Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ o Lè Fúnra Rẹ Pinnu Ọjọ́ Ọ̀la rẹ?

Ǹjẹ́ o Lè Fúnra Rẹ Pinnu Ọjọ́ Ọ̀la rẹ?

Ǹjẹ́ o Lè Fúnra Rẹ Pinnu Ọjọ́ Ọ̀la rẹ?

ǸJẸ́ bí nǹkan ṣe máa rí fún wa nígbẹ̀yìn ti wà lákọọ́lẹ̀? Ṣé ohun tá a bá ṣe nísinsìnyí ló máa sọ bí ọjọ́ ọ̀la wa á ṣe rí?

Ká sọ pé ohun tá a bá ṣe lónìí ló máa sọ bí ọjọ́ ọ̀la wa á ṣe rí, ǹjẹ́ a tún lè sọ pé ohun tí kálukú máa dà tàbí ipò tó máa dé ti wà lákọọ́lẹ̀? Tí ẹ̀dá èèyàn bá sì lè pinnu àtúbọ̀tán wọn, báwo ni Ọlọ́run yóò ṣe mú ohun tó ní lọ́kàn fún ilẹ̀ ayé ṣẹ? Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí lọ́nà tó tẹ́ni lọ́rùn.

Ǹjẹ́ Àyànmọ́ àti Òmìnira Láti Yan Ohun Tó Wuni Bára Mu?

Ìwọ ronú nípa bí Jèhófà Ọlọ́run ṣe dá wa ná. Bíbélì sọ pé: “Àwòrán Ọlọ́run ni ó dá [ènìyàn]; akọ àti abo ni ó dá wọn.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Nítorí pé Ọlọ́run dá wa ní àwòrán ara rẹ̀, a láǹfààní àtiní àwọn ànímọ́ tó ní, irú bí ìfẹ́, ìdájọ́ òdodo, ọgbọ́n àti agbára. Ọlọ́run tún fún wa ní òmìnira láti yan ohun tó bá wù wá. Ìyẹn ló mú ká yàtọ̀ pátápátá sáwọn nǹkan mìíràn tó dá sórí ilẹ̀ ayé. A lè pinnu pé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run la máa tẹ̀ lé, a sì lè pinnu pé a ò ní tẹ̀ lé e. Ìdí nìyẹn tí wòlíì Mósè fi lè sọ pé: “Èmi ń fi ọ̀run àti ilẹ̀ ayé ṣe ẹlẹ́rìí lòdì sí yín lónìí, pé èmi ti fi ìyè àti ikú sí iwájú rẹ, ìbùkún àti ìfiré; kí o sì yan ìyè, kí o lè máa wà láàyè nìṣó, ìwọ àti ọmọ rẹ, nípa nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, nípa fífetí sí ohùn rẹ̀ àti nípa fífà mọ́ ọn.”—Diutarónómì 30:19, 20.

Àmọ́, bí Ọlọ́run ṣe fún wa lómìnira láti yan ohun tó wù wá kò túmọ̀ sí pé a lómìnira pátápátá o. Òmìnira yìí ò ní ká máa ta félefèle, kò sì sọ pé ká má tẹ̀ lé àwọn òfin tó sọ irú ìwà tó yẹ ká máa hù. Kí nǹkan lè máa lọ déédéé lágbàáyé kí àlàáfíà sì lè wà ni Ọlọ́run ṣe ṣe àwọn òfin yìí. Ńṣe ni Ọlọ́run fún wa láwọn òfin yẹn fún àǹfààní ara wa, tá a bá sì tàpá sí wọn pẹ́nrẹ́n, ìyà tó kọjá sísọ lè jẹ wá. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ọ tó o bá tàpá sí òfin òòfà, tó o wá bẹ́ látorí ilé tó ga fíofío!—Gálátíà 6:7.

Síwájú sí i, nítorí pé a lómìnira láti yan ohun tó wù wá, a ní ojúṣe pàtàkì kan táwọn ẹ̀dá tí wọn ò nírú òmìnira yìí kò ní. Òǹkọ̀wé Corliss Lamont béèrè pé: “Tá a bá gbà . . . pé gbogbo ohun táwọn èèyàn ń ṣe ló jẹ́ ohun tí Ọlọ́run ti kọ mọ́ wọn, ṣé ó yẹ ká máa ṣòfin pé ìwà báyìí ni wọ́n gbọ́dọ̀ hù ká sì máa fìyà jẹ wọ́n tí wọn ò bá pa òfin náà mọ́?” Dájúdájú, kò yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ohun tó wù káwọn ẹranko ṣe, wọn kì í káwọ́ pọ̀nyìn rojọ́. Ìdí ni pé wọn ò nírònú, gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe ni Ọlọ́run ti dá mọ́ wọn. Kò sì sẹ́ni tó lè dá kọ̀ǹpútà lẹ́bi pé kí ló dé tó fi ṣe ohun tí wọ́n ti ṣètò sínú rẹ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Nítorí náà, òmìnira tá a ní láti yan ohun tó bá wù wá mú kí iṣẹ́ bàǹtà-banta kan já lé wa léjìká, ìyẹn ni pé a óò dáhùn fún ohun tá a bá ṣe.

