Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ta Ló Ṣe Àwọn Òfin Tó Ń Darí Àwọn Nǹkan Tó Wà Lójú Ọ̀run?

Ta Ló Ṣe Àwọn Òfin Tó Ń Darí Àwọn Nǹkan Tó Wà Lójú Ọ̀run?

Ta Ló Ṣe Àwọn Òfin Tó Ń Darí Àwọn Nǹkan Tó Wà Lójú Ọ̀run?

“ǸJẸ́ ìwọ mọ àwọn òfin tó ń darí ọ̀run?” (Jóòbù 38:33, The New Jerusalem Bible) Ọlọ́run ló béèrè ìbéèrè yìí lọ́wọ́ Jóòbù ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ìdààmú ọkàn bá, láti jẹ́ kó mọ̀ pé ohun tí èèyàn mọ̀ kéré jọjọ tá a bá fi wé ọgbọ́n Ẹlẹ́dàá tí kò ní ààlà. Kí lèrò rẹ nípa ìyàtọ̀ tó wà láàárín ọgbọ́n Ọlọ́run àti tèèyàn?

Àwọn ẹ̀dá èèyàn ti kẹ́kọ̀ọ́ tó pọ̀ gan-an nípa àwọn òfin tó ń darí àwọn nǹkan tó wà lójú ọ̀run, àmọ́ ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ló máa gbà pé ohun púpọ̀ ló ṣì wà táwọn kò tíì mọ̀. Àwọn àwárí tuntun táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń ṣe ń mú kí wọ́n máa ṣe àtúnṣe léraléra sí èrò tí wọ́n ní tẹ́lẹ̀ nípa àwọn nǹkan tó wà lójú ọ̀run. Ṣé àwọn àwárí tuntun táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń ṣe ti sọ ìbéèrè tí Ọlọ́run bi Jóòbù di èyí tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ mọ́? Àbí, àwọn àwárí náà túbọ̀ jẹ́rìí sí i pé Jèhófà ni Ẹni tó ṣe àwọn òfin tó ń darí àwọn nǹkan tó wà lójú ọ̀run?

Bíbélì ní àwọn ọ̀rọ̀ tó jọni lójú gan-an tó máa dáhùn irú àwọn ìbéèrè yẹn. Òótọ́ ni pé Bíbélì kò pe ara rẹ̀ ní ìwé sáyẹ́ǹsì. Àmọ́, nígbà tó bá sọ̀rọ̀ nípa ojú ọ̀run tó kún fún àwọn ìràwọ̀, ohun tó sọ máa ń jẹ́ òótọ́, orí ohun tó sọ làwọn èèyàn sì sábà máa ń fàbọ̀ sí lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n bá fi ṣe ìwádìí.

Ohun Tí Àwọn Kan Sọ Nípa Ojú Ọ̀run

Láti mọ ohun táwọn kan sọ láyé ìgbàanì nípa ojú ọ̀run, ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìyẹn ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn tí wọ́n parí kíkọ Májẹ̀mú Láéláé, tó jẹ́ apá Bíbélì tí wọ́n fi èdè Hébérù kọ. Ní àkókò yẹn, ọ̀mọ̀ràn ará Gíríìsì náà, Aristotle ń kọ́ àwọn ọ̀mọ̀wé jàǹkànjàǹkàn tó wà nígbà ayé rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tó wà lójú ọ̀run. Lónìí, wọ́n ṣì ka Aristotle sí ọ̀kan pàtàkì lára onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó kópa tó pọ̀ gan-an nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì. (Wo  àpótí tó wà lójú ìwé 25.) Gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Encyclopædia Britannica, ṣe sọ, “Aristotle ni ojúlówó onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àkọ́kọ́ nínú ìtàn aráyé. . . . Gbogbo onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ló sì yẹ kó mọrírì iṣẹ́ tó ṣe.”

