Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹgbẹ́ Àwọn Ará Kárí Ayé fún Mi Lókun

Ẹgbẹ́ Àwọn Ará Kárí Ayé fún Mi Lókun

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Ẹgbẹ́ Àwọn Ará Kárí Ayé fún Mi Lókun

GẸ́GẸ́ BÍ THOMSON KANGALE ṢE SỌ Ọ́

Ní April 24, 1993, wọ́n pè mí síbi ayẹyẹ ìyàsímímọ́ ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa tuntun, tó ní ilé mẹ́tàlá nínú, nílùú Lùsákà, lórílẹ̀-èdè Zambia. Níwọ̀n bí mi ò ti lè rìn dáadáa mọ́, Kristẹni arábìnrin tó ń mú wa kiri àwọn ilé yìí fi inú rere bi mí pé, “Àbí wàá fẹ́ kí n gbé àga kan wá, kí o le máa sinmi lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan bá a ṣe ń lọ?” Adúláwọ̀ ni mí, aláwọ̀ funfun lòun. Síbẹ̀ kò fi tìyẹn ṣe. Èyí wú mi lórí gan-an. Mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, torí pé inú rere rẹ̀ ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún mi láti lọ káàkiri gbogbo ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa.

JÁLẸ̀ àwọn ọdún wọ̀nyí wá ni àwọn ìrírí bí eléyìí ti máa ń mú mi lọ́kàn yọ̀, ó sì mú un dá mi lójú pé láàárín àwọn Kristẹni Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ti lè rí irú ìfẹ́ tí Kristi sọ pé a ó fi dá àwọn ọmọlẹ́yìn òun tòótọ́ mọ̀. (Jòhánù 13:35; 1 Pétérù 2:17) Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé bí mo ṣe di ọ̀kan lára àwọn Kristẹni wọ̀nyí nígbà yẹn lọ́hùn-ún ní 1931, ọdún tí wọ́n kéde pé orúkọ tá a gbé ka Bíbélì náà, ìyẹn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, làwọn fẹ́ máa jẹ́.—Aísáyà 43:12.

Bí Mo Ṣe Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ní Áfíríkà

November 1931 ni mo pé ẹni ọdún méjìlélógún. Mo sì ń gbé ìlú Kitwe, lágbègbè ibi tí bàbà pọ̀ sí ní Àríwá Ròdéṣíà (ìyẹn Zambia báyìí). Ọ̀rẹ́ mi kan tá a jọ ń gbá bọ́ọ̀lù ló mú mi mọ àwọn Ẹlẹ́rìí. Mo lọ sáwọn ìpàdé wọn mélòó kan, mo sì wá kọ̀wé sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ wọn nílùú Cape Town, lórílẹ̀-èdè Gúúsù Áfíríkà, mo ní kí wọ́n jọ̀ọ́ fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà, Duru Ọlọrun, a ránṣẹ́ sí mi. Èdè Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n fi kọ ìwé náà, kò sì fi bẹ́ẹ̀ yé mi, torí pé mi ò gbọ́ èdè yẹn dáadáa.

Àgbègbè ibi ti bàbà pọ̀ sí, tó wà ní nǹkan bí òjìlérúgba [240] kìlómítà níhà gúúsù ìwọ̀ oòrùn Adágún Bangweulu, tó wà nítòsí ibi tí mo gbé dàgbà, ń gba ọ̀pọ̀ èèyàn láti àwọn àgbègbè mìíràn síṣẹ́, ní àwọn ibi tí wọ́n ti ń wa bàbà. Àwọn àwùjọ mélòó kan tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí máa ń pàdé pọ̀ níbẹ̀ déédéé fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Láìpẹ́ lẹ́yìn ìgbà yẹn, mo ṣí kúrò nílùú Kitwe lọ sílùú Ndola tí ń bẹ nítòsí, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ mọ́ àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀. Nígbà yẹn, èmi ni olórí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tí wọ́n ń pè ní Prince of Wales. Mo tún ń ṣe ọmọ ọ̀dọ̀ fún máníjà òyìnbó kan tó ń ṣiṣẹ́ ní African Lakes Corporation, ìyẹn iléeṣẹ́ kan tó ní ọ̀pọ̀ ilé ìtajà ní àárín gbùngbùn Áfíríkà.

