Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìlànà Ta Ni O Lè Gbẹ́kẹ̀ Lé?

Ìlànà Ta Ni O Lè Gbẹ́kẹ̀ Lé?

Ìlànà Ta Ni O Lè Gbẹ́kẹ̀ Lé?

Ẹnu ya ẹnì kan tó jẹ́ pé ìgbà àkọ́kọ́ tó máa wá sí Áfíríkà nìyẹn nígbà tó rí ọkùnrin kan tó dúró ṣánṣán sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà. Ó ṣàkíyèsí pé lẹ́yìn ìṣẹ́jú mélòó kan, ṣe ni ọkùnrin yẹn á rọra sún ẹsẹ̀ kẹ́rẹ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan bó ṣe dúró wandi. Ó pẹ́ kí àlejò yìí tó mọ ìdí tí ọkùnrin yẹn fi ń sún. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé òjìji òpó wáyà ìbánisọ̀rọ̀ ló ń fara pa mọ́ sí lábẹ́. Òjìji òpó náà sì ń ṣípò padà díẹ̀díẹ̀ bí oòrùn ọ̀sán ṣe ń lọ kúrò lójú kan.

BÍI ti òjìji tó wá látọ̀dọ̀ oòrùn yẹn, ìgbà gbogbo ni ìgbòkègbodò ọmọ ẹ̀dá àti ìlànà wọn ń yí padà. Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí èyí, Jèhófà Ọlọ́run, tí í ṣe “Baba àwọn ìmọ́lẹ̀ àtọ̀runwá,” kì í yí padà. Ọmọlẹ́yìn náà Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Kò sì sí àyídà ìyípo òjìji lọ́dọ̀ rẹ̀.” (Jákọ́bù 1:17) Wòlíì Hébérù nì, Málákì, ṣàkọsílẹ̀ ohun tí Ọlọ́run tìkára rẹ̀ sọ, pé: “Èmi ni Jèhófà; èmi kò yí padà.” (Málákì 3:6) Ọlọ́run sọ fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nígbà ayé Aísáyà pé: “Àní títí di ọjọ́ ogbó ènìyàn, Ẹnì kan náà ni mí; àti títí di ìgbà orí ewú ènìyàn, èmi fúnra mi yóò máa rù ú. Dájúdájú, èmi yóò gbé ìgbésẹ̀.” (Aísáyà 46:4) Fún ìdí yìí, kò yẹ kí ìgbẹ́kẹ̀lé táa ní nínú àwọn ìlérí Olódùmarè yingin bí ọdún ti ń gorí ọdún.

Ẹ̀kọ́ Tí A Rí Kọ́ Látinú Òfin

Gẹ́gẹ́ bí àwọn ìlérí Jèhófà ti ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, tí kì í sì í yí padà, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ìlànà rẹ̀ nípa ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. Ǹjẹ́ wàá gbẹ́kẹ̀ lé oníṣòwò tó bá ń lo oríṣi òṣùwọ̀n méjì, tó jẹ́ pé ọ̀kan lára rẹ̀ ló péye? Ó dájú pé o ò ní gbẹ́kẹ̀ lé e. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, “òṣùwọ̀n aláwẹ́ méjì tí a fi ń rẹ́ni jẹ jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà, ṣùgbọ́n òkúta àfiwọn-ìwúwo tí ó pé pérépéré jẹ́ ìdùnnú rẹ̀.” (Òwe 11:1; 20:10) Nínú òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó fi àṣẹ yìí kún un, pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe àìṣèdájọ́ òdodo nínú ìdájọ́ ṣíṣe, nínú ìdíwọ̀n, nínú wíwọ̀n, tàbí nínú dídíwọ̀n àwọn ohun olómi. Kí ẹ ní òṣùwọ̀n pípéye, ìwọ̀n pípéye, òṣùwọ̀n eéfà pípéye àti òṣùwọ̀n hínì pípéye. Jèhófà Ọlọ́run yín ni èmi, ẹni tí ó mú yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.”—Léfítíkù 19:35, 36.

Ṣíṣègbọràn sí àṣẹ yẹn jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí ojú rere Ọlọ́run, kí wọ́n sì jàǹfààní púpọ̀ nípa tara. Bákan náà, rírọ̀mọ́ àwọn ìlànà Jèhófà tí kì í yí padà, kì í ṣe kìkì nínú ọ̀ràn ìwọ̀n àti òṣùwọ̀n nìkan, ṣùgbọ́n nínú gbogbo ọ̀ràn ìgbésí ayé pẹ̀lú, máa ń yọrí sí ìbùkún fún àwọn olùjọsìn tó gbẹ́kẹ̀ lé e. Ọlọ́run polongo pé: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn.”—Aísáyà 48:17.

