Ohun Tí Bíbélì Sọ
Kí ni Jésù máa ṣe lọ́jọ́ iwájú?
Jésù kú ní ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ó jíǹde, ó sì pa dà sí ọ̀run. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, Ọlọ́run fún un láṣẹ láti máa ṣàkóso bí Ọba. (Dáníẹ́lì 7:13, 14) Lọ́jọ́ iwájú, Jésù máa lo agbára tó ní gẹ́gẹ́ bí Ọba láti mú kí àlááfíà wà kárí ayé, kí ipò òṣì sì di ohun ìgbàgbé.—Ka Sáàmù 72:7,8, 13.
Jésù máa lo agbára to ní gẹ́gẹ́ bí Ọba láti mú ìwà búburú kúrò ní ayé
Jésù máa ṣe àwọn nǹkan àgbàyanu nígbà tó bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ayé. Á lo agbára tí Ọlọ́run fún un láti sọ àwọn èèyàn di pípé. Wọ́n sì máa gbádùn lórí ilẹ̀ ayé títí láé, níbi tí wọn ò ti ní darúgbó, tí wọn ò sì ní kú mọ́.—Ka Jòhánù 5:26-29; 1 Kọ́ríńtì 15:25, 26.
Kí ni Jésù ń ṣe nísinsìnyí?
Jésù ló ń darí iṣẹ́ ìwàásù tí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ olóòótọ́ ń ṣe kárí ayé báyìí. Wọ́n máa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn láti fi ohun tí Bíbélì sọ nípa Ìjọba Ọlọ́run hàn wọ́n. Jésù wá ṣèlérí fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé òun máa tì wọ́n lẹ́yìn kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ yìí títí di ìgbà tí Ìjọba Ọlọ́run máa pa gbogbo ìjọba èèyàn run.—Ka Mátíù 24:14; 28:19, 20.
Jésù ń lo ìjọ Kristẹni tòótọ́ láti kọ́ àwọn èèyàn ní ọ̀nà ìgbésí ayé tó dára jùlọ. Á sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè la ìparun tó ń bọ̀ sórí ayé búburú yìí já, kí wọ́n sì wọ inú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí.—Ka 2 Pétérù 3:7, 13; Ìṣípayá 7:17.