Mi ò kàwé púpọ̀, ẹnu àwọn òyìnbó tí mò ń bá ṣiṣẹ́ sì ni mo ti gbọ́ tá-tà-tá tí mo mọ̀ nínú èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ṣùgbọ́n mo ń hára gàgà láti kàwé sí i. Mo sì ń wá ọ̀nà láti wọ iléèwé kan nílùú Plumtree, ní Gúúsù Ròdéṣíà (tí à ń pè ní Zimbabwe báyìí). Àmọ́ kí iléèwé yẹn tó bọ́ sí i, mo kọ̀wé sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ nílùú Cape Town lẹ́ẹ̀kejì. Mo sọ fún wọn pé mo ti gba ìwé Duru Ọlọrun náà, mo sì fẹ́ sin Jèhófà ní àkókò kíkún.

Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ nígbà tí mo gba èsì tó sọ pé: “O káre, pé o fẹ́ sin Jèhófà. A gbà ọ́ níyànjú pé kí o fi ọ̀ràn náà sínú àdúrà. Jèhófà á túbọ̀ fi òye òtítọ́ yé ọ, á sì ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ọ láti sìn ín.” Lẹ́yìn tí mo ka lẹ́tà náà nígbà bíi mélòó kan, mo bi àwọn Ẹlẹ́rìí mélòó kan nípa ohun tó yẹ kí n ṣe. Wọ́n sọ pé: “Bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ lo fẹ́ sin Jèhófà, má fi falẹ̀ rárá, bíṣẹ́ ò bá sáà pẹ́ni, à kì í pẹ́ṣẹ́.”

Odindi ọ̀sẹ̀ kan ni mo fi gbàdúrà nípa ọ̀ràn yìí. Mo wá dórí ìpinnu náà pé màá yááfì iléèwé tí mo fẹ́ lọ kí n lè gbájú mọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì tí àwọn Ẹlẹ́rìí ń kọ́ mi. Ọdún tó tẹ̀ lé e, ní January 1932, ni mo ṣèrìbọmi láti fi hàn pé mo ti ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run. Lẹ́yìn tí mo ṣí láti Ndola lọ sílùú Luanshya tí ń bẹ nítòsí ni mo ṣalábàápàdé Jeanette, tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́, a sì ṣègbéyàwó ní September 1934. Jeanette ti bí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin kan ká tó ṣègbéyàwó.

Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, mo tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Ọdún 1937 ni mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ni wọ́n yàn mí ṣe òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò, tí à ń pè ní alábòójútó àyíká nísinsìnyí. Àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò máa ń bẹ àwọn ìjọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà wò láti fún wọn lókun nípa tẹ̀mí.

Wíwàásù Láwọn Ọdún Wọ̀nyẹn

Ní January 1938, wọ́n ní kí n lọ bẹ baálẹ̀ ará Áfíríkà kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sokontwe wò. Òun ló dìídì kọ̀wé pé òun fẹ́ kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá bẹ òun wò. Ọjọ́ mẹ́ta gbáko ni mo fi gun kẹ̀kẹ́ kí n tó dé àdúgbò rẹ̀. Inú rẹ̀ dùn gan-an nígbà tí mo sọ fún un pé lẹ́tà tó kọ sí iléeṣẹ́ wa nílùú Cape Town ló jẹ́ kí wọ́n rán mi wá.

Mo bẹ̀rẹ̀ sí lọ láti ahéré dé ahéré láàárín àwọn èèyàn rẹ̀, mo ní kí wọ́n máa bọ̀ níbi insaka (àtíbàbà ìtagbangba). Mo bá ogunlọ́gọ̀ náà sọ̀rọ̀ nígbà tí wọ́n pé jọ. Mo sì wá bẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Baálẹ̀ abúlé náà àti akọ̀wé rẹ̀ làwọn tó kọ́kọ́ di alábòójútó nínú àwọn ìjọ ibẹ̀. Lónìí, ìjọ tó wà lágbègbè yẹn, tí à ń pè ní Samfya báyìí, ti lé ní àádọ́ta.

Láti 1942 sí 1947, mo sìn ní ìpínlẹ̀ tó wà láyìíká Adágún Bangweulu. Ọjọ́ mẹ́wàá ni mo máa ń lò pẹ̀lú ìjọ kọ̀ọ̀kan. Níwọ̀n bí àwọn òṣìṣẹ́ tó ń ṣe iṣẹ́ ìkórè tẹ̀mí nígbà yẹn ti kéré jọjọ, èrò wa kò yàtọ̀ sí ti Jésù Kristi, Olúwa wa, ẹni tó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́. Nítorí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè láti rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.” (Mátíù 9:36-38) Láyé ọjọ́un, ó nira gan-an láti rìnrìn àjò. Fún ìdí yìí, ńṣe ni Jeanette máa ń dúró sí Luanshya pẹ̀lú àwọn ọmọ nígbà tí mo bá ń bẹ àwọn ìjọ wò. Nígbà yẹn, èmi àti Jeanette ti bí ọmọ méjì sí i, ṣùgbọ́n ọ̀kan lára wọn ṣaláìsí nígbà tó pé ọmọ oṣù mẹ́wàá.

