Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Bíbélì Fàyè Gbà Á Pé Kí Ọkùnrin Fẹ́ Ọkùnrin?

Ṣé Bíbélì Fàyè Gbà Á Pé Kí Ọkùnrin Fẹ́ Ọkùnrin?

ÀRÍYÀNJIYÀN ṣì wà káàkiri lórí bóyá ó dáa kí ọkùnrin máa fẹ́ ọkùnrin. Lọ́dún 2015, Ilé Ẹjọ́ Gíga ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà kéde pé ọkùnrin àtọkùnrin ti lè fẹ́ ara wọn báyìí. Lẹ́yìn náà, àìmọye èèyàn ló lọ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì láti lọ wádìí nípa ọ̀ràn náà. Ìbéèrè tí ọ̀pọ̀ wọn ń béèrè ni pé, “Ṣé Bíbélì fàyè gbà á pé kí ọkùnrin fẹ́ ọkùnrin?”

Bíbélì ò sọ̀rọ̀ lórí bóyá ó bófin mu pé kí ọkùnrin àti ọkùnrin fẹ́ ara wọn. Ṣùgbọ́n ìbéèrè tó ṣe pàtàkì jù ni pé kí ni Bíbélì sọ nípa ìbálòpọ̀ ọkùnrin sí ọkùnrin tàbí obìnrin sí obìnrin?

Ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé àwọn lè dáhùn ìbéèrè yìí bó ṣe wù wọ́n, bẹ́ẹ̀ àwọn ìdáhùn wọn tó tako ara fi hàn pé wọn kò mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa kókó yìí. Àwọn kan sọ pé Bíbélì dẹ́bi fún ìbálòpọ̀ láàárín ọkùnrin àti ọkùnrin. Àwọn míì ní òfin Bíbélì tó sọ pé “nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ” fi hàn pé Bíbélì fàyè gbà á.—Róòmù 13:9.

KÍ NI BÍBÉLÌ SỌ?

Èwo nínú àwọn ọ̀rọ̀ yìí lo gbà pé ó jẹ́ òótọ́?

  1. Bíbélì dẹ́bi fún ìbálòpọ̀ láàárín ọkùnrin àti ọkùnrin.

  2. Bíbélì fàyè gbà á.

  3. Bíbélì ní ká kórìíra àwọn ọkùnrin tó ń bá ọkùnrin bíi tiwọn lò pọ̀.

ÌDÁHÙN:

  1. BẸ́Ẹ̀ NI. Bíbélì sọ pé: ‘Àwọn ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin lò pọ̀ kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.’ (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10) Ọ̀rọ̀ náà kan àwọn obìnrin tó ń bá obìnrin lò pọ̀.—Róòmù 1:26.

  2. BẸ́Ẹ̀ KỌ́. Bíbélì kọ́ wa pé ọkùnrin àti obìnrin tó gbé ara wọn níyàwó nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ara wọn.—Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28; Òwe 5:18, 19.

  3. BẸ́Ẹ̀ KỌ́. Òótọ́ ni pé Bíbélì kò fàyè gba àwọn ọkùnrin àti ọkùnrin tó ń bá ara wọn lò pọ̀, síbẹ̀ sọ pé ká kórìíra àwọn ọkùnrin tó ń bá ọkùnrin lò pọ̀.—Róòmù 12:18. [1]

Kí Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Rò Nípa Ẹ̀?

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé ìlànà ìwà rere tó wà nínú Bíbélì ló dára jù lọ, àwọn ìlànà yẹn la sì ń tẹ̀ lé. (Aísáyà 48:17) [2] Èyí fi hàn pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòdì sí gbogbo ìbálòpọ̀ tó ta ko ìlànà Bíbélì, títí kan ìbálòpọ̀ láàárín ọkùnrin àti ọkùnrin. (1 Kọ́ríńtì 6:18) [3] Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì lẹ́tọ̀ọ́ láti tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì ní ìgbésí ìgbé ayé wa.

Ìlànà Pàtàkì tó wà nínú Bíbélì là ń tẹ̀ lé, ìyẹn ni pé ohun tá a fẹ́ káwọn èèyàn ṣe sí wa ni ká máa ṣe sí wọn

Lẹ́sẹ̀ kan náà, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sapá láti “máa lépa àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.” (Hébérù 12:14) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò fara mọ́ ìbálòpọ̀ láàárín ọkùnrin àti ọkùnrin, síbẹ̀ a kì í fipá mú ẹnikẹ́ni láti gba èrò wa. Bákan náà, a kì í hùwà ìkà sí àwọn ọkùnrin tó ń bá ọkùnrin lò pọ̀ tàbí ká máa yọ̀ tá a bá rí àwọn tó ń hùwà ìkà sí wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ìlànà Pàtàkì tó wà nínú Bíbélì là ń tẹ̀ lé, ìyẹn ni pé ohun tá a fẹ́ káwọn èèyàn ṣe sí wa ni ká máa ṣe sí wọn.—Mátíù 7:12.

