Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àpéjọ Àgbáyé Yóò Wáyé Lọ́dún 2003

Àpéjọ Àgbáyé Yóò Wáyé Lọ́dún 2003

Àpéjọ Àgbáyé Yóò Wáyé Lọ́dún 2003

NÍ Saturday, October 6, 2001, a ṣe ìpàdé ọdọọdún ti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania ní Jersey City, New Jersey, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Lẹ́yìn ìpàdé ọ̀hún, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà àtàwọn àlejò wọn gbádùn àkànṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan. Ní ọjọ́ kejì, ní àwọn àfikún ìpàdé tá a ṣe láwọn ìlú mẹ́rin nílẹ̀ Kánádà àti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, àwọn mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ìkéde tí ó tẹ̀ lé e yìí lẹ́yìn ọ̀rọ̀ àsọparí:

“Bí a ṣe ń wo ọjọ́ iwájú, ó ṣe pàtàkì gan-an pé kí gbogbo àwọn èèyàn Ọlọ́run má ṣe kọ ìpéjọpọ̀ ara wọn sílẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú pé ká máa pé jọ pọ̀, ká sì máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní kejì, pàápàá jù lọ bí a ti rí i pé ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù Jèhófà ń sún mọ́lé. (Hébérù 10:24, 25) Ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ Ìwé Mímọ́ yìí, a ní ìrètí pé a ó ṣe àpéjọ àgbègbè jákèjádò ayé lọ́dún tó ń bọ̀ [ìyẹn 2002]. Nígbà tó bá wá di ọdún 2003, tó bá jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà, ó ṣeé ṣe ká ṣe àwọn àkànṣe àpéjọ àgbáyé láwọn àgbègbè bíi mélòó kan lórí ilẹ̀ ayé. Àkókò tá a wà yìí ló yẹ ká wà lójúfò, ká sì máa ṣọ́nà, ká máa wo bí àwọn nǹkan ṣe ń lọ sí nínú ayé.”

Láìfi gbogbo àìdánilójú àti pákáǹleke tó ń peléke sí i bí ètò ìsinsìnyí ṣe ń sún mọ́ òpin rẹ̀ pè, ìgbòkègbodò àwọn èèyàn Ọlọ́run gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ síwájú ni. Ìhìn rere Ìjọba náà, títí kan ìkìlọ̀ tí Bíbélì fúnni, ni a gbọ́dọ̀ polongo fún gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà, ahọ́n, àti ènìyàn, ká máa sọ fún wọn pé kí wọ́n ‘bẹ̀rù Ọlọ́run, kí wọ́n sì fi ògo fún un, nítorí wákàtí ìdájọ́ láti ọwọ́ rẹ̀ ti sún mọ́lé.’ (Ìṣípayá 14:6, 7) Nítorí náà, lọ́lá Baba wa ọ̀run, a ti wéwèé láti ṣe àpéjọ àgbáyé láwọn àgbègbè bíi mélòó kan ní ọdún 2003.

Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ohun tí à ń wéwèé báyìí ni pé irú ìpéjọpọ̀ bẹ́ẹ̀ yóò wáyé láwọn ìlú ńlá díẹ̀ ní Àríwá Amẹ́ríkà, kété lẹ́yìn ìyẹn yóò tún wáyé nílẹ̀ Yúróòpù. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà ní ọdún 2003, a ó ṣètò pé kí àwọn kan lọ ṣe àpéjọ yìí ní àwọn ìlú bíi mélòó kan ní Éṣíà; nígbà tó bá sì ku díẹ̀ kí ọdún náà parí, àwọn mìíràn yóò lọ sí ilẹ̀ Áfíríkà, Gúúsù Amẹ́ríkà, àti àwọn àgbègbè Pàsífíìkì. A óò ní kí àwọn ẹ̀ka kan ṣètò kí àwọn èèyàn díẹ̀ lọ sí àwọn ibi Àpéjọ kan pàtó, nítorí náà kò ní ṣeé ṣe láti pe gbogbo èèyàn wá. Síbẹ̀síbẹ̀, yóò jẹ́ ohun ìṣírí láti ní àwọn tó mọ níwọ̀nba láti ṣojú fún orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láwọn ibi àpéjọ kọ̀ọ̀kan.

Àwọn ìjọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò ní pẹ́ máa gba ìsọfúnni nípa àpéjọ wọ̀nyí. Ẹ̀ka ilé iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan ni yóò sọ ìlú pàtó tí àwọn tó jẹ́ aṣojú yóò ti lọ ṣe àpéjọ tiwọn àti ọjọ́ tí wọn ó lọ ṣe é. Nítorí náà, a ò fẹ́ kẹ́ ẹ kọ̀wé tàbí kẹ́ ẹ máa béèrè ohunkóhun nípa ọ̀rọ̀ yìí nísinsìnyí.

Àwọn tí a ó yàn láti jẹ́ aṣojú yóò jẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí tó ti ya ara wọn sí mímọ́ tí wọ́n sì ti ṣe batisí, tí wọn yóò jẹ́ àpẹẹrẹ rere, tí wọn ó sì fi ìfẹ́ ará hàn sí àwọn ará tó wà ládùúgbò náà. Àwọn tọ̀hún náà yóò sì láǹfààní láti fi tìfẹ́tìfẹ́ gba àwọn àlejò yìí, kí wọ́n sì ṣaájò wọn gan-an. (Hébérù 13:1, 2) Èyí yóò yọrí sí “pàṣípààrọ̀ ìṣírí.” (Róòmù 1:11, 12) Àwọn ẹ̀ka tá a bá sọ pé kó fi àwọn aṣojú ránṣẹ́ sí orílẹ̀-èdè kan pàtó tàbí sí àwọn orílẹ̀-èdè bíi mélòó kan ni yóò túbọ̀ sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àwọn ìṣètò wọ̀nyí fún àwọn ará.

A ó ṣètò àpéjọ àgbègbè ọlọ́jọ́ mẹ́ta fún ọdún 2003 ní ọ̀pọ̀ jù lọ orílẹ̀-èdè bí a ti máa ń ṣe é tẹ́lẹ̀. Nípa pípéjọpọ̀, gbogbo wa yóò láǹfààní láti ‘fetí sílẹ̀, láti kẹ́kọ̀ọ́, àti láti fún ara wa níṣìírí.’ (Diutarónómì 31:12; 1 Kọ́ríńtì 14:31) Èyí yóò fún gbogbo àwọn èèyàn Ọlọ́run láǹfààní láti ‘tọ́ ọ wò, kí wọ́n sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere.’ (Sáàmù 34:8) Àwọn míṣọ́nnárì yóò wá sí gbogbo àpéjọ àgbáyé àti ọ̀pọ̀ àpéjọ àgbègbè, àwọn kan lára wọn yóò sì kópa nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà.

Nínú ọdún tá a wà yìí, a óò gbádùn Àpéjọ Àgbègbè “Àwọn Olùfi Ìtara Pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run,” èyí tí yóò ta wá jí láti túbọ̀ jẹ́rìí síwájú sí i. Àti pé, ìfojúsọ́nà wa fún ohun tí Jèhófà ní nípamọ́ fún ọdún tó ń bọ̀ yóò túbọ̀ pọ̀ sí i. Èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ‘máa ṣọ́nà, kí a wà lójúfò, kí a sì wà ní ìmúratán’ lójú àkókò tó le koko tó sì ṣe pàtàkì tá a wà yìí.—Mátíù 24:42-44.