Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbẹ̀wò sí Ìlú Tí Wọ́n Ti Ń Wa Góòlù Dúdú

Ìbẹ̀wò sí Ìlú Tí Wọ́n Ti Ń Wa Góòlù Dúdú

Ìbẹ̀wò sí Ìlú Tí Wọ́n Ti Ń Wa Góòlù Dúdú

LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ BRAZIL

Ó ṢEÉ ṣe kó o máà tíì gbọ́ nípa ìlú tí wọ́n ń pè ní Ouro Prêto rí, èyí tó wà ní orílẹ̀-èdè Brazil, àmọ́ ní ọ̀rúndún kejìdínlógún, ìlọ́po mẹ́ta làwọn èèyàn tó ń gbé níbẹ̀ fi ju àwọn tó ń gbé nílùú New York City lọ. Nígbà kan, owó tí wọ́n ń rí nínú ìlú yìí ni wọ́n fi kọ́ ìlú Lisbon tó wà ní ilẹ̀ Potogí, nígbà tí ìsẹ̀lẹ̀ ba ìlú náà jẹ́. Lọ́dún 1980, Àjọ Ètò Ẹ̀kọ́, Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀, àti Àṣà Ìbílẹ̀ ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fi ìlú Ouro Prêto kún Ara Ibi Tí Nǹkan Àlùmọ́ọ́nì Ayé Fìdí Kalẹ̀ Sí, èyí tó wá mú kó jẹ́ ọ̀kan lára ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [700] àwọn ibi tó ta yọ jù lọ lágbàáyé nínú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àtàwọn ohun àdánidá. Kí ló dé tí wọ́n fi fún ìlú Ouro Prêto ní iyì tó tó báyìí? Ìwọ gbé ìtàn ìlú tí kò lẹ́gbẹ́ yìí yẹ̀ wò ná.

Omi Tí Ẹnì Kan Mu Ló Yọrí sí Ṣíṣàwárí Góòlù

Láàárín àádọ́ta ọdún àkọ́kọ́ ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún, ọ̀pọ̀ àwọn olùṣàwárí ọmọ ilẹ̀ Potogí, tí wọ́n ń pè ní bandeirantes, bẹ̀rẹ̀ sí lọ káàkiri ilẹ̀ Brazil, wọ́n ń wá àwọn àgbègbè tuntun, àwọn ẹrú tó jẹ́ ọmọ Íńdíà àti góòlù kiri. Nínú irú ìrìn àjò wọn kan bẹ́ẹ̀, wọ́n wọ àárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè náà títí wọ́n fi dé Òkè Ńlá Itacolomi. Níbẹ̀, olùṣàwárí kan tó ń jẹ́ Duarte Lopes lọ síbi odò kékeré kan tó ń ṣàn láti pa òùngbẹ rẹ̀. Ó fi abọ́ onígi tó wà lọ́wọ́ rẹ̀ bu omi díẹ̀ ó sì mu ún. Bẹ́ẹ̀ ló ṣàkíyèsí pé àwọn òkúta wẹ́wẹ́ kan wà nínú abọ́ onígi náà.

Lopes ta àwọn òkúta náà fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan, ṣùgbọ́n nígbà tí ọ̀rẹ́ náà fura pé òkúta ṣíṣeyebíye làwọn òkúta wẹ́wẹ́ náà, ó fi wọ́n ránṣẹ́ sí gómìnà ìpínlẹ̀ Rio de Janeiro. Nígbà tí gómìnà náà yẹ àwọn òkúta yìí wò, ó rí i pé ojúlówó góòlù ni wọ́n, tí àwọn nǹkan dúdú kan bò lára. Àmọ́ ibo ni góòlù náà ti wá? Gbàrà tí Lopes ti júwe ibi tí Itacolomi wà làwọn olùṣàwárí ti bẹ̀rẹ̀ sí lọ wá ibẹ̀. Lọ́dún 1698, olùṣàwárí kan tó ń jẹ́ Antônio Dias de Oliveira rí òkè ńlá tí wọ́n ti rí góòlù náà. Láìjáfara rárá, ńṣe làwọn tó ń wá góòlù kiri rọ́ lọ sí àgọ́ kan tó wà nítòsí ibi tí wọ́n ti ń rí ohun ṣíṣeyebíye yìí, ìyẹn ibì kan tí wọ́n ń pè ní Vila Rica lẹ́yìn náà. Kò pẹ́ kò jìnnà, àwọn èèyàn tó ń gbé Vila Rica wọ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rin [80,000]. Bí àkókò ti ń lọ, ó di olú ìlú Minas Gerais, wọ́n sì sọ ọ́ ní Ouro Prêto, tó túmọ̀ sí “Góòlù Dúdú.”

