Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí N Máa Wo Àwọn Fídíò Orin?

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí N Máa Wo Àwọn Fídíò Orin?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí N Máa Wo Àwọn Fídíò Orin?

“Àwọn fídíò orin ti lọ wà jù. Ńṣe làwọn kan máa ń dà bí àwọn eré tó ṣe ṣókí tí wọ́n máa ń ṣe lórí tẹlifíṣọ̀n. Wọ́n máa ń fi fídíò orin sọ ìtàn, mo sì máa ń gbádùn bí wọ́n ṣe máa ń fi ijó dárà nínú rẹ̀.”—Casey.

“Wọ́n máa ń jẹ́ kéèyàn mọ àwọn orin tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dórí àtẹ. Wọ́n á jẹ́ kó o mọ àwọn orin tó dùn jù lọ lára àwọn orin tó wà lóde. Yàtọ̀ síyẹn, sísọ̀rọ̀ nípa àwọn fídíò orin jẹ́ ohun tó máa ń lárinrin gan-an.”—Josh.

“Gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ inú fídíò orin ló ṣe pàtàkì sí mi—ẹni tó ń kọrin, irú aṣọ tó wọ̀, àti bó ṣe ń jó. Gbogbo èyí ló máa ń jẹ́ kí n lóye ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú orin náà.”—Kimberly.

“Mo máa ń fẹ́ láti rí ohun tí ẹgbẹ́ olórin tí mo fẹ́ràn jù lọ máa gbé jáde lọ́tẹ̀ yìí. Mo fẹ́ràn àwọn àwòrán àti ìró ohùn tí wọ́n máa ń fi kún fídíò náà kó lè túbọ̀ mórí ẹni wú. Àwọn fídíò kan sì máa ń pani lẹ́rìn-ín. Àmọ́ èèyàn ní láti ṣọ́ra.”—Sam.

BÓYÁ ìwọ náà máa ń gbádùn wíwo àwọn fídíò orin. Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ ń gbé wọn jáde lórí tẹlifíṣọ̀n, wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ náwó lé wọn lórí wọn kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ dùn. Àmọ́, nígbà tí àwọn fídíò orin di ohun táyé ń gba tiẹ̀ gan-an, tó tún jẹ́ pé owó gọbọi làwọn tó ń ta àwo orin ń pa lórí wọn, èyí mú kí wọ́n túbọ̀ máa dá àwọn àrà oríṣiríṣi sínú wọn, tí wọ́n sì ń mú kí wọ́n máa fa àwọn èèyàn mọ́ra sí i. Lóde òní, wọn ò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn lágbo orin, wọ́n sì gbayì gan-an láàárín àwọn ọ̀dọ́. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n kan tiẹ̀ wà tó jẹ́ pé àwọn fídíò orin nìkan ni wọ́n máa ń fi hàn látàárọ̀ ṣúlẹ̀!

Ṣùgbọ́n kí nìdí tí àwọn ọ̀dọ́ kan, irú bíi Sam tá a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ yìí, fi sọ pé ó yẹ kéèyàn ṣọ́ra? Ṣé kì í ṣe pé àwọn fídíò orin kan wà tó lè ní ipa búburú lórí rẹ—bóyá kí wọ́n máa gbin èròkerò sí ọ lọ́kàn, kí wọ́n ba ìwà ọmọlúwàbí rẹ jẹ́, tàbí kí wọ́n tiẹ̀ ba àjọṣe tó o ní pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá rẹ jẹ́? O lè máa wò ó pé irú ìbéèrè wo lèyí kẹ̀. Àmọ́ rò ó wò ná, bó o bá fẹ́ lúwẹ̀ẹ́ nínú odò kan tàbí nínú òkun, tó o sì rí àwọn àmì ìkìlọ̀ pé ó léwu láti lúwẹ̀ẹ́ níbẹ̀, ǹjẹ́ á bọ́gbọ́n mu láti kọ etí dídi sí irú ìkìlọ̀ bẹ́ẹ̀? Rárá o. Bó bá rí bẹ́ẹ̀ nígbà náà, ó bọ́gbọ́n mu kó o ṣàyẹ̀wò àwọn ìkìlọ̀ díẹ̀ nípa àwọn fídíò orin.

