Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n Méje

Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n Méje

Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n Méje

ÀWỌN ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nísàlẹ̀ yìí wà nínú ìwé àtọdúnmọ́dún kan tó ní àwọn ọ̀rọ̀ tó wúlò gan-an, tó sì jẹ́ pé àwọn ọ̀rọ̀ náà ṣì bá ìgbà mu. Wo bí àwọn ọ̀rọ̀ yìí ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ bí wàá ṣe máa ṣọ́ owó ná.

1. “Olùfẹ́ fàdákà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú fàdákà, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ olùfẹ́ ọlà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú owó tí ń wọlé wá.” (Oníwàásù 5:10) Kì í ṣe tálákà kan tó ń jowú àwọn olówó ló kọ ọ̀rọ̀ yìí o. Àmọ́, Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó lówó jù lọ tó tíì gbé ayé rí ló kọ ọ̀rọ̀ náà. Àwọn ìrírí tó ní àtàwọn àkíyèsí tó ṣe ló sì mú kí ó kọ ọ̀rọ̀ yìí. Àwọn tó jẹ́ olówó lóde òní pẹ̀lú sì ti sọ irú ọ̀rọ̀ yìí.

2. “Bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí. Àmọ́ ṣá o, àwọn tí ó pinnu láti di ọlọ́rọ̀ máa ń ṣubú sínú ìdẹwò.” (1 Tímótì 6:8, 9) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ló kọ ọ̀rọ̀ yìí, ó fi iṣẹ́ tí ì bá sọ ọ́ di olówó gidi sílẹ̀, ó sì wá di ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi. Pọ́ọ̀lù kò dà bí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn kan lóde òní, kò fàyè gba ìdẹwò èyíkéyìí tó lè mú kí ó máa kó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ tàbí àwọn tí wọ́n jọ ń siṣẹ́ nífà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi òótọ́ inú sọ pé: “Èmi kò ṣojúkòkòrò fàdákà tàbí wúrà tàbí aṣọ ọ̀ṣọ́ ènìyàn kankan. Ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ pé ọwọ́ wọ̀nyí ni ó ti ṣiṣẹ́ fún àwọn àìní tèmi àti ti àwọn tí ń bẹ pẹ̀lú mi.”—Ìṣe 20:33, 34.

3. “Ta ni nínú yín tí ó fẹ́ kọ́ ilé gogoro kan tí kò ní kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbéṣirò lé ìnáwó náà, láti rí i bí òun bá ní tó láti parí rẹ̀?” (Lúùkù 14:28) A lè fi àpèjúwe Jésù yìí wé ohun kan tó lè ṣẹlẹ̀ sí ẹ: Ká sọ pé o fẹ́ ra nǹkan, àgàgà tó bá jẹ́ pé ńṣe lo fẹ́ ra ọjà ọ̀hún láwìn, ṣé o kàn máa rà á láìronú dáadáa ni, àbí wàá ṣe sùúrù kó o sì gbéṣirò lé iye tó máa ná ẹ? Ǹjẹ́ lóòótọ́ lo nílò nǹkan ọ̀hún, ṣé owó rẹ sì ká a?

4. ‘Ayá-nǹkan ni ìránṣẹ́ awínni.’ (Òwe 22:7) Ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí ti fi hàn pé kì í ṣohun tó bọ́gbọ́n mu pé kéèyàn sọ ọ́ di àṣà láti máa ra nǹkan láwìn àti kéèyàn máa jẹ gbèsè ní àwọn ọ̀nà míì. Nínú ìwé kan tí Ọ̀gbẹ́ni Michael Wagner ṣe lọ́dún 2009, tó pe àkọlé rẹ̀ ní Your Money, Day One, ó sọ pé: “Lóde òní, kì í ṣohun tó ṣàjèjì láti rí i pé ẹnì kan jẹ gbèsè iye tí ó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án owó dọ́là, [nǹkan bíi mílíọ̀nù kan àbọ̀ náírà] ní ibi mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tàbí kó tiẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ.”

5. “Ẹni burúkú ń yá nǹkan, kì í sì í san án padà, ṣùgbọ́n olódodo ń fi ojú rere hàn, ó sì ń fúnni ní ẹ̀bùn.” (Sáàmù 37:21) Àwọn kan rò pé ọ̀nà tó rọrùn tí wọ́n lè gbà tí wọn ò fi ní san gbèsè tí wọ́n jẹ́ ni pé, kí wọ́n sọ pé àwọn ti wọ oko gbèsè. Àmọ́, ọ̀rọ̀ àwọn tó fojú pàtàkì wo àjọṣe àárín àwọn àti Ọlọ́run kò rí bẹ́ẹ̀, yàtọ̀ sí pé wọ́n máa ń rí i pé àwọn san gbèsè tí wọ́n bá jẹ́, tó bá wà ní agbára wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n tún máa ń fún àwọn èèyàn lára ohun tí wọ́n bá ní.

6. “Èmi ti jẹ́ ọ̀dọ́ rí, mo sì ti darúgbó, síbẹ̀síbẹ̀, èmi kò tíì rí i kí a fi olódodo sílẹ̀ pátápátá, tàbí kí ọmọ rẹ̀ máa wá oúnjẹ kiri.” (Sáàmù 37:25) Ọkùnrin kan tí wọ́n hùwà ìrẹ́jẹ sí ló kọ ọ̀rọ̀ yìí. Ọ̀pọ̀ ọdún ló fi ń sá kiri, nígbà míì inú ihò àpáta ló máa ń fara pa mọ́ sí, ó sì máa ń wá ààbò lọ sí ìlú àjèjì. Dáfídì ni ìsáǹsá tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí, nígbà tó yá, ó wá di ọba Ísírẹ́lì àtijọ́. Nígbà ayé rẹ̀, àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí i jẹ́ kó rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé ni ọ̀rọ̀ tó kọ yìí.

7. “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Ọkùnrin tí ó tóbi lọ́lá jù lọ tó tíì gbé ayé rí ló sọ ọ̀rọ̀ yìí. Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé “nítorí ìdùnnú tí a gbé ka iwájú rẹ̀,” ó fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣiṣẹ́ sin àwọn èèyàn. Ní báyìí, ó wà ní ọ̀rún lọ́wọ́ ọ̀tún Jèhófà, “Ọlọ́run aláyọ̀,” ó sì ti di ẹni ẹ̀mí tí kò lè kú mọ́.—Hébérù 12:2; 1 Tímótì 1:11.

Kí ìgbésí ayé wa lè nítumọ̀ dáadáa, àfi ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, ká máa ṣe gbogbo nǹkan tí agbára wa bá ká láti máa ṣèrànwọ́ fáwọn èèyàn. Ó dájú pé wàá gbà pé, ó sàn ká máa ṣọ́wó ná, ká lè máa fún àwọn èèyàn lára ohun tá a ní, ju ká kàn máa náwó nítorí ìgbádùn ti ara wa nìkan.