Ǹjẹ́ Bíbélì Fọwọ́ Sí Ìwà Ẹ̀tanú?

Àwọn kan sọ pé Bíbélì fara mọ́ ṣíṣe ẹ̀tanú sí àwọn ọkùnrin tó ń bá ọkùnrin lò pọ̀ àti pé aláṣejù làwọn tó ń rin kinkin mọ́ òfin Bíbélì. Wọ́n tún sọ pé ‘ìgbà ojú dúdú ni wọ́n kọ Bíbélì. Àmọ́ láyé ọ̀làjú tá a wà yìí, kò sídìí láti ṣe ẹ̀tanú sí ẹnikẹ́ni torí ibi tó ti wá, ẹ̀yà tó jẹ́ àti ojú tó fi ń wo ìbálòpọ̀.’ Wọ́n gbà pé àwọn tí kò fara mọ́ àwọn ọkùnrin tó ń bá ọkùnrin lò pọ̀ kò yàtọ̀ sí ẹni tó ń ṣe ẹ̀tanú sí ẹnì kan torí àwọ̀ rẹ̀. Ṣé àfiwé yìí bọ́gbọ́n mú? Rárá o. Kí nìdí?

Ìdí ni pé ìyàtọ̀ wà nínú kéèyàn kórìíra ìwà àwọn ọkùnrin tó ń bá ọkùnrin lò pọ̀ àti kéèyàn kórìíra ẹni náà fúnra rẹ̀. Bíbélì sọ fún àwọn Kristẹni pé kí wọ́n máa bọ̀wọ̀ fún onírúurú èèyàn. (1 Pétérù 2:17) [4] Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé gbogbo ìwà táwọn èèyàn bá ń hù làwa Kristẹni gbọ́dọ̀ fara mọ́.

Wo àpẹẹrẹ yìí: Tí ọ̀kan lára àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ bá ń mu sìgá, àmọ́ tí ìwọ kórìíra sìgá torí o mọ̀ pé ó léwu, ṣé ó máa bọ́gbọ́n mu káwọn èèyàn sọ pé o kì í ṣe ọ̀làjú? Àbí ṣé a lè sọ pé ẹ̀tanú lò ń ṣe torí pé ìwọ́ kì í mu sìgá? Ṣé ó máa bọ́gbọ́n mú tí ẹni náà bá sọ pé kó o fara mọ́ sìgá mímú?

Ìlànà Bíbélì làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yàn láti máa tẹ̀ lé nínú ohun gbogbo. A kò fọwọ́ sí àwọn ìwà tí Bíbélì sọ pé kò dáa. Àmọ́ a kì í fi àwọn èèyàn ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí ká ṣèkà fún wọn torí wọ́n yàn láti ṣe ohun tó yàtọ̀ sí tiwa.

Ṣé Ohun Tí Bíbélì Sọ Yìí Le Jù?

Àwọn tó jẹ́ pé bíbá ọkùnrin bíi tiwọn lò pọ̀ ló máa ń wù wọ́n ńkọ́? Ṣé wọ́n bí i mọ́ wọn ni? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ṣé kì í ṣe ìkà ni tá a bá ní kí wọ́n má ṣe oun tó wù wọ́n?

Bíbélì ò sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ń mú kó máa wu ọkùnrin kan láti ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin, àmọ́ ó jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ìwà kan wà tó ti di bárakú fáwọn kan. Síbẹ̀, Bíbélì sọ pé a gbọ́dọ̀ yàgò fún ìwà tí kò tọ́ tá a bá fẹ́ rí ojúure Ọlọ́run, títí kan àṣà káwọn ọkùnrin máa bá ara wọn lò pọ̀.—2 Kọ́ríńtì 10:4, 5.

