Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ohun Tó Ò Ń Gbèrò Kò Ta Ko Ìfẹ́ Ọlọ́run?

Ṣé Ohun Tó Ò Ń Gbèrò Kò Ta Ko Ìfẹ́ Ọlọ́run?

Ṣé Ohun Tó Ò Ń Gbèrò Kò Ta Ko Ìfẹ́ Ọlọ́run?

ẸYẸ akọrin aláwọ̀ ràkọ̀ràkọ̀ kan wà tó ń jẹ́ Clark’s nutcracker. Èèyàn lè rí ẹyẹ yìí bó ṣe ń fò káàkiri inú igbó níhà ìwọ̀ oòrùn Amẹ́ríkà Ti Àríwá. Ó máa ń kó èso tó pọ̀ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [33,000] jọ lọ́dún, ó sì máa ń tọ́jú wọn pa mọ́ sínú ilẹ̀ sí ọ̀nà tó tó ẹgbẹ̀rún méjì ààbọ̀. Ó ń ṣe èyí láti fi múra sílẹ̀ de ìgbà tí òtútù máa ń mú gan-an. Ká sòótọ́, ẹyẹ yìí ní “ọgbọ́n àdámọ́ni” tó fi lè ronú pé á dáa kóun kó oúnjẹ pa mọ́ torí ọjọ́ iwájú.—Òwe 30:24.

Ọgbọ́n téèyàn ní ga ju ìyẹn lọ fíìfíì. Nínú gbogbo ẹ̀dá tí Jèhófà dá sáyé, kò sí èyí tí ọgbọ́n ẹ̀ tó ti èèyàn tó bá dọ̀rọ̀ ká kẹ́kọ̀ọ́ látara ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, ká sì lo ohun tá a kọ́ yìí nígbà tá a bá ń wéwèé nípa ọjọ́ ọ̀la. Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n Ọba sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ni ìwéwèé tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ènìyàn.”—Òwe 19:21.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èèyàn lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, kò sóhun tá a lè ṣe ju pé ká gbé àwọn ìwéwèé wa karí ohun tá a rò pé ó lè ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la. Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan lè máa ronú nípa ohun tó máa ṣe lọ́la, ìyẹn tó bá ṣẹlẹ̀ pé ilẹ̀ ọ̀la mọ́ bá a láàyè. Ohun tó dájú ni pé ojúmọ́ ọ̀la máa mọ́, àmọ́ ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ dájú ni bóyá ẹnì náà máa dọ̀la. Òǹkọ̀wé Bíbélì kan tó ń jẹ́ Jákọ́bù la òótọ́ yìí mọ́lẹ̀ pé: “Ẹ kò mọ ohun tí ìwàláàyè yín yóò jẹ́ lọ́la.”—Jákọ́bù 4:13, 14.

Ọ̀rọ̀ ti Jèhófà Ọlọ́run ò rí báyẹn. Ó mọ “paríparí òpin” láti “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀.” Kò sí ohunkóhun tó máa dí ìfẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ kó má ṣẹ. Ó sọ pé: “Ìpinnu tèmi ni yóò dúró, gbogbo nǹkan tí mo bá sì ní inú dídùn sí ni èmi yóò ṣe.” (Aísáyà 46:10) Kí ló wá máa ṣẹlẹ̀ nígbà tí ohun téèyàn gbèrò bá ta ko ìfẹ́ Ọlọ́run?

Ibi Tó Máa Ń Já Sí Téèyàn Bá Ń Gbèrò Láìfi Ti Ọlọ́run Pè

Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́rin sẹ́yìn, àwọn tó kọ́ Ilé Gogoro Bábélì ń wá báwọn èèyàn ò ṣe ní tàn káàkiri ilẹ̀ ayé. Wọ́n sọ pé: “Ó yá! Ẹ jẹ́ kí a tẹ ìlú ńlá kan dó fún ara wa kí a sì tún kọ́ ilé gogoro tí téńté rẹ̀ dé ọ̀run, ẹ sì jẹ́ kí a ṣe orúkọ lílókìkí fún ara wa, kí a má bàa tú ká sórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”—Jẹ́nẹ́sísì 11:4.

