Jẹ́nẹ́sísì 23:1-20

  • Ikú Sérà àti ibi ìsìnkú (1-20)

23  Ọdún mẹ́tàdínláàádóje (127) ni Sérà lò kó tó kú; gbogbo ọjọ́ ayé Sérà nìyẹn.+  Sérà kú sí Kiriati-ábà,+ ìyẹn Hébúrónì,+ ní ilẹ̀ Kénáánì.+ Ábúráhámù wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ̀fọ̀, ó sì ń sunkún nítorí Sérà.  Lẹ́yìn náà, Ábúráhámù kúrò níbi tí òkú ìyàwó rẹ̀ wà, ó sì sọ fún àwọn ọmọ Hétì+ pé:  “Àjèjì ni mo jẹ́ nílẹ̀ yìí,+ àárín yín ni mo sì ń gbé. Ẹ fún mi níbì kan tí mo lè sìnkú sí nílẹ̀ yín, kí n lè sin òkú ìyàwó mi síbẹ̀.”  Àwọn ọmọ Hétì dá Ábúráhámù lóhùn pé:  “Gbọ́ wa, olúwa mi. Ìjòyè Ọlọ́run* lo jẹ́ láàárín wa.+ O lè sin òkú ìyàwó rẹ sí ibi tó dáa jù nínú àwọn ibi ìsìnkú wa. Ẹnikẹ́ni nínú wa ò ní sọ pé kí o má sin òkú ìyàwó rẹ síbi ìsìnkú òun.”  Ábúráhámù wá dìde, ó sì tẹrí ba fún àwọn èèyàn ilẹ̀ náà, fún àwọn ọmọ Hétì,+  ó sọ fún wọn pé: “Bí ẹ* bá gbà pé kí n sin òkú ìyàwó mi, ẹ fetí sí mi, kí ẹ sì rọ Éfúrónì ọmọ Sóhárì,  pé kó ta ihò Mákípẹ́là tó jẹ́ tiẹ̀ fún mi; ó wà ní ìkángun ilẹ̀ rẹ̀. Ẹ jẹ́ kó tà á fún mi níṣojú yín ní iye fàdákà+ tó bá jẹ́, kí n lè ní ilẹ̀ tí màá fi ṣe ibi ìsìnkú.”+ 10  Éfúrónì wà láàárín àwọn ọmọ Hétì níbi tí wọ́n jókòó sí. Torí náà, Éfúrónì ọmọ Hétì dá Ábúráhámù lóhùn lójú àwọn ọmọ Hétì àti gbogbo àwọn tó gba ẹnubodè ìlú rẹ̀+ wọlé, ó ní: 11  “Rárá olúwa mi! Fetí sí mi. Mo fún ọ ní ilẹ̀ náà àti ihò tó wà níbẹ̀. Mo fún ọ níṣojú àwọn ọmọ àwọn èèyàn mi. Lọ sin òkú ìyàwó rẹ.” 12  Ni Ábúráhámù bá tẹrí ba níwájú àwọn èèyàn ilẹ̀ náà, 13  ó sì sọ fún Éfúrónì níṣojú àwọn èèyàn náà, ó ní: “Jọ̀ọ́, fetí sí mi! Màá fún ọ ní iye fàdákà tí ilẹ̀ náà bá jẹ́. Gbà á ní ọwọ́ mi, kí n lè sin òkú ìyàwó mi síbẹ̀.” 14  Éfúrónì dá Ábúráhámù lóhùn pé: 15  “Olúwa mi, fetí sí mi. Ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ṣékélì* fàdákà ni ilẹ̀ yìí jẹ́, àmọ́ kí ni ìyẹn já mọ́ láàárín èmi àti ìwọ? Torí náà, lọ sin òkú ìyàwó rẹ.” 16  Ábúráhámù gbọ́ ohun tí Éfúrónì sọ, Ábúráhámù sì wọn iye fàdákà tí Éfúrónì sọ níṣojú àwọn ọmọ Hétì fún un, ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ṣékélì* fàdákà, ó lo ìwọ̀n tí àwọn oníṣòwò+ ń lò nígbà yẹn. 17  Nípa báyìí, ilẹ̀ Éfúrónì tó wà ní Mákípẹ́là níwájú Mámúrè, ilẹ̀ náà àti ihò tó wà níbẹ̀ àti gbogbo igi tó wà lórí ilẹ̀ náà wá di 18  ohun ìní Ábúráhámù, èyí tó rà níṣojú àwọn ọmọ Hétì àti gbogbo àwọn tó ń gba ẹnubodè ìlú rẹ̀ wọlé. 19  Lẹ́yìn náà, Ábúráhámù sin Sérà ìyàwó rẹ̀ sínú ihò tó wà ní Mákípẹ́là níwájú Mámúrè, ìyẹn ní Hébúrónì, ní ilẹ̀ Kénáánì. 20  Nípa báyìí, àwọn ọmọ Hétì fún Ábúráhámù ní ilẹ̀ náà àti ihò tó wà níbẹ̀, ó sì di ohun ìní rẹ̀ tó fi ṣe ibi ìsìnkú.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí kó jẹ́, “Ìjòyè pàtàkì.”
Tàbí “ọkàn yín.”
Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.
Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.