Góòlù Dúdú Fa Ìtàjẹ̀sílẹ̀

Láàárín ọdún 1700 sí 1820, ẹgbẹ̀fà tọ́ọ̀nù góòlù làwọn tó ń ṣàwárí góòlù wà jáde nínú ilẹ̀—èyí jẹ́ ìdá ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo góòlù tí wọ́n mú jáde kárí ayé ní àkókò yẹn. Àmọ́ ibo ni gbogbo góòlù yẹn ń lọ? Ńṣe ni wọ́n máa ń yọ́ wọn ní ibì kan tí wọ́n ń pè ní Casa dos Contos, tàbí Ilé Ìyí-Nǹkan-Padà, tí wọ́n á sì wá ṣe wọ́n sí ọ̀pá gbọọrọ gbọọrọ. Lẹ́yìn náà, ìdá kan nínú márùn-ún góòlù náà á lọ sápò ìdílé ọba ilẹ̀ Potogí, èyí dúró fún owó orí táwọn tó ń wa góòlù náà ń san.

Àwọn tó wá tẹ̀dó náà ta ko owó orí yìí. Ọ̀kan lára wọn tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Felipe dos Santos ru àwọn awakùsà, àwọn ọkùnrin ológun àtàwọn mẹ́ńbà ṣọ́ọ̀ṣì sókè láti ta ko àṣẹ Ọba ilẹ̀ Potogí. Àmọ́ àwọn Potogí jà padà. Lọ́dún 1720, wọ́n yẹgi fún Felipe dos Santos wọ́n sì fi ẹṣin wọ́ òkú rẹ̀ kiri láwọn òpópónà. Bí àwọn awakùsà náà ṣe padà sídìí iṣẹ́ wọn nìyẹn tí owó orí náà sì ń ga sí i.

Àmọ́ ṣá o, èyí kàn dáwọ́ ìṣọ̀tẹ̀ náà dúró fúngbà díẹ̀ ni. Ní ọ̀rúndún yẹn kan náà, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Joaquim da Silva Xavier tún dìde, tí ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Tiradentes, èyí tó túmọ̀ sí “olùfa eyín tu”—ìyẹn ń tọ́ka sí ọ̀kan lára iṣẹ́ tó máa ń ṣe. Ó jẹ́ ọ̀kan lára agbo àwọn akéwì, àwọn amòfin, àtàwọn ọkùnrin ológun ìlú Ouro Prêto, tí wọ́n máa ń pàdé déédéé ní ilé àlùfáà kan tó ń jẹ́ Toledo. Níbẹ̀rẹ̀, ohun tí wọ́n máa ń sábà sọ̀rọ̀ lé lórí ni ìmọ̀ ọgbọ́n orí, èyí tí wọ́n máa ń fi dápàárá, àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n kọjá sórí ọ̀rọ̀ ìṣèlú ayé ìgbà náà. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ìjíròrò wọn di ti ọlọ̀tẹ̀, tí wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ lóhùn kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ nípa bí ohun tí Ìjọba ilẹ̀ Potogí ń béèrè ṣe ń mú ìnira bá wọn. Ọbabìnrin ilẹ̀ Potogí, Dona Maria Kìíní, ti kìlọ̀ ṣáájú pé bíbẹ́ ni wọ́n máa bẹ́ orí àwọn tó bá dìtẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, lọ́dún 1788, Tiradentes, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ogun ojú omi lásìkò náà, ló jẹ́ aṣáájú nínú Inconfidência Mineira, èyí tó túmọ̀ sí Ọ̀tẹ̀ Ìlú Minas Gerais.

