Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÌGBÉYÀWÓ

Wíwo Àwòrán Ìṣekúṣe Lè Tú Ìgbéyàwó Rẹ Ká

Wíwo Àwòrán Ìṣekúṣe Lè Tú Ìgbéyàwó Rẹ Ká

 Àṣírí ẹ̀ tú sọ́wọ́ ìyàwó rẹ̀. Ó bẹ ìyàwó rẹ̀ gan-an pé kó dárí ji òun. Ó ní òun ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́, kò sì ṣe bẹ́ẹ̀ fáwọn àkókò kan. Àmọ́ nígbà tó yá, ó tún bẹ̀rẹ̀. Tọ́rọ̀ bá sì ti rí bẹ́ẹ̀, ṣe lá tún bẹ ìyàwó ẹ̀ pé òun ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.

 Ṣé irú nǹkan báyìí ń ṣẹlẹ̀ sí ìwọ náà? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ kó o mọ bí àwòrán ìṣekúṣe tí ò ń wò ṣe ń ba ìyàwó ẹ lọ́kàn jẹ́ àti bó o ṣe lè jáwọ́ pátápátá nínú àṣà burúkú yìí. a

Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa

 Ohun tó yẹ kó o mọ̀

 Àwòrán ìṣekúṣe lè tú ìgbéyàwó ká. Ó lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá ìyàwó ẹ, ó sì lè má fọkàn tán ẹ mọ́. b

 Tí ọkọ kan bá ń wo àwòrán ìṣekúṣe, ó lè máa ṣe ìyàwó rẹ̀ bíi pé:

  •   Ọkọ ẹ̀ ti já a kulẹ̀. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Sarah sọ pé, “Ṣe ló ń ṣe mí bíi pé ọkọ mi ń ṣe àgbèrè léraléra.”

  •   Òun ò wúlò. Obìnrin kan sọ pé bí ọkọ òun ṣe sọ wíwo àwòrán ìṣekúṣe dàṣà ti jẹ́ kóun máa wo ara òun bí ẹni tí ò “wúlò, tí ò sì níyì.”

  •   Ọkọ òun kò ṣeé fọkàn tán. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Helen sọ pé, “Gbogbo nǹkan tí ọkọ mi bá ń ṣe ni mo máa ń fura sí.”

  •   Òun ń ṣàníyàn. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Catherine sọ pé, “Bí ọkọ mi ṣe sọ wíwo àwòrán ìṣekúṣe di bárakú ti jẹ́ kí n máa ṣàníyàn ṣáá.”

 Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Bíbélì sọ pé kí ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀. (Éfésù 5:25) Ṣé ọkọ kan máa sọ pé òun nífẹ̀ẹ́ ìyàwó òun dénú tó bá ń hu ìwà tó ń jẹ́ kí aya rẹ̀ ní àwọn ìṣòro tá a mẹ́nu kàn lókè yìí?

 Ohun tó yẹ kó o ṣe

 Kò rọrùn rárá láti jáwọ́ nínú àṣà wíwo àwòrán ìṣekúṣe. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Stacey sọ pé, “Ọkọ mi ti jáwọ́ nínú mímu sìgá, igbó àti ọtí àmujù, àmọ́ kò rọrùn fún un láti fi wíwo àwòrán ìṣekúṣe sílẹ̀.”

 Tó bá ń ṣòro fún ẹ láti jáwọ́ nínú àṣà yìí, àwọn àbá tó tẹ̀ lé e yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti jáwọ́ pátápátá.

  •   Ó yẹ kó o mọ ìdí tí àwòrán ìṣekúṣe fi burú. Àwòrán ìṣekúṣe máa ń jẹ́ kẹ́nì kan rò pé òun ń gbádùn ara òun, àmọ́ ṣe ló máa ń mú kí ìfẹ́ sọnù láàárín tọkọtaya, kì í sì í jẹ́ kí wọ́n fọkàn tán ara wọn. Kódà, ó lè ṣòro fún wọn láti dúró ti ara wọn nígbà ìṣòro. Èyí tó burú jù ni pé, ẹni tó bá ń wo àwòrán ìṣekúṣe ò bọ̀wọ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run tó dá ìgbéyàwó sílẹ̀.

     Ìlànà Bíbélì: “Kí ìgbéyàwó ní ọlá.”​—Hébérù 13:4.

