Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ojú wo ni àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù ní ọjọ́ Jésù fi ń wo àwọn gbáàtúù?

Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni, àwọn aṣáájú ìlú àtàwọn aṣáájú ẹ̀sìn ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì máa ń fojú ẹ̀gàn wo àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wé. Àwọn Farisí sọ pé: “Ogunlọ́gọ̀ yìí tí kò mọ Òfin jẹ́ ẹni ègún.”—Jòhánù 7:49.

Ìwádìí tí wọ́n ṣe fi hàn pé àwọn aṣáájú ìlú àtàwọn aṣáájú ẹ̀sìn máa ń pe àwọn tí kò mọ̀wé ní ʽam-ha·ʼaʹrets, tàbí “àwọn èèyàn ilẹ̀ náà.” Ní ìbẹ̀rẹ̀, àwọn èèyàn tó ń gbé láwọn àgbègbè kan ni wọ́n máa ń fi gbólóhùn yìí pè, ó sì jẹ́ èdè ọ̀wọ̀. Yàtọ̀ sí àwọn tálákà àtàwọn ẹni rírẹlẹ̀, wọ́n tún ń pe àwọn ọlọ́lá bẹ́ẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 23:7, Bibeli Mimọ; 2 Àwọn Ọba 23:35; Ísíkíẹ́lì 22:29.

Àmọ́ nígbà ayé Jésù, àwọn tí kò mọ Òfin Mósè tàbí àwọn tí kò lè tẹ̀ lé gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ òfin àtọwọ́dọ́wọ́ tí àwọn rábì ṣe ni wọ́n ń pè bẹ́ẹ̀. Ìwé Míṣínà (àkójọ àlàyé ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò láti fi kọ ìwé Támọ́dì) sọ pé, èèyàn kò gbọ́dọ̀ sùn mọ́jú ní ilé àwọn ʽam-ha·ʼaʹrets. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The Encyclopedia of Talmudic Sages sọ pé, ọ̀mọ̀wé ọgọ́rùn-ún ọdún kejì tó ń jẹ́ Rabbi Meir kọ́ni pé: “Nígbà tí ọkùnrin kan bá fi ọmọ rẹ̀ lọ́kọ fún am ha’aretz, ńṣe ló dà bí ìgbà tó di ọmọ náà lókùn tó sì jù ú síwájú kìnnìún pé kó pa á jẹ.” Ìwé Támọ́dì ròyìn pé rábì míì sọ pé, “àwọn tí kò mọ̀wé kò ní ní àjíǹde.”

Nígbà tí Bíbélì bá lo orúkọ náà Késárì, kí ló túmọ̀ sí?

Késárì ni orúkọ tí ìdílé Gaius Julius Caesar ń jẹ́, èyí sì jẹ́ ọ̀kan lára orúkọ táwọn ará Róòmù máa ń jẹ́. Ọkùnrin yìí ló di aláṣẹ Róòmù lọ́dún 46 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Àwọn olú ọba ilẹ̀ Róòmù kan tó jẹ lẹ́yìn rẹ̀ náà gbà láti máa jẹ́ Késárì, títí kan àwọn mẹ́ta tí Bíbélì dárúkọ wọn, ìyẹn Ọ̀gọ́sítọ́sì, Tìbéríù àti Kíláúdíù.—Lúùkù 2:1; 3:1; Ìṣe 11:28.

Tìbéríù di olú ọba ní ọdún 14 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, òun ló sì ṣàkóso lákòókò tí Jésù fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Nítorí náà, òun ló wà lórí òye nígbà tí wọ́n bi Jésù ní ìbéèrè nípa owó orí, Jésù sì dá wọ́n lóhùn pé: “Ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” (Máàkù 12:17) Ó ṣe kedere pé kì í ṣe Tìbéríù nìkan ni Késárì tí Jésù ní lọ́kàn nínú ìdáhùn rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, orúkọ náà, “Késárì” dúró fún aláṣẹ ìlú, ìyẹn ìjọba.

Ní nǹkan bí ọdún 58 Sànmánì Kristẹni, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lo ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù láti gbé ẹjọ́ rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Késárì nígbà tí wọ́n fẹ́ ṣe màgòmágó nínú ẹjọ́ rẹ̀. (Ìṣe 25:8-11) Ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni pé, òun kò fẹ́ kí Nérò tó jẹ́ olú ọba nígbà yẹn dá ẹjọ́ òun, ilé ẹjọ́ tó ga jù lọ ní Róòmù lòun fẹ́ kó ṣèdájọ́ náà.

Késárì tó jẹ́ orúkọ ìdílé ti wá di ara orúkọ ọba, àní tó fi jẹ́ pé lẹ́yìn tí olú ọba tó jẹ kẹ́yìn ní ìdílé Késárì ti parí ìṣàkóso rẹ̀, wọ́n ṣì ń lo orúkọ náà láti fi pe àwọn ọba tó ń ṣàkóso Róòmù.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Dínárì fàdákà tí wọ́n ya àwòrán Tìbéríù sí