Ọ̀gbẹ́ni Aristotle fara balẹ̀ ṣe ohun kan tó rí bí ayé àti ojú ọ̀run. Ó ṣe àwọn àgbá tó lé ní àádọ́ta [50], ó kì wọ́n bọnú ara wọn, ó fi àwọn tó kéré sínú àwọn tó tóbi, àgbá ti ayé wa yìí ló fi sí àárín. Ó ṣe àwọn ìràwọ̀, ó fi wọ́n rọ̀ sí ara àgbá tó tóbi jù lọ. Ó fi àwọn pílánẹ́ẹ̀tì tó rí bíi bọ́ọ̀lù rọ̀ sára àwọn àgbá tí kò jìnnà sí àgbá tí ayé wa yìí wà láàárín rẹ̀. Ó sọ pé àwọn àgbá tí ayé wa yìí wà láàárín wọn máa wà bẹ́ẹ̀ títí láé ni, wọn kò lè tóbi jù bẹ́ẹ̀ lọ. Lónìí, àwọn èrò Aristotle yìí lè dà bí àwàdà lójú wa, àmọ́ èrò yẹn ni àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kà sí òótọ́ gidi fún nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] ọdún.

Àmọ́, báwo ni ohun tí Aristotle fi kọ́ni ṣe rí tá a bá fi wé ohun tí Bíbélì fi kọni? Èwo ni ẹ̀kọ́ tó jẹ́ òótọ́? Ẹ jẹ́ ká gbé ìbéèrè mẹ́ta yẹ̀ wò nípa àwọn òfin tó ń darí àwọn nǹkan tó wà lójú ọ̀run. Àwọn ìdáhùn náà yóò jẹ́ ká lè ní ìgbàgbọ́ nínú Ẹni tó ni Bíbélì, Ẹni tó ṣe “àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ ọ̀run.”—Jóòbù 38:33.

1. Ṣé Àwọn Nǹkan Tó Wà Lójú Ọ̀run Kò Lè Tóbi Ju Bí Wọ́n Ṣe Wà Lọ?

Ọ̀gbẹ́ni Aristotle sọ pé àwọn nǹkan tó wà lójú ọ̀run kò lè tóbi ju bí wọ́n ṣe wà lọ. Àgbá tí ìràwọ̀ rọ̀ mọ́ kò lè sún kì tàbí kí ó tóbi ju bí ó ṣe wà lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn àgbá yòókù.

Ǹjẹ́ ohun tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ni Bíbélì sọ bíi ti Aristotle? Rárá o, Bíbélì kò ṣàlàyé ọ̀rọ̀ yìí ní tààràtà. Àmọ́ wo ọ̀rọ̀ alárinrin tó fi ṣàpèjúwe kókó náà, ó ní: “Ẹnì kan wà tí ń gbé orí òbìrìkìtì ilẹ̀ ayé, tí àwọn olùgbé inú rẹ̀ dà bí tata, Ẹni tí ó na ọ̀run gẹ́gẹ́ bí aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ oníhò wínníwínní, tí ó tẹ́ ẹ bí àgọ́ láti máa gbé inú rẹ̀.”—Aísáyà 40:22. *

Èwo ló tọ̀nà nínú méjèèjì lónìí, ṣé àwọn àgbá tí Aristotle ṣe ni àbí àpèjúwe tí Bíbélì ṣe nípa bí ayé ṣe rí? Lóde òní, kí ni ìwádìí nípa àwọn ohun tó wà lójú ọ̀run sọ nípa ọ̀ràn yìí? Ó jọ àwọn onímọ̀ nípa sánmà lójú gan-an ní ọgọ́rùn-ún ọdún lọ́nà ogún láti mọ̀ pé àwọn nǹkan tó wà lójú ọ̀run lè tóbi sí i. Kódà, ó jọ pé àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ máa ń já sọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Ṣàṣà àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, bí wọ́n bá tiẹ̀ wà, ló rò ó tẹ́lẹ̀ rí pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ń ṣẹlẹ̀. Lónìí, àwọn onímọ̀ nípa àwọn ohun tó wà lójú ọ̀run gbà gbọ́ pé, ṣe ni ọ̀run bẹ̀rẹ̀ láti ibi kékeré, tó sì ń fẹ̀ síwájú sí i láti ìgbà yẹn wá. Ní kúkúrú, ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ti sọ àwọn àgbá tí Aristotle ṣe yẹn di ohun tí kò wúlò mọ́.

Ọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ ńkọ́? Kò ṣòro láti fojú inú wo wòlíì Aísáyà bó ṣe ń wo ojú ọ̀run tó kún fún ìràwọ̀, tó sì rí i pé ojú ọ̀run tẹ́ rẹrẹ bí àgọ́ tí wọ́n nà jáde. * Ó tiẹ̀ ti lè ṣàkíyèsí bí ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Onírìísí Wàrà ṣe jọ “aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ oníhò wínníwínní.”

Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀rọ̀ Aísáyà mú ká fojú inú yàwòrán ohun tó sọ. Tá a bá fojú inú wo àgọ́ tí wọ́n ń lò ní àkókò tí wọ́n kọ Bíbélì, ó ṣeé ṣe ká rí ìdì aṣọ kékeré tí wọ́n nà jáde, kí wọ́n tó fi bo orí àwọn òpó, tí wọ́n fi ṣe àgọ́ téèyàn lè gbé inú rẹ̀. Bákan náà, a lè fojú inú wo oníṣòwò kan tó gbé ìdì aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ oníhò wínníwínní, tó nà án sílẹ̀ kí oníbàárà rẹ̀ lè yẹ̀ ẹ́ wò. Nínú ọ̀ràn méjèèjì yìí, ìdì kékeré kan ni wọ́n nà jáde àmọ́ ó fẹ̀ sí i nígbà tí wọ́n nà án.

Àmọ́ ṣá o, a kò sọ pé àkàwé tí Bíbélì fi àgọ́ àti aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ oníhò wínníwínní ṣe wá túmọ̀ sí pé àwọn ohun tó wà lójú ọ̀run máa ń tóbi sí i. Ṣùgbọ́n, ṣé kò jọni lójú pé àlàyé tí Bíbélì ṣe nípa ojú ọ̀run bá èyí tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní ṣe mú gan-an? Aísáyà gbé láyé ní ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún mẹ́ta ṣáájú ìgbà ayé Aristotle, ìyẹn sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún mélòó kan ṣáájú kí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tó fúnni ní ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ nípa ọ̀ràn yìí. Síbẹ̀, kò sídìí fún ṣíṣe àtúnṣe sí ohun tí wòlíì Hébérù onírẹ̀lẹ̀ yẹn ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀, àmọ́ wọ́n ṣàtúnṣe sí èrò Aristotle nípa àgbá tó hùmọ̀.

2. Kí Ló Gbé Àwọn Nǹkan Tó Wà Lójú Ọ̀run Dúró?

Nígbà tí Aristotle wo ayé òun ọ̀run, ó rí i pé wọ́n kún fún oríṣiríṣi nǹkan. Ó rí ayé àti oríṣi ohun mẹ́rin nínú rẹ̀. Àwọn nǹkan náà ni ilẹ̀, omi, afẹ́fẹ́ àti iná. Ní ti ọ̀run, ó fojú inú rí àwọn àgbá tó ní àwọn nǹkan tó lè mú kí wọ́n wà títí lọ láì bà jẹ́. Ó sọ pé àwọn ìràwọ̀ àtàwọn nǹkan míì tó wà lójú ọ̀run rọ̀ mọ́ àwọn àgbá tí a kò lè fojú rí. Ó pẹ́ táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti sọ pé èrò Aristotle jóòótọ́ nítorí ó jọ pe èrò rẹ̀ bọ́gbọ́n mu, ìyẹn ni pé, tí ohun kan bá dúró láì ṣubú, á jẹ́ pé ó dúró lórí ohun míì ni tàbí kó rọ̀ mọ́ ohun kan.