Àmọ́, ìfẹ́ Ọlọ́run fún ilẹ̀ ayé yàtọ̀ pátápátá sí ìyẹn. Ó ti pàṣẹ fún Nóà àtàwọn ọmọ rẹ̀ pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 9:1) Kí ni Ọlọ́run ṣe sóhun táwọn ọlọ̀tẹ̀ ará Bábélì yìí ń gbèrò láti ṣe? Ó da èdè wọn rú kí wọ́n má bàa gbọ́ ara wọn yé. Kí ni àbájáde rẹ̀? Bíbélì sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ Jèhófà tú wọn ká kúrò níbẹ̀ sórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 11:5-8) Àwọn tó ń kọ́ Bábélì wá kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì kan tipátipá. Ẹ̀kọ́ náà ni pé: Tí ìwéwèé èèyàn bá ta ko ìfẹ́ Ọlọ́run, “ìmọ̀ràn Jèhófà ni yóò dúró.” (Òwe 19:21) Ǹjẹ́ ò ń kọ́gbọ́n látara irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ bó o ṣe ń pinnu ọ̀nà tí wàá gbà lo ìgbésí ayé rẹ?

Ọkùnrin Ọlọ́rọ̀ Kan Tí Kò Lọ́gbọ́n Nínú

Ìwọ lè má máa gbèrò àtikọ́ ilé gogoro, àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló ń gbèrò àtikó òbítíbitì owó gegere sínú àkáǹtì wọn, kí wọ́n sì kó ọrọ̀ jọ pelemọ kí wọ́n lè rí nǹkan fàbọ̀ bá nígbà tí wọ́n bá fẹ̀yìn tì. Kò sóhun tó burú nínú kéèyàn kó èrè ohun tó ti fàárọ̀ ọjọ́ ẹ̀ ṣe. Sólómọ́nì gan-an sọ pé: “Kí olúkúlùkù ènìyàn máa jẹ, kí ó sì máa mu ní tòótọ́, kí ó sì rí ohun rere nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀. Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni.”—Oníwàásù 3:13.

A máa jíhìn fún Jèhófà lórí ọ̀nà tá a bá gbà lo ẹ̀bùn yìí. Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn, Jésù tẹnu mọ́ kókó yìí fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nígbà tó sọ àpèjúwe kan fún wọn. Ó sọ pé: “Ilẹ̀ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan mú èso jáde dáadáa. Nítorí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí rò nínú ara rẹ̀, pé, ‘Kí ni èmi yóò ṣe, nísinsìnyí tí èmi kò ní ibì kankan láti kó àwọn irè oko mi jọ sí?’ Nítorí náà, ó wí pé, ‘Èyí ni èmi yóò ṣe: Ṣe ni èmi yóò ya àwọn ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ mi lulẹ̀, èmi yóò sì kọ́ àwọn tí ó tóbi, ibẹ̀ ni èmi yóò sì kó gbogbo ọkà mi jọ sí àti gbogbo àwọn ohun rere mi; ṣe ni èmi yóò sọ fún ọkàn mi pé: “Ọkàn, ìwọ ní ọ̀pọ̀ ohun rere tí a tò jọ pa mọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún; fara balẹ̀ pẹ̀sẹ̀, máa jẹ, máa mu, máa gbádùn.”’” (Lúùkù 12:16-19) Ó dà bíi pé ohun tí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yẹn ń gbèrò mọ́gbọ́n dání, àbí? Ńṣe ni ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yẹn ń múra sílẹ̀ de ọjọ́ ọ̀la, bíi ti ẹyẹ tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀.

Ṣùgbọ́n ohun kan wà tí kò mọ́gbọ́n dání nínú ọ̀nà tí ọkùnrin yẹn gbà ń ronú. Jésù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó sọ pé: “Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wí fún un pé, ‘Aláìlọ́gbọ́n-nínú, òru òní ni wọn yóò fi dandan béèrè ọkàn rẹ lọ́wọ́ rẹ. Ta ni yóò wá ni àwọn ohun tí ìwọ tò jọ pa mọ́?’” (Lúùkù 12:20) Ṣé Jésù ń ta ko ohun tí Sólómọ́nì ń sọ ni pé iṣẹ́ àti èrè rẹ̀ jẹ́ ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run? Rárá o. Kí wá ni Jésù fẹ́ fà yọ? Ó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni ó máa ń rí fún ẹni tí ó bá ń to ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara rẹ̀ ṣùgbọ́n tí kò ní ọrọ̀ síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”—Lúùkù 12:21.

