Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìjọba Násì Kò Lè Yí Ìgbàgbọ́ Mi Pa Dà

Ìjọba Násì Kò Lè Yí Ìgbàgbọ́ Mi Pa Dà

Ìjọba Násì Kò Lè Yí Ìgbàgbọ́ Mi Pa Dà

Gẹ́gẹ́ Bí Hermine Liska Ṣe Sọ ọ́

KÒ SÍ wàhálà kankan nígbà tí mo wà lọ́mọdé, àmọ́ gbàrà tí Adolf Hitler àti ẹgbẹ́ òṣèlú Násì rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso orílẹ̀-èdè wa, ìyẹn Austria ní ọdún 1938, ni wàhálà ti bẹ̀rẹ̀. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí wọ́n fi sọ ọ́ di ọ̀ranyàn pé kí èmi àti àwọn tá a jọ wà níléèwé máa sọ pé, “Ti Hitler ni Ìgbàlà,” ká máa kọ orin Násì, ká sì wọ ẹgbẹ́ àwọn ọ̀dọ́ tó ń ṣètìlẹ́yìn fún Hitler. Àmọ́ gbogbo rẹ̀ pátá ni mo pinnu pé mi ò ní bá wọn lọ́wọ́ sí. Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀.

Oko kan tó wà ní St. Walburgen ní àgbègbè Carinthia, ní orílẹ̀-èdè Austria ni èmi àtàwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin mẹ́rin gbé dàgbà. Orúkọ àwọn òbí mi ni Johann àti Elisabeth Obweger. Ní ọdún 1925, bàbá mi di ọ̀kan lára àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn orúkọ tí wọ́n máa ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn. Màmá mi ṣe ìrìbọmi ní ọdún 1937. Láti kékeré ni wọ́n ti fi àwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì kọ́ mi, wọ́n sì mú kí n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn ohun tí Ọlọ́run dá. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ti kọ́ mi pé kò bójú mu láti jọ́sìn èèyàn èyíkéyìí. Jésù Kristi sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún.”—Lúùkù 4:8.

Bàbá mi àti màmá mi máa ń ṣe àwọn èèyàn lálejò gan-an. A máa ń ní ọ̀pọ̀ àlejò, àwọn mélòó kan tó ń bá wa ṣiṣẹ́ ní oko wa sì ń gbé pẹ̀lú àwa méje tá a wà nínú ìdílé wa. Títí di òní, ó jẹ́ àṣà tó wọ́pọ̀ ní àgbègbè Carinthia láti máa kọ orin, torí náà a máa ń kọrin gan-an, a sì tún máa ń gbádùn bá a ṣe jọ máa ń jíròrò Bíbélì. Inú mi ṣì máa ń dùn tí mo bá rántí bí ìdílé wa ṣe máa ń kóra jọ sídìí tábìlì tó wà ní yàrá ìgbàlejò wa ní gbogbo òwúrọ̀ ọjọ́ Sunday láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Ìbẹ̀rù Wọlé Dé

Mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọmọ ọdún mẹ́jọ nígbà tí orílẹ̀-èdè Jámánì gba àkóso orílẹ̀-èdè Austria. Látìgbà yẹn ni wọ́n ti túbọ̀ ń fínná mọ́ àwọn èèyàn láti máa kọ́wọ́ ti ẹgbẹ́ òṣèlú Násì, kò sì pẹ́ tí wọ́n fi sọ ọ́ di ọ̀ranyàn pé, nígbà táwọn èèyàn bá fẹ́ kí ara wọn, kí wọ́n máa sọ pé, “Ti Hitler ni Ìgbàlà.” Mi ò gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀, torí bí mo bá ṣe bẹ́ẹ̀ ó máa túmọ̀ sí pé mo gbà gbọ́ pé Hitler ni olùgbàlà! Jésù Kristi ni mo mọ̀ gẹ́gẹ́ bí Olùgbàlà mi. (Ìṣe 4:12) Gbogbo ìgbà ni àwọn olùkọ́ àtàwọn tá a jọ ń lọ sí iléèwé máa ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ torí ìgbàgbọ́ mi. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mọ́kànlá, ọ̀gá àgbà iléèwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ tí mo wà sọ pé: “Hermine, màá dá ẹ pa dà sí ìpele kìíní. Mi ò lè fàyè gba ọmọ alágídí bíi tìẹ ní kíláàsì mi!”

