Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Àrùn Gbẹ̀mígbẹ̀mí Táráyé Ò Kọbi Ara Sí” Yìí Máa Tó Dópin!

“Àrùn Gbẹ̀mígbẹ̀mí Táráyé Ò Kọbi Ara Sí” Yìí Máa Tó Dópin!

“Àrùn Gbẹ̀mígbẹ̀mí Táráyé Ò Kọbi Ara Sí” Yìí Máa Tó Dópin!

“BÍ A bá fi ayé òde òní wéra pẹ̀lú àwọn ọdún bíi mélòó kan sẹ́yìn, kò sí àní-àní pé oúnjẹ pọ̀ yamùrá nínú ayé tá à ń gbé lónìí. . . . Oúnjẹ tó wà láyé tó gbogbo èèyàn jẹ, kí ó sì tún ṣẹ́ kù sílẹ̀ rẹpẹtẹ . . . gẹ́gẹ́ bí a ṣe fojú wò ó.” Èyí ni ohun tí ìwádìí kan tí Àjọ Ìlera Àgbáyé ṣe fi hàn. Bí ọ̀rọ̀ bá wá rí bẹ́ẹ̀, kí lohun náà gan-an tó ń fa àìjẹunrekánú?

Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé: “Ìṣòro ibẹ̀ ni pé a ò pèsè oúnjẹ tó tó láti jẹ bẹ́ẹ̀ ni a ò pín in dọ́gba. Lọ́pọ̀ ìgbà, ojú àwọn tálákà tó wà láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, tí ilẹ̀ wọn ń méso púpọ̀ jáde ni wọ́n ṣe máa ń kó irè oko wọ̀ǹtìwọnti lọ́pọ̀ yanturu. Ojú wọn báyìí náà ni wọ́n á sì tún fi tà á fún orílẹ̀-èdè mìíràn láti fi gba owó, tí àwọn á sì wà lọ́wọ́ òfo tí ebi á sì má a pa wọ́n. Ìyẹn túmọ̀ sí èrè ojú ẹsẹ̀ fún ìwọ̀nba èèyàn kéréje àti àdánù ọlọ́jọ́ pípẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.” Ìwádìí kan tí Àjọ Tí Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Oúnjẹ àti Iṣẹ́ Àgbẹ̀ ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé ‘ìdá kan nínú márùn-ún àwọn èèyàn tó lọ́rọ̀ jù lọ’ lágbàáyé ‘ló ń jẹ ìdá márùnlélógójì gbogbo ẹran àti ẹja tó wà láyé; nígbà tí ìdá kan nínú márùn-ún àwọn tó tòṣì jù lọ lágbàáyé ń jẹ kìkì ìdá márùn-ún péré nínú àwọn oúnjẹ wọ̀nyí.’

Lọ́nà mìíràn, “bí kò ṣe sí ẹ̀kọ́ tó yè kooro àti ìsọfúnni tó péye tún máa ń fa àìjẹunrekánú,” gẹ́gẹ́ bí Àjọ Tí Ń Bójú Tó Àkànlò Owó Tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ṣètò fún Àwọn Ọmọdé ṣe sọ. Ìròyìn náà ń bá a lọ pé: “Láìsí pé a wá ọ̀nà tó gbéṣẹ́ gan-an láti pèsè àwọn ìsọfúnni tó máa la àwọn èèyàn lóye, ká sì ṣètò àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó máa wà lárọ̀ọ́wọ́tó ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn, a ò lè ní ìmọ̀, òye, àti ìṣarasíhùwà tá a máa nílò láti fòpin sí àìjẹunrekánú.” Àmọ́ ní ìdàkejì, àìsí oúnjẹ máa ń ṣàkóbá fún ìlera ẹnì kan, kò sì ní jẹ́ kó ṣeé ṣe fún un láti ní ẹ̀kọ́ tó yè kooro—nípa bẹ́ẹ̀ ìṣòro bàǹtàbanta ni ọ̀ràn yìí jẹ́.