Kí ni Bíbélì sọ? Ọ̀rọ̀ tí ọkùnrin olóòótọ́ náà Jóòbù sọ nípa Jèhófà wà nínú Bíbélì, ó ní: “Ó so ilẹ̀ ayé rọ̀ sórí òfo.” (Jóòbù 26:7) Ó dájú pé ohun tí kò bọ́gbọ́n mu ni irú ọ̀rọ̀ yìí máa jẹ́ lójú Aristotle.

Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹtàdínlógún Sànmánì Kristẹni, ìyẹn ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] ọdún lẹ́yìn ìgbà ayé Jóòbù, àbá tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì nígbà yẹn ni pé ọ̀pọ̀ nǹkan wà lọ́rùn lóòótọ́, àmọ́ kì í ṣe àgbá, àwọn nǹkan olómi ló wà níbẹ̀. Àmọ́ nígbà tí ọgọ́rùn-ún ọdún kẹtàdínlógún yẹn fẹ́ parí ni onímọ̀ físíìsì náà, Ọ̀gbẹ́ni Isaac Newton gbé èrò kan tó yàtọ̀ pátápátá jáde. Ó sọ pé agbára òòfà ló so àwọn nǹkan tó wà lójú ọ̀run pọ̀. Ohun tí Ọ̀gbẹ́ni Newton sọ yìí túbọ̀ sún mọ́ ohun tí Bíbélì sọ pé ayé àtàwọn nǹkan tó wà lójú ọ̀run so rọ̀ sórí “òfo,” ìyẹn ni pé wọ́n kò dúró sórí nǹkan kan, bó sì ṣe rí lójú èèyàn nìyẹn.

Láyé ìgbà yẹn, àwọn èèyàn ṣàtakò gan-an sí àbá tí Ọ̀gbẹ́ni Newton gbé jáde nípa agbára òòfà. Ó ṣì ṣòro gan-an fún ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì láti gbà pé kò sí nǹkan kan tó gbé àwọn ìràwọ̀ àtàwọn nǹkan míì lójú ọ̀run dúró. Báwo ni ayé wa àtàwọn ìràwọ̀ ṣe lè rọ̀ sórí òfo? Ó dà bí nǹkan àràmàǹdà lójú àwọn èèyàn kan. Láti ìgbà ayé Aristotle ni ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti gbà gbọ́ pé gbalasa òfuurufú kò kàn lè ṣófo, nǹkan gbọ́dọ̀ wà níbẹ̀.

Òótọ́ ni pé Jóòbù kò mọ ohunkóhun nípa ohun tí a kò lè fojú rí tó so ayé rọ̀ tó fi ń yí oòrùn po. Àmọ́ kí ló mú kó sọ pé ayé wa yìí so rọ̀ “sórí òfo”?

Síwájú sí i, ohun tí Bíbélì sọ pé kò sí ohun tó gbé ayé dúró mú kéèyàn béèrè ìbéèrè míì pé: Kí ló mú kí ayé àtàwọn nǹkan tó wà lójú ọ̀run máa tọ òpó ọ̀nà wọn tí wọ́n kò yà gba ibòmíràn? Kíyè sí ọ̀rọ̀ tó wọni lọ́kàn tí Ọlọ́run fi béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ Jóòbù, ó ní: “Ìwọ ha lè so àwọn ìdè àgbájọ ìràwọ̀ Kímà pinpin, tàbí ìwọ ha lè tú àní àwọn okùn àgbájọ ìràwọ̀ Késílì?” (Jóòbù 38:31) Ní alaalẹ́, ní gbogbo ìgbésí ayé Jóòbù, ó máa ń rí àwọn ìràwọ̀ tí wọ́n jọra wọn, tí wọ́n máa ń yọ, tí wọ́n sì máa ń wọ̀. * Àmọ́, kí nìdí tí àwọn ìràwọ̀ yẹn fi jọ ara wọn, tí wọn kò sì yàtọ̀ bí ọdún ti ń gorí ọdún, àní fún ọ̀pọ̀ ọdún pàápàá? Ìdè wo ló so àwọn ìràwọ̀ yẹn àtàwọn nǹkan míì tó wà lójú ọ̀run sí àyè wọn? Ó dájú pé, ohun àgbàyanu ló máa jẹ́ lójú Jóòbù bó ti ń ronú nípa nǹkan wọ̀nyẹn.