Nítorí pé èmi àtàwọn ẹ̀gbọ́n mi kò gbà láti pe Hitler ní olùgbàlà, wọ́n pe Bàbá mi sí ilé ẹjọ́. Wọ́n ní kó fọwọ́ sí ìwé pé òun kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́. Ìwé náà tún sọ pé ìlànà ìjọba Násì ló máa fi tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ dàgbà. Torí pé bàbá mi kọ̀ láti fọwọ́ sí ìwé náà, ilé ẹjọ́ kó àwa ọmọ kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí wa, wọ́n sì mú mi lọ sí ibi tí wọ́n ti ń tún àwọn èèyàn kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, ibẹ̀ sì fi nǹkan bí ogójì [40] kìlómítà jìnnà sílé wa.

Kò pẹ́ tí àárò ilé fi bẹ̀rẹ̀ sí í sọ mí, mo sì máa n sunkún gan-an. Obìnrin tó ń ṣàbójútó ibi ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà gbìyànjú láti fipá mú mi wọ ẹgbẹ́ àwọn ọ̀dọ́ tó ń ti Hitler lẹ́yìn, àmọ́ pàbó ni gbogbo ìsapá rẹ̀ já sí. Àwọn ọmọbìnrin tá a jọ wà níbẹ̀ máa ń gbìyànjú láti gbé ọwọ́ ọ̀tún mi sókè tí wọ́n bá ń kí àsíá Násì, àmọ́ mi ò gbà fún wọn. Ńṣe ni ọ̀rọ̀ mi dà bíi ti àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ìgbàanì tí wọ́n sọ pé: “Kò ṣeé ronú kàn fún àwa, láti fi Jèhófà sílẹ̀ láti lè sin àwọn ọlọ́run mìíràn.” (Jóṣúà 24:16)

Wọn kò gbà kí àwọn òbí mi máa wá wò mí. Àmọ́, àwọn òbí mi máa ń wá ọ̀nà láti rí mi láìjẹ́ kí wọ́n mọ̀, bóyá lójú ọ̀nà nígbà tí mo bá ń lọ sí iléèwé tàbí ní ilé ìwé. Àwọn àkókò díẹ̀ tí wọ́n fi bá mi sọ̀rọ̀ fún mi níṣìírí gan-an láti máa bá a nìṣó gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́ sí Jèhófà. Nígbà kan tí àwọn òbí mi wá wò mí, bàbá mi fún mi ní Bíbélì kékeré kan, mo sì rọra fi pa mọ́ sábẹ́ bẹ́ẹ̀dì mi. Bo tilẹ̀ jẹ́ pé ńṣe ni mo máa ń sá pa mọ́ bí mo bá fẹ́ kà á, mo gbádùn kíka Bíbélì yẹn! Ní ọjọ́ kan, ó kù díẹ̀ kí wọ́n mú mi, àmọ́ mo yára fi Bíbélì náà pa mọ́ sábẹ́ aṣọ tí mo máa ń tẹ́ sórí bẹ́ẹ̀dì mi.

Wọ́n Mú Mi Lọ sí Ilé Àwọn Obìnrin Tó Jẹ́jẹ̀ẹ́ Láti Wà Láìlọ́kọ

Nígbà tí àwọn aláṣẹ rí i pé pàbó ni gbogbo ìsapá wọn láti tún mi dá lẹ́kọ̀ọ́ já sí, wọ́n fura pé àwọn òbí mi ṣì ń ní ipa lórí mi. Torí náà, ní oṣù September ọdún 1942, wọ́n fi ọkọ̀ ojú irin gbé mi lọ sí ìlú Munich, ní orílẹ̀-èdè Jámánì. Nígbà tí mo débẹ̀, wọ́n fi mí sí ilé ẹ̀kọ́ àwọn Kátólíìkì kan tí wọ́n ń pè ní Adelgunden, àwọn obìnrin tó jẹ́jẹ̀ẹ́ láti wà láìlọ́kọ ló tún wà níbẹ̀. Nígbà tí àwọn obìnrin náà rí Bíbélì mi, wọ́n gbà á lọ́wọ́ mi.

