Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Nígbà Táa Bá Ṣe Ohun Tó Pọ̀ Jù

Ohun Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Nígbà Táa Bá Ṣe Ohun Tó Pọ̀ Jù

Ohun Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Nígbà Táa Bá Ṣe Ohun Tó Pọ̀ Jù

ÀWỌN TÓ Ń GBÉ ÌWỌ̀ OÒRÙN AYÉ MÁA Ń FẸ́ LÁTI ṢE ÀWỌN NǸKAN NÍ KÓYÁKÓYÁ PẸ̀LÚ ÌRỌ̀RÙN.

Ẹ̀RỌ tó ń fọ abọ́ ti dín àkókò tí wọ́n ń lò nílé ìgbọ́únjẹ kù. Bákan náà pẹ̀lú ni ẹ̀rọ ìfọṣọ ń dín àkókò kù nídìí aṣọ fífọ̀. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn èèyàn míì ni kò tilẹ̀ ní láti fi ilé wọn sílẹ̀ mọ́ kí wọ́n tó rajà àti kí wọ́n tó gbowó ní báńkì—ohun tí wọ́n á kàn ṣe ni pé, wọ́n á ṣí kọ̀ǹpútà wọn, wọ́n á sì lo Íńtánẹ́ẹ̀tì.

Bó ṣe rí gan-an nìyẹn, ó kéré tán, dé àyè kan, ayé ti wá kún fún oríṣiríṣi ìhùmọ̀, èyí tó ń dín àkókò kù àti èyí tó ń dín iṣẹ́ kù. Fún ìdí yẹn, o lè ronú pé àwọn èèyàn á wá ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkókò láti lò pẹ̀lú ìdílé wọn, kí wọ́n sì sinmi. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ sábà máa ń sọ pé ṣe ló túbọ̀ ń rẹ àwọn sí i, tí ara sì ń ni àwọn ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Àwọn ohun tó ń fà á pọ̀ o, wọ́n sì díjú.

Wàhálà ọ̀ràn owó ló ṣì ga jù nínú àwọn ìdí tó ń fà á. Nígbà tí Ojúkò Tó Ń Ṣèwádìí Tó Sì Ń Dáni Lẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ọ̀ràn Ilé Iṣẹ́ ní Ọsirélíà ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ iye wákàtí táwọn èèyàn ń lò lẹ́nu iṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè yẹn, ó rí i pé “ọ̀pọ̀ jaburata ló ń ṣiṣẹ́ fún ohun tó lé ní wákàtí mọ́kàndínláàádọ́ta lọ́sẹ̀” àti pé “àwọn wákàtí iṣẹ́ tó lé sí i yìí ṣeé ṣe kó ní ipa tí kò dára rárá lórí ìdílé àti ìgbésí ayé àwọn ará ìlú.” Ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ ló yàn láti máa gbé ní ìgbèríko, níbi tó parọ́rọ́ díẹ̀ lẹ́yìn ìlú. Ìyẹn sì lè túmọ̀ sí lílo ọ̀pọ̀ wákàtí lọ́sẹ̀—kódà lójúmọ́ pàápàá—ní dídu ọkọ̀ ojú irin àti bọ́ọ̀sì wọ̀, tàbí wíwọkọ̀ lọ wọkọ̀ bọ̀ lójú ọ̀nà tó kún fọ́fọ́. Àbárèbábọ̀ rẹ̀ ni pé, ńṣe nìyẹn túbọ̀ ń mú kí ọjọ́ iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan gùn sí i, kí ó sì tún dá kún wàhálà ọjọ́ náà.

Ǹjẹ́ Gbèsè Oorun Ń Yọ Ọ́ Lẹ́nu?

Ìṣòro oorun sísùn ti wá wọ́pọ̀ láwọn ọdún àìpẹ́ yìí débi pé, wọ́n ti dá àwọn ilé ìtọ́jú àìsàn tó ní í ṣe pẹ̀lú oorun sísùn sílẹ̀ níbi púpọ̀ lágbàáyé. Àwọn tó ń ṣèwádìí ti rí i pé, nígbà táwọn èèyàn kò bá sun oorun tó bó ṣe yẹ déédéé, ńṣe ni gbèsè oorun máa di gọbọi sí wọn lọ́rùn. Ara wọ́n máa ń fẹ́ láti san gbèsè yìí, ó sì máa ń fẹ́ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ nípa jíjẹ́ kó rẹ̀ wọ́n. Àmọ́ o, nítorí ìgbésí ayé òde oní, èyí tó ń gba oorun lójú ẹni, ó ṣì máa ń rẹ ọ̀pọ̀ èèyàn tẹnutẹnu.