Kí Ló Dé Tí Ìlànà Ìwà Híhù Fi Dìdàkudà Lónìí?

Bíbélì tọ́ka sí ìdí tí ìlànà ìwà híhù fi dìdàkudà lónìí. Ìwé tó gbẹ̀yìn Bíbélì, ìyẹn Ìṣípayá, ṣàpèjúwe ogun kan tó jà ní ọ̀run, èyí tí àbájáde rẹ̀ nípa lórí gbogbo ènìyàn títí di òní olónìí. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Ogun sì bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀run: Máíkẹ́lì àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ bá dírágónì náà jagun, dírágónì náà àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sì jagun ṣùgbọ́n kò borí, bẹ́ẹ̀ ni a kò rí àyè kankan fún wọn mọ́ ní ọ̀run. Bẹ́ẹ̀ ni a fi dírágónì ńlá náà sọ̀kò sísàlẹ̀, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì, ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà; a fi í sọ̀kò sísàlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé, a sì fi àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sọ̀kò sísàlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀.”—Ìṣípayá 12:7-9.

Kí ló ṣẹlẹ̀ kété lẹ́yìn ogun náà? Jòhánù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ní tìtorí èyí, ẹ máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin ọ̀run àti ẹ̀yin tí ń gbé inú wọn! Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé àti fún òkun, nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.”—Ìṣípayá 12:12.

‘Ègbé dé bá ilẹ̀ ayé’ nígbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní bẹ́ sílẹ̀ lọ́dún 1914, tó sì mú òpin dé bá sànmánì ìlànà ìwà híhù tó yàtọ̀ gan-an sí ti òde òní. Òpìtàn nì, Barbara Tuchman, ṣàkíyèsí pé: “Ogun Ńlá tó jà ní 1914 sí 1918 ni ohun tó dà bí ìlà tó fìyàtọ̀ sáàárín àkókò yẹn àti àkókò tiwa. Ní ti pé ó gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí tí ì bá ti wúlò gan-an ní àwọn ọdún tó tẹ̀ lé e, ní ti pé ó fòpin sí ọ̀pọ̀ nǹkan téèyàn gbà gbọ́, tó pa èrò wa dà, tó sì mú wa lọ́kàn gbọgbẹ́, tó sì wá yí ọ̀nà ìrònú òun ìhùwà ọmọ aráyé padà, tó fi wá yàtọ̀ pátápátá sí bó ṣe rí tẹ́lẹ̀.” Ọ̀gbẹ́ni Eric Hobsbawm, tí í ṣe òpìtàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ gbà pẹ̀lú rẹ̀, ó ní: “Láti ọdún 1914 ni ìlànà ìwà híhù táa kà sí ti ọmọlúwàbí nígbà yẹn ti bà jẹ́ pátápátá nínú àwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà . . . Kò rọrùn láti lóye báa ṣe tètè padà kánmọ́kánmọ́ báyẹn sídìí ohun tí kò ní yàtọ̀ sí ìwà ẹhànnà lójú àwọn baba ńlá wa tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún.”

Nínú ìwé Humanity—A Moral History of the Twentieth Century, òǹṣèwé náà, Jonathan Glover sọ pé: “Ọ̀kan lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó gbàfiyèsí lákòókò tiwa ni bí òfin ìwà rere ṣe ń kásẹ̀ nílẹ̀.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò dá a lójú pé òfin ìwà rere ṣì wà, nítorí bí ẹ̀sìn ṣe ń wọ̀ọ̀kùn ní Ìwọ̀ Oòrùn ayé, síbẹ̀ ó kìlọ̀ pé: “Àwa tí kò gbà pé òfin ìwà rere ti ẹ̀sìn wúlò, ṣì ní láti banú jẹ́ gidigidi pé irú òfin bẹ́ẹ̀ ti ń pòórá.”

Àìfọkàntánni tó gbòde kan lóde òní—ì báà jẹ́ nínú iṣẹ́ ajé, tàbí ìṣèlú, tàbí ẹ̀sìn, tàbí nínú àjọṣe àárín ẹnì kìíní kejì àti láàárín àwọn mẹ́ńbà ìdílé pàápàá—àti wàhálà tó ti dá sílẹ̀, jẹ́ ara ètekéte Èṣù láti mú ègbé wá sórí àwọn olùgbé ayé. Sátánì ti pinnu láti ja ìjà àjàkú-akátá àti láti mú gbogbo àwọn tó ń gbìyànjú láti gbé níbàámu pẹ̀lú ìlànà Ọlọ́run dání pẹ̀lú ara rẹ̀ lọ sí ìparun.—Ìṣípayá 12:17.

