Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ pé èèyàn gbọ́dọ̀ lọgun tí wọ́n bá fẹ́ fipá bá a lò pọ̀?

Ẹnikẹ́ni tí ẹni tí ń fipá báni lò kò bá tíì rá mú lójijì rí kò lè lóye bí ọ̀ràn náà ṣe lè jẹ́ káyé ẹni bà jẹ́ tó. Ìrírí náà máa ń kó jìnnìjìnnì bá ẹni tí ọ̀ràn náà kàn gan-an débi pé ó lè dà á láàmú ní gbogbo ìyókù ọjọ́ ayé rẹ̀. a Ọ̀dọ́bìnrin Kristẹni kan tó bọ́ sọ́wọ́ ẹni tí ń fipá báni lò pọ̀ lọ́dún bíi mélòó kan sẹ́yìn sọ pé: “Mi ò mọ ọ̀rọ̀ tí mo lè fi ṣàlàyé bí àyà mi ṣe já tó lálẹ́ ọjọ́ yẹn; bẹ́ẹ̀ náà ni hílàhílo tó ti bá mi látìgbà yẹn kò ṣeé fẹnu sọ.” Abájọ tí ọ̀pọ̀ èèyàn kì í tiẹ̀ fẹ́ ronú nípa ọ̀ràn tí ń dẹ́rù bani yìí rárá. Síbẹ̀, òótọ́ làwọn èèyàn máa ń fẹ́ fipá báni lò pọ̀ nínú ayé búburú yìí.

Bíbélì ò fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ rárá nípa ọ̀ràn ìfipábáni-lòpọ̀ bíi mélòó kan tó wáyé àti nípa àwọn tó gbìyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀ láyé ọjọ́un. (Jẹ́nẹ́sísì 19:4-11; 34:1-7; 2 Sámúẹ́lì 13:1-14) Àmọ́ ó tún fúnni nímọ̀ràn nípa ohun tó yẹ kéèyàn ṣe nígbà tí wọ́n bá fẹ́ fipá bá a lò pọ̀. Ohun tí Òfin sọ nípa ọ̀ràn náà wà nínú Diutarónómì 22:23-27. Ipò méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni èyí sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ìkíní ni pé, ọkùnrin kan rí ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan nínú ìlú kan, ó sì bá a dà pọ̀. Obìnrin náà ò sì lọgun tàbí kó pariwo pé káwọn èèyàn wá gba òun. A jẹ́ pé obìnrin náà jẹ̀bi nìyẹn “fún ìdí náà pé kò lọgun nínú ìlú ńlá náà.” Ká ní ó lọgun ni, bóyá àwọn èèyàn tó wà nítòsí ì bá gbà á sílẹ̀. Èkejì, ọkùnrin kan rí ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan nílùú, níbi tó ti “rá a mú, tí ó sì sùn tì í.” Kí obìnrin náà lè bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀, ó “lọgun, ṣùgbọ́n kò sí ẹnì kankan láti gbà á sílẹ̀.” Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí ti obìnrin àkọ́kọ́, ó hàn gbangba pé obìnrin yìí ko fara mọ́ ohun tí olubi yìí fẹ́ ṣe rárá. Ó kọ̀ jálẹ̀, ó kébòòsí pé káwọn èèyàn gba òun, àmọ́ agbára ọkùnrin náà ju tirẹ̀ lọ. Bó ṣe lọgun yẹn fi hàn pé kò nífẹ̀ẹ́ sírú nǹkan bẹ́ẹ̀ rárá; kò jẹ̀bi ìwà àìtọ́ kankan.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni òde òní kò sí lábẹ́ Òfin Mósè, síbẹ̀ ìlànà tá a mẹ́nu kàn níbẹ̀ yẹn yóò tọ́ wọn sọ́nà. Ohun tá a sọ lókè yìí fi ìjẹ́pàtàkì dídènà irú nǹkan bẹ́ẹ̀ àti lílọgun káwọn èèyàn lè wá gbani hàn. Kéèyàn lọgun nígbà tí wọ́n bá fẹ́ fipá bá a lò pọ̀ ṣì jẹ́ ohun tá a kà sí ìwà ọgbọ́n. Ògbógi kan nínú ọ̀ràn dídẹ́kun ìwà ipá sọ pé: “Bí wọ́n bá rá obìnrin kan mú, ohun ìjà tó gbéṣẹ́ jù lọ tó lè lò ni pé kó fi ohùn rara kígbe.” Igbe tí obìnrin kan bá ké lè mú káwọn èèyàn mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ kí wọ́n sì wá gbà á sílẹ̀, ó sì lè mú kí olubi náà bẹ̀rù kó sì sá lọ. Ọ̀dọ́bìnrin Kristẹni kan tí ẹni tí ń fipá báni lò pọ̀ kan rá mú sọ pé: “Mo fi gbogbo agbára mi kígbe ní ohùn rárá, ó sì sá sẹ́yìn. Nígbà tó tún sún mọ́ mi, mo lọgun mo sì ki eré mọ́lẹ̀. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ mo ti máa ń ronú pé, ‘Báwo ni kíkígbe ṣe lè ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí ìgìrìpá ọkùnrin bá rá mi mú tó sì jẹ pé ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ ló fẹ́ ṣe?’ Àmọ́ mo ti wáá rí i pé ó gbéṣẹ́!”

