Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Nìdí Tí Ọ̀nà Tí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Ń Ṣe Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa Fi Yàtọ̀ sí Ti Àwọn Ẹlẹ́sìn Tó Kù?

Kí Nìdí Tí Ọ̀nà Tí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Ń Ṣe Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa Fi Yàtọ̀ sí Ti Àwọn Ẹlẹ́sìn Tó Kù?

 Ohun tí Bíbélì sọ gẹ́lẹ́ nípa bó ṣe yẹ ká máa ṣe Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa tí wọ́n tún ń pè ní “oúnjẹ Olúwa” àti Ìrántí Ikú Jésù ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé. (1 Kọ́ríńtì 11:20; Bíbélì Mímọ́) Àmọ́ ní ìyàtọ̀ pátápátá, ìgbàgbọ́ àti ohun tí àwọn ẹlẹ́sìn míì máa ń ṣe nípa oúnjẹ alẹ́ Olúwa kò bá ohun tí Bíbélì sọ mu.

Ìdí tá a fi ń ṣe é

 Ìdí tá a fi ń ṣe Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ni pé ká lè rántí Jésù, ká sì fi ẹ̀mí ìmoore hàn fún bó ṣe fi ara rẹ̀ rúbọ nítorí wa. (Mátíù 20:28; 1 Kọ́ríńtì 11:24) Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa kì í ṣe ààtò ẹ̀sìn tàbí àṣà ẹ̀sìn táá jẹ́ ká gba oore ọ̀fẹ́ tàbí ká rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. a Bíbélì kọ́ wa pé ìgbàgbọ́ nínú Jésù ló máa jẹ́ ká rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà, kì í ṣe ààtò ẹ̀sìn.​—Róòmù 3:​25; 1 Jòhánù 2:​1, 2.

Báwo ló ṣe yẹ ká máa ṣe é tó?

 Jésù pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa ṣe ìrántí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, àmọ́ kò sọ ní pàtó bí wọ́n ṣe gbọ́dọ̀ máa ṣe é léraléra tó. (Lúùkù 22:19) Àwọn kan rò pé oṣooṣù ló yẹ kó jẹ́, àwọn míì sì máa ń ṣe é lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, lójoojúmọ́, ní àìmọye ìgbà lóòjọ́ tàbí iye ìgbà tó bá ti ń wu èèyàn jẹ. b Bó ti wù kó rí, díẹ̀ lára àwọn ohun pàtàkì tó yẹ ká fi sọ́kàn rèé.

 Alẹ́ ọjọ́ táwọn Júù ṣe Ìrékọjá ni Jésù dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀, ọjọ́ yẹn náà ló sì kú. (Mátíù 26:​1, 2) Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ò kàn ṣèèṣì wáyé. Ìwé Mímọ́ fi ikú ìrúbọ Jésù yìí wé ti ọ̀dọ́ àgùntàn Ìrékọjá. (1 Kọ́ríńtì 5:​7, 8) Ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún ni wọ́n máa ń ṣe Ìrékọjá yìí. (Ẹ́kísódù 12:​1-6; Léfítíkù 23:5) Bákan náà, ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún làwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ máa ń ṣe Ìrántí ikú Kristi, c àpẹẹrẹ tó bá Bíbélì mu yìí sì ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé.

Ọjọ́ àti àkókò

 Kì í ṣe bó ṣe yẹ ká máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi léraléra tó nìkan la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀, àpẹẹrẹ yìí tún jẹ́ ká mọ ọjọ́ àti àkókò tó yẹ ká máa ṣe é. Jésù dá ìrántí ikú rẹ̀ sílẹ̀ lẹ́yìn tí oòrùn wọ̀ ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Nísàn, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni (S.K.) níbàámu pẹ̀lú kàlẹ́ńdà òṣùpá ti àwọn Júù. (Mátíù 26:18-​20, 26) Bíi ti àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, ọdọọdún la máa ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi ní ọjọ́ tó bọ́ sí yìí gẹ́lẹ́. d

 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ Friday ni ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Nísàn, ọdún 33 S.K. bọ́ sí, síbẹ̀ ìrántí yìí lè bọ́ sí ọjọ́ míì láàárín ọ̀sẹ̀ nínú ọdún. Bí wọ́n ṣe máa ń mọ ọjọ́ tí Nísàn ọjọ́ kẹrìnlá bọ́ sí nínú ọdún nígbà ayé Jésù la fi máa ń mọ ìgbà tá a máa ṣe Ìrántí ikú Jésù dípò ká lo ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣírò rẹ̀ nínú kàlẹ́ńdà àwọn Júù ti òde òní. e

Búrẹ́dì àti wáìnì

 Búrẹ́dì aláìwú àti wáìnì pupa tó ṣẹ́ kù lára oúnjẹ Ìrékọjá ni Jésù lò fún ohun tuntun tó dá sílẹ̀ yìí. (Mátíù 26:26-​28) Apẹẹrẹ Jésù là ń tẹ̀ lé bí a ṣe ń lo búrẹ́dì aláìwú tí wọn ò fi ìwúkàrà tàbí àwọn èròjà míì sí àti ògidì wáìnì pupa, kì í ṣe omi àjàrà dídùn tàbí wáìnì dídùn tí wọ́n fi nǹkan dídùn àtàwọn èròjà míì sí.