Àwọn ìdè wọ̀nyẹn kò ní wúlò tó bá jẹ́ pé ara àwọn àgbá kan tí Aristotle sọ pé ó wà lọ́run ni àwọn ìràwọ̀ so rọ̀ sí. Ẹgbẹ̀rún ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà ni àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó wá mọ̀ sí i nípa “àwọn ìdè” tàbí “àwọn okùn” tí a kò lè fojú rí tó so àwọn ìràwọ̀ mọ́ra wọn bí wọ́n ti ń lọ lójú sánmà. Ọ̀gbẹ́ni Isaac Newton àti Albert Einstein di olókìkí nítorí ohun tí wọ́n ṣàwárí nípa ojú ọ̀run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jóòbù kò mọ ohunkóhun nípa ohun tí Ọlọ́run fi so àwọn nǹkan tó wà lójú ọ̀run pọ̀. Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí tó wà nínú ìwé Jóòbù ti jẹ́ òótọ́ fún àwọn ẹgbẹ̀rún ọdún, ó sì wúlò fíìfíì ju èrò ọ̀mọ̀wé Aristotle lọ. Ta ló lè ní irú ìjìnlẹ̀ òye bẹ́ẹ̀ bí kò ṣe Ẹni tó ṣe òfin tó ń darí àwọn nǹkan tó wà lójú ọ̀run?

3. Ṣé Wọ́n Máa Wà Títí Láé Ni àbí Wọ́n Máa Ń Bà Jẹ́?

Ọ̀gbẹ́ni Aristotle gbà gbọ́ pé ìyàtọ̀ ńláǹlà ló wà láàárín ọ̀run àti ayé. Ó sọ pé ayé lè yí pa dà, kí ó bà jẹ́, kí ó sì yọ́, àmọ́ ohun tí wọ́n fi ṣe ìràwọ̀ kì í yí pa dà, ó sì máa ń wà títí ayérayé ni. Aristotle sọ pé àwọn àgbá àtàwọn nǹkan tó rọ̀ mọ́ àwọn àgbá náà kì í yí pa dà, wọn kì í gbó, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kì í kú.

Ṣé ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nìyẹn? Sáàmù 102:25-27 kà pé: “Láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn ni ìwọ ti fi àwọn ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé lélẹ̀, ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Àwọn tìkára wọn yóò ṣègbé, ṣùgbọ́n ìwọ tìkára rẹ yóò máa wà nìṣó; àti gẹ́gẹ́ bí ẹ̀wù, gbogbo wọn yóò gbó. Gẹ́gẹ́ bí aṣọ, ìwọ yóò pààrọ̀ wọn, wọn yóò sì lo ìgbà wọn parí. Ṣùgbọ́n bákan náà ni ìwọ wà, àwọn ọdún rẹ kì yóò sì parí.”