Síbẹ̀, mo pinnu pé mi ò ní jẹ́ kí ohunkóhun ba ìgbàgbọ́ mi jẹ́, mi ò sì lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì. Nígbà tí mo sọ fún ọ̀kan lára àwọn obìnrin tó jẹ́jẹ̀ẹ́ láti wà láìlọ́kọ yẹn pé àwọn òbí mi máa ń ka Bíbélì fún mi lọ́jọ́ Sunday, ohun tó ṣe yà mí lẹ́nu. Ńṣe ló dá Bíbélì mi pa dà fún mi! Ó ṣe kedere pé ohun tí mo sọ wọ̀ ọ́ lọ́kàn. Kódà, ó gbà kí n ka Bíbélì náà fún òun.

Lọ́jọ́ kan, olùkọ́ kan sọ fún mi pé: Hermine, irun pípọ́n lo ní, àwọ̀ búlúù sì ni ẹyinjú rẹ. Ọmọ ilẹ̀ Jámánì ni ẹ́, o kì í ṣe Júù. Jèhófà ni Ọlọ́run àwọn Júù.”

Mo dá a lóhùn pé: “Àmọ́, Jèhófà ló dá ohun gbogbo. Òun ni Ẹlẹ́dàá gbogbo wa pátá!”

Ọ̀gá àgbà iléèwé náà gbìyànjú láti yí mi lérò pa dà. Nígbà kan ó sọ pé: “Hermine, jẹ́ kí n sọ nǹkan kan fún ẹ, ẹ̀gbọ́n rẹ kan ti wọṣẹ́ ológun. Àpẹẹrẹ dáadáa tó yẹ kó o tẹ̀ lé nìyẹn!” Mo mọ̀ pé ọ̀kan lára àwọn ẹ̀gbọ́n mi ti wọṣẹ́ ológun, àmọ́ mi ò fẹ́ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.

Mo sọ pé: “Mi ò kì í ṣe ọmọlẹ́yìn ẹ̀gbọ́n mi, ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi ni mí.” Ọ̀gá àgbà iléèwé náà halẹ̀ mọ́ mi pé òun máa mú mi lọ sí ibi tí wọ́n ti ń wo àwọn alárùn ọpọlọ, ó tiẹ̀ sọ pé kí obìnrin kan tó ti jẹ́jẹ̀ẹ́ láti wà láìlọ́kọ múra láti mú mi lọ síbẹ̀. Àmọ́, kò ṣe ohun tó sọ yìí.

Ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1943, wọ́n ju bọ́ǹbù sí ìlú Munich wọ́n sì kó àwọn ọmọ tó wà ní Adelgunden lọ sí àrọko. Ní àkókò yẹn mo sábà máa ń ronú nípa ọ̀rọ̀ tí Màmá mi sọ fún mi, ó ní: “Bó bá ṣẹlẹ̀ pé a ò wà pa pọ̀ mọ́, tí o kò tiẹ̀ rí lẹ́tà kankan gbà látọ̀dọ̀ mi, rántí pé Jèhófà àti Jésù á máa wà pẹ̀lú rẹ. Wọn kò ní fi ẹ́ sílẹ̀ láé. Torí náà máa gbàdúrà.”

Wọ́n Jẹ́ Kí N Pa Dà Sílé

Ní oṣù March ọdún 1944, wọ́n dá mi pa dà sí Adelgunden torí bí wọ́n ṣe ń ju bọ́ǹbù léraléra ní ìlú Munich. Níbẹ̀, lọ́pọ̀ ìgbà tọ̀sán tòru la máa ń wà ní àwọn ilé tí wọ́n kọ́ fáwọn èèyàn láti máa fara pa mọ́ sí nígbà tí wọ́n bá ju bọ́ǹbù látinú ọkọ̀ òfuurufú. Síbẹ̀, gbogbo ìgbà ni àwọn òbí mi ń béèrè pé kí wọ́n dá mi pa dà sọ́dọ̀ àwọn. Nígbà tó yá, wọ́n gbà pẹ̀lú àwọn òbí mi, mo sì pa dà sílé ní ìparí oṣù April ọdún 1944.