Ọkọ̀ ò pọ̀ láyé ọjọ́un, bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀nà ò pọ̀. Lọ́jọ́ kan, mo fi kẹ̀kẹ́ Jeanette rìnrìn àjò kan tó lé ní igba [200] kìlómítà. Bí mo ṣe ń lọ, bí mo bá fẹ́ sọdá odò kékeré, ńṣe ni màá gbé kẹ̀kẹ́ náà sí èjìká, tí màá fọwọ́ kan dì í mú, tí màá sì fi ọwọ́ kejì lúwẹ̀ẹ́ dé òdìkejì. Ó wá ṣẹlẹ̀ pé iye àwọn Ẹlẹ́rìí pọ̀ sí i lọ́nà tó kàmàmà ní Luanshya. Àní nígbà tó di 1946, èèyàn ẹgbàá ó dín àádọ́jọ [1,850] ló wá síbi Ìṣe Ìrántí ikú Kristi.

Wọ́n Gbé Àtakò Dìde sí Iṣẹ́ Wa

Lákòókò kan nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì ń lọ lọ́wọ́, alága ìjọba ìbílẹ̀ Kawambwa ní kí n yọjú sóun, ó sì sọ pé: “Mi ò fẹ́ kó o lo àwọn ìwé Watch Tower Society mọ́, nítorí pé a ti gbẹ́sẹ̀ lé wọn báyìí. Ṣùgbọ́n mo lè fún ọ ní àwọn ìwé tó o lè máa ṣèwádìí nínú rẹ̀, láti fi kọ àwọn ìwé mìíràn tó o lè máa lò lẹ́nu iṣẹ́ rẹ.”

Mo dá a lóhùn pé: “Àwọn ìwé tí mo ní ti tó mi. Mi ò fẹ́ òmíràn.”

“O ò tíì mọ àwọn ará Amẹ́ríkà ṣá. Wọ́n á kàn ṣì ọ́ lọ́nà ni,” ló fi dá mi lóhùn (ìdí ni pé Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà la ti ń tẹ àwọn ìwé wa nígbà yẹn).

Mo fèsì pé: “Rárá o, àwọn tí èmi ń bá ṣiṣẹ́ pọ̀ kò ní ṣì mí lọ́nà.”

Ó wá bi mí pé: “Ṣé o ò lè sọ fáwọn ìjọ rẹ pé kí wọ́n máa dáwó bí àwọn ìjọ yòókù ṣe ń dáwó fún ìtìlẹyìn ogun ni?”

Mo fèsì pé: “Iṣẹ́ àwọn ońṣẹ́ ọba ni láti lọ sọ fún wọn.”

Ó wá sọ pé: “Kí ló dé tí o ò lọ sílé lọ rò ó wò ná?”

Mo dá a lóhùn pé: “Nínú Ẹ́kísódù 20:13 àti 2 Tímótì 2:24, Bíbélì pàṣẹ pé a ò gbọ́dọ̀ pànìyàn, a ò sì gbọ́dọ̀ jà.”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó jẹ́ kí n lọ, ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni alága ìjọba ìbílẹ̀ Fort Rosebery, ìlú tí à ń pè ní Mansa báyìí, ránṣẹ́ pè mí. Ó sọ pé: “Ìdí tí mo fi pè ọ́ ni láti jẹ́ kó o mọ̀ pé ìjọba ti gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ìwé yín.”

Mo dá a lóhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni. Mo ti gbọ́ bẹ́ẹ̀.”

“Nítorí náà, lọ sí gbogbo ìjọ yín, kí o sì sọ fáwọn tẹ́ ẹ jọ ń jọ́sìn pé kí wọ́n kó gbogbo ìwé wọ̀nyẹn wá. Ṣó o gbọ́?”

Mo fèsì pé: “Ìyẹn kì í ṣe iṣẹ́ mi. Iṣẹ́ àwọn ońṣẹ́ ọba nìyẹn.”