Kíyè sí pé onísáàmù tó kọ̀wé yìí ní igba [200] ọdún ṣáájú ìgbà ayé Aristotle, kò fi ayé wé ìràwọ̀, bíi pé ayé lè bà jẹ́, tí àwọn ìràwọ̀ á sì wà títí ayérayé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń fi ayé àti ọ̀run wé Ọlọ́run, tó jẹ́ Ẹni Ẹ̀mí alágbára tó darí dídá wọn. * Ohun tí Sáàmù yìí ń sọ ni pé àwọn ìràwọ̀ lè bà jẹ́ bí ohun tó wà nínú ayé ṣe lè bà jẹ́. Kí sì ni àwárí tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní ti ṣe?

Ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì nípa àwọn nǹkan tó wà nínú ilẹ̀ ṣètìlẹ́yìn fún ohun tí Bíbélì àti Aristotle sọ pé ayé lè bà jẹ́. Ẹ̀rí fi hàn pé, ọ̀gbàrá máa ń jẹ àwọn àpáta, àmọ́ àwọn òkè tó ń yọ eérú àtàwọn nǹkan míì tó wà nínú ilẹ̀ máa ń ṣàtúnṣe sí àwọn àpáta tí ọ̀gbàrá jẹ náà.

Àwọn ìràwọ̀ ńkọ́? Ṣé wọ́n máa ń bà jẹ́, bí Bíbélì ṣe sọ àbí wọ́n máa ń wà títí ayérayé bí Aristotle ṣe kọ́ni? Láti ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìndínlógún tí àwọn onímọ̀ sánmà ará Yúróòpù kọ́kọ́ rí àwọn ìràwọ̀ tó bú gbàù ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì nípa èrò Aristotle, pé àwọn ìràwọ̀ máa ń wà títí ayérayé. Láti ìgbà yẹn làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti máa ń kíyè sí i pé àwọn ìràwọ̀ lè kú nígbà tí wọ́n bá bú gbàù tàbí kí wọ́n máa jó díẹ̀díẹ̀ títí wọ́n á fi kú tàbí kí wọ́n kọ lu ara wọn. Àmọ́, àwọn onímọ̀ sánmà tún ti ṣàkíyèsí pé àwọn ìràwọ̀ tuntun máa ń jáde látinú ẹ̀fúùfù nígbà tí àwọn ìràwọ̀ tó ti gbó bá bú gbàù. Nítorí náà, àpèjúwe tí Bíbélì ṣe pé àwọn ìràwọ̀ ń gbó bí aṣọ tí à sì ń pààrọ̀ wọn tọ̀nà gan-an. * Ẹ wo bó ṣe jọni lójú tó pé onísáàmù ayé àtijọ́ yìí kọ ọ̀rọ̀ tó bá àwárí tí wọ́n ṣe lóde òní mu gan-an!

Síbẹ̀, o lè máa ṣe kàyéfì pé: ‘Ṣé ohun tí Bíbélì ń kọ́ni ni pé lọ́jọ́ kan ayé tàbí àwọn ìràwọ̀ máa pa rẹ́ tàbí kí a pààrọ̀ wọn?’ Rárá o, Bíbélì ṣèlérí pé wọ́n yóò wà títí láé. (Sáàmù 104:5; 119:90) Àmọ́, kì í ṣe nítorí pé àwọn nǹkan yìí lè fúnra wọn wà títí ayérayé, kàkà bẹ́ẹ̀ Ọlọ́run tó dá wọn ló ṣèlérí pé òun á mú kí wọ́n wà títí láé. (Sáàmù 148:4-6) Kò sọ bí òun ṣe máa ṣe é, àmọ́ ṣé kò bọ́gbọ́n mu pé Ẹni tó dá ayé àti ọ̀run á ní agbára láti mú kí wọ́n wà títí láé? Ó dájú pé bí ọ̀gá kọ́lékọ́lé kan ṣe máa bójú tó ilé tó kọ́ fún ara rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀, bákan náà ni Jèhófà ṣe máa bójú tó àwọn nǹkan yìí.

Ta Ló Yẹ Kó Gba Ògo àti Ọlá Nǹkan Wọ̀nyí?