Àìṣègbè àti Ìfẹ́ Àìmọtara-Ẹni-Nìkan sí Àwọn Ẹlòmíràn

Láìka gbogbo àwọn ohun tó ń ṣèdíwọ́ yìí sí, àwọn ògbógi kan lórí ọ̀ràn yìí ṣì ní i lọ́kàn pé nǹkan máa dára lọ́jọ́ iwájú. Bí àpẹẹrẹ, Jacques Diouf, tó jẹ́ olùdarí àgbà fún Ètò Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Oúnjẹ àti Iṣẹ́ Àgbẹ̀, sọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé e yìí láti fi ìrètí rẹ̀ hàn, ó ní: “Mò ń fojú inú wo ayé kan níbi tí gbogbo ọkùnrin, obìnrin àti ọmọdé á ti máa ní oúnjẹ aṣaralóore ní ànító àti àníṣẹ́kù, lójoojúmọ́. Nínú ohun tí mò ń fojú inú rí, ìyàtọ̀ ńláǹlà tó wà láàárín àwọn olówó àti tálákà ti dín kù. Mo fojú inú rí bí àwọn èèyàn ṣe ń ní àmúmọ́ra fúnra wọn dípò ẹ̀tanú; tí àlàáfíà jọba dípò ogun abẹ́lé; tí wọ́n ń lo àwọn ohun àmúṣọrọ̀ ilẹ̀ lọ́nà tó lè ṣeni láǹfààní dípò bíba àyíká jẹ́; tí aásìkí wà fún tẹrútọmọ dípò ìbànújẹ́ tó lékenkà.”

Àmọ́ ṣá o, gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i, kí ìrètí yìí tó lè di ohun gidi, ohun tó ń béèrè ju mímú oúnjẹ pọ̀ sí i àti pípín in kiri lọ. Ó ń béèrè pé kí àìṣègbè àti ìfẹ́ àìmọtara-ẹni-nìkan sí àwọn ẹlòmíràn gbilẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn ànímọ́ rere yìí kò sí nínú iṣẹ́ ajé òde òní.

Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe láti fòpin sí àwọn ìṣòro kàǹkà bí ìwọra, àìrówóná, gbọ́nmi-si omi-ò-to, àti ìmọtara-ẹni-nìkan kó bàa lè ṣeé ṣe fún wa láti fòpin sí àìjẹunrekánú? Àbí, àlá tí kò lè ṣẹ lèyí jẹ́?

Ojútùú Gidi Kan Ṣoṣo Tó Wà

Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ, kò yẹ kí àwọn ìṣòro ńlá tó ń fa àìjẹunrekánú yà wá lẹ́nu. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, . . . aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, . . . aláìní ìfẹ́ ohun rere, . . . àwọn tí wọ́n ní ìrísí fífọkànsin Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọ́n já sí èké ní ti agbára rẹ̀.”—2 Tímótì 3:1-5.

Ǹjẹ́ àwọn ẹ̀dá èèyàn lè fòpin sí irú àwọn ìwà tó ti di bárakú bẹ́ẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run? Kò dájú pé yóò ṣeé ṣe, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Bóyá o ti ṣàkíyèsí pé nígbà míì, àwọn èèyàn kan tó wà nípò àṣẹ máa ń fẹ́ láti wá nǹkan ṣe sí àwọn ìṣòro tó wà láwùjọ, àmọ́ ìmọtara-ẹni-nìkan, ìfẹ́ owó, àti àìpé ẹ̀dá àwọn ẹlòmíràn kì í jẹ́ kí wọ́n lè ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ fi tinútinú ṣe.—Jeremáyà 10:23.

Síbẹ̀síbẹ̀, ojútùú tó wà fún un kì í ṣe àlá tí kò lè ṣẹ. Bíbélì ṣèlérí pé Ìjọba Ọlọ́run yóò fòpin sí ìrẹ́nijẹ àti sí gbogbo àwọn ìṣòro mìíràn tó ń pọ́n aráyé lójú lónìí.

