Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọrọ̀ Ajé Ti Dẹnu Kọlẹ̀ Pátápátá

Ọrọ̀ Ajé Ti Dẹnu Kọlẹ̀ Pátápátá

Ọrọ̀ Ajé Ti Dẹnu Kọlẹ̀ Pátápátá

“ỌRỌ̀ ajé kò tíì burú tó báyìí rí.” Ohun tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀, Encyclopædia Britannica Online sọ nìyẹn nípa ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀ lágbàáyé lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Ìṣòro yìí tó bẹ̀rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ́dún 2007 lágbára gan-an ni, ó sì ṣàkóbá fún ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, débi pé ó mú kí àwọn èèyàn rántí bí ọrọ̀ ajé ṣe lọ sílẹ̀ lọ́nà tó gadabú láwọn ọdún 1930.

Kí ló fa ìṣòro yìí? Ìwé ìròyìn Newsweek dáhùn pé: “Ó ti mọ́ àwọn èèyàn lára láti máa yáwó ṣáá.” Kí ló dé tí àwọn èèyàn fi máa ń yáwó ṣáá láti ra nǹkan tí agbára wọn kò gbé?

Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà gbà pé ètò ọrọ̀ ajé àgbáyé tó ń sọ àwọn èèyàn di oníwọra ló fa ìṣòro yìí. Ohun tí wọ́n ń sọ fún wọn ni pé: “Ṣáà máa ra tibí, kó o sì máa ra tọ̀hún!” Bóyá o lè sanwó rẹ̀, àbí o kò lè san án. Onímọ̀ ètò ọrọ̀ ajé kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Chris Farrell, sọ nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní The New Frugality, pé: “Ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀ yìí ti fojú àwọn èèyàn han màbo, wọ́n sì ti wá mọ̀ pé, ewu wà nínú kéèyàn kàn máa yáwó ṣáá.”

Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló jìyà gan-an nígbà tí ọrọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Lọ́dún tó kọjá, àkọlé kan tó wà níwájú ìwé ìròyìn Sunday Times, ti orílẹ̀-èdè South Africa sọ pé: “Pẹ̀lú bó ṣe jẹ́ pé nǹkan ti ń yàtọ̀ díẹ̀díẹ̀ báyìí, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló ṣì ń jìyà nítorí ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀ yẹn, àwọn èèyàn . . . ṣì ń jìyà gan-an nítorí àtijẹ àtimu.” Ìwé ìròyìn yẹn tún sọ pé, “ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́ta èèyàn [lórílẹ̀-èdè South Africa] tí wọ́n ṣì jẹ gbèsè tó lé ní oṣù mẹ́ta lórí àwọn nǹkan tí wọ́n lò; àwọn èèyàn tó sì tó ẹgbàá márùnlélọ́gọ́fà [250, 000] tí wọ́n jẹ́ kòlà-kò-ṣagbe ni iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ wọn lọ́dún méjì sẹ́yìn.”

Iṣẹ́ ti bọ́ lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Nígbà tí ìwé ìròyìn kàn tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣúnná owó, ìyẹn Financial Times ń sọ̀rọ̀ nípa bóyá nǹkan ti ń pa dà bọ̀ sípò lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ó ní : “Ohun tá a lè pe àyípadà tó wáyé láti oṣù June, ọdún 2009, ni ‘Ìjákulẹ̀ Tó Kọjá Àfẹnusọ.’” Ìwé ìròyìn yẹn tún sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ ètò ọrọ̀ ajé ronú pé nítorí pé àwọn èèyàn á ṣì máa san gbèsè tí wọ́n jẹ díẹ̀díẹ̀, èyí kò ní jẹ́ kí ètò ọrọ̀ ajé tẹ̀ síwájú fún ọdún bíi mélòó kan.

Tó bá jẹ́ pé ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀ yẹn ti ṣàkóbá fún ẹ, ó dájú pé wàá gbà pé òótọ́ ni ohun tí ọ̀gbẹ́ni David Beart sọ nínú àròkọ rẹ̀ kan, pé: “Ó jọ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni à ń sọ nípa ìṣòro ìṣúnná owó tó ń da aráyé láàmù, àmọ́ ohun tí àwọn èèyàn ń sọ nípa bá a ṣe lè yanjú ìṣòro náà kò tó nǹkan.”

Àwọn àpilẹ̀kọ tó kàn máa ṣèrànwọ́ fún àwọn tí gbèsè kò jẹ́ kí wọ́n rímú mí. A máa dáhùn àwọn ìbéèrè bí: Àwọn àǹfààní wo ló wà nínú fífi owó pa mọ́? Kí lo lè ṣe tó bá jẹ́ pé o ti jẹ gbèsè? Báwo lo ṣe lè túbọ̀ máa ṣọ́wó ná?