Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Máa Tọ́jú Owó Pa Mọ́?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Máa Tọ́jú Owó Pa Mọ́?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Máa Tọ́jú Owó Pa Mọ́?

ÀWỌN kan sọ pé, “Ó máa ń sú àwọn láti máa tọ́jú owó pa mọ́, ṣùgbọ́n àwọn máa ń gbádùn kí àwọn máa ra àwọn nǹkan bí aṣọ, àwọn ohun èlò tó ń bá iná ṣiṣẹ́ àtàwọn nǹkan míì bẹ́ẹ̀.”

Bóyá ètò ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀ nínú ayé ti ṣàkóbá fún ẹ tàbí kò tiẹ̀ kàn ẹ́ rárá, o lè jàǹfààní tó o bá ṣàgbéyẹ̀wò bó o ṣe lè máa tọ́jú owó àti bó o ṣe lè máa fi ọgbọ́n náwó. Kíyè sí àwọn ìmọ̀ràn tó wá láti ibi tó ṣeé gbára lé, èyí tó ti ran ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn lọ́wọ́ láti ọ̀pọ̀ ọdún kí wọ́n lè bójú tó àwọn ìṣòro ìnáwó wọn.

Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n Mẹ́ta Láyé Àtijọ́

Nínú ọ̀kan lára àwọn àkàwé tí Jésù ará Násárétì ṣe, ó sọ ìlànà pàtàkì kan téèyàn lè máa tẹ̀ lé lórí ọ̀rọ̀ ìnáwó. Nínú àkàwé náà, ọ̀gá kan gba ìránṣẹ́ rẹ̀ níyànjú pé: “Ó yẹ kí ìwọ ti kó àwọn owó fàdákà mi sọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ báǹkì, nígbà tí mo bá sì dé, èmi ì bá wá gba ohun tí ó jẹ́ tèmi pẹ̀lú èlé.” (Mát. 25:27) Ohun tí Jésù sọ nígbà yẹn ṣì wúlò gan-an lóde òní. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀.

Láwọn orílẹ̀-èdè kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí, èlé tó máa ń gun orí owó láàárín nǹkan bí ọdún mẹ́wàá máa ń ju iye téèyàn fi dókòwò lọ. Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo báńkì ló máa ń fúnni ní irú èlé bẹ́ẹ̀ lóde òní, èlé tó sì máa ń gun orí owó téèyàn fi dókòwò kì í sábà pọ̀ tó bí ẹni tó dókòwò ṣe rò pé ó máa tó. Àmọ́, ó bọ́gbọ́n mu pé kéèyàn máa tọ́jú owó pa mọ́ nítorí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì.

Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa kókó yìí pé: “Ọgbọ́n jẹ́ fún ìdáàbòbò, gẹ́gẹ́ bí owó ti jẹ́ fún ìdáàbòbò.” (Oníwàásù 7:12) Àmọ́, owó kò lè dáàbò bò ẹ́, bí o kò bá tọ́jú owó pa mọ́! Bíbélì fún wa ní ìṣírí pé: “Kí olúkúlùkù yín  . . ya ohun kan sọ́tọ̀ gedegbe ní ìpamọ́ gẹ́gẹ́ bí ó ti lè máa láásìkí.”—1 Kọ́ríńtì 16:2.

Bí O Ṣe Lè Máa Tọ́jú Owó

Àkọ́kọ́, kó o tó ra ohun kan tí owó rẹ̀ pọ̀ gan-an, kọ́kọ́ bi ara rẹ pé, ṣé mo nílò nǹkan yìí lóòótọ́?