Ká sọ pé Jèhófà Ọlọ́run ti kọ gbogbo ohun tá a máa ṣe mọ́ wa kí wọ́n tó bí wa, tó tún wá fìyà jẹ wá nítorí pé a ṣe nǹkan ọ̀hún, ẹ ò rí i pé ńṣe lèyí máa fi hàn pé Ọlọ́run kì í ṣe onídàájọ́ òdodo àti onífẹ̀ẹ́? Àmọ́ Ọlọ́run kì í ṣe bẹ́ẹ̀ o, nítorí pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́,” ‘ìdájọ́ òdodo sì ni gbogbo ọ̀nà rẹ̀.’ (1 Jòhánù 4:8; Diutarónómì 32:4) Àwọn tó gba àyànmọ́ gbọ́ sọ pé Ọlọ́run ti ‘kọ ìgbàlà tàbí ìparun mọ́ kálukú wa láti ayérayé.’ Àmọ́, Ọlọ́run ò lè fún wa lómìnira láti yan ohun tó bá wù wá kó tún wá kọ ìgbàlà tàbí ìparun mọ́ wa. Níwọ̀n bí a ti ní òmìnira láti yan ohun tó bá wù wá, èyí túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ò yàn nǹkan kan mọ́ wa nìyẹn.

Bíbélì fi hàn kedere pé ohun tá a bá ṣe nísinsìnyí ni yóò pinnu ohun tí yóò jẹ́ àtúbọ̀tán wa. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run pàrọwà fún àwọn tó ń hùwà ibi pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ yí padà, olúkúlùkù kúrò nínú ọ̀nà búburú rẹ̀ àti kúrò nínú ìbálò búburú yín . . . kí n má [bàa] mú ìyọnu àjálù wá bá yín.” (Jeremáyà 25:5, 6) Ǹjẹ́ o rò pé àrọwà yìí wúlò ká ní Ọlọ́run ti kádàrá ohun tó máa jẹ́ ìgbẹ̀yìn kálukú tẹ́lẹ̀? Síwájú sí i, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Nítorí náà, ẹ ronú pìwà dà, kí ẹ sì yí padà, kí a lè pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́, kí àwọn àsìkò títunilára lè wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀.” (Ìṣe 3:19) Ǹjẹ́ o rò pé Jèhófà yóò sọ fáwọn èèyàn pé kí wọ́n ronú pìwà dà, tó bá jẹ́ pé ó ti kọ ìparun mọ́ wọn tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀?

Ìwé Mímọ́ sọ pé Ọlọ́run ní káwọn kan wá bá Jésù Kristi jọba ní ọ̀run. (Mátíù 22:14; Lúùkù 12:32) Àmọ́, Bíbélì sọ pé bí wọn ò bá ní ìforítì títí dópin, wọ́n á pàdánù àǹfààní yẹn. (Ìṣípayá 2:10) Ǹjẹ́ o rò pé Ọlọ́run á ní kí wọ́n wá bá Jésù jọba tó bá jẹ́ pé ó ti kádàrá wọn pé òun ò ní yàn wọ́n? Tún wo ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn onígbàgbọ́ bíi tiẹ̀. Ó sọ pé: “Bí a bá mọ̀ọ́mọ̀ sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà lẹ́yìn rírí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́ gbà, kò tún sí ẹbọ kankan tí ó ṣẹ́ kù fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.” (Hébérù 10:26) Ká ní Ọlọ́run ti kọ ohun tó máa jẹ́ ìgbẹ̀yìn wọn mọ́ wọn tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ ni, irú ìkìlọ̀ bẹ́ẹ̀ kì bá tí wúlò. Àmọ́, àwọn kan sọ pé Ọlọ́run ti kádàrá àwọn èèyàn kan pé wọ́n máa bá Jésù jọba. Ṣé òótọ́ ni?

Ṣé Ẹnì Kọ̀ọ̀kan Ni Ọlọ́run Kádàrá Àbí Ẹgbẹ́ Lódindi?