Àwọn Kan Tí Mo Ṣèèṣì Bá Pàdé Tẹ́wọ́ Gba Òtítọ́

À ń bá iṣẹ́ ìwàásù wa lọ ní pẹrẹu lẹ́yìn ogun náà. Ní 1947, mo ṣẹ̀ṣẹ̀ parí bíbẹ ìjọ kan wò ní abúlé Mwanza ni. Mo wá béèrè ibi tí mo ti lè rí tíì rà. Wọ́n ní kí n lọ sílé Ọ̀gbẹ́ni Nkonde, níbi tí wọ́n ti ń ta tíì. Ọ̀gbẹ́ni Nkonde àti ìyàwó rẹ̀ gbà mí tọwọ́tẹsẹ̀. Mo bi Ọ̀gbẹ́ni Nkonde bóyá á fẹ́ ka àkòrí náà “Ọrun Apadi, Ibi Isimi Kan Ninu Ireti” nínú ìwé “Jeki Ọlọrun Jẹ Olõtọ” bí mo ṣe ń mu tíì mi lọ́wọ́.

Mo wá bí i lẹ́yìn tí mo mu tíì mi tán pé: “Kí ni òye rẹ nípa ọ̀run àpáàdì báyìí?” Ohun tó kà wú u lórí gan-an. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá bẹ̀rẹ̀ sí bá a ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Òun àti ìyàwó rẹ̀ sì ṣèrìbọmi lẹ́yìn náà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé òun fúnra rẹ̀ kò ṣe Ẹlẹ́rìí mọ́ nígbà tó yá, ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀ kan ń ṣe Ẹlẹ́rìí nìṣó. Kódà, Pilney, ọ̀kan lára àwọn ọmọ rẹ̀, ṣì ń sìn ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Zambia títí di bá a ṣe ń wí yìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyá Pilney ti darúgbó kùjọ́kùjọ́, síbẹ̀ Ẹlẹ́rìí olóòótọ́ ṣì ni.

Mo Lọ Sìn Fúngbà Díẹ̀ ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà

Ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa ní Àríwá Ròdéṣíà, èyí tá a dá sílẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ 1948 ní Lùsákà, yàn mí sí Tanganyika (ìyẹn Tanzania báyìí). Ẹlẹ́rìí mìíràn bá èmi àti ìyàwó mi fẹsẹ̀ rin àárín àwọn àgbègbè olókè ńláńlá lọ síbi iṣẹ́ mi tuntun yìí. Ìrìn àrìnwọ́dìí náà gba ọjọ́ mẹ́ta gbáko. Èmi ru ẹrù ìwé, ìyàwó mi ru aṣọ wa, Ẹlẹ́rìí tá a jọ lọ sì ru àwọn ohun èlò ibùsùn.

Nígbà tá a dé ìlú Mbeya ní March 1948, iṣẹ́ pọ̀ láti ṣe láti fi ran àwọn ará lọ́wọ́ láti túbọ̀ mú ara wọn bá ẹ̀kọ́ Bíbélì mu. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, àwọn èèyàn Watchtower ni wọ́n mọ̀ wá sí lágbègbè yẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará ti tẹ́wọ́ gba orúkọ náà Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn aráàlú ò tíì mọ̀ nípa rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ó pọn dandan kí àwọn Ẹlẹ́rìí kan yọwọ́ nínú àwọn àṣà ìbílẹ̀ tó wé mọ́ jíjúbà àwọn òkú. Ṣùgbọ́n ó jọ pé àtúnṣe tó nira jù lọ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni fífẹsẹ̀ ìgbéyàwó wọn múlẹ̀ lábẹ́ òfin, kí ó lè jẹ́ èyí tó ní ọlá lójú gbogbo èèyàn.—Hébérù 13:4.

Nígbà tó yá, mo ní àǹfààní sísìn ní àwọn àgbègbè mìíràn ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà, títí kan Uganda. Mo lo nǹkan bí ọ̀sẹ̀ mẹ́fà nílùú Entebbe àti Kampala, níbi tá a ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti mọ̀ nípa òtítọ́ Bíbélì.

Wọ́n Ní Kí N Wá sí New York City

Lẹ́yìn tí mo sìn ní Uganda fún sáà kan, mo dé Dar es Salaam, tí í ṣe olú ìlú Tanganyika, níbẹ̀rẹ̀ ọdún 1956. Lẹ́tà kan láti orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lágbàáyé ti ń dúró dè mí níbẹ̀. Wọ́n sọ nínú lẹ́tà náà pé kí n bẹ̀rẹ̀ sí palẹ̀ mọ́ láti wá sí New York fún àpéjọ àgbáyé tí yóò wáyé níbẹ̀ láti July 27 sí August 3, 1958. Láìṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ, ara mi wà lọ́nà gan-an.