Ẹnì kan tó jẹ́ amí ló sọ orúkọ àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà fún àwọn aláṣẹ. Ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣà wọ́n lọ́kọ̀ọ̀kan tí wọ́n sì rán wọn nígbèkùn lọ sí ilẹ̀ Áfíríkà láti lọ kú síbẹ̀. Tiradentes ní tirẹ̀ fimú dánrin nínú yàrá ẹ̀wọ̀n mímóoru tí wọ́n jù ú sí ní ìpínlẹ̀ Rio de Janeiro kí wọ́n tó wá yẹgi fún un ní April 21, ọdún 1792 tí wọ́n sì bẹ́ orí rẹ̀. Ńṣe ni wọ́n gbé orí Tiradentes kọ́ sára òpó kan ní gbàgede ìlú Ouro Prêto, wọ́n gé ara rẹ̀ sọ́nà mẹ́rin, wọ́n sì so àwọn apá àti ẹsẹ̀ rẹ̀ mọ́ ara àwọn òpó lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ àwọn ọ̀nà kan. Fún àkókò díẹ̀, èyí mú kí ẹnikẹ́ni tó lè ti fẹ́ dáná ọ̀tẹ̀ tọwọ́ ọmọ rẹ̀ bọṣọ. Àmọ́ ní ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn náà, ìyẹn ọdún 1822, ilẹ̀ Brazil gbòmìnira lọ́wọ́ ilẹ̀ Potogí.

Ìṣúra Iṣẹ́ Ọnà, Ìtàn àti Ìsìn

Bí àkókò ti ń lọ, wọ́n wa gbogbo góòlù ìlú Ouro Prêto tán, iyì rẹ̀ sì dín kù. Àmọ́ ìlú náà ṣì ní àwọn iṣẹ́ ọnà àtàwọn ohun mìíràn tó ń ránni létí ìtàn rẹ̀. Kò ṣòro láti rí díẹ̀ lára àwọn nǹkan wọ̀nyí ní Ibi Ìkóhun-Ìṣẹ̀ǹbáyé-Sí ti Inconfidência, tó wà ní gbàgede Praça Tiradentes. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, gbọ̀ngàn ìlú àti ọgbà ẹ̀wọ̀n ni ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí yìí jẹ́, àmọ́ ó ti wá di ibi tó ń ránni létí iṣẹ́ ọnà, ìtàn, àtàwọn ohun ìbànújẹ́ tó ti wáyé ní ìlú náà.

Lára àwọn nǹkan tí wọ́n ṣàfihàn níbẹ̀ ni ìwé àṣẹ tí wọ́n fi pa Tiradentes, èyí tí Ọbabìnrin Dona Maria Kìíní fọwọ́ sí, àti àṣẹ́kù lára igi tí wọ́n gbé e kọ nígbà tí wọ́n fẹ́ pa á. Lábẹ́ àwọn bíríkì pẹlẹbẹ onígun mẹ́rin tí wọ́n tò ní ìlà ìlà bí ìgbà tí wọ́n to bẹ́ẹ̀dì sínú ilé elérò púpọ̀, ni wọ́n sin egungun díẹ̀ lára àwọn ọlọ̀tẹ̀ ẹlẹgbẹ́ Tiradentes sí. Nínú àwọn yàrá tó wà ní àjà mìíràn nínú ilé náà, wọ́n kó àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé pa mọ́ síbẹ̀, àwọn nǹkan tó ti wà kí ilẹ̀ Brazil tó gbòmìnira àtàwọn nǹkan tó wà lákòókò tí olú ọba ń ṣàkóso.

