Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kíkọ́ Bá A Ṣe Lè Máa Fọgbọ́n Bá Àwọn Èèyàn Lò

Kíkọ́ Bá A Ṣe Lè Máa Fọgbọ́n Bá Àwọn Èèyàn Lò

Kíkọ́ Bá A Ṣe Lè Máa Fọgbọ́n Bá Àwọn Èèyàn Lò

PEGGY gbọ́ bí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n ṣe ń sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sí àbúrò rẹ̀. Ó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ṣé o rò pé ọ̀nà tó yẹ kó o gbà bá àbúrò rẹ sọ̀rọ̀ nìyẹn? Wo bó o ṣe jẹ́ kí ojú rẹ̀ fà ro!” Kí nìdí tí obìnrin yìí fi sọ bẹ́ẹ̀? Ńṣe ló ń gbìyànjú àtikọ́ ọmọ rẹ̀ béèyàn ṣe ń lo ọgbọ́n inú àti bá a ṣe ń gba tàwọn ẹlòmíràn rò.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba Tímótì alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ tó kéré sí i lọ́jọ́ orí níyànjú láti “jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ [tàbí ẹni tó ń lo ọgbọ́n inú] sí gbogbo ènìyàn.” Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, Tímótì á máa gba ti bí nǹkan ṣe ń rí lára àwọn ẹlòmíràn rò. (2 Tímótì 2:24) Kí ni ọgbọ́n inú? Báwo lo ṣe lè túbọ̀ ní ànímọ́ yìí? Báwo lo sì ṣe lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti mú ànímọ́ yìí dàgbà?

Kí Ni Ọgbọ́n Inú?

Ọgbọ́n inú túmọ̀ sí níní ọgbọ́n láti mọ bí ipò kan ti gbẹgẹ́ tó, kéèyàn sì ṣe nǹkan tàbí kó sọ̀rọ̀ lọ́nà tó tuni lára jù lọ. Ẹni tó bá ní ọgbọ́n inú lè fòye mọ bí nǹkan ṣe rí lára àwọn ẹlòmíràn. Bí ọmọ-ìka èèyàn ṣe lè mọ̀ pé ohun kan le, tàbí pé ó rọ̀, tó lè mọ ohun tó dán lára, tó mọ èyí tó gbóná, tàbí èyí tó nírun lára, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹni tó ní ọgbọ́n inú ṣe lè fọgbọ́n mọ bí nǹkan ṣe rí lára àwọn ẹlòmíràn, kó sì mọ bí ọ̀rọ̀ àti iṣé òun ṣe nípa lórí wọn. Àmọ́ ṣíṣe èyí kì í wulẹ̀ ṣe ohun téèyàn kàn ń mọ̀ ọ́n ṣe; ó kan fífi gbogbo ọkàn fẹ́ láti yẹra fún ohun tó lè ba àwọn ẹlòmíràn nínú jẹ́.

A rí àpẹẹrẹ ẹnì kan tí kò lo ọgbọ́n inú nínú ìtàn tí Bíbélì sọ nípa Géhásì ìránṣẹ́ Èlíṣà. Obìnrin ará Ṣúnámáítì tí ọmọ rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ kú wá sọ́dọ̀ Èlíṣà, kíyẹn lè tù ú nínú. Nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nípa bí ohun gbogbo ṣe rí, ó fèsì pé: “Dáadáa ni.” Àmọ́ nígbà tó dé ọ̀dọ̀ wòlíì náà, “Géhásì sún mọ́ tòsí láti tì í kúrò.” Èlíṣà ní tirẹ̀ sì sọ pé: “Jọ̀wọ́ rẹ̀ jẹ́ẹ́, nítorí ọkàn rẹ̀ korò nínú rẹ̀.”—2 Àwọn Ọba 4:17-20, 25-27.

