Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

APÁ KẸRIN

Bí Ẹ Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná

Bí Ẹ Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná

“Ìmọ̀ràn ni a fi ń fìdí àwọn ìwéwèé múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.”Òwe 20:18

Gbogbo wa la nílò owó ká lè pèsè àwọn ohun tí ìdílé wa nílò. (Òwe 30:8) Ó ṣe tán, ‘owó jẹ́ fún ìdáàbòbò.’ (Oníwàásù 7:12) Ó lè ṣòro fún tọkọtaya láti jọ máa sọ̀rọ̀ nípa owó, àmọ́ ẹ má ṣe jẹ́ kí owó dá wàhálà sílẹ̀ láàárín yín. (Éfésù 4:32) Ó yẹ kí tọkọtaya fọkàn tán ara wọn, kí wọ́n sì jọ máa pinnu bí wọ́n ṣe fẹ́ ná owó.

1 Ẹ FARA BALẸ̀ ṢÈTÒ ÌNÁWÓ YÍN

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Ta ni nínú yín tí ó fẹ́ kọ́ ilé gogoro kan tí kò ní kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbéṣirò lé ìnáwó náà, láti rí i bí òun bá ní tó láti parí rẹ̀?” (Lúùkù 14:28) Ó ṣe pàtàkì pé kí ẹ jọ máa ṣètò bí ẹ ṣe máa ná owó yín. (Ámósì 3:3) Ẹ jọ pinnu ohun tó yẹ kí ẹ rà àti iye tí ẹ máa lè ná. (Òwe 31:16) Má kàn máa ra ohun tí o bá rí torí pé owó wà lọ́wọ́ rẹ. Má ṣe tọrùn bọ gbèsè. Má ṣe ná ju owó tí o ní lọ.Òwe 21:5; 22:7.

OHUN TÍ O LÈ ṢE:

  • Tí owó bá ṣẹ́ kù sí yín lọ́wọ́ ní ìparí oṣù, ẹ jọ pinnu ohun tí ẹ máa fi ṣe

  • Tí iye tí ẹ ná bá pọ̀ ju iye tó wọlé fún yín, ẹ ṣètò bí ẹ ṣe máa dín ìnáwó yín kù. Bí àpẹẹrẹ, ẹ máa se oúnjẹ fúnra yín dípò kí ẹ máa ra oúnjẹ jẹ

2 Ẹ MÁA FINÚ HAN ARA YÍN, Ẹ MÁ SÌ ṢE JU ARA YÍN LỌ

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: Máa fi òtítọ́ ṣe ohun gbogbo “kì í ṣe níwájú Jèhófà nìkan, ṣùgbọ́n níwájú àwọn ènìyàn pẹ̀lú.” (2 Kọ́ríńtì 8:21) Ẹ má fi ohunkóhun pa mọ́ fún ara yín nípa iye tó ń wọlé fún yín àti bí ẹ ṣe ń náwó.

Rí i dájú pé ò ń fọ̀rọ̀ lọ ọkọ tàbí aya rẹ tí o bá fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì tó jẹ mọ́ ìnáwó. (Òwe 13:10) Àlàáfíà máa wà láàárín yín tí ẹ bá jọ ń sọ̀rọ̀ nípa ìnáwó yín. Ṣe ni kí o gbà pé ẹ̀yin méjèèjì lẹ ni owó tó ń wọlé fún ẹ, kì í ṣe tìẹ nìkan.1 Tímótì 5:8.

OHUN TÍ O LÈ ṢE:

  • Ẹ jọ fẹnu kò lórí iye tí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín lè ná láìsọ fún ẹnì kejì

  • Ẹ má ṣe dúró dìgbà tí bùkátà bá délẹ̀ kí ẹ tó jọ sọ̀rọ̀ nípa owó