Ohun tí Jésù ń kọ́ àwọn èèyàn ni pé Jèhófà fẹ́ ká máa ro ti Òun àti nǹkan tó jẹ́ ìfẹ́ Òun bá a ṣe ń gbèrò àwọn ohun tá a máa ṣe. Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yẹn ì bá lọ́rọ̀ sọ́dọ̀ Ọlọ́run tó bá jẹ́ pé ó ń wá báá ṣe túbọ̀ máa jọ́sìn Ọlọ́run dáadáa, táá sì máa ní ọgbọ́n àti ìfẹ́ sí i. Àmọ́, àwọn ọ̀rọ̀ tó ń jáde lẹ́nu ọkùnrin yẹn ò fi hàn pé ọkàn rẹ̀ wà nínú irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀, bákan náà, kò ronú pé kóun fi díẹ̀ lára àwọn irè oko òun sílẹ̀ káwọn aláìní lè rí nǹkan kó tàbí kóun fún Jèhófà ní ọrẹ ẹbọ ẹ̀bùn. Kò sóhun tó kan ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yẹn pẹ̀lú irú ìwà ọ̀làwọ́ tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu yìí. Gbogbo ohun tó ń rò kò ju bí yóò ṣe máa jayé orí rẹ̀ nínú ọlá ńlá pẹ̀lú ìdẹ̀ra.

Ǹjẹ́ o ti kíyè sí i pé ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló jẹ́ pé nǹkan tí wọ́n ń lé nígbèésí ayé tiwọn náà dà bíi ti ọkùnrin ọlọ́rọ̀ tí Jésù ṣàpèjúwe yìí? Bóyá a rí já jẹ àbí a ò rí já jẹ, ó rọrùn kí ìfẹ́ láti ní dúkìá àti ọrọ̀ dẹkùn mú wa, ká sì pa àjọṣe àárín àwa àti Ọlọ́run tì nítorí ohun tá a nílò àtohun tó máa ń wù wá láti ní nígbèésí ayé. Kí lo lè ṣe kó o máa bàa kó sínú ìdẹkùn yìí?

Gbígbìyànjú Láti Fi Ìgbésí Ayé Ẹni Ṣe Nǹkan Rere

Ìwọ́ lè má lówó lọ́wọ́ bíi ti ọkùnrin ọlọ́rọ̀ inú àpèjúwe Jésù, kó jẹ́ pé ńṣe lò ń yí i mọ́ ọn. Síbẹ̀, bó o bá ti gbéyàwó, ó dájú pé wàá máa gbèrò bó o ṣe máa pèsè àwọn ohun tó ṣe pàtàkì fún ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ, tó bá sì ṣeé ṣe, wàá fẹ́ káwọn ọmọ rẹ kàwé wọn lákàyanjú. Tó bá jẹ́ pé àpọ́n ni ẹ́, lára àwọn ohun tó o lè máa lépa ni bó o ṣe máa rí iṣẹ́ tàbí bí iṣẹ́ ò ṣe ní bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́ kó o má bàa di bùkátà sọ́rùn àwọn míì. Kò burú láti máa lépa nǹkan wọ̀nyí.—2 Tẹsalóníkà 3:10-12; 1 Tímótì 5:8.

Síbẹ̀, ṣíṣe àwọn nǹkan táwọn èèyàn kà sí ohun rere nígbèésí ayé, bíi ká rí jẹ, ká rí mu ká sì tún níṣẹ́ tó dáa lọ́wọ́, lè sún èèyàn sí ṣíṣe ohun tí kó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Lọ́nà wo? Jésù sọ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ọjọ́ Nóà ti rí, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn yóò rí. Nítorí bí wọ́n ti wà ní ọjọ́ wọnnì ṣáájú ìkún omi, wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó, a sì ń fi àwọn obìnrin fúnni nínú ìgbéyàwó, títí di ọjọ́ tí Nóà wọ ọkọ̀ áàkì; wọn kò sì fiyè sí i títí ìkún omi fi dé, tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn yóò rí.”—Mátíù 24:37-39.