Ní orílẹ̀-èdè Ìwọ Oòrùn kan, ìpín ogún nínú ọgọ́rùn-ún ni àsìkò oorun fi dín sí ti ọgọ́rùn-ún ọdún tó kọjá, látorí ìpíndọ́gba oorun wákàtí mẹ́sàn-án sí wákàtí méje lálaalẹ́. Ẹ̀rí jaburata làwọn olùṣèwádìí ti kó jọ tó fi hàn pé gbèsè oorun máa ń fa ìṣòro ẹ̀kọ́ kíkọ́ àti rírántí nǹkan, àkóbá nínú ọpọlọ, àti ètò ara fún ìgbóguntàrùn tí kò fi bẹ́ẹ̀ lágbára. Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wa mọ̀ fúnra wa pé, ó rọrùn púpọ̀ fẹ́ni tó ti rẹ̀ láti ṣe àwọn àṣìṣe. Ohun tó bani nínú jẹ́ ni pé, àwọn àṣìṣe yìí lè jẹ́ èyí tó lágbára gan-an kó sì tún pani lára.

Àbájáde Búburú Tí Àárẹ̀ Ń Fà

Àárẹ̀ tó máa ń tìdí wákàtí iṣẹ́ tó gùn sí i àti dídín òṣìṣẹ́ kù jáde ni wọ́n sọ pé ó pẹ̀lú ohun tó fa díẹ̀ lára àwọn àgbákò tó burú jù lọ tó ṣẹlẹ̀ ní apá ìparí ọ̀rúndún ogún. Lára àwọn wọ̀nyí ni ìjábá tó ṣẹlẹ̀ ní Chernobyl, lórílẹ̀-èdè Ukraine; bíbú tí ọkọ̀ gbalasa òfuurufú Challenger bú gbàù; àti epo tó tú dà sójú okun nígbà tí ọkọ̀ ojú omi agbépo Exxon Valdez lọ sẹrí mọ́ òkìtì iyanrìn kan ní Prince William Sound, lórílẹ̀-èdè Alaska.

Àyẹ̀wò pàtàkì kan ni wọ́n ń ṣe lọ́wọ́ nígbà tí ìbúgbàù tó wáyé ní Chernobyl ṣẹlẹ̀ ní iléeṣẹ́ ẹ̀rọ agbára átọ́míìkì ọ̀hún. Martin Moore-Ede, nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní The 24-Hour Society, sọ pé, “àwùjọ àwọn onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tó ti rẹ̀ tẹnutẹnu ló ń darí [àyẹ̀wò náà], àwọn tó jẹ́ pé wọ́n ti wà ní iléeṣẹ́ náà fún wákàtí mẹ́tàlá ó kéré tán, tàbí kó jù bẹ́ẹ̀ lọ nítorí ìdádúró tó ṣẹlẹ̀ fún wákàtí mẹ́wàá kí wọ́n tó ṣẹ̀ṣẹ̀ rí àṣẹ gbà pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.” Ohun tó wù kó jẹ́, gẹ́gẹ́ bí ìwádìí àìpẹ́ yìí kan ṣe sọ, àbájáde ọlọ́jọ́ pípẹ́ kan nípa ìtànṣán tó tú jáde náà ni, bí àwọn ọmọdé ní ilẹ̀ Ukraine tó ń ní àrùn jẹjẹrẹ gògóńgò ṣe fi ìlọ́po mẹ́wàá lé sí i láti ọdún 1986 wá.