Èkejì, tó o bá nílò ohun kan, fara balẹ̀ wá èyí tó jẹ́ tuntun tàbí àlòkù tó ṣì dáa. Àwọn òbí kan lórílẹ̀-èdè Norway tí orúkọ wọn ń jẹ́ Espen àti Janne, fẹ́ ra kẹ̀kẹ́ àwọn ọmọdé fún Daniel ọmọ wọn. Wọ́n rí èyí tí ẹnì kan ti lò díẹ̀ rà ní ìdajì iye tí wọn ì bá ra tuntun. Espen sọ pé: “Ó dá mi lójú pé a ṣì máa rí i tà ní owó tó jọjú bí Daniel kò bá lò ó mọ́.” Àmọ́, ó sọ pé: “Ó lè gba àkókò gan-an kéèyàn tó lè rí nǹkan àlòkù tó ṣì dáa.” a

Ìkẹ́ta, má kàn máa ra ohun tó o bá ṣáà ti rí, ronú dáadáa kó o tó rà á. Tó o bá wá rí i pé o nílò nǹkan náà lóòótọ́, o lè wá èyí tí kò wọ́nwó àmọ́ tó lè ṣe iṣẹ́ kan náà, tàbí kó o lọ sí ibi tí wọ́n ti ń ta èyí tí àwọn kan ti lò tẹ́lẹ̀. O tún lè máa dín owó tí ò ń ná kù tí kì í bá ṣe àwọn ọjà tí wọ́n ń ṣe ní àwọn ilé iṣẹ́ tó gbajúmọ̀ gan-an lo máa ń fẹ́ láti rà. Láfikún sí i, dípò tí wàá fi lọ ra aṣọ àwọn ọmọdé tó lòde níbi tí ọjà ti máa ń gbówó lórí, o lè kúkú lo èyí tí àwọn ọmọ rẹ kan ti lò tẹ́lẹ̀.

Bákan náà, ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ jòjòló lè ra ìtẹ́dìí ọmọ tí wọ́n fi aṣọ ṣe, èyí tí ó máa lè fọ̀ tí á sì tún un lò. Nínú ìwé kan tí obìnrin kan tó ń jẹ́ Denise Chambers ṣe, èyí tó sọ nípa bí èèyàn ṣe lè máa ṣọ́wó náà, ìyẹn ìwé Budgeting—Personal Spending and Money Management a Key to Weathering the Storm, ó sọ pé: “Ìtẹ́dìí ọmọ téèyàn máa sọ nù lẹ́yìn tó bá ti lò ó lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo lè ná èèyàn ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì owó dọ́là tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ láàárín ọdún méjì, ìyẹn nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [₦300,000] náírà. Àmọ́ iye téèyàn máa ná sórí ìtẹ́dìí aláṣọ láàárín ọdún méjì kò lè ju ọgọ́rùn-ún mẹ́ta sí ọgọ́rùn-ún márùn-ún dọ́là, ìyẹn nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùnlélógójì [₦45,000] sí ẹgbẹ̀rún márùn-ún lé láàádọ́rin [₦75,000] náírà.” Obìnrin náà fi kún un pé: “Àwọn ìtẹ́dìí aláṣọ tí wọ́n ń ṣe báyìí máa ń rọrùn láti lò, kò tún ní dá ìdọ̀tí sáàárín ìlú!”

Ìkẹrin, téèyàn bá se oúnjẹ fúnra rẹ̀, kì í náni lówó tó kéèyàn lọ ra oúnjẹ tí wọ́n ti sè. Tó o bá ní àwọn ọmọ tí wọ́n ṣì wà níléèwé, ńṣe ni kó o kọ́ wọn láti máa se oúnjẹ dípò tí wàá fi máa fún wọn lówó láti lọ ra oúnjẹ tó wọ́n. Bákan náà, dípò tí wàá fi máa ra àwọn ọtí ẹlẹ́rìndòdò tí owó rẹ̀ wọ́n, oò ṣe kúkú mu omi dípò rẹ̀. Ó máa jẹ́ kí ara rẹ le, kò sì ní ná ẹ lówó púpọ̀.