  •   Gbà pé o ṣàṣìṣe. Má ṣe sọ pé, ‘Mi ò bá má wo àwòrán ìṣekúṣe ká sọ pé ìyàwó mi ń fìfẹ́ hàn sí mi bó ṣe yẹ.’ Kò yẹ kí o máa dá ìyàwó rẹ lẹ́bi, torí ìyẹn máa jẹ́ kó rọrùn fún ẹ láti tún wò ó nígbàkigbà tí ìyàwó ẹ bá ṣe ohun tó dùn ẹ́.

     Ìlànà Bíbélì: “Àdánwò máa ń dé bá kálukú nígbà tí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ bá fà á mọ́ra, tó sì tàn án jẹ.”​—Jémíìsì 1:14.

  •   Má fi ohunkóhun pa mọ́ fún ẹnì kejì rẹ. Ọkọ kan tó ń jẹ́ Kevin sọ pé: “Ojoojúmọ́ ni mo máa ń bi ìyàwó mi bóyá ó kíyè sí mi pé mo ń wo ohunkóhun tí ò dáa. Ohun tí mo ń ṣe yìí ò jẹ́ kó máa rò pé mo ń fi nǹkan pa mọ́ fún òun.”

     Ìlànà Bíbélì: “[Ó] ń wù wá láti jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo.”​—Hébérù 13:18.

  •   Máa ṣọ́ra. Tó ò bá ṣọ́ra, o tún lè bẹ̀rẹ̀ sí í wo àwòrán ìṣekúṣe kódà lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tó o ti jáwọ́ nínú ẹ̀. Kevin tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lókè sọ pé: “Odindi ọdún mẹ́wàá gbáko ni mi ò fi wo àwòrán ìṣekúṣe mọ́, ọkàn mi sì balẹ̀ pé mo ti borí ìṣòro náà. Àmọ́ mo tún lè pa dà bẹ̀rẹ̀ sí í wò ó tí mo bá gba ìwà burúkú yìí láyè.”

     Ìlànà Bíbélì: “Kí ẹni tó bá rò pé òun dúró kíyè sára kó má bàa ṣubú.”​—1 Kọ́ríńtì 10:12.

  •   Ronú, kó o lè mọ ohun tó o máa ṣe. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé èròkerò lè máa wá sí ẹ lọ́kàn, ìwọ lo máa pinnu bóyá wàá gbà á láyè. Èròkerò náà máa tètè lọ tó o bá ronú lórí àwọn nǹkan míì.

     Ìlànà Bíbélì: “Kí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín mọ bó ṣe máa kó ara rẹ̀ níjàánu nínú jíjẹ́ mímọ́ àti nínú iyì, kì í ṣe nínú ojúkòkòrò ìbálòpọ̀ tí kò níjàánu.”​—1 Tẹsalóníkà 4:4, 5.

  •   Yẹra fún ohun tó lè mú kí ọkàn rẹ máa fà sí àwòrán ìṣekúṣe. Ìwé náà Willpower’s Not Enough sọ pé, “Tó o bá gba èròkérò láyè, ṣe ló máa dà bíi pé o ṣá ìṣáná lẹ́gbẹ̀ẹ́ epo pẹtiróòlù . . . ṣe lá kàn gbiná gbàù.”

     Ìlànà Bíbélì: “Kí aburú kankan má ṣe jọba lórí mi.”​—Sáàmù 119:133.

  •   Má ṣe sọ̀rètí nù. Ohun kan ni pé ó lè pẹ́ gan-an kódà ó lè gba ọ̀pọ̀ ọdún kí ìyàwó ẹ tó fọkàn tán ẹ. Àmọ́, ohun táwọn tó ti ṣẹlẹ̀ sí sọ fi hàn pé ó ṣì lè fọkàn tán ẹ.

     Ìlànà Bíbélì: “Ìfẹ́ máa ń ní sùúrù.”​—1 Kọ́ríńtì 13:4.

a Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọkọ la darí àpilẹ̀kọ yìí sí, ìlànà tó wà nínú rẹ̀ máa ṣe àwọn ìyàwó tó ń wo àwòrán ìṣekúṣe láǹfààní.

b Àwọn tọkọtaya kan ronú pé táwọn bá ń wo àwòrán ìṣekúṣe pa pọ̀, ìyẹn máa jẹ́ káwọn túbọ̀ máa fìfẹ́ hàn síra wọn. Àmọ́, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò bá ìlànà Bíbélì mu.​—Òwe 5:15-20; 1 Kọ́ríńtì 13:4, 5; Gálátíà 5:22, 23.