Nígbà tí ọjọ́ kò, èmi àti alábòójútó arìnrìn-àjò mìíràn, ìyẹn Luka Mwango, wọkọ̀ òfuurufú láti Ndola lọ sílùú Salisbury (tí à ń pè ní Harare báyìí), ní Gúúsù Ròdéṣíà, lẹ́yìn náà sílùú Nairobi, lórílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà. A wá tibẹ̀ wọkọ̀ òfuurufú lọ sílùú London, nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, níbi tí wọ́n ti gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀. Nígbà tí àkókò tó láti sùn lóru ọjọ́ tá a dé sí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, inú wa kàn ń dùn ni. A ò yéé sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn òyìnbó aláwọ̀ funfun ṣe ń ṣaájò àwa adúláwọ̀ ará Áfíríkà. Ìrírí yìí fún wa níṣìírí lọ́pọ̀lọpọ̀.

Níkẹyìn, a dé New York, níbi tá a ti ṣe àpéjọ náà. Lọ́jọ́ kan ní àpéjọ náà, mo sọ ìròyìn nípa bí iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń lọ sí ní Àríwá Ròdéṣíà. Lọ́jọ́ yẹn, nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́wàá [200,000] èèyàn ló péjú-pésẹ̀ sí Polo Grounds àti Pápá Ìṣeré Yankee nílùú New York. Mi ò lè sùn mọ́jú lóru ọjọ́ yẹn bí mo ṣe ń ronú nípa àǹfààní àgbàyanu tí mo ní yìí.

Bíi kí àpéjọ náà má parí ló rí. Àmọ́ àjò ò lè dùn kónílé má relé. Nígbà tá à ń darí bọ̀ nílé, àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tún fi tìfẹ́tìfẹ́ ṣaájò wa. Ìṣọ̀kan àwa èèyàn Jèhófà, láìka ẹ̀yà tàbí orílẹ̀-èdè sí, hàn gbangba-gbàǹgbà sí wa nígbà ìrìn àjò yẹn!

Mò Ń Bá Iṣẹ́ Ìsìn Mi Lọ Láìka Àwọn Àdánwò Sí

Lọ́dún 1967, wọ́n ní kí n lọ ṣe ìránṣẹ́ àgbègbè—ìyẹn òjíṣẹ́ tó ń rìnrìn àjò láti àyíká dé àyíká. Nígbà yẹn, iye àwa Ẹlẹ́rìí ní Zambia ti lé ní ẹgbàá mẹ́tàdínlógún ààbọ̀ [35,000]. Nígbà tó yá, tí ara mi ò fi bẹ́ẹ̀ le mọ́, wọ́n tún ní kí n lọ ṣe alábòójútó àyíká ní àgbègbè ibi tí wọ́n ti ń wa bàbà. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, àìsàn gbé Jeanette dè, ó sì kú ní December 1984, ó ṣe olóòótọ́ sí Jèhófà dójú ikú.

Lẹ́yìn ikú rẹ̀, ó dùn mí gan-an nígbà tí àwọn àna mi tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ sọ pé èmi ni mo fi agbára ẹ̀mí òkùnkùn pa á. Àmọ́ àwọn kan tó mọ̀ nípa àìsàn Jeanette, tí wọ́n sì bá dókítà tó tọ́jú rẹ̀ sọ̀rọ̀, ṣàlàyé bí ọ̀ràn ṣe jẹ́ fún àwọn ìbátan ìyàwó mi náà. Ni àdánwò míì bá tún dé o. Àwọn ìbátan kan fẹ́ kí n tẹ̀ lé àṣà ìbílẹ̀ tí wọ́n ń pè ní ukupyanika. Ní àdúgbò tí mo ti wá, àṣà wọn ni pé kí ọkọ tàbí aya ẹni tó kú ní ìbálòpọ̀ takọtabo pẹ̀lú ẹbí tó sún mọ́ olóògbé náà tímọ́tímọ́. Àmọ́, mo yarí kanlẹ̀ pé mi ò ṣe.

Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, àwọn ẹbí fi mí lọ́rùn sílẹ̀. Mo dúpẹ́ pé Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ láti dúró láìyẹsẹ̀. Oṣù kan lẹ́yìn ìsìnkú ìyàwó mi, arákùnrin kan wá bá mi, ó ní: “Arákùnrin Kangale, ohun tó wú wa lórí jù lọ nígbà ikú ìyàwó rẹ ní pé o ò fàyè gba àṣà ìbílẹ̀ kankan tó lòdì sí ìlànà Ọlọ́run. A dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ gan-an ni.”

Ìkórè Tó Kàmàmà

Ó ti pé ọdún márùnlélọ́gọ́ta báyìí tí mo ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ẹ wo bí ayọ̀ mi ti kún tó láàárín ọdún wọ̀nyí bí mo ti ń rí ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìjọ tí a ti dá sílẹ̀ àti ọ̀pọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a ti kọ́ sáwọn àgbègbè tí mo ti sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò! Látorí nǹkan bí àwa Ẹlẹ́rìí tí iye wa jẹ́ ẹgbẹ̀rìnlá [2,800] lọ́dún 1943, iye àwa olùpòkìkí Ìjọba náà ti lé ní ẹgbàá mọ́kànlélọ́gọ́ta [122,000] báyìí ní Zambia. Àní lọ́dún tó kọjá, ó lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ò lé ẹgbàáje [514,000] èèyàn tó wá sí Ìṣe Ìrántí lórílẹ̀-èdè yìí, tí iye àwa èèyàn inú rẹ̀ kò pé mílíọ̀nù mọ́kànlá.

Jèhófà ń tọ́jú mi dáadáa lọ́wọ́ tí mo wà yìí. Nígbà tí mo bá ń fẹ́ ìtọ́jú, Kristẹni arákùnrin kan a gbé mi lọ sí ilé ìwòsàn. Àwọn ìjọ kan ṣì ń pè mí láti wá sọ àsọyé fún wọn, èyí sì ń gbé mi ró gan-an ni. Ìjọ tí mò ń dara pọ̀ mọ́ ṣètò pé kí àwọn Kristẹni arábìnrin máa bá mi tọ́jú ilé. Àwọn arákùnrin sì ń yọ̀ǹda láti mú mi lọ sáwọn ìpàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Mo mọ̀ pé kò síbi tí mo ti lè rí irú ìtọ́jú onífẹ̀ẹ́ wọ̀nyí gbà láé tí kì í bá ṣe pé mò ń sin Jèhófà. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ pé ó ń lò mí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Mo tún dúpẹ́ fún ọ̀pọ̀ ẹrù iṣẹ́ tí mo ti láǹfààní láti bójú tó títí di bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí.

Ojú mi ti di bàìbàì. Nígbà tí mo bá ń rìn lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, mo gbọ́dọ̀ tẹsẹ̀ dúró lọ́pọ̀ ìgbà kí n sinmi díẹ̀ lójú ọ̀nà. Ó jọ pé àpò mi ti wúwo ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, nítorí náà mo máa ń kó àwọn ìwé tí mi ò bá ní lò nípàdé kúrò nínú rẹ̀ kí ó lè fúyẹ́. Iṣẹ́ ìsìn pápá mi kì í sábàá kọjá dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn tó ń wá bá mi nílé. Síbẹ̀, ẹ wo bí inú mi ṣe máa ń dùn tó nígbà tí mo bá wẹ̀yìn wò, tí mo sì rí ìbísí gígọntíọ tó ti wáyé! Mo ti sìn ní pápá tí ọ̀rọ̀ Jèhófà tó wà ní Aísáyà 60:22 ti ní ìmúṣẹ tó kàmàmà. Ibẹ̀ kà pé: “Ẹni tí ó kéré yóò di ẹgbẹ̀rún, ẹni kékeré yóò sì di alágbára ńlá orílẹ̀-èdè. Èmi tìkára mi, Jèhófà, yóò mú un yára kánkán ní àkókò rẹ̀.” Ní tòdodo, ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ yìí ti ṣojú ẹ̀mí mi, kì í ṣe ní Zambia nìkan bí kò ṣe jákèjádò ayé. b

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ ìwé yìí jáde, ṣùgbọ́n kò sí nílẹ̀ mọ́ báyìí.

b Ó bani nínú jẹ́ pé níkẹyìn, Arákùnrin Kangale di ẹni tí kò lókun kankan mọ́, ó sì kú gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́ bá a ṣe ń múra àpilẹ̀kọ yìí sílẹ̀ pé kí a gbé e jáde.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Thomson rèé lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwòrán ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa ní Zambia

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa ní Zambia lónìí