Ó wọ́pọ̀ dáadáa nígbà kan kí àwọn ìdílé máa dá oko kékeré. Ǹjẹ́ o lè máa ṣọ̀gbìn àwọn nǹkan bíi mélòó kan tó o lè jẹ? Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn, tó fi mọ́ àwọn tó ń gbé ilé elérò púpọ̀ tàbí ilé kékeré ló ní ibi tí wọ́n lè máa fi dáko. Ó lè yà ẹ́ lẹ́nu láti rí bí irè oko rẹ ṣe máa pọ̀ tó, tó o bá fi ilẹ̀ kékeré dáko!

Tún ronú lórí èyí: Tó bá pọ́n dandan pé kó o ní fóònù alágbèéká, ǹjẹ́ o lè máa lò ó fún àwọn ìpè pàjáwìrì nìkan, kó o sì rọra máa fi ìwọ̀nba owó ìpè sórí rẹ̀? Tó o bá sì ní ẹ̀rọ tó máa ń gbẹ aṣọ tó o bá fọ̀, ǹjẹ́ o lè dín bó o ṣe ń lò ó kù? O lè máa sá àwọn kan lára aṣọ tó o bá fọ̀ sórí okùn níta, nígbà míì, o tiẹ̀ lè sá gbogbo rẹ̀ sí ìta. O tún lè máa lo ẹ̀rọ amúlétutù àti amúlémóoru níwọ̀nba. Kó o tó tan àwọn ohun èlò yẹn, bi ara rẹ pé, ‘Ṣé ooru tàbí òtútù ń mú gan-an lóòótọ́?’ O tún lè ní kí àwọn ẹlòmíì sọ fún ẹ, ohun tí wọ́n ṣe láti dín iná mànàmáná tí wọ́n ń lò kù.

Ó tún máa ṣàǹfààní tó o bá ṣí àkáǹtì tí èlé á ti máa gun orí owó rẹ tàbí kó o ṣètò ìbánigbófò tí wọ́n á ti fi èlé sórí owó rẹ. Ọkùnrin kan tó jẹ́ olùyọ̀ǹda ara ẹni lórílẹ̀-èdè South Africa, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hilton, ṣàlàyé bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí èèyàn máa lo ọgbọ́n tó bá kan ọ̀ràn fifi owó pa mọ́, ó sọ pé: “Nígbà míì, báńkì àtàwọn ilé iṣẹ́ tó ń bójú tó ọ̀ràn owó máa ń kógbá wọlé. Irú ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí wa rí.” Torí náà, báńkì tí ìjọba fọwọ́ sí ní kó o máa lò, kó o lè rí owó rẹ gbà pa dà tó bá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n kógbá wọlé.

Bí O Ṣe Lè Bọ́ Nínú Gbèsè

Àkọ́kọ́, Gbìyànjú láti máa san ju iye tó yẹ kó o máa san lóṣooṣù lórí gbèsè tó o bá jẹ àti lórí káàdì tí wọ́n fi ń rajà láwìn tàbí àwọn gbèsè míì.

Èkejì, gbèsè tí owó èlé tí ò ń san lórí rẹ̀ pọ̀ jù ni kó o máa kọ́kọ́ san.

Ẹ̀kẹta, dín owó tí ò ń ná kù. Èyí ṣe pàtàkì gan-an.

Ṣé o ti ra ọjà kan rí torí pé wọ́n fi ẹnu dídùn polówó rẹ̀? Baálé ilé kan tó ń jẹ́ Danny, tó wà lórílẹ̀-èdè Sweden, sọ pé irú ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí òun rí. Ó ní okòwò kan tó ń mowó wọlé fún un, àmọ́ ńṣe ló tà á kó bàa lè san gbèsè tó jẹ. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i yìí ti kọ́ ọ lọ́gbọ́n, ní báyìí ó ti mọ béèyàn ṣe ń ṣọ́ owó ná. Ó wá fúnni ní ìmọ̀ràn yìí: “Ṣọ́ra fún ojúkòkòrò. Jẹ́ kí owó tó ń wọlé fún ọ tẹ́ ọ lọ́rùn.”

