Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Jèhófà fàyè gba ìkóbìnrinjọ láàárín àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ìgbàanì, ìyẹn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àmọ́ kò fàyè gbà á mọ́ báyìí. Ṣé àwọn ìlànà rẹ̀ máa ń yí padà ni?

Ojú tí Jèhófà fi ń wo ìkóbìnrinjọ kò tíì yí padà. (Sáàmù 19:7; Málákì 3:6) Kò sí lára ètò tó ṣe fún ìran ènìyàn níbẹ̀rẹ̀ kò sì sí lára ti ìsinsìnyí pẹ̀lú. Nígbà tí Jèhófà dá Éfà fún Ádámù, ó jẹ́ ká mọ̀ pé ìlànà òun ni aya kan fún ọkọ kan. “Ìdí nìyẹn tí ọkùnrin yóò ṣe fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ tí yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.”—Jẹ́nẹ́sísì 2:24.

Nígbà tí Jésù Kristi wà lórí ilẹ̀ ayé, ó tún ọ̀rọ̀ yìí sọ nígbà tó ń dáhùn ìbéèrè àwọn tó ń bi í nípa ìkọ̀sílẹ̀ àti títún ìgbéyàwó ṣe. Ó ní: “Ẹ kò ha kà pé ẹni tí ó dá wọn láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ṣe wọ́n ní akọ àti abo, ó sì wí pé, ‘Nítorí ìdí yìí ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan’? Tí ó fi jẹ́ pé wọn kì í ṣe méjì mọ́, bí kò ṣe ara kan.” Jésù wá fi kún un pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, bí kò ṣe lórí ìpìlẹ̀ àgbèrè, tí ó sì gbé òmíràn níyàwó, ṣe panṣágà.” (Mátíù 19:4-6, 9) Èyí jẹ́ kó hàn gbangba pé fífẹ́ aya kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ kún èyí tá a fẹ́ sílé tún jẹ́ ìwà panṣágà.

Kí wá nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìkóbìnrinjọ láyé ọjọ́un? Ẹ má gbàgbé pé Jèhófà kọ́ ló fi àṣà yẹn lélẹ̀. Ẹni tá a kọ́kọ́ dárúkọ nínú Bíbélì pé ó ní ju aya kan ni Lámékì, tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Kéènì. (Jẹ́nẹ́sísì 4:19-24) Aya kọ̀ọ̀kan ni Nóà àtàwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ní nígbà tí Jèhófà mú Ìkún Omi ayé ọjọ́ Nóà wá. Gbogbo àwọn tó ní ju ìyàwó kan lọ pátá ni Ìkún Omi náà pa run.

Nígbà tí Jèhófà wá yan orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí àwọn èèyàn rẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn ìyẹn, ìkóbìnrinjọ ti wá di àṣà tó ń lọ láàárín wọn nígbà náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù lọ lára wọn ló ní aya kan péré. Ọlọ́run ò sọ pé káwọn ìdílé tí wọ́n ti ní ju aya kan tú ká o. Dípò ìyẹn, ńṣe ló ṣètò ohun táwọn tó ti ṣe bẹ́ẹ̀ gbọ́dọ̀ ṣe.—Ẹ́kísódù 21:10, 11; Diutarónómì 21:15-17.

Kì í ṣe inú kìkì ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nípa ohun tó jẹ́ ìlànà Jèhófà fún ìgbéyàwó níbẹ̀rẹ̀ nìkan la ti rí i pé fífàyè gba ìkóbìnrinjọ jẹ́ ohun tó wà fúngbà díẹ̀ àmọ́ a tún rí èyí nínú ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ lábẹ́ ìmísí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. Ó ní: “Kí olúkúlùkù ọkùnrin ní aya tirẹ̀, kí olúkúlùkù obìnrin sì ní ọkọ tirẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 7:2) A tún mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ̀wé pé ọkùnrin èyíkéyìí tá a bá yàn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ Kristẹni gbọ́dọ̀ jẹ́ “ọkọ aya kan.”—1 Tímótì 3:2, 12; Títù 1:6.

Látàrí èyí, àyè tí Jèhófà fi gba ìkóbìnrinjọ dópin nígbà tá a dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀ ní nǹkan bí ẹgbàá ọdún sẹ́yìn. Àkókò yẹn ni ìlànà fún ìgbéyàwó wá padà sí bó ṣe rí nígbà tí Ọlọ́run kọ́kọ́ da ọkùnrin àti obìnrin: ìyẹn ọkọ kan fún aya kan. Ìlànà táwọn èèyàn Ọlọ́run sì ń tẹ̀ lé jákèjádò ayé lónìí nìyẹn.—Máàkù 10:11, 12; 1 Kọ́ríńtì 6:9, 10.