Àwọn Ewu Tó Wà Nínú Rẹ̀

Ó yẹ kó o gbà pé ohun tó ò ń rí àti ohun tó ò ń gbọ́ lè nípa lórí rẹ! Bíbélì sọ fún wa pé, Sọ́ọ̀lù, ọba tó kọ́kọ́ jẹ ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì, lo orin lọ́nà tó ṣàǹfààní—ìyẹn ni láti fi mú kí ara tù ú. (1 Sámúẹ́lì 16:14-23) Ǹjẹ́ orin tún lè ní ipa búburú lórí ẹni? Ìwé náà, Rock and Roll—Its History and Stylistic Development ṣàlàyé pé: “Bí orin ṣe dára tó náà ló tún ní àbùkù tiẹ̀. Bí a bá gbà pé orin rọ́ọ̀kì ti ní ipa rere lórí àwọn èèyàn (gẹ́gẹ́ bí ìrírí ti fi hàn), ó tún yẹ ká gbà pé ó ti ní ipa búburú lórí àwọn èèyàn (gẹ́gẹ́ bí ìrírí ti fi hàn). Bí ẹnì kan bá ń fọ́nnu pé, ‘Ní tèmi o, mo máa ń gbọ́ orin dáadáa, àmọ́ kì í nípa kankan lórí mi,’ á jẹ́ pé onítọ̀hún kò mọ ohun tó ń sọ tàbí pé kò dákan mọ̀ rárá.”

Léraléra ni Bíbélì fi hàn pé ohun tá a bá fi ojú rí máa ń nípa lórí ìrònú àti ìmọ̀lára wa. (Òwe 27:20; 1 Jòhánù 2:16) Nítorí náà, bí àwọn tó ń gbé fídíò orin jáde ṣe ń fi ohun téèyàn lè fojú rí kún orin lọ́nà tó máa fi wọni lọ́kàn ṣinṣin máa ń mú kí ipa tí orin ń ní lórí àwọn tó ń gbọ́ ọ pọ̀ sí i gidigidi. Irú àwọn nǹkan wo ni wọ́n sábà máa ń fi hàn?

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwádìí kan fi hàn, nǹkan bí ìdá mẹ́tàdínlọ́gọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn fídíò orin rọ́ọ̀kì ló máa ń ní ìwà ipá nínú. Nǹkan bí ìdá mẹ́rìndínlọ́gọ́rin ló sì ń ní ìwà pálapàla nínú. Ìwádìí mìíràn lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé ìdá márùndínlọ́gọ́rin àwọn fídíò tí wọ́n ń fi sọ ìtàn ló ń ní ìṣekúṣe nínú, nígbà tí ohun tó lé ní ìdajì wọn sì ní ìwà ipá nínú, tí èyí sábà máa ń jẹ́ sí àwọn obìnrin. Pẹ̀lú gbogbo ìsọfúnni yìí, ǹjẹ́ wíwo irú àwọn fídíò bẹ́ẹ̀ lè ṣèpalára fún ọ lóòótọ́? Ìwé ìròyìn kan sọ pé “àwọn ìwádìí mẹ́tàdínlógójì tí wọ́n ṣe fi hàn pé wíwo àwọn fídíò orin lè mú kí àwọn ọ̀dọ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà tètè máa ní ìbálòpọ̀ tàbí kí wọ́n máa ní ìbálòpọ̀ tó léwu.” Bákan náà, kò sí àní-àní pé bí àwọn olórin ṣe ń gbìyànjú láti ta àwọn tó ti ń kọrin ṣáájú wọn àtàwọn ẹlẹgbẹ́ wọn yọ, ńṣe ni wọ́n túbọ̀ ń mú kí àwọn ohun tó burú tí wọ́n ń fi hàn nínú àwọn fídíò orin pọ̀ sí i.

