Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀

O lè ní ìgbeyàwó àti ìdílé tó láyọ̀ tó o bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò.

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú

O lè ní ìgbéyàwó àti ìdílé tó láyọ̀ tó o bá fi àwọn ìlànà Bíbélì tó wà nínú ìwé pẹlẹbẹ yìí sílò.

APÁ 1

Ẹ Jẹ́ Kí Ọlọ́run Ràn Yín Lọ́wọ́ Kí Ẹ Lè Jẹ́ Tọkọtaya Aláyọ̀

Ìbéèrè méjì wà tó rọrùn tó o lè bi ara ẹ tó máa jẹ́ kó o rí ohun tó o lè ṣe kí ìgbéyàwó ẹ lè túbọ̀ láyọ̀.

APÁ 2

Ẹ Jẹ́ Olóòótọ́ sí Ara Yín

Ṣé tí ẹnì kan bá ṣáà ti ń sá fún ìṣekúṣe, ó ti jẹ́ olóòótọ́ sí ẹnì kejì rẹ̀ nìyẹn?

APÁ 3

Bí Ẹ Ṣe Lè Máa Yanjú Ìṣòro

Ọwọ́ téèyàn bá fi mu ìgbeyàwó ló máa pinnu bóyá ìgbeyàwó èèyàn á dún, kó sì láyọ̀ tàbí á kan, kó sì nira.

APÁ 4

Bí Ẹ Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná

Àǹfààní wo lo wà nínú kẹ́ ẹ máa sọ òótọ́ fún ara yín, kẹ́ ẹ sì fọkàn tán ara yín?

APÁ 5

Bí Ẹ Ṣe Lè Jẹ́ Kí Àlàáfíà Jọba Láàárín Ẹ̀yin Àtàwọn Mọ̀lẹ́bí Yín

O lè bọ̀wọ̀ fún àwọn òbí rẹ, síbẹ̀ kí ìyẹn má da ìgbéyàwó rẹ rú.

APÁ 6

Bí Ọmọ Ṣe Ń Yí Nǹkan Pa Dà Láàárín Tọkọtaya

Ṣé ọmọ bíbí lè mú kí ìgbéyàwó rẹ sunwọ̀n sí i?

APÁ 7

Bí O Ṣe Lè Máa Kọ́ Ọmọ Rẹ

Ìbáwí kọjá kéèyàn kàn máa ṣòfin, kó sì máa fìyà jẹ ẹni tó bá rú u.

APÁ 8

Nígbà tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀

Wá ìrànlọ́wọ́ tó yẹ.

APÁ 9

Ẹ Jọ Máa Sin Jèhófà Nínú Ìdílé Yín

Báwo lo ṣe lè túbọ̀ gbádùn ìjọsìn ìdílé rẹ?