Nígbà tí mo lọ dágbére fún ọ̀gá àgbà iléèwé wa, ó sọ pé: “Hermine, kó o kọ̀wé sí wa tó o bá délé. Bó o ṣe ń ṣe yìí ni kó o máa ṣe o.” Ìwà ọ̀gá àgbà yìí ti yí pa dà pátápátá! Mo gbọ́ pé kò pẹ́ lẹ́yìn tí mo kúrò níbẹ̀, tí bọ́ǹbù fi pa ọmọbìnrin mẹ́sàn-án àti obìnrin mẹ́ta tó ti jẹ́jẹ̀ẹ́ láti wà láìlọ́kọ. Nǹkan burúkú gbáà ni ogun!

Bí ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn tilẹ̀ bà mí nínú jẹ́, inú mi dùn pé mo tún pa dà sọ́dọ̀ àwọn ìdílé mi. Ní oṣù May ọdún 1944, nígbà tí ogun ṣì ń lọ lọ́wọ́, mo ṣe ìrìbọmi nínú ọpọ́n ìwẹ̀ kan, láti fi hàn pé mo ti ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà. Nígbà tí ogun náà dáwọ́ dúró ní ọdún 1945, ó wù mí láti sọ fún àwọn èèyàn nípa ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, tó jẹ́ ìrètí kan ṣoṣo fún aráyé láti ní àlàáfíà àti ààbò tó wà pẹ́ títí, torí náà mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún.—Mátíù 6:9, 10.

Ní ọdún 1950, mo pàdé Erich Liska, ọ̀dọ́kùnrin kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti ìlú Vienna, ní orílẹ̀-èdè Austria, ó ń sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò. A ṣègbéyàwó ní ọdún 1952, fún àkókò díẹ̀ èmi àti ọkọ mi jọ lọ ṣe ìbẹ̀wò sí àwọn ìjọ kan, ká lè mú kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run túbọ̀ dára.

A bí àkọ́bí wa ní ọdún 1953, a sí bí ọmọ méjì míì lẹ́yìn náà. Torí pé ojúṣe wa ti wá pọ̀ sí i, a fi iṣẹ́ alákòókò kíkún sílẹ̀ ká lè bójú tó àwọn ọmọ wa. Mo ti wá rí i pé bí èèyàn bá dúró ti Ọlọ́run, kò ní jáni kulẹ̀, àmọ́ ó máa ń fúnni lágbára. Kò já mi kulẹ̀ rí. Pàápàá jù lọ, láti ìgbà tí ọkọ mi ọ̀wọ́n ti kú ní ọdún 2002, Jèhófà máa ń tù mí nínú, ó sì ń fún mi lókun.

Bí mo bá ronú nípa àwọn ohun tí mo ti fi ìgbésí ayé mi ṣe, mo máa ń dúpẹ́ gan-an pé nígbà tí mo ṣì kéré ni àwọn òbí mi ti kọ́ mi láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, tó ń fúnni ní ọgbọ́n tòótọ́. (2 Tímótì 3:16, 17) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó ń bá a nìṣó láti fún mi lókun kí n lè máa fara da àwọn àdánwò ìgbésí ayé.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 23]

“Mi ò kì í ṣe ọmọlẹ́yìn ẹ̀gbọ́n mi . . . ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi ni mí”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Èmi àti ìdílé wa rèé ní oko wa tó wà ní St. Walburgen

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Àwọn òbí mi, Elisabeth àti Johann Obweger rèé

[Credit Line]

Fọ́tò méjèèjì: Nípa ìyọ̀ǹda Foto Hammerschlag

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Èmi àti ọkọ mi, Erich rèé