Kódà nígbà tí ọ̀ràn náà bá jẹ́ èyí tó bani nínú jẹ́, tí wọ́n borí obìnrin kan tí wọ́n sì fipá bá a lò pọ̀, ìjà fitafita tó jà àti igbe tó ké káwọn èèyàn lè gbà á sílẹ̀ kò já sásán. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi hàn pé ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti dènà ẹni tó rá a mú náà. (Diutarónómì 22:26) Pẹ̀lú ohun búburú tó ṣẹlẹ̀ sí i yìí, ó ṣì lè ní ẹ̀rí ọkàn tó dára, àwọn èèyàn á máa fi ọ̀wọ̀ rẹ̀ wọ̀ ọ́, ọkàn rẹ̀ sì lè balẹ̀ pé òun mọ́ tónítóní lójú Ọlọ́run. Ìrírí ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ náà lè dá ọgbẹ́ sí i lọ́kàn, àmọ́ mímọ̀ pé òun sa gbogbo ipá òun láti bọ́ lọ́wọ́ olubi náà yóò wo ọgbẹ́ náà sàn díẹ̀díẹ̀.

Tá a bá lóye ibi tí ọ̀rọ̀ inú Diutarónómì 22:23-27 yìí ti gbéṣẹ́, a gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ohun tá a sọ ní ṣókí yìí kò kan gbogbo ipò tí ọ̀ràn náà ti lè wáyé. Bí àpẹẹrẹ, kò sọ nípa ipò tó jẹ́ pé ìbẹ̀rùbojo mú kí obìnrin tí wọ́n rá mú náà má lè dún pẹ́nkẹ́n, tó dákú lọ gbári, tàbí tí kò tiẹ̀ mira mọ́ rárá, bẹ́ẹ̀ ni kò sọ nípa ẹni tí wọn ò jẹ́ kó kígbe rárá bóyá tí wọ́n fi ọwọ́ tàbí nǹkan míì dí i lẹ́nu. Àmọ́, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jèhófà mọ ohun gbogbo, títí kan èrò inú, yóò fi òye àti àìṣègbè bójú tó irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, nítorí pé “gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo.” (Diutarónómì 32:4) Ó mọ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sì rí gbogbo ìsapá tí obìnrin náà ṣe láti dènà ẹni tó rá a mú ọ̀hún. Nítorí náà, ẹni tí kò bá rọ́nà kígbe àmọ́ tó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe nínú irú ipò bẹ́ẹ̀ lè fi ọ̀ràn náà lé Jèhófà lọ́wọ́.—Sáàmù 55:22; 1 Pétérù 5:7.

Láìka ìyẹn sí, gbogbo ìgbà làwọn obìnrin Kristẹni kan tí wọ́n ti fagbára mú tí wọ́n sì ti fipá bá lò pọ̀ rí máa ń banú jẹ́ nítorí ẹ̀rí ọkàn tó ń dá wọn lẹ́bi. Nígbà tí wọ́n bá ronú nípa rẹ̀, wọ́n máa ń rò pé ó yẹ káwọn ti ṣe ju ohun táwọn ṣe lọ láti dènà aburú náà. Àmọ́, dípò kí wọ́n máa dá ara wọn lẹ́bi, irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè gbàdúrà sí Jèhófà, kí wọ́n sọ pé kó ran àwọn lọ́wọ́, kí wọ́n sì ní ìgbọ́kànlé nínú inú-rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ tó pọ̀ yanturu.—Ẹ́kísódù 34:6; Sáàmù 86:5.

Nítorí ìdí èyí, àwọn obìnrin Kristẹni tí wọ́n ń fara da ọgbẹ́ ọkàn tí ohun tójú wọn rí lọ́dọ̀ ẹni tí ń fipá báni lò pọ̀ ti fà fún wọn lè ní ìdánilójú pé Jèhófà lóye ẹdùn ọkàn wọn. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú un dá wọn lójú pé: “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.” (Sáàmù 34:18) Ohun mìíràn tó tún lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kojú hílàhílo tó bá wọn ni kí wọ́n gbà pé àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni lóye wọn, wọn ò sì ní padà lẹ́yìn àwọn. (Jóòbù 29:12; 1 Tẹsalóníkà 5:14) Síwájú sí i, ìsapá tí àwọn tí ọ̀ràn náà kàn bá ṣe láti máa ronú nípa àwọn ohun tó ń gbéni ró yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.”—Fílípì 4:6-9.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin tó ń kó sọ́wọ́ àwọn tí ń fipá báni lò pọ̀ ni àpilẹ̀kọ yìí ń sọ, síbẹ̀ ìlànà tá a jíròrò níbẹ̀ tún kan àwọn ọkùnrin tí wọ́n máa fẹ́ fipá bá lò pọ̀ pẹ̀lú.