Jẹ́nẹ́sísì 34:1-31

  • Ṣékémù fipá bá Dínà lò pọ̀ (1-12)

  • Àwọn ọmọ Jékọ́bù ṣẹ̀tàn (13-31)

34  Dínà ọmọbìnrin tí Líà+ bí fún Jékọ́bù sábà máa ń lọ sọ́dọ̀* àwọn ọmọbìnrin ilẹ̀ náà.+  Nígbà tí Ṣékémù, ọmọ Hámórì, ọmọ Hífì,+ tó jẹ́ ìjòyè ilẹ̀ náà rí i, ó mú un, ó sì bá a sùn, ó fipá bá a lò pọ̀.  Ọkàn rẹ̀ wá fà mọ́ Dínà ọmọ Jékọ́bù gan-an, ó nífẹ̀ẹ́ ọmọbìnrin náà, ó sì ń fìfẹ́ rọ̀ ọ́ bó ṣe ń bá a sọ̀rọ̀.*  Níkẹyìn, Ṣékémù sọ fún Hámórì+ bàbá rẹ̀ pé: “Fẹ́ ọmọbìnrin yìí fún mi kí n fi ṣe aya.”  Àwọn ọmọ Jékọ́bù ń bójú tó agbo ẹran rẹ̀ nínú pápá nígbà tó gbọ́ pé ọkùnrin náà ti bá Dínà ọmọ rẹ̀ sùn. Jékọ́bù ò sì sọ nǹkan kan títí wọ́n fi dé.  Nígbà tó yá, Hámórì bàbá Ṣékémù jáde lọ bá Jékọ́bù sọ̀rọ̀.  Àmọ́ nígbà tí àwọn ọmọ Jékọ́bù gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, wọ́n pa dà wálé láti inú pápá lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Inú wọn ò dùn rárá, inú sì bí wọn gidigidi, torí ó ti dójú ti Ísírẹ́lì bó ṣe bá ọmọ Jékọ́bù+ sùn, ohun tí kò yẹ kó ṣẹlẹ̀.+  Hámórì sọ fún wọn pé: “Ọkàn Ṣékémù ọmọ mi ń fà sí* ọmọ yín. Ẹ jọ̀ọ́, ẹ fún un kó fi ṣe aya,  kí ẹ sì bá wa dána.* Ẹ fún wa ní àwọn ọmọbìnrin yín, kí ẹ̀yin náà sì fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wa.+ 10  Ẹ lè máa gbé lọ́dọ̀ wa, ilẹ̀ yìí yóò sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó yín. Ẹ máa gbé ibẹ̀, ẹ máa ṣòwò, kí ẹ sì wà níbẹ̀.” 11  Ṣékémù sọ fún bàbá ọmọbìnrin náà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ kí n rí ojúure yín, màá sì fún yín ní ohunkóhun tí ẹ bá bi mí. 12  Ẹ lè béèrè owó orí ìyàwó tó pọ̀ gan-an àti ẹ̀bùn+ lọ́wọ́ mi. Mo ṣe tán láti fún yín ní ohunkóhun tí ẹ bá bi mí. Ẹ ṣáà fún mi ní ọmọbìnrin náà kí n fi ṣe aya.” 13  Àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù wá fi ẹ̀tàn dá Ṣékémù àti Hámórì bàbá rẹ̀ lóhùn torí Ṣékémù ti bá Dínà arábìnrin wọn sùn. 14  Wọ́n sọ fún wọn pé: “A ò lè ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀, pé ká fún ọkùnrin tí kò dádọ̀dọ́*+ ní arábìnrin wa torí ohun ìtìjú ló jẹ́ fún wa. 15  Ohun kan ṣoṣo tó lè mú ká gbà ni pé: kí ẹ dà bíi wa, kí gbogbo ọkùnrin+ yín sì dádọ̀dọ́.* 16  Àá wá fún yín ní àwọn ọmọbìnrin wa, àwa náà á sì fẹ́ àwọn ọmọbìnrin yín, àá máa bá yín gbé, àá sì di ọ̀kan. 17  Àmọ́ tí ẹ ò bá fetí sí wa, kí ẹ sì dádọ̀dọ́, àá mú ọmọ wa lọ.” 18  Ọ̀rọ̀ wọn múnú Hámórì+ àti Ṣékémù ọmọ+ rẹ̀ dùn. 19  Torí ọmọkùnrin náà fẹ́ràn ọmọ Jékọ́bù gan-an, kíá ló ṣe ohun tí wọ́n sọ,+ òun sì ni wọ́n kà sí èèyàn pàtàkì jù lọ ní gbogbo ilé bàbá rẹ̀. 