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “[Ọlọ́run] ti fi gbogbo ìbùkún ti ẹ̀mí ní àwọn ibi ọ̀run bù kún wa ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti yàn wá ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ ṣáájú ìgbà pípilẹ̀ ayé. . . . Nítorí ó yàn wá ṣáájú sí ìsọdọmọ fún ara rẹ̀ nípasẹ̀ Jésù Kristi.” (Éfésù 1:3-5) Kí ni Ọlọ́run ti yàn ṣáájú, kí sì ni pé a ti yàn wọ́n “ṣáájú ìgbà pípilẹ̀ ayé” túmọ̀ sí?

Ẹsẹ Bíbélì yìí sọ pé Ọlọ́run ti yan àwọn kan lára àwọn ọmọ Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́, láti bá Kristi jọba ní ọ̀run. (Róòmù 8:14-17, 28-30; Ìṣípayá 5:9, 10) Èrò àwọn kan ni pé àìmọye ọdún ṣáájú kí wọ́n tó bí àwọn èèyàn kan ni Jèhófà Ọlọ́run ti kádàrá wọn pé wọ́n á láǹfààní yìí. Àmọ́, ìyẹn ta ko òmìnira tí Ọlọ́run fún àwa ẹ̀dá èèyàn láti yan ohun tó bá wù wá. Ẹgbẹ́ àwọn tí yóò bá Jésù jọba lápapọ̀ ni Ọlọ́run yàn tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, kì í ṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn.

Jẹ́ ká ṣàpèjúwe rẹ̀ báyìí ná: Ká sọ pé ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, ìjọba pinnu láti dá ẹgbẹ́ kan sílẹ̀. Ká sọ pé ìjọba ti sọ ojúṣe ẹgbẹ́ náà tẹ́lẹ̀, bí ẹgbẹ́ náà yóò ṣe máa lo agbára àti iye àwọn tó máa wà nínú ẹgbẹ́ náà. Nígbà tákòókò sì tó, ẹgbẹ́ tí ìjọba ti pinnu láti dá sílẹ̀ yìí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Àwọn tó wà nínú ẹgbẹ́ náà wá ṣèwé kan tó kà pé: “Ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni ìjọba ti pinnu ohun tí yóò jẹ́ ojúṣe ẹgbẹ́ wa. A ti wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tí ìjọba yàn fún wa pé ká ṣe báyìí.” Ṣé wàá rò pé ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni ìjọba ti kádàrá ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó wà nínú ẹgbẹ́ náà pé wọ́n máa wà níbẹ̀? Ó dájú pé o kò ní rò bẹ́ẹ̀. Lọ́nà kan náà, Jèhófà ti pinnu tẹlẹ̀ pé òun yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ tí yóò mú àwọn ohun burúkú tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù fà kúrò. Àmọ́ ṣá o, àwùjọ àwọn tó máa ṣèjọba yẹn lódindi ni Ọlọ́run kádàrá tẹ́lẹ̀, kì í ṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn. Ẹ̀yìn-ọ̀-rẹyìn ló wá yàn wọ́n, ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn bá sì ṣe ló máa fi hàn bóyá yóò rí èrè yẹn gbà níkẹyìn tàbí kò ní rí i gbà.

Ayé wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “[Ọlọ́run] ti yàn wá ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ ṣáájú ìgbà pípilẹ̀ ayé?” Kì í ṣe ayé tó bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ bá o. Ayé ìgbà yẹn “dára gan-an ni,” kò sí ẹ̀ṣẹ̀ níbẹ̀, kò sì sí ìyà rárá. (Jẹ́nẹ́sísì 1:31) Ayé ìgbà yẹn kò nílò “ìtúsílẹ̀” kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.—Éfésù 1:7.

Ayé tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn ni ayé tó bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn nínú ọgbà Édẹ́nì. Ayé tó ní lọ́kàn yìí yàtọ̀ sí èyí tí Ọlọ́run ṣètò níbẹ̀rẹ̀. Ó jẹ́ ayé tó bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Ádámù àti Éfà bẹ̀rẹ̀ sí í bímọ, ìyẹn ayé àwọn èèyàn tó ti di àjèjì sí Ọlọ́run, tí wọ́n ti di ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ìdíbàjẹ́. Ayé tá à ń wí yìí ni ayé àwọn èèyàn tó ṣeé rà padà nítorí pé wọn ò mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ bíi ti Ádámù àti Éfà tí kò ṣeé rà padà.—Róòmù 5:12; 8:18-21.