Báwo ni Géhásì ṣe lè hùwà òmùgọ̀ báyẹn tí kò sì lo ọgbọ́n inú rárá? Òótọ́ ni pé obìnrin náà ò sọ ohun tó ń ṣe é nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Àmọ́, ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ni kì í sọ̀rọ̀ ara wọn fún gbogbo èèyàn. Síbẹ̀síbẹ̀, ohun tó ń ṣe é ti ní láti hàn lójú rẹ̀ lọ́nà kan ṣáá. Ó hàn gbangba pé Èlíṣà ti rí i pé ìdààmú bá obìnrin náà, àmọ́ Géhásì ò mọ̀, tàbí kó kàn mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìkọbi ara sí i. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ṣàpèjúwe ohun tó sábà máa ń fa ìwà tí kò fi ọgbọ́n inú hàn. Tẹ́nì kan bá ti ka iṣẹ́ rẹ̀ sí bàbàrà jù, ó lè kùnà láti mọ ohun tó jẹ́ àìní àwọn tó ń bá lò tàbí kó má tiẹ̀ bìkítà nípa wọn. Ńṣe ló dà bí ẹni tó ń wa bọ́ọ̀sì, tí ọ̀ràn àtidé ibi tó ń lọ lásìkó ká lára débi tí ò fi dúró kó èrò.

Tá a bá fẹ́ yẹra fún dídi ẹni tí kì í lo ọgbọ́n inú bíi Géhásì, a gbọ́dọ̀ là kàkà láti jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí àwọn èèyàn, nítorí pé a ò mọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn gan-an. A gbọ́dọ̀ máa wà lójúfò sí àwọn àmì tó ń fi bí nǹkan ṣe rí lára àwọn ẹlòmíràn hàn ká sì máa bá wọn sọ̀rọ̀ tàbí ká máa hùwà lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ sí wọn. Báwo lo ṣe lè túbọ̀ mú kí bó o ṣe ń ṣe nínú ọ̀ràn yìí sunwọ̀n sí i?

Lílóye Bí Ọ̀ràn Ṣe Rí Lára Àwọn Ẹlòmíràn

Ọ̀gá ni Jésù nínú mímọ bí nǹkan ṣe rí lára àwọn ẹlòmíràn àti nínú mímọ ọ̀nà tó dára jù lọ láti bá wọn lò lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́. Ilé Símónì, Farisí, ló ti ń jẹ́un lọ́jọ́ kan, nígbà tí obìnrin kan “tí a mọ̀ sí ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ìlú ńlá náà” wá bá a. Obìnrin náà ò sọ̀rọ̀ kankan, àmọ́ ọ̀nà tó gbà hùwà fi ohun púpọ̀ hàn. “Ó sì mú orùba alabásítà òróró onílọ́fínńdà wá, àti, ní bíbọ́ sí ipò kan lẹ́yìn lẹ́bàá ẹsẹ̀ [Jésù], ó sunkún, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi omijé rẹ̀ rin ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ̀ nù ún kúrò. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó fi ẹnu ko ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́, ó sì fi òróró onílọ́fínńdà náà pa á.” Jésù mọ ohun tí gbogbo èyí túmọ̀ sí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Símónì kò sọ ohunkóhun, síbẹ̀ ó ṣeé ṣe fún Jésù láti mọ̀ pé ohun tó ń sọ nínú ọkàn rẹ̀ ni pé: “Ọkùnrin yìí, bí ó bá jẹ́ wòlíì ni, ì bá mọ ẹni àti irú obìnrin tí ẹni tí ń fọwọ́ kan òun jẹ́, pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.”—Lúùkù 7:37-39.

Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo bí ọ̀ràn náà ì bá ṣe burú tó ká ní Jésù lé obìnrin náà dà nù, tàbí tó bá sọ fún Símónì pé: “Ìwọ aláìmọ̀kan yìí! Ṣé o ò rí i pé obìnrin yìí ń ronú pìwà dà ni?” Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Jésù rọra fọgbọ́n sọ àpèjúwe kan fún Símónì nípa ọkùnrin kan tó dárí gbèsè ńlá ji ẹnì kan, tó sì tún dárí gbèsè tó kéré gan-an ji ẹlòmíràn. Jésù wáá bi í pé: “Èwo nínú wọn ni yóò nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ jù?” Nípa bẹ́ẹ̀, dípò tí ì bá fi dà bíi pé ó dá Símónì lẹ́bi, ńṣe ni Jésù gbóríyìn fún Símónì nítorí pé ó fèsì tó tọ́nà. Lẹ́yìn náà ó wá jẹ́ kí Símónì rí ọ̀pọ̀ àmì tó fi bí nǹkan ṣe rí lára obìnrin náà gan-an hàn àti àwọn ohun tó fi hàn pé ó ti ronú pìwà dà. Jésù wá yíjú sí obìnrin náà, ó sì rọrá jẹ́ kó mọ̀ pé òun lóye ìmí ẹ̀dùn rẹ̀. Ó sọ fún un pé a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì í, ó sì tún sọ pé: “Ìgbàgbọ́ rẹ ti gbà ọ́ là; máa bá ọ̀nà rẹ lọ ní àlàáfíà.” Ẹ ò rí i pé àwọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n wọ̀nyẹn á túbọ̀ fún un lókun láti ṣe ohun tí ó tọ́! (Lúùkù 7:40-50) Ó ṣeé ṣe fún Jésù láti lo ọgbọ́n inú nítorí pé ó kíyè sí bí nǹkan ṣe ń rí lára àwọn èèyàn ó sì fi ìyọ́nú bá wọn lò.

Gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe ran Símónì lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ náà ló yẹ kí àwa náà kẹ́kọ̀ọ́ bá a ṣe lè lóye ìmí ẹ̀dùn àwọn èèyàn bí wọn ò tiẹ̀ sọ ohun tó ń ṣe wọn jáde, ká sì kọ́ àwọn ẹlòmíràn láti máa ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn òjíṣẹ́ tó jẹ́ onírìírí lè kọ́ àwọn ẹni tuntun ní ànímọ́ yìí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Lẹ́yìn tí wọ́n bá tí wàásù ìhìn rere náà fáwọn èèyàn, wọ́n lè kíyè sí àwọn àmì tó fi irú ẹni táwọn tí wọ́n bá sọ̀rọ̀ jẹ́ hàn. Ṣé ẹni tó ń tijú ni, ṣe oníyèméjì ni, ṣé ẹni tínú máa ń bí ni, tàbí ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ dí? Ọ̀nà wo ló máa dára jù lọ láti ràn án lọ́wọ́? Àwọn alàgbà tún lè ṣèrànwọ́ fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n ti lè ṣẹ ara wọn nítorí àìlo ọgbọ́n inú. Ran ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn lọ́wọ́ láti lóye ìmí ẹ̀dùn ẹnì kejì. Ṣé ó rò pé a fi ìwọ̀sí lọ òun ni, tàbí pé a pa òun tì, tàbí a ṣi òun lóye? Báwo ni inú rere ṣe lè tù ú nínú?

Ó dára káwọn òbí ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti ní ìyọ́nú, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé èyí ló máa jẹ́ kí wọ́n lo ọgbọ́n inú. Ọmọ Peggy tá a mẹ́nu kàn níṣàájú yẹn kíyè sí bí ojú àbúrò rẹ̀ ṣe fà ro, tí inú rẹ̀ bà jẹ́, tí omijé sì lé ròrò sí i lójú, ó sì wá mọ̀ pé òun tí kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àbúrò òun. Ohun tí ìyá rẹ̀ retí gan-an ló ṣe, ó kábàámọ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀ ó sì pinnu láti yí padà. Àwọn ọmọ Peggy méjèèjì yìí ló fi àwọn ohun tí wọ́n kọ́ láti kékeré náà sílò tí wọ́n sì wá di ẹni tí ń sọni di ọmọ ẹ̀yìn àti olùṣọ́ àgùntàn nínú ìjọ Kristẹni ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn.

Fi Hàn Pé O Lóye

Ọgbọ́n inú ṣe pàtàkì gan-an àgàgà nígbà tí gbọ́nmi-si-omi-ò-tó bá wà láàárín ìwọ àti ẹnì kan. O ti lè ṣe ohun kan tó buyì onítọ̀hún kù. Kíkọ́kọ́ gbóríyìn fúnni ló sábà máa ń dára jù lọ. Dípò tí wàá fi máa ṣe lámèyítọ́ rẹ̀, gbájú mọ́ bí ìṣòro náà ṣe máa yanjú. Ṣàlàyé bí ohun tó ṣe yẹn ṣe dùn ọ́ tó, kó o sì sọ ohun pàtó tí wàá fẹ́ kó ṣàtúnṣe rẹ̀. Wá múra tán láti tẹ́tí sí i. Bóyá ńṣe lo ṣì í lóye.

Àwọn èèyàn máa ń fẹ́ rí i pé o lóye èrò àwọn, kódà bó ò tiẹ̀ fara mọ́ ọn. Ọgbọ́n inú ni Jésù fi sọ̀rọ̀ láti fi hàn pé òun lóye ohun tó ń dun Màtá. Ó ní: “Màtá, Màtá, ìwọ ń ṣàníyàn, o sì ń ṣèyọnu nípa ohun púpọ̀.” (Lúùkù 10:41) Bákan náà, nígbà tẹ́nì kan bá sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro kan, dípò kó o máa wá ojútùú sí i kó o tó gbọ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ náà, ọ̀nà tó bọ́gbọ́n mu jù lọ láti fi hàn pé o lóye ni pé kó o tún ìṣòro tàbí awuyewuye náà sọ lọ́rọ̀ ara rẹ. Èyí jẹ́ ọ̀nà oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ láti fi hàn pé o lóye.