 Àwọn ẹlẹ́sìn kan máa ń lo búrẹ́dì tó ní ìwúkàrà tàbí amóhunwú, àmọ́ nínú Bíbélì, ìwúkàrà sábà máa ń dúró fún ẹ̀ṣẹ̀ àti ìdíbàjẹ́. (Lúùkù 12:1; 1 Kọ́ríńtì 5:​6-8; Gálátíà 5:​7-9) Torí náà, kìkì búrẹ́dì tí kò ní yálà ìwúkàrà tàbí àwọn èròjà míì nínú ló yẹ ká fi ṣàpẹẹrẹ ara aláìlẹ́ṣẹ̀ Kristi. (1 Pétérù 2:​22) Ohun míì tí kò bá Bíbélì mu tí àwọn kan ń ṣe ni pé wọ́n máa lo omi àjàrà dídùn dípò wáìnì. Ìdí tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kan fi máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n lòdì sí ọtí mímu, ìyẹn ò sì bá Bíbélì mu.​—1 Tímótì 5:​23.

Nǹkan ìṣàpẹẹrẹ ni Búrẹ́dì àti wáìnì, kì í ṣe ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ Jésù gan-gan

 Ohun ìṣàpẹẹrẹ tàbí àmì ni búrẹ́dì aláìwú àti wáìnì pupa tá a máa ń gbé káàkiri níbi Ìrántí Ikú Kristi, wọ́n dúró fún ara àti ẹ̀jẹ̀ Kristi. Wọn kì í yí pa dà di ara àti ẹ̀jẹ̀ Jésù lọ́nà ìyanu gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ṣe rò. Wo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀.

  •   Tí Jésù bá pàṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n mu ẹ̀jẹ̀ òun gan-gan, ńṣe nìyẹn fi hàn pé ó fẹ́ kí wọ́n rú òfin Ọlọ́run tó ní kí wọ́n má ṣe jẹ ẹ̀jẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 9:4; Ìṣe 15:28, 29) Àmọ́, ìyẹn ò lè ṣeé ṣe torí Jésù kò ní sọ fún àwọn èèyàn láé pé kí wọ́n rú òfin Ọlọ́run tó pé ẹ̀jẹ̀ ní ohun ọlọ́wọ̀.​—Jòhánù 8:​28, 29.

  •   Tó bá jẹ́ pé àwọn àpọ́sítélì ti ń mu ẹ̀jẹ̀ Jésù ni, kò ní sọ fún wọn pé ẹ̀jẹ̀ òun ni “a óò tú jáde.” Èyí fi hàn pé kò tíì ṣe ìrúbọ náà.​—Mátíù 26:28.

  •   Jésù fi ara rẹ̀ rúbọ “lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún tún un ṣe mọ́ láé.” (Hébérù 9:​25, 26) Àmọ́, tí búrẹ́dì àti wáìnì náà bá yí pa dà di ara àti ẹ̀jẹ̀ Jésù nígbà Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, a jẹ́ pé ìrúbọ tí Jésù ti ṣe ni àwọn tó ń jẹ búrẹ́dì tí wọ́n sì ń mu wáìnì ń tún ṣe.

  •   Jésù sọ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi,” kò sọ pé “ní ìrúbọ mi.”​—1 Kọ́ríńtì 11:24.

 Ọ̀rọ̀ tí àwọn ẹsẹ Bíbélì kan lò ni àwọn tó gbà gbọ́ pé búrẹ́dì àti wáìnì máa ń yí pa dà di ara àti ẹ̀jẹ̀ Jésù gbé ẹ̀kọ́ wọn kà. Bí àpẹẹrẹ, nínú ọ̀pọ̀ ìtúmọ̀ Bíbélì, ohun tí wọ́n ní Jésù sọ nípa wáìnì ni pé: “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi.” (Mátíù 26:28) Àmọ́, a tún lè túmọ̀ ọ̀rọ̀ Jésù yìí sí: ‘Èyí túmọ̀ sí ẹ̀jẹ̀ mi,’ “Èyí dúró fún ẹ̀jẹ̀ mi” tàbí “Èyí ṣàpẹẹrẹ ẹ̀jẹ̀ mi.” f Ńṣe ni Jésù ń lo àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ bó ṣe máa ń ṣe tó bá ń kọ́ni.​—Mátíù 13:34, 35.