Jèhófà Ọlọ́run lágbára láti ṣètò lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ bí yóò ṣe wá ojútùú sóhun tó máa jẹ́ àbájáde ọ̀tẹ̀ tó wáyé ní ọgbà Édẹ́nì. Nítorí náà, gbàrà tí ọ̀tẹ̀ yẹn ti wáyé ni Ọlọ́run ti ṣètò ìjọba kan, ìyẹn Ìjọba Mèsáyà tí Jésù Kristi yóò ṣàkóso rẹ̀. Ìjọba yẹn ni Ọlọ́run yóò lò láti mú kí aráyé bọ́ lọ́wọ́ àwọn àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù. (Mátíù 6:10) Ọlọ́run ti ṣètò ìjọba yìí “ṣáájú ìgbà pípilẹ̀ ayé” tó jẹ́ ti àwọn èèyàn tó ṣeé rà padà, ìyẹn ṣáájú kí Ádámù àti Éfà tó bẹ̀rẹ̀ sí í bímọ.

Kéèyàn tó lè ṣe ohun kan láṣeyọrí, ó gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣètò bó ṣe máa ṣe ohun náà. Ìyẹn ló mú káwọn tó gbà gbọ́ nínú kádàrá lérò pé gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lágbàáyé ni Ọlọ́run ti kọ sílẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ pé yóò ṣẹlẹ̀. Òǹkọ̀wé Roy Weatherford sọ nínú ìwé rẹ̀ pé: “Lójú ọ̀pọ̀ lára àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí, ńṣe ló dà bíi pé téèyàn bá ní Ọlọ́run ò kádàrá àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ tẹ́lẹ̀, èèyàn ò gbà pé ó tóbi lọ́ba nìyẹn.” Àmọ́, ṣé dandan ni kí Ọlọ́run kádàrá gbogbo ohun tó máa ṣẹlẹ̀?

Agbára Jèhófà kò mọ síbì kan, ọgbọ́n rẹ̀ ò sì láfiwé. Nítorí náà, ó lè yanjú ohunkóhun tó bá ṣẹlẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀ látàrí báwọn ẹ̀dá ọwọ́ rẹ̀ ṣe ń lo òmìnira tó fún wọn láti yan ohun tó ba wù wọ́n. (Aísáyà 40:25, 26; Róòmù 11:33) Ó lè ṣe èyí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láìjẹ́ pé ó ti rò ó tẹ́lẹ̀. Ọlọ́run Olódùmarè ò dà bí àwa èèyàn tá a máa ń ṣàṣìṣe tágbára wa sì láàlà. Nítorí náà, kò pọn dandan kó kádàrá ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí èèyàn kọ̀ọ̀kan láyé kí wọ́n tó bí onítọ̀hún. (Òwe 19:21) Nínú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì mélòó kan, “ète ayérayé” ni Éfésù 3:11 sọ pé Ọlọ́run ní, kò sọ pé ó ti kádàrá gbogbo ohun tó máa ṣẹlẹ̀.

Bó O Ṣe Lè Pinnu Ọjọ́ Ọ̀la Rẹ

Ọlọ́run ní ohun kan lọ́kàn láti ṣe fún ilẹ̀ ayé, ó sì ti pinnu ohun náà tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Ìṣípayá 21:3, 4 sọ pé: “Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” Dájúdájú, ilẹ̀ ayé yóò di Párádísè bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí níbẹ̀rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28) Àmọ́, ìbéèrè kan rèé o: Ṣé wàá wà níbẹ̀? Ohun tó o bá ń ṣe nísinsìnyí ló máa fi hàn bóyá wàá wà níbẹ̀ tàbí o kò ní sí níbẹ̀. Jèhófà kò kọ ìyè tàbí ìparun mọ́ ọ.

Ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, yóò mú kó ṣeé ṣe fún ẹnikẹ́ni tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ láti ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòhánù 3:16, 17; Ìṣe 10:34, 35) Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ ní ìyè àìnípẹ̀kun; ẹni tí ó bá ń ṣàìgbọràn sí Ọmọ kì yóò rí ìyè.” (Jòhánù 3:36) O lè yan ìyè nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kó o lè mọ̀ nípa Ọlọ́run, Ọmọ rẹ̀ àti ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Bákan náà, o ní láti fi ohun tó o bá kọ́ sílò. Jẹ́ kó dá ọ lójú pé tó o bá hùwà ọgbọ́n tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ‘wàá máa gbé nínú ààbò, wàá sì wà láìní ìyọlẹ́nu lọ́wọ́ ìbẹ̀rùbojo ìyọnu àjálù.’—Òwe 1:20, 33.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Èèyàn ò dà bí ẹranko o, èèyàn yóò dáhùn fún ohun tó bá ṣe

[Credit Line]

Ẹyẹ idì: Foto: Cortesía de GREFA