Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÌGBÉYÀWÓ

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÌGBÉYÀWÓ Bí Ẹ Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÌGBÉYÀWÓ Bí Ẹ Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

Nígbà tó o wo àkọsílẹ̀ owó rẹ tó wà ní báńkì àtàwọn gbèsè míì tó o fẹ́ san, o wá rí i pé owó ò dúró sọ́wọ́ rẹ rárá. Kò tíì pẹ́ tẹ́ ẹ ṣègbéyàwò, àmọ́ ẹ ti náwó kọjá bó ṣe yẹ. Ṣé ẹ̀bi ọkọ tàbí ìyàwó rẹ ni? Kọ́kọ́ fara balẹ̀ ná, má sọ pé ẹnì kan ló jẹ̀bí! Ńṣe ni kẹ́ ẹ ronú pa pọ̀, kẹ́ ẹ sì sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó ṣeé ṣe kó fà á tí ẹ̀yin méjèèjì fi kó sí ìṣòro yìí. a

ÌDÍ TÓ FI MÁA Ń ṢẸLẸ̀

Ìyípadà. Tó bá jẹ́ pé ọ̀dọ̀ àwọn òbí ẹ lò ń gbé kó o tó ṣègbéyàwó, ọ̀rọ̀ pé kéèyàn máa sanwó tibí sanwó tọ̀hún lè ṣàjèjì sí ẹ. Ó tún lè ṣàjèjì sí ẹ pé kí ìnáwó da ìwọ àtẹnì kan pọ̀. Ó sì lè jẹ́ pé èrò ìwọ àti ọkọ tàbí ìyàwó rẹ yàtọ̀ síra tó bá kan ọ̀rọ̀ owó. Bí àpẹẹrẹ, ó lè jẹ́ pé ọ̀kan nínú ẹ̀yin méjèèjì fẹ́ràn kó ṣáà máa náwó, nígbà tó jẹ́ pé èkejì fẹ́ràn kó máa fowó pa mọ́. Ó máa gba àkókò díẹ̀ kí tọkọtaya tó lè ṣe ìyípadà tó yẹ, kí wọ́n sì jọ fohùn ṣọ̀kan nípa bí wọ́n ṣe fẹ́ máa náwó.

Ṣe ni gbèsè dà bíi koríko tó ń hù sínú ọ̀gbà, téèyàn ò bá ti wá nǹkan ṣe sí i, ṣe lá máa pọ̀ sí i

Fífi nǹkan falẹ̀. Ọkùnrin oníṣòwò kan tó rí tajé ṣe tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jim sọ pé, nígbà tí òun ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó òun ò mọ bí wọ́n ṣe ń ṣètò nǹkan, ìyẹn sì ṣàkóbá fún òun. Ó wá fi kún un pé: “Torí pé mi ò tètè lọ san àwọn owó tá a jẹ, ẹgbẹẹgbẹ̀rún dọ́là ni èmi àti ìyàwó mi fi san owó èlé, owó wá tán lọ́wọ́ wa.”

Ohun tí ẹ ò fúra sí pé ó ń gbé owó lọ. Tí kì í bá ṣe pé èèyàn ń yọ owó lápò ra nǹkan, ó rọrùn láti ná ju iye téèyàn fẹ́ ná lọ. Èyí lè ṣẹlẹ̀ tó bá jẹ́ pé káàdì tí wọ́n fi ń rajà láwìn tàbí èyí tí owó wà lórí rẹ̀ lẹ fi ń rajà, tàbí tí ẹ̀ ń rajà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Yàtọ̀ síyẹn, ó rọrùn fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó láti tọrùn bọ gbèsè, èyí sì máa ń mú kí wọ́n náwó ju bó ṣe yẹ lọ.

Ohun yòówù kó fà á, ọ̀rọ̀ owó lè dá wàhálà sílẹ̀ nínú ìgbéyàwó. “Ìwé kan tó ń jẹ́ Fighting for Your Marriage, tó dá lórí ohun téèyàn lè ṣe tí ìgbéyàwó rẹ̀ ò fi ní tú ká sọ pé: “Kò sí bí tọkọtaya kan ṣe lè lówó tó, ọ̀rọ̀ owó ṣì ni èyí tó pọ̀ jù nínú wọn sọ pé ó jẹ́ olórí ìṣòro àwọn. Owó ló sábà máa ń fa ìjà láàárín tọkọtaya.”