Àwọn èèyàn tó wà ṣáájú Ìkún-omi gbà pé àwọn ń fi ìgbésí ayé àwọn ṣe ohun rere. Àmọ́, ìṣòro wọn ni pé “wọn kò fiyè sí” ìfẹ́ Ọlọ́run, ìyẹn ni láti fi àkúnya omi tó máa kárí ayé fọ ayé burúkú ìgbà yẹn mọ́. Ó dájú pé wọ́n á máa wò ó pé ńṣe ni Nóà kàn ń fi ayé ẹ̀ tàfàlà. Àmọ́, nígbà tí Ìkún-omi dé, ó wá ṣe kedere pé ọ̀nà tí Nóà àtàwọn ará ilé ẹ̀ gbà gbé ìgbésí ayé wọn ló bọ́gbọ́n mu jù lọ.

Lónìí, gbogbo ẹ̀rí tá a ń rí ló fi hàn pé àkókò òpin là ń gbé yìí. (Mátíù 24:3-12; 2 Tímótì 3:1-5) Láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run yóò “fọ́” ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí “túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn.” (Dáníẹ́lì 2:44) Lábẹ́ Ìjọba yẹn, ayé yóò di Párádísè. Àìsàn àti ikú kò ní sí mọ́. (Aísáyà 33:24; Ìṣípayá 21:3-5) Gbogbo ẹ̀dá tó bá ń gbé láyé yóò wà níṣọ̀kan, wọ́n á sì bọ́ lọ́wọ́ ebi.—Sáàmù 72:16; Aísáyà 11:6-9.

Àmọ́ kí Jèhófà tó gbégbèésẹ̀, ó fẹ́ ká kọ́kọ́ “wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mátíù 24:14) Níbàámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run yìí, nǹkan bíi mílíọ̀nù méje àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń wàásù ìhìn rere yìí ní ilẹ̀ igba ó lé mẹ́rìndínlógójì [236], ní èdè tó ju irínwó lọ.

Láwọn ọ̀nà kan, ìgbé ayé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè ṣàjèjì lójú àwọn èèyàn, kódà wọ́n lè máa fi wá ṣe yẹ̀yẹ́. (2 Pétérù 3:3, 4) Bíi táwọn tó ń gbé ṣáájú Ìkún-omi, púpọ̀ èèyàn lónìí ni kòókòó jàn-ánjàn-án ìgbésí ayé ń gba gbogbo àkókò wọn. Wọ́n lè máa wo ẹnikẹ́ni tí kò bá lo ìgbésí ayé ẹ̀ bíi tiwọn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí kò fayé ẹ̀ ṣe nǹkan rere. Ṣùgbọ́n lójú tàwọn tí wọ́n nígbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run, ẹní bá fìgbésí ayé ẹ̀ sin Ọlọ́run gan-an ló fayé ẹ̀ ṣe nǹkan rere.

Nítorí náà, bóyá ọlọ́rọ̀ ni ẹ́ tàbí tálákà tàbí kò-là-kò-ṣagbe, bó o ṣe ń gbèrò ohun tó o máa ṣe, ó bọ́gbọ́n mu pé kó o máa tún un yẹ̀ wò látìgbàdégbà. Bó o ṣe ń ṣe èyí, máa bi ara rẹ pé, ‘Ṣé ohun tí mò ń gbèrò àtiṣe kò ta ko ìfẹ́ Ọlọ́run?’

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Tí ìwéwèé èèyàn bá ta ko ìfẹ́ Ọlọ́run, ìmọ̀ràn Jèhófà ni yóò dúró

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ inú àkàwé Jésù kò gbé ìfẹ́ Ọlọ́run yẹ̀ wò nígbà tó ń gbèrò ohun tó máa ṣe