Ǹjẹ́ ọ̀ràn àìfọkàntánni tó gbòde kan yìí ní ojútùú? Àpọ́sítélì Pétérù dáhùn pé: “Ṣùgbọ́n ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí [Ọlọ́run], nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.” (2 Pétérù 3:13) A lè gbẹ́kẹ̀ lé ìlérí yẹn nítorí pé kì í ṣe kìkì pé Ọlọ́run ní agbára láti mú ète rẹ̀ ṣẹ nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún mú un dá wa lójú pé òun yóò mú un ṣẹ. Ní ti ‘ọ̀rọ̀ èyíkéyìí tó bá ti ẹnu Jèhófà jáde,’ ó kéde pé: “Kì yóò padà sọ́dọ̀ mi láìní ìyọrísí, ṣùgbọ́n ó dájú pé yóò ṣe èyí tí mo ní inú dídùn sí, yóò sì ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tí mo tìtorí rẹ̀ rán an.” Ìlérí yìí mà ṣeé gbíyè lé o!—Aísáyà 55:11; Ìṣípayá 21:4, 5.

Gbígbé Níbàámu Pẹ̀lú Ìlànà Ọlọ́run

Nínú ayé tí ìlànà rẹ̀ kò dúró sójú kan, tó sì ń díbàjẹ́ yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sapá láti gbé níbàámu pẹ̀lú ìlànà ìwà híhù tó wà nínú Bíbélì. Ìyẹn ló jẹ́ kí wọ́n yàtọ̀ pátápátá sáwọn ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn, àwọn èèyàn sì ń ṣàkíyèsí wọn, àti nígbà mìíràn, wọ́n ń pẹ̀gàn wọn.

Níbi àpéjọpọ̀ kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní London, oníròyìn kan láti iléeṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n kan béèrè lọ́wọ́ ọ̀kan lára aṣojú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbẹ̀ bóyá Kristẹni ni wọ́n lóòótọ́. Ó dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Kristẹni àtàtà ni wá, nítorí pé Jésù ni àwòkọ́ṣe wa. Ìmọtara-ẹni-nìkan pọ̀ nínú ayé yìí, ìdí nìyẹn táa fi ń wo Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà, òtítọ́, àti ìyè. A gbà gbọ́ pé òun ni Ọmọ Ọlọ́run, pé kì í ṣe apá kan Mẹ́talọ́kan, nítorí náà báa ṣe lóye Bíbélì yàtọ̀ sí báwọn ẹ̀sìn ńláńlá ṣe lóye rẹ̀.”

Nígbà tí wọ́n gbé ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwò náà jáde lórí tẹlifíṣọ̀n BBC, oníròyìn náà kádìí ètò náà nílẹ̀ nípa sísọ pé: “Mo ti kọ́ ohun púpọ̀ nípa ìdí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi wá ń kanlẹ̀kùn wa. Mi ò sì rò pé mo tíì rí ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25,000] èèyàn rí, tí gbogbo wọn múra dáadáa báyẹn, tí gbogbo wọn jẹ́ ọmọlúwàbí, tí gbogbo wọn sì jọ wà pa pọ̀ níbì kan náà àti nígbà kan náà.” Láìsí àní-àní, ẹ̀rí tó dáa mà nìyí o látọ̀dọ̀ ará ìta, tó sì fi hàn pé ó mọ́gbọ́n dání láti tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run tí kì í yí padà!

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan lè kórìíra gbígbé níbàámu pẹ̀lú ìlànà tí ẹlòmíì gbé kalẹ̀, a rọ̀ ẹ́ pé kí o yíjú sí Bíbélì rẹ, kí o sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìlànà Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n má fi mọ sórí wíwulẹ̀ yẹ̀ ẹ́ wò lóréfèé. Tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, pé: “Jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí, ṣùgbọ́n ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín padà, kí ẹ lè ṣàwárí fúnra yín ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.” (Róòmù 12:2) Lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ládùúgbò rẹ, kí o sì di ojúlùmọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀. Wàá rí i pé èèyàn bíi tìrẹ ni wọ́n, tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìlérí Bíbélì, tí wọ́n sì fi hàn pé àwọn fọkàn tán Ọlọ́run nípa gbígbìyànjú láti gbé níbàámu pẹ̀lú ìlànà rẹ̀.

Rírọ̀ mọ́ ìlànà Ọlọ́run tí kì í yí padà, tó sì ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé nínú ìgbésí ayé rẹ yóò mú ìbùkún wá fún ọ dájúdájú. Kọbi ara sí ìkésíni Ọlọ́run pé: “Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fetí sí àwọn àṣẹ mi ní tòótọ́! Nígbà náà, àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò, òdodo rẹ ì bá sì dà bí ìgbì òkun.”—Aísáyà 48:18.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Lónìí, àìfọkàntánni wà nínú iṣẹ́ ajé, ìṣèlú, ẹ̀sìn, àti àjọṣe láàárín ìdílé