Lẹ́yìn tí ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe ti ìjọba ti ṣèwádìí kínníkínní nípa ohun tó fa ìbúgbàù ọkọ̀ gbalasa òfuurufú Challenger, ìròyìn tí wọ́n mú wá sọ pé, ọ̀kan lára àwùjọ tó ń ṣíṣẹ́ náà ti fi ọ̀rìn lé nírínwó [480] ìgbà ṣe àlékún iṣẹ́ fún ogún wákàtí, tí àwùjọ mìíràn sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún méjì, ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti méjìlá [2,512] ìgbà. Ìròyìn ọ̀hún fi kún un pé, àárẹ̀ tó ti mú àwọn òṣìṣẹ́ náà, èyí tó wáyé nítorí “ọ̀pọ̀ ọjọ́ tí wọ́n ti fi ṣiṣẹ́ kọjá àkókò láìsun oorun tí ó tó,” tún jẹ́ kókó pàtàkì nínú ohun tó mú kí wọ́n pa àṣẹ tó dá wàhálà sílẹ̀ náà pé kí ọkọ̀ ọ̀hún gbéra láìtíì tó àkókò. Ìròyìn náà wá sọ pé “táṣejù bá ti wọ iye àkókò téèyàn fi ń ṣiṣẹ́, ńṣe ni bó ṣe yẹ káwọn òṣìṣẹ́ ṣe dáadáa sí máa ń dín kù, tí ṣíṣeé ṣe pé kéèyàn ṣàṣìṣe yóò sì máa ga sí i.”

Níbàámu pẹ̀lú nǹkan tẹ́gbẹ́ òṣìṣẹ́ sọ, àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ ojú omi Exxon Valdez náà ní láti ṣiṣẹ́ fún àkókò tó túbọ̀ pọ̀ sí i kí wọ́n sì tún ṣe àfikún iṣẹ́, nítorí àwọn òṣìṣẹ́ tó ti dín kù, èyí tí wọ́n sọ pé nítorí kí ìnáwó lè dín kù ni. Ìròyìn nípa ìjábá náà ṣàlàyé pé, láti àárọ̀ kùtù ọjọ́ yẹn lọ̀gá tó ń bojú tó ọkọ̀ ojú omi náà ti ń ṣiṣẹ́ láìsùn títí wá fi di ìgbà tí ọkọ̀ náà rì ní déédéé agogo méjìlá kọjá lóru. Epo tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù méjìlélógójì lítà—tó jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí irú epò tó pọ̀ bẹ́ẹ̀ yẹn máa tú dànù nínú ìtàn Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà—fa jàǹbá bíbanilẹ́rù láwọn etíkun àti fáwọn ẹran ìgbẹ́, ó sì gba ohun tó ju bílíọ̀nù méjì dọ́là lọ láti fọ̀ ọ́ kúrò.

Àwọn Ọṣẹ́ Tí Àárẹ̀ Ń Yọ́ Kẹ́lẹ́ Ṣe

Nígbà tí wọ́n fojú bu ọṣẹ́ tí àárẹ̀ ń ṣe, ó kéré tán, ó ń ná gbogbo ayé lápapọ̀ ní irínwó dín mẹ́tàlélógún [377] bílíọ̀nù dọ́là lọ́dọọdún! Àmọ́ kò sí iye owó tó lè tó àdánù tó ń ṣe fún ẹ̀mí èèyàn àti ìlera, bó ṣe jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń nípa lórí wọn. Ẹ jẹ́ ká mú jàǹbá mọ́tò gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ kan. Níbàámu pẹ̀lú ohun tí ilé ìtọ́jú àwọn tó níṣòro oorun ní Sydney, lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà sọ, nǹkan bí ìpín ogún sí ọgbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún jàǹbá mọ́tò tó ń ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè yẹn ló jẹ́ pé nítorí pé àwọn awakọ̀ gbàgbé sùn lọ níbi tí wọ́n ti ń wakọ̀ ló fà á. Wọ́n tún fojú bù ú pé, ó kéré tán, títòògbé ń dá kún ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún [100,000] jàǹbá mọ́tò lọ́dọọdún ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà.