A máa mọ ìdáhùn sí ìbéèrè yìí tá a bá ronú lórí díẹ̀ lára àwọn òfin tó ń darí àwọn nǹkan tó wà lójú ọ̀run. Tá a bá ronú nípa ẹni tó mú kí àìmọye ìràwọ̀ wà lójú ọ̀run tó lọ salalu, tó fi ìdè agbára òòfà so wọ́n pọ̀ sí ibi tí wọ́n wà, tó sì mú kí wọ́n máa lọ yípoyípo, ǹjẹ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí kò jẹ́ àgbàyanu lójú wa?

Bóyá ohun tó mú kí àwọn nǹkan yìí jẹ́ àgbàyanu lójú wa ni Aísáyà 40:26 sọ lọ́nà tó ṣe kedere pé: “Ẹ gbé ojú yín sókè réré, kí ẹ sì wò. Ta ni ó dá nǹkan wọ̀nyí? Ẹni tí ń mú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn jáde wá ni, àní ní iye-iye, àwọn tí ó jẹ́ pé àní orúkọ ni ó fi ń pe gbogbo wọn.” Ó fi àwọn ìràwọ̀ wé ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ogun kan, tó ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọmọ ogun. Láìsí ìdarí látọ̀dọ̀ ọ̀gágun, àwọn ọmọ ogun wọ̀nyẹn kò lè wà létòlétò. Láìsí àwọn òfin látọ̀dọ̀ Jèhófà, àwọn pílánẹ́ẹ̀tì, àwọn ìràwọ̀, àtàwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ kò lè wà létòlétò lójú òpó tí wọ́n ń tọ̀, ńṣe ni gbogbo wọn á kàn forí gbárí ni. Àmọ́ fójú inú wo Ọ̀gágun kan tó ní ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ọmọ ogun, tó ń pàṣẹ fún wọn, tó tún mọ orúkọ ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn, ibi tí wọ́n wà àti ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wọn!

Àwọn òfin tó ń darí àwọn nǹkan tó wà lójú ọ̀run jẹ́ ká mọ díẹ̀ lára ọgbọ́n tí kò láàlà tí Ọ̀gágun yìí ní. Ta ló lè ṣe irú àwọn òfin bẹ́ẹ̀, tó sì tún mí sí àwọn èèyàn láti ṣàkọsílẹ̀ ohun tó jóòótọ́ nípa àwọn ọ̀ràn yìí ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún, àní ní àwọn ẹgbẹ̀rún ọdún ṣáájú kí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó lóye wọn? Ó dájú pé, kò sí àwáwí fún wa tá ò fi ní gbà pé Jèhófà ló tọ́ láti gba gbogbo “ògo àti ọlá” nǹkan wọ̀nyí.—Ìṣípayá 4:11.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Ó jọni lójú gan-an pé Bíbélì pe ayé ní òbìrìkìtì tàbí àgbá, ìyẹn ọ̀nà míì tí wọ́n lè túmọ̀ ọ̀rọ̀ Hébérù náà sí. Ọ̀gbẹ́ni Aristotle àti àwọn ará Gíríìsì ayé ìgbàanì tiẹ̀ dábàá pé ayé rí roboto, síbẹ̀, wọ́n ṣì ń jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yìí ní ọ̀pọ̀ ẹgbẹ̀rún ọdún lẹ́yìn náà.

^ Ó lè jẹ́ àwùjọ ìràwọ̀ Pleiades ló ń jẹ́ “àgbájọ ìràwọ̀ Kímà.” Ó lè jẹ́ pé àgbájọ ìràwọ̀ Orion ló ń jẹ́ “àgbájọ ìràwọ̀ Késílì.” Ó máa tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún kí ìrísí àwọn ìràwọ̀ náà tó lè yí pa dà.

