Émọ́sì 3:1-15

  • Ìkéde ìdájọ́ Ọlọ́run (1-8)

    • Ọlọ́run ń fi àṣírí ọ̀rọ̀ rẹ̀ hàn (7)

  • Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Samáríà (9-15)

3  “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nípa yín, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, nípa gbogbo ìdílé tí mo mú jáde kúrò nílẹ̀ Íjíbítì:   ‘Ẹ̀yin nìkan ni mo mọ̀ nínú gbogbo ìdílé tó wà láyé.+ Ìdí nìyẹn tí màá fi mú kí ẹ jíhìn nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín.+   Ǹjẹ́ àwọn méjì lè jọ rìn láìjẹ́ pé wọ́n ṣe àdéhùn?*   Ǹjẹ́ kìnnìún máa ké ramúramù nínú igbó láìjẹ́ pé ó ti rí ẹran tó fẹ́ pa? Ǹjẹ́ ọmọ kìnnìún* máa kùn hùn-ùn láti ibi tó fara pa mọ́ sí láìjẹ́ pé ọwọ́ rẹ̀ ti tẹ nǹkan kan?   Ǹjẹ́ ẹyẹ lè kó sí pańpẹ́ lórí ilẹ̀ láìjẹ́ pé ẹnì kan ti dẹ pańpẹ́ náà?* Ṣé pańpẹ́ lè ré lórí ilẹ̀ nígbà tí kò tíì mú nǹkan kan?   Tí èèyàn bá fun ìwo nínú ìlú, ǹjẹ́ àyà àwọn ará ìlú kò ní já? Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ nínú ìlú, ǹjẹ́ kì í ṣe Jèhófà ló fà á?   Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ kò ní ṣe ohunkóhunLáìjẹ́ pé ó ti fi àṣírí ọ̀rọ̀ náà* han àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ wòlíì.+   Kìnnìún ti ké ramúramù!+ Ta ni kò ní bẹ̀rù? Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ti sọ̀rọ̀! Ta ni kò ní sọ tẹ́lẹ̀?’+   ‘Ẹ kéde rẹ̀ lórí àwọn ilé gogoro tó láàbò ní ÁṣídódìÀti lórí àwọn ilé gogoro tó láàbò nílẹ̀ Íjíbítì. Ẹ sọ pé: “Ẹ kóra jọ sórí àwọn òkè Samáríà;+Ẹ wo ìdàrúdàpọ̀ tó wà ní àárín rẹ̀ Àti jìbìtì tó wà nínú rẹ̀.+ 10  Nítorí wọn kò mọ bí a ti ń ṣe ohun tí ó tọ́,” ni Jèhófà wí,“Àwọn tó ń mú ìwà ipá àti ìparun pọ̀ sí i nínú àwọn ilé gogoro wọn tó láàbò.”’ 11  Nítorí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí,‘Ọ̀tá kan máa yí ilẹ̀ náà ká,+Á sì mú kí agbára rẹ tán,Ohun tó wà nínú àwọn ilé gogoro rẹ tó láàbò ni wọ́n á sì kó lọ.’+ 12  Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,‘Bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe ń já ẹsẹ̀ méjì tàbí etí kan gbà kúrò lẹ́nu kìnnìún,Bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe já àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà,Àwọn tó ń jókòó sórí ibùsùn rèǹtèrente àti sórí àga ìnàyìn tó rẹwà* ní Samáríà.’+ 13  ‘Ẹ gbọ́, kí ẹ sì kìlọ̀ fún* ilé Jékọ́bù,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí. 14  ‘Ní ọjọ́ tí màá mú kí Ísírẹ́lì jíhìn nítorí ìdìtẹ̀* rẹ̀,+Ni màá mú kí àwọn pẹpẹ Bẹ́tẹ́lì pẹ̀lú jíhìn;+A ó ṣẹ́ àwọn ìwo pẹpẹ náà, wọ́n á sì já bọ́ sílẹ̀.+ 15  Màá wó ilé ìgbà òtútù àti ilé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn lulẹ̀.’ ‘Àwọn ilé tí wọ́n fi eyín erin kọ́ á ṣègbé,+Àwọn ilé ńlá* á sì pa run,’+ ni Jèhófà wí.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “wọ́n pàdé bí wọ́n ṣe ṣàdéhùn?”
Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”
Tàbí kó jẹ́, “láìjẹ́ pé ìdẹ wà nínú rẹ̀?”
Tàbí “àṣírí rẹ̀.”
Tàbí “àga ìnàyìn ará Damásíkù.”
Tàbí “jẹ́rìí lòdì sí.”
Tàbí “ìwà ọ̀daràn.”
Tàbí kó jẹ́, “Ọ̀pọ̀ ilé.”