Síbẹ̀, àwọn àbájáde tó ń wá látinú káàárẹ̀ múni lè má mọ síbẹ̀ yẹn. Ẹnì kan tó ní jàǹbá mọ́tò tí wọ́n sì sáré gbé lọ sílé ìwòsàn fún iṣẹ́ abẹ á máa retí pé kí dókítà òun wà lójúfò, kórí rẹ̀ sì jí pépé. Àmọ́, nítorí pé ọwọ́ dókítà dí tó sì ti ń ṣiṣẹ́ fún àkókò gígùn, ó lè má wà lójúfò rárá, kórí rẹ̀ má sì jí pépé! Ìròyìn tó wá látọwọ́ Àjọ Tó Wà fún Ìlera àti Wíwà Lálàáfíà ní Ọsirélíà ṣí i payá pé, nǹkan bí ìpín mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún dókítà ló ń fi èyí tó ju wákàtí márùnlélọ́gọ́ta ṣiṣẹ́ lọ́sẹ̀, ìpín mẹ́tàdínlógún nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo àwọn amọṣẹ́dunjú ló tiẹ̀ tún ń lò ju àkókò yẹn lọ, tó sì jẹ́ pé ìpín márùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn “ọ̀jẹ̀ wẹ́wẹ́ dókítà” ló ń fi èyí tó ju ọgọ́rin wákàtí ṣiṣẹ́ lọ́sẹ̀!

Martin Moore-Ede sọ pé: “Àwọn ẹ̀rọ máa ń ní àlàyé nípa báa ṣe gbọ́dọ̀ lò wọ́n, wọ́n láwọn ìkìlọ̀ táa lẹ̀ mọ́ wọn lára, àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí ìlò wọn. Àwọn èèyàn kò mú irú ìdáàbòbò bẹ́ẹ̀ wá sáyé. . . . Ohun tó wá ya èèyàn lẹ́nu ni pé, ohun táa mọ̀ nípa ọ̀nà tí ara èèyàn ń gbà ṣiṣẹ́ kéré jọjọ sí báa ṣe mọ tinú-tòde àwọn ẹ̀rọ tí ènìyàn ń lò.”

Ara wa kò ní àwọn iná pupa tó ń ṣe kìlọ̀kìlọ̀ àti ìró ìdágìrì tó máa sọ fún wa pé ó tó, ká dáwọ́ dúró tàbí pé ká tẹ̀ ẹ́ jẹ́jẹ́. Síbẹ̀síbẹ̀, ó ní àwọn àmì tó fi ń ṣèkìlọ̀ fún wa. Àwọn èyí ní nínú, bíi kó rẹ èèyàn tẹnutẹnu, kí ìṣesí èèyàn yàtọ̀, ìsoríkọ́, kí kòkòrò àrùn tètè máa ráyè lára èèyàn. Tóo bá ń rí àwọn àmì wọ̀nyí—tí kì í sì í ṣe pé o láìsàn kan lára tẹ́lẹ̀—ó lè jẹ́ pé àkókò tó fún ẹ láti ṣàtúnyẹ̀wò bóo ṣe ń gbé ìgbésí ayé ẹ.

Àkóbá Tí Ọwọ́ Tó Dí Jù Máa Ń Ṣe fún Àjọṣe Ẹ̀dá

Ìgbésí ayé onímásùnmáwo, téèyàn kì í sùn tó yìí tún ní àkóbá tó ń ṣe fún àjọṣe ẹ̀dá ènìyàn. Gbé ọ̀ràn John àti Maria a, tọkọtaya kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó yẹ̀ wò. Àwọn náà fẹ́ ní ohun tí èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn tọkọtaya tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó máa ń fẹ́ láti ní—ìyẹn ilé tó tura àti owó rẹpẹtẹ. Bẹ́ẹ̀ làwọn méjèèjì bá tara bọ iṣẹ́ ṣíṣe lójú méjèèjì. Àmọ́ nítorí àkókò iṣẹ́ tí kì í dọ́gba, wọn ò ráyè tó fúnra wọn. Kò pẹ́ kò jìnnà, àjọṣe wọn ò fi bẹ́ẹ̀ dán mọ́rán mọ́. Àmọ́ wọ́n dágunlá sí àwọn àmì tí wọ́n ń rí, wọ́n sì ń báṣẹ́ tó ń gbà wọ́n lákòókò náà lọ ní pẹrẹu, títí tí ìgbéyàwó wọn ẹnu àìpẹ́ fi túká.