Ògbógi kan nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ sọ pé: “Ọ̀pọ̀ máa ń jiyàn pé ohun tí àwọ́n ń gbọ́, àti èyí tí àwọ́n ń rí nínú fídíò orin kò yàtọ̀ sí ohun tó wà nínú àwọn orin ìgbà àtijọ́ . . . Àmọ́ ó dà bíi pé ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn olórin ayé òde òní ló máa ń ní ìwà àfojúdi, tí wọ́n á máa gbé ìsọkúsọ àti ìwà tí kò bójú mu lárugẹ kí àwọn àwo orin wọn lè tà gan-an.” Ìwé ìròyìn Chicago pẹ̀lú sọ̀rọ̀ lórí àwọn tó máa ń wo fídíò orin lórí ìkànnì tẹlifíṣọ̀n kan báyìí, ó ní: “Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìran tí kò bójú mu tó ń gbé àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè lárugẹ ni wọ́n máa ń wò níbẹ̀.”

Ìwé ìròyìn Chicago tún sọ̀rọ̀ nípa fídíò orin kan, tó ṣe àfihàn “ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó jókòó lórí tábìlì nínú ilé oúnjẹ kan tó sì sọ orí sẹ́yìn. Ọgbẹ́ ńlá kan tó kún fún ẹ̀jẹ̀ fara hàn ní ọrùn rẹ̀, orí rẹ̀ sì jábọ́ sílẹ̀.” Ìròyìn mìíràn fi hàn pé nínú fídíò bíburú jáì kan, ọkùnrin kan ń bọ́ aṣọ tó wọ̀ sọ́rùn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan, ó sì tún bẹ̀rẹ̀ sí fa ẹran ara rẹ̀ àti iṣan ara rẹ̀ ya pẹ̀lú. Wọ́n tún fi àwọn nǹkan mìíràn tó ń múni gbọ̀n rìrì tí kò ṣeé fẹnu sọ hàn nínú fídíò náà.

Àwọn kan lè sọ pé ọ̀rọ̀ ò rí bí wọ́n ṣe sọ ọ́ yẹn, pé àwọn fídíò tá a sọ̀rọ̀ nípa wọn níbí ni kò dára rárá, àti pé ọ̀pọ̀ fídíò orin ni kò fi bẹ́ẹ̀ burú. Àwọn kan tiẹ̀ lè sọ pé àwọn kò rí ohun gidi kan tó ń ríni lára tàbí tó ń múni gbọ̀n rìrì nínú àwọn fídíò náà. Àmọ́ ṣé kì í ṣe pé ohun tí èyí wulẹ̀ ń túmọ̀ sí ni pé, wíwo irú àwọn fídíò bẹ́ẹ̀ láwòtúnwò ti ra irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ níyè? Casey, ọ̀dọ́mọkùnrin tá a mẹ́nu kàn ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, sọ pé: “Bí o kò bá fi ààlà sí ohun tó ò ń wò, ohun tó ti máa ń rí ọ lára tẹ́lẹ̀ yóò di ohun tí kò ní ṣe ọ́ bákan mọ́. O ò ní mọ ìgbà tí yóò máa wù ọ́ láti wo àwọn fídíò tó burú ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, tí àwọn ohun tó ti máa ń mú ọ gbọ̀n rìrì á wá di ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ burú mọ́ lójú rẹ.”

Kí ló lè jẹ́ àbájáde èyí? Ó lè wá di ohun tó ṣòro fún ọ gan-an láti fi làákàyè ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Nítorí pé ó rọrùn gan-an kí àwọn ohun tí kò dára nípa lórí ìrònú wa, Bíbélì rọ̀ wá pé ká “fi ìṣọ́ ṣọ́ ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ àti agbára láti ronú.” (Òwe 3:21; 5:2) Àbájáde búburú mìíràn ni pé, wọ́n lè ba àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run jẹ́. Ǹjẹ́ ìyẹn kọ́ lohun tó ṣe pàtàkì sí ọ jù lọ? Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé kó o pa àjọṣe yẹn mọ́ nípa ṣíṣe àwọn ohun tó bá yẹ ní ṣíṣe láti yàgò fún eré ìnàjú èyíkéyìí tí kò bá bójú mu. Báwo lo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?