20  Hámórì àti Ṣékémù ọmọ rẹ̀ wá lọ sí ẹnubodè ìlú náà,+ wọ́n sì sọ fún àwọn ọkùnrin ìlú wọn pé: 21  “Àwọn ọkùnrin yìí fẹ́ kí àlàáfíà wà láàárín wa. Ẹ jẹ́ kí wọ́n máa gbé ilẹ̀ yìí, kí wọ́n sì máa ṣòwò níbí, torí ilẹ̀ yìí fẹ̀ dáadáa, ó lè gbà wọ́n. A lè fi àwọn ọmọbìnrin wọn ṣe aya, a sì lè fún wọn ní àwọn ọmọbìnrin wa.+ 22  Ohun kan ṣoṣo tó lè mú kí wọ́n gbà láti bá wa gbé, ká lè di ọ̀kan ni pé: kí gbogbo ọkùnrin àárín wa dádọ̀dọ́*+ bíi tiwọn. 23  Nígbà náà, gbogbo ohun ìní wọn, ọrọ̀ wọn àti gbogbo ẹran ọ̀sìn wọn á di tiwa. Torí náà, ẹ jẹ́ ká ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ kí wọ́n lè máa bá wa gbé.” 24  Gbogbo àwọn tó ń gba ẹnubodè ìlú rẹ̀ jáde fetí sí Hámórì àti Ṣékémù ọmọ rẹ̀, gbogbo ọkùnrin sì dádọ̀dọ́, gbogbo àwọn tó ń gba ẹnubodè ìlú jáde. 25  Àmọ́ ní ọjọ́ kẹta, nígbà tí wọ́n ṣì ń jẹ̀rora, àwọn ọmọ Jékọ́bù méjì, Síméónì àti Léfì tí wọ́n jẹ́ ẹ̀gbọ́n+ Dínà mú idà wọn, wọ́n yọ́ lọ sí ìlú náà, wọ́n sì pa gbogbo ọkùnrin.+ 26  Wọ́n fi idà pa Hámórì àti Ṣékémù ọmọ rẹ̀, wọ́n wá mú Dínà kúrò ní ilé Ṣékémù, wọ́n sì lọ. 27  Àwọn ọmọ Jékọ́bù yòókù lọ síbi tí wọ́n ti pa àwọn ọkùnrin náà, wọ́n sì kó ohun ìní àwọn ará ìlú náà, torí wọ́n ti kẹ́gàn bá arábìnrin+ wọn. 28  Wọ́n kó àwọn agbo ẹran wọn, ọ̀wọ́ ẹran wọn, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn àti gbogbo ohun tó wà nínú ìlú náà àti nínú oko. 29  Wọ́n tún kó gbogbo ohun ìní wọn, wọ́n mú gbogbo àwọn ọmọ wọn kéékèèké àti àwọn ìyàwó wọn, wọ́n sì kó gbogbo ohun tó wà nínú ilé wọn. 30  Ni Jékọ́bù bá sọ fún Síméónì àti Léfì+ pé: “Wàhálà ńlá lẹ kó mi sí yìí,* torí ẹ máa mú kí àwọn ọmọ Kénáánì àti àwọn Pérísì tó ń gbé ilẹ̀ yìí kórìíra mi. Mo kéré níye, ó sì dájú pé wọ́n á kóra jọ láti bá mi jà, wọ́n á sì pa mí run, èmi àti ilé mi.” 31  Àmọ́ wọ́n sọ pé: “Ṣé ó yẹ kí ẹnikẹ́ni ṣe irú nǹkan yìí sí arábìnrin wa nígbà tí kì í ṣe aṣẹ́wó?”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “lọ rí.”
Ní Héb., “sọ̀rọ̀ tó wọ̀ ọ́ lọ́kàn.”
Tàbí “Ọkàn Ṣékémù ọmọ mi rọ̀ mọ́.”
Tàbí “kí àwọn èèyàn wa sì máa fẹ́ra wọn.”
Tàbí “tí kò kọlà.”
Tàbí “kọlà.”
Tàbí “kọlà.”
Tàbí “Ohun tó máa mú kí wọ́n ta mí nù lẹ ṣe yìí.”