Aísáyà 9:6, 7 fún wa ní ìrètí àgbàyanu yìí: “A ti bí ọmọ kan fún wa, a ti fi ọmọkùnrin kan fún wa; ìṣàkóso ọmọ aládé yóò sì wà ní èjìká rẹ̀. Orúkọ rẹ̀ ni a ó sì máa pè ní Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn, Ọlọ́run Alágbára Ńlá, Baba Ayérayé, Ọmọ Aládé Àlàáfíà. Ọ̀pọ̀ yanturu ìṣàkóso ọmọ aládé àti àlàáfíà kì yóò lópin, lórí ìtẹ́ Dáfídì àti lórí ìjọba rẹ̀ láti lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in àti láti gbé e ró nípasẹ̀ ìdájọ́ òdodo àti nípasẹ̀ òdodo, láti ìsinsìnyí lọ àti títí dé àkókò tí ó lọ kánrin. Àní ìtara Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò ṣe èyí.”

Ìjọba yìí náà làwọn èèyàn ń gbàdúrà fún nígbà tí wọ́n bá ń gba Àdúrà Olúwa, tí wọ́n bá ń sọ fún Ọlọ́run pé: “Kí ìjọba rẹ dé.” (Mátíù 6:9, 10) Kíyè sí i pé Aísáyà sọ pé “ìtara Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò ṣe èyí.” Ní ti tòótọ́, láti àtètèkọ́ṣe ni Jèhófà Ọlọ́run ti ń rí sí i pé òun pèsè àwọn ohun táwọn ẹ̀dá èèyàn nílò. Ó ti ṣètò ilẹ̀ ayé yìí láti máa mú ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ jáde fún gbogbo èèyàn.

Sáàmù 65:9-13 sọ nípa rẹ̀ pé: “Ìwọ ti yí àfiyèsí rẹ sí ilẹ̀ ayé, kí o lè fún un ní ọ̀pọ̀ yanturu; ìwọ sọ ọ́ di ọlọ́rọ̀ gidigidi. Ìṣàn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kún fún omi. Ìwọ ti pèsè ọkà wọn sílẹ̀, nítorí pé bí ìwọ ṣe pèsè ilẹ̀ ayé sílẹ̀ nìyẹn. Fífi omi rin aporo rẹ̀ gbingbin wáyé, àti mímú ògúlùtu rẹ̀ tẹ́jú; ìwọ fi ọ̀pọ̀ yanturu ọ̀wààrà òjò mú un dẹ̀; ìwọ bù kún èéhù rẹ̀ pàápàá. . . . Àwọn pápá ìjẹko ni a ti fi àwọn agbo ẹran bò, àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ni a sì fi ọkà bò kanlẹ̀.”

Láìsí àní-àní, Ẹlẹ́dàá wa Jèhófà ni olùpèsè tó ga jù lọ fún ọmọ aráyé. Òun ni “Ẹni tí ń fi oúnjẹ fún gbogbo ẹlẹ́ran ara: nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Sáàmù 136:25.

Kí á ní ìdánilójú pé Ìjọba Ọlọ́run lábẹ́ ìṣàkóso Kristi yóò bójú tó gbogbo èèyàn. Bíbélì sọ pé: “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.” Yàtọ̀ síyẹn, oúnjẹ yóò wà fún gbogbo èèyàn lọ́gbọọgba, nítorí pé “[Jésù Kristi] yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́. . . . Yóò sì gba ọkàn àwọn òtòṣì là.” (Sáàmù 72:12, 13, 16) Nítorí náà, mọ́kàn le! “Àrùn gbẹ̀mígbẹ̀mí táráyé ò kọbi ara sí” yìí máa tó yanjú pátápátá láìpẹ́.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]

“Mímú ebi àti àìjẹunrekánú kúrò ṣeé ṣe bí a bá fojú bí ipò nǹkan ṣe rí wò ó. Àwọn ohun tá a lè lò wà. Ohun tó jẹ́ ìpèníjà ibẹ̀ ni pé . . . kí orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan tó wà lágbàáyé, àti gbogbo orílẹ̀-èdè lápapọ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀.”—Àjọ Ìlera Àgbáyé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]