Ìwé tí wọ́n pè ní The 24-Hour Society sọ pé: “Ìwádìí fi hàn pé ìkọ̀sílẹ̀ tó ń ṣẹlẹ̀ nínú àwọn ìdílé tó ń ṣe àwọn iṣẹ́ táwọn èèyàn máa ń lọ gbaṣẹ́ lọ́wọ́ ara wọn fi ìpín ọgọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún lé sí tàwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ojúmọ́.” Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ tọkọtaya ló jẹ́ pé yálà wọ́n ń ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ohun tí wọ́n máa ń kó mọ́ra nínú ìgbésí ayé pọ̀ débi pé, tó bá yá, wọ́n á fúnra wọn fòpin sí ìgbéyàwó wọn. Ní ti àwọn mìíràn, másùnmáwo àti àárẹ̀ lè mú wọn dẹni tó bẹ̀rẹ̀ sí joògùn yó, kí wọ́n máa mutí nímukúmu, kí wọ́n má sì lè jẹun dáadáa—àwọn nǹkan tó jẹ́ pe kì í ṣe pé wọ́n ń dá kún àárẹ̀ ara nìkan ni, àmọ́ tí wọ́n tún lè yọrí sí àwọn ìṣòro mìíràn, títí kan híhùwà àìdáa sọ́mọdé pàápàá.

Láti lè ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti kojú dídí tọ́wọ́ wọn máa ń dí fọ́fọ́, ńṣe làwọn ilé ìtọ́jú ọmọ wẹ́wẹ́ wá ń fojoojúmọ́ pọ̀ sí i, àwọn kan tiẹ̀ wà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ fún wákàtí mẹ́rìnlélógún lóòjọ́. Fún ọ̀pọ̀ ọmọdé, tẹlifíṣọ̀n tiẹ̀ kúkú ti wá di abánitọ́jú ọmọ. Kò sí àní-àní pé, bí àwọn ọmọ bá máa dàgbà di àgbàlagbà tó ní láárí, tí wọ́n á lè kápá ìrònú wọn dáadáa, ó n béèrè pé káwọn òbí wọn lo àkókò gidi pẹ̀lú wọn. Ìdí rèé tó fi bọ́gbọ́n mu pé káwọn òbí tó máa ń rẹ̀ débi tí wọn ò fi ní lè ráyè fún àwọn ọmọ wọn, nítorí àtigbé ayé ìgbádùn tí kò pọndandan, rò ó dáadáa kí wọ́n lè mọ̀ bí ohun tí wọ́n ń ṣe yìí bá máa pé wọn tó sì tún máa pé àwọn ọmọ wọn.

Ìṣòro tó ń dojú kọ àwùjọ onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tí ń yára gbèrú lóde òní kò yọ àwọn àgbàlagbà sílẹ̀. Bí àwọn nǹkan ṣe ń yí padà kíákíá àti báwọn nǹkan ìgbàlódé ṣe ń ya lu ọjà máa ń mú kọ́kàn ọ̀pọ̀ nínú wọn pòrúurùu, kí àyà máa fò wọ́n, àní kí wọ́n tiẹ̀ tún máa rò pé àwọn ò bóde mu mọ́. Nítorí náà, kí ni wọ́n lè máa retí lọ́jọ́ iwájú?

Ṣé pé kò sọ́gbọ́n kankan ti gbogbo wa lọ́mọdé àti lágbà lè rí dá sọ́ràn ayé tó ń fojoojúmọ́ sáré tete yìí ni? Àbí àwọn ohun kan wà táa lè ṣe láti kojú rẹ̀ ká sì tún mú ìgbésí ayé wa sunwọ̀n sí i? Ẹ jẹ́ ká máa yọ̀, àwọn ohun táa lè ṣe wà, gẹ́gẹ́ bí a óò ti rí i nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ padà.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Àárẹ̀ lè wà lára ohun tó túbọ̀ dá kún àjálù alágbára átọ́míìkì tó ṣẹlẹ̀ ní Chernobyl, bíbú tí ọkọ̀ gbalasa òfuurufú “Challenger” bú gbàù, àti jàǹbá ọkọ̀ ojú omi “Exxon Valdez” tó tú epo dà sójú òkun

[Àwọn Credit Line]

Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure U.S. Department of Energy’s International Nuclear Safety Program

Fọ́tò NASA

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Kòókòó jàn-ánjàn-án ìgbésí ayé lè kó ìgbéyàwó sínú ìṣòro

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí mutí nímukúmu láti fi kojú ìṣòro náà