Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan Wà Nínú Bíbélì?

Ǹjẹ́ Ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan Wà Nínú Bíbélì?

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .

Ǹjẹ́ Ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan Wà Nínú Bíbélì?

▪ Ọ̀kan lára ohun tí àwọn èèyàn sábà máa ń sọ pé ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan túmọ̀ sí ni pé: “Àwọn Ẹni mímọ́ mẹ́ta ló wà (Baba, Ọmọ, Ẹ̀mí Mímọ́), wọ́n ní ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn jẹ́ ẹni ayérayé, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn jẹ́ Olódùmarè, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta bára dọ́gba, ọ̀kan kò ju èkejì lọ, pé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì jẹ́ Ọlọ́run, síbẹ̀ gbogbo wọn para pọ̀ jẹ́ Ọlọ́run kan ṣoṣo.” Ǹjẹ́ èyí bá ẹ̀kọ́ Bíbélì mu?

Ìwé Mátíù 28:19 ni àwọn èèyàn sábà máa ń fi ti ẹ̀kọ́ yìí lẹ́yìn. Nínú Bíbélì Mímọ́, Jésù sọ nínú ẹsẹ yẹn pé: “Nitorina ẹ lọ, ẹ ma kọ́ orilẹ-ède gbogbo, ki ẹ si ma baptisi wọn li orukọ Baba, ati ni ti Ọmọ, ati ni ti Ẹmí Mimọ́.” Lóòótọ́, ẹsẹ Bíbélì yìí mẹ́nu kan Baba, Ọmọ àti ẹ̀mí mímọ́. Àmọ́ ẹsẹ yìí kò sọ pé àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta jẹ́ ẹyọ kan ṣoṣo. Ṣe ni Jésù ń pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó jẹ́ Júù pé kí wọ́n máa kọ́ àwọn èèyàn kí wọ́n sì máa batisí wọn ní orúkọ Baba, Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́. Kí ni àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè Júù gbà gbọ́?

Nígbà tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì gba májẹ̀mú Òfin Mósè, èyí tó wà nínú Bíbélì, ara òfin tí wọ́n gbà ni pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ní àwọn ọlọ́run mìíràn níṣojú mi láé.” (Diutarónómì 5:7) Ẹni mélòó ló ń bá wọn sọ̀rọ̀ nínú ẹsẹ Bíbélì yìí? Ìwé Diutarónómì 6:4 sọ ọ́ lọ́nà tó ṣe kedere, ó ní: “Fetí sílẹ̀, ìwọ Ísírẹ́lì: Jèhófà Ọlọ́run wa, Jèhófà kan ṣoṣo ni,” kò sọ pé Ọlọ́run mẹ́talọ́kan ni. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ṣe ni Ọlọ́run ṣẹ̀ṣẹ̀ dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò ní Íjíbítì níbi tí àwọn èèyàn ti ń sin àwọn ọlọ́run mẹ́ta-mẹ́ta tó wà pa pọ̀. Hórúsì, Ósírísì àti Ísísì (tó wà ní àwòrán apá òsì) sì jẹ́ ọ̀kan nínú irú ọlọ́run mẹ́ta bẹ́ẹ̀. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé Ọlọ́run kan ṣoṣo ni kí wọ́n máa sìn. Báwo ló ti ṣe pàtàkì tó pé kí àwọn èèyàn lóye òfin yìí? Rábì kan, ìyẹn dókítà J. H. Hertz, sọ pé: “Bí Ọlọ́run ṣe kéde rẹ̀ gbangba gbàǹgbà yìí pé Ọlọ́run kan ṣoṣo ni kí wọ́n máa sìn, ṣe ló fi hàn pé òun ka sísin ọ̀pọ̀ ọlọ́run léèwọ̀ . . . Shema [ìyẹn ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ àwọn Júù] kò fàyè gba ẹ̀kọ́ Ọlọ́run mẹ́talọ́kan tí wọ́n fi sínú ẹ̀kọ́ àwọn Kristẹni rárá, torí ó lòdì sí jíjẹ́ tí Ọlọ́run jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo.” *

Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé inú ẹ̀yà Júù ni wọ́n bí Jésù sí, òfin yìí kan náà ni wọ́n fi kọ́ ọ. Lẹ́yìn tí Jésù ṣe ìrìbọmi, tí Èṣù wá dán an wò, ó sọ fún Èṣù pé: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì! Nítorí a kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún.’” (Mátíù 4:10; Diutarónómì 6:13) Ó kéré tán, a lè rí ohun méjì kọ́ látinú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Àkọ́kọ́, ṣe ni Sátánì fẹ́ tan Jésù kó lè jọ́sìn òun dípò tí yóò fi máa jọ́sìn Jèhófà. Ká ní apá kan lára Ọlọ́run kan ṣoṣo yẹn ni Jésù jẹ́ ni, ohun tí Sátánì fẹ́ kó ṣe yẹn kò ní bọ́gbọ́n mu rárá. Ìkejì, nígbà tí Jésù sọ pé “òun nìkan ṣoṣo” nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn, tí kò sọ pé “àwa nìkan ṣoṣo,” ńṣe ni Jésù ń mú kó ṣe kedere pé Ọlọ́run kan ṣoṣo ló wà, èyí tó yẹ ká máa sìn. Ká ní Jésù jẹ́ ara Ọlọ́run Mẹ́talọ́kan ni, ì bá sọ pé “àwa nìkan ṣoṣo.”

Tí àwọn èèyàn bá ti ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run, tí wọ́n sì ṣe tán láti máa sìn ín, wọ́n máa ń batisí wọn “ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́.” (Mátíù 28:19) Àwọn yẹn á ti mọ̀ pé Jèhófà ni Aláṣẹ gíga jù, wọ́n á sì gbà bẹ́ẹ̀, wọ́n á sì tún mọ̀ pé Jésù Kristi ń kó ìpa pàtàkì nínú bí ète Jèhófà ṣe ń ṣẹ. (Sáàmù 83:18; Mátíù 28:18) Wọ́n á tún ti lóye ohun tí Ọlọ́run ń lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, tó jẹ́ ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀ fún, àti iṣẹ́ tó ń ṣe.—Jẹ́nẹ́sísì 1:2; Gálátíà 5:22, 23; 2 Pétérù 1:21.

Ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan ti ń rú ọ̀pọ̀ èèyàn lójú láti ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn. Ṣùgbọ́n ṣe ni Jésù la àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lóye ní tiẹ̀, tó sì darí wọn sọ́dọ̀ Jèhófà tó jẹ́ “Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà.”—Jòhánù 17:3.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ àwọn Júù pé ọ̀kan ṣoṣo ni Ọlọ́run, èyí tó wà nínú Ṣémà, ìyẹn àdúrà tó dá lórí Diutarónómì 6:4, jẹ́ apá pàtàkì lára ààtò ìsìn nínú sínágọ́gù.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 23]

Musée du Louvre, Paris