? (Diutarónómì 26:12)

5. Aṣẹ́wó tẹ́lẹ̀ rí wo ló wá di ìyá ńlá fún Jésù? (Mátíù 1:5)

6. Ìlú wo ni Pọ́ọ̀lù ti dojúlùmọ̀ pẹ̀lú Ákúílà àti Pírísílà? (Ìṣe 18:1-3)

7. Irú “ọ̀ṣọ́” wo ni Pétérù dámọ̀ràn fún àwọn Kristẹni obìnrin? (1 Pétérù 3:3, 4)

8. Iṣẹ́ wo la gbọ́dọ̀ ṣe kí òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí tó dé? (Mátíù 24:14)

9. Orúkọ náà Késárì, di orúkọ oyè ọlọ́ba tó ṣe déédéé pẹ̀lú kí ni?

10. Apá pàtàkì wo lára ìhámọ́ra tẹ̀mí Kristẹni ló máa jẹ́ kó lè “paná gbogbo ohun ọṣẹ́ oníná ti ẹni burúkú náà”? (Éfésù 6:16)

11. Kí ni wọ́n ń lò láti gbé ọkọ̀ òkun rìn láyé àtijọ́? (Ìsíkíẹ́lì 27:6, 7, 29)

12. Kì ní kò sí lára oúnjẹ tí ènìyàn ń jẹ ṣáájú Ìkún Omi? (Jẹ́nẹ́sísì 9:3, 4)

13. Kí ni ohun tó ń ta omi dànù tí wọ́n lò fún ọkọ̀ áàkì? (Jẹ́nẹ́sísì 6:14)

14. Kí ni Jésù pè ní “ìtannijẹ,” èyí tó lè fún ọ̀rọ̀ Ìjọba náà pa tó sì lè sọ ènìyàn di “aláìléso”? (Mátíù 13:22)

15. Kí ni Pétérù sọ pé yóò jẹ́ àbájáde wíwẹ ọkàn ẹni mọ́ gaara nípa ‘ìgbọràn sí òtítọ́’? (1 Pétérù 1:22)

16. Nígbà tí “ẹ̀mí mímọ́ ka sísọ ọ̀rọ̀ náà ní àgbègbè Éṣíà léèwọ̀” lákòókò ìrìn-àjò míṣọ́nnárì Pọ́ọ̀lù ẹlẹ́ẹ̀kejì, ibo ló lọ? (Ìṣe 16:6)

17. Ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀ tó túmọ̀ sí “ọmọkùnrin” wo ló sábà máa ń fara hàn nínú orúkọ àwọn Hébérù? (Jẹ́nẹ́sísì 35:18)

18. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Ùsáyà Ọba lẹ́yìn tó ti fi ìwà ọ̀yájú sun tùràrí nínú tẹ́ńpìlì? (2 Kíróníkà 26:19-21)

19. Kí ni wọ́n sábà máa ń fi ṣe ẹ̀wù tí wòlíì kan máa ń wọ̀? (2 Àwọn Ọba 1:8; Mátíù 3:4)

20. Késárì wo ló ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun ló ní kí wọ́n pa Pọ́ọ̀lù?

21. Ta lẹni náà táa sọ ní pàtó pé ó kọ́kọ́ lo orúkọ Ọlọ́run? (Jẹ́nẹ́sísì 4:1)

Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè

1 .“Àgọ́ ìpàdé”

2. Éfésù ni

3. Aṣíwájú

4. Ìdá mẹ́wàá. Nítorí pé wọn kò ní lára ogún ilẹ̀ náà, ṣùgbọ́n iṣẹ́ ìsìn ibi mímọ́ ni wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ fún

5. Ráhábù

6. Kọ́ríńtì

7. “Ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ìwà tútù”

8. A gbọ́dọ̀ wàásù “ìhìn rere ìjọba” náà ní gbogbo ayé

9. Olú Ọba

10. “Apata ńlá ti ìgbàgbọ́”

11. Ìgbòkun àti àjẹ̀

12. Ẹran

13. Ọ̀dà bítúmẹ́nì

14. ‘Agbára ọrọ̀’

15. “Ìfẹ́ni ará tí kò ní àgàbàgebè”

16. ‘Ó gba Fíríjíà àti ilẹ̀ Gálátíà kọjá’

17. Bẹni

18. Jèhófà fi àrùn ẹ̀tẹ̀ kọlù ú

19. Irun ràkúnmí tàbí ti ewúrẹ́

20. Nero

21. Éfà