Bí O Ṣe Lè Dáàbò Bo Ara Rẹ

Lákọ̀ọ́kọ́ ná, gbà pé ó lòdì pátápátá láti máa wo ìran èyíkéyìí tó bá ń ṣe àfihàn ohun tí Bíbélì dìídì dá lẹ́bi. (Sáàmù 11:5; Gálátíà 5:19-21; Ìṣípayá 21:8) Bí fídíò kan bá ń gbé àwọn ohun tí kò “yẹ àwọn ènìyàn mímọ́” lárugẹ, o gbọ́dọ̀ pinnu láti má ṣe wò ó mọ́. (Éfésù 5:3, 4) Lóòótọ́ o, ó lè má rọrùn láti yí tẹlifíṣọ̀n sí ìkànnì mìíràn tàbí láti pa á, bó bá jẹ́ pé fídíò alárinrin kan lò ń wò. Nítorí náà, ohun tó dára ni pé kó o gbàdúrà bíi ti onísáàmù tó kọ̀wé pé: “Mú kí ojú mi kọjá lọ láìrí ohun tí kò ní láárí.”—Sáàmù 119:37.

Ó lè máa rí ọ lára tó o bá wo àwọn fídíò tó ń múni gbọ̀n rìrì bí irú àwọn tá a mẹ́nu kàn lókè. Àmọ́, ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ ni wọ́n fi ṣe àwọn fídíò kan. Àwọn ibi tí wọ́n ti fi ìwà pálapàla hàn lè má pọ̀ nínú wọn tàbí kó jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni wọ́n á máa gbé e sí i. Wọ́n lè ti fi ọgbọ́n ṣètò àwọn ọ̀rọ̀ inú orin náà àtàwọn ohun tí wọ́n máa fi hàn kó lè gbé àwọn ìlànà kan tí inú Ọlọ́run kò dùn sí yọ láìsí pé wọ́n sọ̀rọ̀ tàbí fi ohun kan tó burú jáì hàn ní kedere. Àmọ́, bó bá dà bíi pé ọkàn rẹ dá ọ lẹ́bi díẹ̀ lórí fídíò kan tó o wò, ó lè jẹ́ pé kò bójú mu nìyẹn tàbí pé kò bá ìlànà Kristẹni mu lọ́nà kan tàbí òmíràn. Nígbà náà, báwo lo ṣe lè pinnu ohun tó yẹ kó o wò àti ohun tó yẹ kó o yàgò fún nígbà tí fídíò kan kò bá fi àwọn ìwà tó burú hàn ní kedere?

Lóòótọ́, bóyá ò ń wo fídíò orin tàbí o kì í wò ó rárá jẹ́ ìpinnu tìẹ fúnra rẹ àti ti àwọn òbí rẹ, tí wọ́n ní ẹrù iṣẹ́ láti pinnu ohun tó o lè wò àti èyí tó ò lè wò. (Éfésù 6:1, 2) Ṣùgbọ́n, bí àwọn òbí rẹ bá gbà ọ́ láyè láti máa wo fídíò orin, kò yẹ kó jẹ́ pé ohun tó bá ṣáà ti dára lójú rẹ ni yóò máa darí rẹ. Hébérù 5:14 rọ̀ wá pé ká ‘kọ́ agbára ìwòye wa’ kó bàa lè ṣeé ṣe fún wa “láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” A lè kọ́ agbára ìwòye wa nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìlànà Bíbélì, èyí tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti pinnu ohun tó dára àti ohun tó burú lójú Jèhófà. Bí o bá ń ṣàṣàrò lórí irú àwọn ìlànà Bíbélì bẹ́ẹ̀, wàá lè mọ ohun tó lè ṣàkóbá fún ìlera rẹ nípa tẹ̀mí, kódà nígbà tí kò bá sí ìlànà Bíbélì pàtó kan láti tọ́ ọ sọ́nà.

Bọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn ìlànà Bíbélì wo ní pàtó ló lè tọ́ ọ sọ́nà nínú ọ̀ràn wíwo fídíò orin? A óò jíròrò èyí nínú àpilẹ̀kọ tó máa jáde lọ́jọ́ iwájú.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 14]

“Bí ẹnì kan bá ń fọ́nnu pé, ‘Ní tèmi o, mo máa ń gbọ́ orin dáadáa, àmọ́ kì í nípa kankan lórí mi,’ á jẹ́ pé onítọ̀hún kò mọ ohun tó ń sọ tàbí pé kò dákan mọ̀ rárá”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ṣé lóòótọ́ lo lè wo ohun tí kò dára kó má sì nípa lórí rẹ?