Àwọn wo ló ń jẹ búrẹ́dì tí wọ́n sì ń mu wáìnì?

 Tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá ń ṣe Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, àwọn kéréje lára wa ló máa ń jẹ búrẹ́dì tí wọ́n sì ń máa mu wáìnì. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?

 Ẹ̀jẹ̀ tí Jésù fi rúbọ ló fìdí “májẹ̀mú tuntun” múlẹ̀, èyí tó rọ́pò májẹ̀mú tó wà láàárín Jèhófà Ọlọ́run àti orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́. (Hébérù 8:​10-​13) Àwọn tó wà nínú májẹ̀mú tuntun náà ló máa ń jẹ nínú ohun ìṣàpẹẹrẹ nígbà Ìrántí Ikú Kristi. Kì í ṣe gbogbo Kristẹni ló ń jẹ ẹ́, ṣùgbọ́n kìkì ‘àwọn tí Ọlọ́run ti pè’ lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ ló ń jẹ ẹ́. (Hébérù 9:​15; Lúùkù 22:20) Àwọn wọ̀nyí ló máa bá Kristi jọba lókè ọ̀run, Bíbélì sì sọ pé kìkì àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] èèyàn ló máa ní àǹfààní yìí.​—Lúùkù 22:28-​30; Ìṣípayá 5:​9, 10; 14:​1, 3.

 Yàtọ̀ sí “agbo kékeré” tó máa bá Kristi jọba, èyí tó pọ̀ jù lára wa ń retí láti wà lára “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tó máa ní ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé. (Lúùkù 12:32; Ìṣípayá 7:​9, 10) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa tá a nírètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé kò ní jẹ nínú ohun ìṣàpẹẹrẹ náà nígbà ìrántí Ikú Kristi, à ń dara pọ̀ láti dúpẹ́ fún ìrúbọ tí Jésù ṣe nítorí wa.​—1 Jòhánù 2:2.

a Ìwé McClintock àti Strong’s Cyclopedia, Volume IX, ojú ìwé 212, sọ pé: “Ọ̀rọ̀ náà ara olúwa kò sí nínú Májẹ̀mú Tuntun, kò sì síbi tí wọ́n ti lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà μυστήριον [my·steʹri·on] láti fi tọ́ka sí ìrìbọmi tàbí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa tàbí ààtò èyíkéyìí míì.”

b Àwọn Bíbélì kan lo ọ̀rọ̀ tó túmọ̀ sí “ṣíṣe nǹkan léraléra” nígbà tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, bí wọ́n sì ṣe máa ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀ yẹn ni pé ó yẹ ká máa ṣe é léraléra. Àmọ́ ohun tí èdè Gíríìkì tí Bíbélì lò nígbà tó ń sọ̀rọ̀ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa yìí túmọ̀ sí ni “nígbàkúùgbà.”—1 Kọ́ríńtì 11:25, 26; Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀.

c Wo ìwé The New Schaff-Herzog Encyclopedia of Religious Knowledge, Volume IV, ojú ìwé 43 àti 44, àti ìwé McClintock and Strong’s Cyclopedia, Volume VIII, ojú ìwé 836.

d Wo ìwé The New Cambridge History of the Bible, Volume 1, ojú ìwé 841.

e Àwọn onímọ̀ nípa sánmà fi òṣùpá tuntun ṣírò ìgbà tí oṣù Nísàn bẹ̀rẹ̀. Ìyẹn sì ni wọ́n lò nínú Kàlẹ́ńdà àwọn Júù ti òde òní láti fi mọ ìbẹ̀rẹ̀ oṣù Nísàn. Àmọ́, ọ̀nà yìí kọ́ ni wọ́n ń gbà mọ̀ ọ́n ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìgbà tí òṣùpá tuntun bá kọ́kọ́ yọ ní Jerúsálẹ́mù ni oṣù Nísàn bẹ̀rẹ̀, èyí sì lè jẹ́ ọjọ́ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lẹ́yìn ọjọ́ táwọn onímọ̀ nípa sánmà fi òṣùpá tuntun ṣírò pó bọ́ sí. Ìdí nìyẹn tí ọjọ́ tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi fi sábà máa ń yàtọ̀ sí ọjọ́ táwọn Júù òde òní máa ń ṣe Ìrékọjá.

f Wo ìwé A New Translation of the Bible, tí James Moffatt ṣe; ìwé The New Testament​—A Translation in the Language of the People, tí Charles B. Williams ṣe; àti ìwé The Original New Testament, tí Hugh J. Schonfield ṣe.