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Ẹ pinnu láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀. Dípò kí ẹ máa dá ara yín lẹ́bi, ńṣe ni kẹ́ ẹ jọ sọ̀rọ̀ lórí bí ẹ ṣe lè máa ṣọ́wó ná. Láti ìbẹ̀rẹ̀ ìjíròrò yín ni kí ẹ ti jọ pinnu pé ẹ kò ní jẹ́ kí owó dá ìjà sílẹ̀ láàárín yín.—Ìlànà Bíbélì: Éfésù 4:32.

Ẹ ṣètò ìnáwó yín. Lóṣooṣù, ẹ kọ gbogbo ìnáwó tí ẹ fẹ́ ṣe sílẹ̀, títí dórí ìnáwó tó kéré jù. Ìyẹn á jẹ́ kí ẹ rí ibi tí ẹ ń ná owó yín sí, ẹ tún máa mọ àwọn ohun tí kò pọn dandan tí ẹ ń náwó lé lórí. Èyí á sì jẹ́ kí owó máa dúró lọ́wọ́ yín.

Ẹ kọ àwọn ìnáwó tó pọn dandan tí ẹ fẹ́ ṣe sílẹ̀, irú bí owó oúnjẹ, aṣọ, owó ilé, ìnáwó lórí ọkọ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹ kọ iye owó tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ma ná yín sílẹ̀, bóyá lóṣooṣù.—Ìlànà Bíbélì: Lúùkù 14:28.

‘Ajigbèsè ni ìránṣẹ́ onígbèsè.’—Òwe 22:7, Bibeli Mimọ

Ẹ máa tọ́jú owó fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ohun tí ẹ ti kọ sílẹ̀ (oúnjẹ, owó ilé, owó pẹtiróòlù àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ). Ohun tí àwọn kan máa ń ṣe ni pé wọ́n ti ní àpòòwé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún àwọn ìnáwó yìí, wọ́n sì máa ń fi owó sínú ọ̀kọ̀ọ̀kàn wọn. b Tí owó bá ti tán nínú àpòòwé kan, wọ́n lè pa ìnáwó yẹn tì tàbí kí wọ́n yọ owó láti inú àpòòwé míì sínú èyí tí owó inú ẹ̀ ti tán.

Ronú dáadáa nípa ọwọ́ tí o fi mú àwọn nǹkan ìní. Àwọn nǹkan ìgbàlódé téèyàn ní kọ́ ló ń fúnni láyọ̀. Ó ṣe tán, Jésù sọ pé: “Tí ẹnì kan bá tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu pàápàá, ìwàláàyè rẹ̀ kò wá láti inú àwọn ohun tí ó ní.” (Lúùkù 12:15) Lọ́pọ̀ ìgbà, bó o ṣe ń náwó ló máa fi hàn bóyá o gba ọ̀rọ̀ ti Jésù sọ yìí gbọ́ lóòótọ́.—Ìlànà Bíbélì: 1 Tímótì 6:8.

Ṣe àwọn àyípadà. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Aaron tó ti tó ọdún méjì tó ti ṣègbéyàwó sọ pé: “Àwọn ìkànnì tẹlifíṣọ̀n téèyàn ń sanwó ẹ̀ àti kéèyàn máa lọ jẹun nílé oúnjẹ lè má kọ́kọ́ dà bíi pé ó nira, àmọ́ wọ́n máa ń gbọ́nni lówó lọ. Àmọ́ ní báyìí, èmi àti ìyàwó mi ti gbà pé àwọn nǹkan kan wà tí a kò ni máa náwó lé lórí mọ́, torí ká lè máa ṣọ́wó ná.”

a Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó ni a darí àpilẹ̀kọ yìí sí, gbogbo àwọn tọkọtaya ni àwọn ìlànà tó wà níbẹ̀ wúlò fún.

b Tó bá jẹ́ pé orí ẹ̀rọ lo ti máa ń sanwó tàbí tó jẹ́ pé káàdì tí wọ́n fi ń rajà láwìn ni ò ń lò, àkọsílẹ̀ gbogbo ìnáwó tó ò ń ṣe ni kó o fi sínú àpòòwé kọ̀ọ̀kan.