Mọ Ohun Tí Kò Yẹ Ní Sísọ

Nígbà tí Ẹ́sítérì Ayaba fẹ sọ fún ọkọ rẹ̀ pé kó ṣàtúnṣe ọ̀tẹ̀ tí Hámánì dì láti pa àwọn Júù run, ó fọgbọ́n ṣètò àwọn ọ̀ràn náà kó lè bọ́ sí àkókò tínú ọkọ rẹ̀ dùn. Ìgbà yẹn ló tó mẹ́nu kan kókó tó gbẹgẹ́ yìí. Àmọ́ a tún kọ́ ẹ̀kọ́ kan nípa ṣíṣàkíyèsí ohun tí kò sọ. Ó rọra fọgbọ́n yẹra fún mímẹ́nu kan ipa tí ọkọ rẹ̀ kó nínú ète búburú náà.—Ẹ́sítérì 5:1-8; 7:1, 2; 8:5.

Bákan náà, nígbà tá a bá lọ sílé Kristẹni arábìnrin kan tí ọkọ rẹ̀ kì í ṣe onígbàgbọ́, dípò tá ó fi yọ Bíbélì síta lójú ẹsẹ̀, a ò ṣe kọ́kọ́ fọgbọ́n béèrè ohun tó nífẹ̀ẹ́ sí gan-an? Nígbà tí àjèjì kan bá wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, tó múra bákan ṣáá tàbí tí ẹnì kan bá padà wá sípàdé lẹ́yìn tó ti sán lọ fún àkókò gígùn, ńṣe ló yẹ ká kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ káàbọ̀ dípò ká máa sọ̀rọ̀ nípa ìmúra rẹ̀ tàbí nípa bí kò ṣe wá sípàdé fún àkókò gígùn. Nígbà tó o bá sì kíyè sí i pé ẹni tuntun kan ní èrò tí kò tọ̀nà, ohun tó dára jù lọ ni pé kó o máà tún èrò onítọ̀hún ṣe lójú ẹsẹ̀. (Jòhánù 16:12) Ọgbọ́n inú wé mọ́ kéèyàn fi inú rere hàn nípa mímọ ohun tó yẹ ní sísọ.

Ọ̀rọ̀ Tí Ń Múni Lára Dá

Kíkọ́ béèyàn ṣe ń fi ọgbọ́n inú sọ̀rọ̀ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gbádùn àjọṣe aláyọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, kódà nígbà tí ẹni kan bá ṣì ọ́ lóye tó sì ń bínú sí ọ gan-an. Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn ọkùnrin Éfúráímù “gbìyànjú kíkankíkan láti bẹ̀rẹ̀ aáwọ̀ pẹ̀lú” Gídíónì, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ náà gan-an àti nípa gbígbóríyìn tinútinú fún ohun táwọn ọkùnrin Éfúráímù ti gbé ṣe wà lára èsì ọlọgbọ́n tó fún wọn. Ohun tó ń jẹ́ ọgbọ́n inú gan-an nìyí, nítorí pé ó mọ ìdí tí wọ́n fi ń bínú, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tó ní sì jẹ́ kínú wọn rọ̀.—Àwọn Onídàájọ́ 8:1-3; Òwe 16:24.

Gbogbo ìgbà ni kó o máa gbìyànjú láti ronú lórí ipa tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ máa ní lórí àwọn ẹlòmíràn. Sísapá láti jẹ́ ẹni tó ń lo ọgbọ́n inú yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní ayọ̀ tá a ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú ìwé Òwe 15:23 pé: “Ènìyàn ń yọ̀ nínú ìdáhùn ẹnu rẹ̀, ọ̀rọ̀ tí ó sì bọ́ sí àkókò mà dára o!”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Àwọn òbí lè kọ́ àwọn ọmọ wọn láti máa gba ti àwọn ẹlòmíràn rò

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Àwọn Kristẹni òjíṣẹ́ tó jẹ́ onírìírí lè kọ́ àwọn ẹnì tuntun bí wọ́n ṣe máa jẹ́ ẹni tó ń lo ọgbọ́n inú