^ Nítorí pé Jèhófà lo Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo gẹ́gẹ́ “àgbà òṣìṣẹ́” láti dá ohun gbogbo, a tún lè lo àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí fún Ọmọ náà.—Òwe 8:30, 31; Kólósè 1:15-17; Hébérù 1:10.

^ Ní ọ̀gọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún, onímọ̀ sáyẹ́ǹsì William Thomson, tí wọ́n tún ń pè ní Lord Kelvin, ṣàwárí òfin kejì nípa agbára ooru, èyí tó ṣàlàyé ìdí tí àwọn nǹkan tó wà lójú ọ̀run fi máa ń bà jẹ́ bí àkókò ti ń lọ. Ohun tó mú kó ní èrò yìí ni pé ó fara balẹ̀ ka ohun tó wà ní Sáàmù 102:25-27.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]

 Ó Nípa Lórí Àwọn Èèyàn Gan-an

“Ọ̀gbẹ́ni Aristotle jẹ́ ọ̀mọ̀ràn àti onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ayé ìgbàanì tó nímọ̀ jù lọ.” Ìwé tó sọ èyí ni The 100—A Ranking of the Most Influential Persons in History. Kò ṣòro láti rí ohun tó mú kí wọ́n máa sọ irú gbólóhùn bẹ́ẹ̀ nípa ọkùnrin tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí. Aristotle (ó gbé láyé ní ọdún 384 sí 322 ṣáájú Sànmánì Kristẹni) kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ gbajúgbajà ọ̀mọ̀ràn tó ń jẹ́ Plato, nígbà tó yá, Aristotle kọ́ ọmọ aládé tó di Alexander Ńlá lẹ́kọ̀ọ́. Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ayé àtijọ́ ti wí, Aristotle kọ ohun tó pọ̀ rẹpẹtẹ, títí kan nǹkan bí àádọ́sàn-án [170] ìwé, iye tí a rí tó ṣẹ́ kù lára àwọn ìwé yìí jẹ́ mẹ́tàdínláàádọ́ta [47]. Ó kọ ohun tó pọ̀ gan-an nípa ìmọ̀ sánmà, ẹ̀kọ́ nípa ohun alààyè, ẹ̀kọ́ nípa oògùn pípò, ẹ̀kọ́ nípa ẹranko, ẹ̀kọ́ físíìsì, ìmọ̀ nípa ilẹ̀ àti ohun tó wà nínú rẹ̀ àti ẹ̀kọ́ nípa ìrònú òun ìhùwà ẹ̀dá. Fún ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún kò sí ẹlòmíì tó ṣàwárí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àwọn ohun alààyè bíi ti Aristotle. Ìwé The 100 sọ pé: “Ipa tí Aristotle ní lórí èrò àwọn èèyàn Ìwọ Oòrùn ayé ẹ̀yìn ìgbà tiẹ̀ pọ̀ jọjọ.” Àmọ́, ó fi kún un pé: “Ní nǹkan bí ọdún 500 sí 1500 Sànmánì Kristẹni, wọ́n ń kan sáárá sí Aristotle gan-an débi pé wọ́n sọ ọ́ di òrìṣà.”

[Àwọn Credit Line]

Royal Astronomical Society/Photo Researchers, Inc.

Látinú ìwé A General History for Colleges and High Schools, 1900

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26, 27]

Agbára òòfà ló so àwọn nǹkan tó wà lójú ọ̀run rọ̀ sí àyè wọn

[Credit Line]

NASA and The Hubble Heritage Team (AURA/STScl)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26, 27]

Ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ pleiades

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Àwọn ìràwọ̀ kan máa ń fọ́ sí wẹ́wẹ́

[Credit Line]

ESA/Hubble

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Àwọn ìràwọ̀ tuntun máa ń jáde látinú ẹ̀fúùfù

[Credit Line]

J. Hester and P. Scowen (AZ State Univ.), NASA

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 24]

© Peter Arnold, Inc./Alamy