Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìbẹ́yà-Kan-Náà-Lòpọ̀?

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìbẹ́yà-Kan-Náà-Lòpọ̀?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Ọlọ́run dá àwa èèyàn lọ́nà tí a ó fi lè ní ìbálòpọ̀. Àmọ́, ọkùnrin àti obìnrin tó ti ṣègbéyàwó nìkan ló gbà láyè láti ní ìbálòpọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28; Léfítíkù 18:22; Òwe 5:18, 19) Bíbélì sọ pé kò dára kí àwọn tí kì í ṣe ọkọ àti aya jọ máa ní ìbálòpọ̀, yálà kí ọkùnrin máa bá ọkùnrin lòpọ̀ tàbí kí obìnrin máa bá obìnrin lòpọ̀. (1 Kọ́ríńtì 6:18) Ó tún kan ìṣekúṣe, fífi ọwọ́ pa àwọn ibi kọ́lọ́fín ara ẹlòmíì, ìbálòpọ̀ láti ẹnu tàbí látinú ihò ìdí.

 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kò fọwọ́ sí ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀, síbẹ̀ kó sọ pé ká kórìíra àwọn tó ń bá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé ká “máa bọlá fún onírúurú ènìyàn gbogbo.”​—1 Pétérù 2:17.

Ǹjẹ́ wọ́n lè bí àṣà bíbá ẹ̀yà-kan-náà-lòpọ̀ mọ ẹnì kan?

Bíbélì kò ṣàlàyé ohun tó ń fa bíbá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀, àmọ́ ó sọ pé gbogbo wa lá bí pẹ̀lú èròkérò tó máa ń mú ká fẹ́ láti ṣe ohun tí Ọlọ́run kórìíra. (Róòmù 7:21-​25) Dípò ká máa wádìí ohun tó ń mú kí ẹnì kan ní àṣà bíbá ẹ̀yà-kan-náà-lòpọ̀, ohun tí Bíbélì sọ ni pé Ọlọ́run kórìíra àṣà yìí.

Bí o ṣe lè mú inú Ọlọ́run dùn tó bá ṣe ọ́ bíi pé kó o bá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìrẹ lò pọ̀.

Bíbélì sọ pé: “Ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú.” (Kólósè 3:5) Tó o bá fẹ́ mú èrò búburú, tó lè mú kó o ṣèṣekúṣe kúrò lọ́kàn rẹ̀, àfi kó o má máa ro èròkerò. Tó o bá ń ro ohun tó dára nígbà gbogbo, èròkérò á tètè wábi gbà. (Fílípì 4:8; Jákọ́bù 1:14, 15) Ó lè kọ́kọ́ nira o, àmọ́ wàá borí èròkérò tó bá yá. Ọlọ́run ṣèlérí pé òun á sọ ọ́ “di ẹni titun ninu ninu ọkan” rẹ.​—Éfésù 4:22-​24, Bíbélì Ìròhìn Ayọ̀.

 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó máa ń wù láti ní ìbálòpọ̀ láàárín ọkùnrin sí obìnrin náà ní láti sapá kí wọ́n lè máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà inú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tí kò tíì ní ọkọ tàbí aya tí wọn ò sì tíì fẹ́ lọ́kọ tàbí láya àti àwọn tó ti ní ọkọ tàbí aya sílé àmọ́ tí ẹni tí wọ́n fẹ́ sílé kò lè fi ìbálòpọ̀ tẹ́ wọn lọ́run bí wọ́n ṣe fẹ́ gbọ́dọ̀ kó ara wọn níjàánu tó bá ń ṣe wọ́n bíi pé kí wọ́n ṣe ìṣekúṣe. Àwọn tó ń tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run á máa gbé ìgbé ayé aláyọ̀. Àwọn tó máa ń wù láti bá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiwọn lò pọ̀ náà lè gbé ìgbé ayé aláyọ̀ tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni wọ́n fẹ́ mú inú Ọlọ́run.​—Diutarónómì 30:19.