Ohun Ìdùnnú Fáwọn Tó Fẹ́ràn Òkúta Ṣíṣeyebíye

Béèyàn bá rìn lọ sí apá ibi tí gbàgede Praça Tiradentes parí sí, lọ́wọ́ òkè, yóò já sí ibòmíràn tí wọ́n tún kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ìṣúra pa mọ́ sí—ìyẹn ibi tí wọ́n ń pè ní Ààfin Gómìnà, níbi táwọn gómìnà àtàwọn ààrẹ Orílẹ̀-èdè ń gbé nígbà kan rí. Báyìí, ó ti di ilé ẹ̀kọ́ Escola de Minas, ìyẹn ibi tí wọ́n ti ń kọ́ ẹ̀kọ́ síwájú sí i nípa ìwakùsà, ìmọ̀ nípa ilẹ̀ àtàwọn ohun tó wà nínú rẹ̀, àti ìmọ̀ nípa irin. Ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí ilé ẹ̀kọ́ náà ṣàfihàn ọ̀kẹ́ kan [20,000] àwọn ohun àmúṣọrọ̀ inú ilẹ̀, àwọn òkúta ṣíṣeyebíye, kristali, ouro prêto, tí í ṣe góòlù dúdú náà kò sì gbẹ́yìn tí gbogbo wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Lónìí, kò sí góòlù púpọ̀ bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Síbẹ̀, wọ́n ṣì ń rí àwọn òkúta ṣíṣeyebíye ní àgbègbè náà, àwọn òkúta bí beryl aláwọ̀ búlúù àti aláwọ̀ ewé àti tópásì aláwọ̀ ìyeyè ti àkókò olú ọba. Ní nǹkan bí àádọ́ta ọdún sẹ́yìn, ìwọ̀nba èèyàn ló mọ iṣẹ́ ọnà gbígbẹ́ àwọn òkúta oníyebíye yìí lámọ̀dunjú. Àmọ́ lónìí, àwọn tó ń wá àwọn òkúta ṣíṣeyebíye yìí kiri àtàwọn ṣọ́ọ̀bù tí wọ́n ti ń ta àwọn ohun ọ̀ṣọ́ ti pọ̀ ní àgbègbè Praça Tiradentes. Kì í ṣe pé àwọn tó ni ṣọ́ọ̀bù náà á ṣàlàyé bó o ṣe lè dá àwọn òkúta ṣíṣeyebíye náà mọ̀ nìkan ni, àmọ́ wọ́n á tún fi àwọn tó ń gbẹ́ àwọn òkúta náà àtàwọn tó ń dán an hàn ọ́, tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ láwọn yàrá tó wà lẹ́yìn àwọn ṣọ́ọ̀bù náà. Inú àwọn náà á sì dùn láti fi bí wọ́n ṣe ń gbẹ́ ẹ hàn ọ́. Àyẹ́sí àti aájò àwọn èèyàn ìlú náà fi hàn pé àǹfààní ńlá ni wọ́n kà á sí láti máa gbé ní ìlú kan tí ìtàn rẹ̀ ń fa àwọn èèyàn mọ́ra.

Bó o bá fẹ́ ṣeré lọ sí ilẹ̀ Brazil, rí i dájú pé o fẹsẹ̀ kan dé ìlú Ouro Prêto—ìlú ẹlẹ́wà tó sì fani mọ́ra gbáà ni.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 16]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Ouro Prêto

[Credit Line]

Àwòrán ilẹ̀: Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]

Nígbà tí wọ́n bá mú àwọn nǹkan dúdú tó bo àwọn òkúta yìí kúrò, góòlù ni wọ́n máa bá níbẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Ìlú Ouro Prêto, tí Òkè Ńlá Itacolomi wà lẹ́yìn rẹ̀ lọ́hùn-ún

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Ibi Ìkóhun-Ìṣẹ̀ǹbáyé-Sí ti Inconfidência, lágbègbè Praça Tiradentes

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Àwọn òkúta iyebíye aláwọ̀ búlúù, aláwọ̀ ìyeyè àti aláwọ̀ ewé

[Credit Line]

Àwọn òkúta ṣíṣeyebíye: Brasil Gemas, Ouro Preto, MG