Gbèsè Tí Kò Ṣe Yẹ̀ Sílẹ̀

Ìwọ̀nba èèyàn ló lè san owó ilé tí wọ́n rà lẹ́ẹ̀kan náà. Torí náà, ọ̀pọ̀ ló máa ń yá owó ní báńkì láti fi ra ilé. Ńṣe ni owó tí wọ́n ń san sí báńkì lóṣooṣù dà bí ìgbà tí ayálégbé ń san owó ilé. Àmọ́ bí wọ́n bá ti san owó tí wọ́n yá tán, ilé náà di tiwọn nìyẹn!

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti rí i pé ó ṣàǹfààní kí àwọn ya owó ra mọ́tò tí kì í fi bẹ́ẹ̀ jẹ epo. Bí wọ́n bá tètè san owó náà tán, mọ́tò náà á wá di ohun ìní tó wúlò gan-an, ìyẹn sì tún jẹ́ ọ̀nà kan téèyàn lè gbà ṣọ́ owó ná. b Àwọn míì ti rí i pé ó ṣàǹfààní kí àwọn ra mọ́tò tí ẹnì kan ti lò rí, àmọ́ tí kò ní máa yọnu, tí wọn kò sì tíì lò púpọ̀. Ọ̀nà tí àwọn míì ń gbà ṣọ́ owó ná ni pé wọ́n máa ń wọ ọkọ̀ èrò tàbí kí wọ́n gun kẹ̀kẹ́.

Ohun yòówù kó o fẹ́ dáwọ́ lé, mọ ìwọ̀n ara rẹ, má ṣe ra ohun tí apá rẹ kò ká, kó o sì máa ronú jinlẹ̀ kó o tó ṣe ìpinnu. Tó bá jẹ́ pé ńṣe lo kàn máa ń náwó bó ṣe wù ẹ́, ó lè wá mọ́ ẹ lára, ó sì lè fa ìṣòro fún ẹ. Torí náà, kọ́ bí wàá ṣe máa ṣọ́wó ná, kó o sì máa fọgbọ́n náwó, èyí tó máa jẹ́ kó o lè ní ayọ̀ tó wà pẹ́ títí.

Síwájú sí i, kó má bàa sú ẹ láti máa tọ́jú owó pa mọ́, o gbọ́dọ̀ mọ bí o ṣe lè máa ṣọ́wó ná. Èyí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Kó o lè rí i dájú pé kì í ṣe ọjà tí ẹnì kan jí lo rà, ó bọ́gbọ́n mu pé kó o gba rìsíìtì ọjà tó o rà, kí orúkọ ẹni tó ta ọjà náà àti àdírẹ́sì onítọ̀hún sì wà lára rìsíìtì náà.

b Má ṣe gbàgbé pé, tí iṣẹ́ bá bọ́ lọ́wọ́ rẹ, tí o kò sì lè san owó tó o yá pa dà, wọ́n lè gba ilé tàbí mọ́tò náà lọ́wọ́ rẹ, wọ́n kò sì ní dá owó tó o ti san pa dà fún ẹ.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

ÀWỌN Ọ̀NÀ TÓ O LÈ MÁA GBÀ TỌ́JÚ OWÓ PA MỌ́

Wá àwọn ohun tí wọ́n fẹ́ tà

Ra aṣọ níbi tí wọ́n ti ń tajà ní ẹ̀dínwó tàbí kó o ra èyí tí ẹnì kan ti lò rí

Kọ́ àwọn ọmọ rẹ láti máa se oúnjẹ fúnra wọn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Dín iye tí ò ń ná lórí oúnjẹ kù nípa dídá oko kékeré. Máa sá aṣọ síta dípò tí wàá fi máa lo ẹ̀rọ láti gbẹ aṣọ