Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Dáàbò Bo Ara Mi Lọ́wọ́ Àwọn Tó Ń Fi Ìṣekúṣe Lọ̀ Mí?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Dáàbò Bo Ara Mi Lọ́wọ́ Àwọn Tó Ń Fi Ìṣekúṣe Lọ̀ Mí?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Ṣàyẹ̀wò àwọn ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́ tá a gbé ka àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì:

  1.   Mọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe. Máa ṣe dáadáa sí àwọn tí ẹ jọ ń ṣiṣẹ́, kó o sì bọ̀wọ̀ fún wọn. Àmọ́, ṣọ́ra kí ọ̀rẹ́ tí ò ń bá wọn ṣe má lọ di pé tí wọ́n bá fi ìṣekúṣe lọ̀ ẹ́, wà á gbà.​—Mátíù 10:16; Kólósè 4:6.

  2.   Múra lọ́nà tó bójú mu. Tó o bá ń wọ aṣọ tí kò bójú mu, àwọn èèyàn á máa ro nǹkan míì nípa rẹ. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé ká múra “pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú.”​—1 Tímótì 2:9.

  3.   Mọ irú ẹni tó yẹ kó o bá ṣọ̀rẹ́. Tó bá jẹ́ pé àwọn tó máa ń bá àwọn èèyàn tage tàbí àwọn tó máa ń fi ìṣekúṣe lọni lò ń bá ṣọ̀rẹ́, ńṣe lò ń rìn ní bèbè ibi tí wọ́n á ti fi ìṣekúṣe lọ̀ ẹ́.​—Òwe 13:20.

  4.   Yẹra fún ọ̀rọ̀ rírùn. Tètè kúrò níbi tí wọ́n bá ti ń sọ̀rọ̀ “tí ń tini lójú tàbí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ tàbí ìṣẹ̀fẹ̀ rírùn.”​—Éfésù 5:4.

  5.   Yẹra fún àwọn ipò tó lè fà ọ́ sínú ìdẹwò. Bí àpẹẹrẹ, má ṣe gbà láti dúró lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá parí iṣẹ́, àfi tí ìdí pàtàkì tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ bá wà fún ṣíṣe bẹ́ẹ̀.​—Òwe 22:3.

  6.   Dúró lórí ìpinnu rẹ. Tí ẹnìkan bá ń fi ìṣekúṣe lọ̀ ẹ́, sọ fún un pé o kórìíra ìwà tó ń hù yẹn. (1 Kọ́ríńtì 14:9) Bí àpẹẹrẹ, o lè sọ pé: “Bó o ṣe ń fara nù mí yẹn ń ni mí lára. Mi ò fẹ́.” O lè kọ lẹ́tà sí ẹni tó ń fi ìṣekúṣe lọ̀ ẹ́, kó o sì ṣàlàyé ohun tó ṣe, bó ṣe rí lára rẹ àti pé o kò ní fẹ́ kírú ohun tó ṣe yẹn wáyé mọ́. Jẹ́ kó yé ẹni tó ń fi ìṣekúṣe lọ̀ ẹ́ pé ohun tó o gbà gbọ́ àti ẹ̀kọ́ ìwà rere tó o kọ́ ló mú kó o ṣe ìpinnu yìí.​—1 Tẹsalóníkà 4:3-5.

  7.   Wá ìrànlọ́wọ́. Tí ẹni náà kò bá jáwọ́, sọ fún ọ̀rẹ́ rẹ kan tó o fọkàn tán, ẹnì kan nínú ìdílé rẹ, òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ tàbí ẹnì tó mọ̀ nípa bí wọ́n ṣe ń ṣèrànwọ́ fún àwọn tí wọ́n fi ìṣekúṣe lọ̀. (Òwe 27:9) Àdúrà ti ran ọ̀pọ̀ àwọn tó ní irú ìṣòro yìí lọ́wọ́. Kódà tí o kò bá gbàdúrà rí, má ṣe fojú kéré ìrànlọ́wọ́ tí Jèhófà “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo” yóò ṣe fún ọ.​—2 Kọ́ríńtì 1:3.

 Fífi ìṣekúṣe lọni ti sọ ibi iṣẹ́ di ibi tí kò fara rọ fún ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn, ṣùgbọ́n Bíbélì lè ràn ọ́ lọ́wọ́.