Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wọ́n “Ń Gbọ́” Ìhìn Ìjọba náà ní Brazil

Wọ́n “Ń Gbọ́” Ìhìn Ìjọba náà ní Brazil

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

Wọ́n “Ń Gbọ́” Ìhìn Ìjọba náà ní Brazil

Ọ̀PỌ̀ lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílẹ̀ Brazil ló ti tẹ́wọ́ gba ìpèníjà kíkọ́ Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Brazil kí wọ́n lè polongo ìhìn rere Ìjọba náà láwọn àgbègbè tàwọn adití pọ̀ sí. Ìsapá wọn ń ní àṣeyọrí tó dára gan-an, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìrírí tó tẹ̀ lé e yìí ṣe fi hàn.

Eva, a obìnrin adití kan ní São Paulo, bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ èdè àwọn adití lẹ́yìn tí òun àtàwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kó lọ sọ́dọ̀ ọkùnrin kan tí òun náà jẹ́ adití. Eva àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ ọkùnrin yìí rí àwùjọ àwọn adití tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí ní ilé ìtajà kan, àwọn Ẹlẹ́rìí náà sì sọ pé kí wọ́n wá báwọn ṣe ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Wọ́n fara mọ́ ìkésíni náà, níwọ̀n bí wọ́n ti rò pé ibi àríyá kan ni.

Ìwọ̀nba díẹ̀ ni Eva lóye lára ohun tí wọ́n sọ nípàdé ọ̀hún nítorí pé èdè adití tó mọ̀ kò tó nǹkan. Lẹ́yìn náà, àwọn Ẹlẹ́rìí bíi mélòó kan pè é pé kó wá fi nǹkan panu nílé àwọn. Wọ́n fi àwọn àwòrán tó wà nínú ìwé pẹlẹbẹ Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae! ṣàlàyé ìlérí Ọlọ́run nípa Párádísè orí ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ iwájú fún un. Inú Eva dùn sí ohun tó gbọ́ yìí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wá sípàdé déédéé.

Kété lẹ́yìn ìyẹn ni Eva fi ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ sílẹ̀ kó lè máa gbé ìgbésí ayé tó bá ìlànà Bíbélì mu. Láìfi inúnibíni gbígbóná janjan táwọn èèyàn rẹ̀ gbé dìde pè, ó bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ó sì ṣe batisí lọ́dún 1995. Oṣù mẹ́fà lẹ́yìn ìyẹn ni Eva forúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà, tàbí ẹni tí ń fi àkókò kíkún pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run. Òun náà ti ran àwọn adití mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ́wọ́ débi táwọn yẹn fi ya ara wọn sí mímọ́ tí wọ́n sì ṣe ìrìbọmi.

Àtìgbà tí wọ́n ti bí Carlos ló ti ya adití. Láti kékeré ló sì ti jẹ́ ajoògùnyó, tó ń lọ́wọ́ nínú ìwà pálapàla, tó sì ń jalè. Ìgbà táwọn mìíràn tó jẹ́ ọmọọ̀ta bíi tirẹ̀ halẹ̀ mọ́ ọn ló sá lọ sí São Paulo tó lọ gbé lọ́dọ̀ João fúngbà díẹ̀. Bíi ti Carlos náà ni João ṣe jẹ́ odi, ó sì tún jẹ́ oníwàkiwà pẹ̀lú.

Ọdún bíi mélòó kan lẹ́yìn ìyẹn ni Carlos fetí sí ìhìn Ìjọba náà, èyí tó sún un láti mú ìgbésí ayé rẹ̀ bá ìlànà Bíbélì mu, ó sì fìdí ìgbéyàwó rẹ̀ múlẹ̀ lábẹ́ òfin. Lẹ́yìn tí Carlos ṣe gbogbo ohun tí Ìwé Mímọ́ béèrè, ó ṣe batisí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí láti fi hàn pé ó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà. Láàárín àkókò kan náà ni João fetí sí ìhìn rere, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Carlos ò mọ̀ nípa èyí, òun náà sì yí ìgbésí ayé rẹ̀ padà lọ́nà tó kàmàmà. Nígbà tí João kẹ́kọ̀ọ́ pé inú Jèhófà kò dùn sí lílo àwọn ère, kíá ló kó gbogbo eré “àwọn ẹni mímọ́” tó ní sílé dà nù. Lẹ́yìn tí João yí ọ̀nà tó ń gbà gbé ìgbésí ayé tẹ́lẹ̀ padà, òun náà ṣe batisí.

Inú Carlos àti João dùn gan-an nígbà táwọn méjèèjì jọ pàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tí wọ́n sì rí àyípadà tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wọn ti ṣe! Àwọn méjèèjì ló ti di olórí ìdílé tó ṣeé gbára lé báyìí, wọ́n sì ń fi ìtara pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run.

Ọgbọ̀n ìjọ ni wọ́n ti ń lo èdè adití ní orílẹ̀-èdè Brazil lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, wọ́n sì ní àádọ́jọ ó lé mẹ́rin [154] àwùjọ, tó ní àwọn akéde tó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá [2,500] nínú, àwọn bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] lára wọn sì jẹ́ adití. Ní Àpéjọ Àgbègbè “Àwọn Olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” tí wọ́n ṣètò fún àwọn adití ní Brazil lọ́dún 2001, àwọn èèyàn tó wá síbẹ̀ lé ní ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000], àwọn mẹ́rìndínlógójì ló sì ṣe batisí. Pẹ̀lú ìbùkún Jèhófà, a nírètí pé àwọn adití púpọ̀ sí i ló ṣì máa tẹ́wọ́ gba ìhìn Ìjọba náà.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ padà.