Àmọ́ àwọn kan lè sọ pé ohun tí Bíbélì sọ yẹn ti le jù. Èrò wọn ni pé gbogbo ohun tọ́kàn èèyàn bá ti fà sí léèyàn gbọ́dọ̀ ṣe. Tàbí pé ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ ṣe pàtàkì gan-an débi pé kó ṣeé fi sára kú. Ṣùgbọ́n, Bíbélì pọ́n àwa èèyàn lé, torí ó sọ pé a lè kápá ìfẹ́ ọkàn láti ní ìbálòpọ̀. A ò dà bí àwọn ẹranko, a lè yàn láti ṣe ohun tó wà lọ́kàn wa tàbí ká má ṣe é.—Kólósè 3:5. [5]

Wo àfiwé yìí ná: Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan sọ pé àwọn ìwà kan wà tó ti mọ́ àwọn kan lára láti kékeré wọn, irú bí ìbínú. Bíbélì ò sọ ohun tó máa ń mú káwọn kan máa bínú, àmọ́ ó sọ pé àwọn kan máa ń “fi ara wọn fún ìbínú,” wọ́n sì máa ń fi “ara wọn fún ìhónú.” (Òwe 22:24; 29:22) Síbẹ̀, Bíbélì sọ pé: “Jáwọ́ nínú ìbínú, kí o sì fi ìhónú sílẹ̀.”—Sáàmù 37:8; Éfésù 4:31.

Bóyá la máa rẹ́nì kan tó máa sọ pé ìmọ̀ràn yìí ò wúlò tàbí pé ìmọ̀ràn yẹn ti le kọjá ohun tí oníbìínú èèyàn lè tẹ̀ lé. Kódà àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n tó gbà pé wọ́n máa ń bí ìbínú mọ́ọ̀yàn ṣì máa ń sapá láti ran àwọn oníbìínú èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè borí ìwà yìí.

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà máa ń ṣèrànwọ́ fún àwọn tó bá ní ìwà èyíkéyìí tí Bíbélì sọ pé kò dáa títí kan ìbálòpọ̀ láàárín ọkùnrin àti obìnrin tí kì í ṣe tọkọtaya. Bíbélì gba àwọn tó ń dá àṣà yìí níyànjú pé: “Kí olúkúlùkù yín mọ bí yóò ti ṣèkáwọ́ ohun èlò tirẹ̀ nínú ìsọdimímọ́ àti ọlá, kì í ṣe nínú ìdálọ́rùn olójúkòkòrò fún ìbálòpọ̀ takọtabo.”—1 Tẹsalóníkà 4:4, 5.

“Ohun Tí Àwọn Kan Lára Yín Ti Jẹ́ Rí Nìyẹn”

Ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn tó di Kristẹni ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ti wá, bí wọ́n sì ṣe gbé ìgbé ayé wọn yàtọ̀ síra, wọ́n ṣe ìyípadà pàtàkì nígbèésí ayé wọn. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó jẹ́ ‘àgbèrè, abọ̀rìṣà, panṣágà, àti àwọn ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin lò pọ̀.’ Ó wá fi kún un pé: “Ohun tí àwọn kan lára yín ti jẹ́ rí nìyẹn.”1 Kọ́ríńtì 6:9-11.

Nígbà tí Bíbélì sọ pé “ohun tí àwọn kan lára yín ti jẹ́ rí nìyẹn,” ṣé ó wá túmọ̀ sí pé kò tún wu àwọn ọkùnrin tó máa ń bá ọkùnrin sùn láti ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ mọ́ ni? Ó ṣeé ṣe kó ṣì máa wù wọ́n, torí pé Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa rìn nípa ẹ̀mí, ẹ kì yóò sì ṣe ìfẹ́-ọkàn ti ẹran ara rárá.”—Gálátíà 5:16.

Kíyè sí i pé Bíbélì kò sọ pé èròkerò kò ní máa wá sí ẹni tó jẹ́ Kristẹni lọ́kàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa pinnu láti má ṣe ohun tó wá sí i lọ́kàn. Àwọn Kristẹni máa ń kọ́ láti kápá irú èrò bẹ́ẹ̀, wọ́n kì í ronú lé e lórí débi tí wọ́n fi máa hù ú níwà.—Jákọ́bù 1:14, 15. [6]

Bíbélì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé ìyàtọ̀ wà nínú kí nǹkan wá síni lọ́kàn àti kéèyàn ṣe nǹkan náà. (Róòmù 7:16-25) Ọkùnrin tó bá ń wù láti ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin lè kápá àṣà yìí tí ó bá ń ṣọ́ ohun tó ń fi ọkàn rẹ̀ rò. Bó ṣe máa ṣe tí èròkérò míì bá wá sí i lọ́kàn, irú bí ìbínú, panṣágà àti ojúkòkòrò.—1 Kọ́ríńtì 9:27; 2 Pétérù 2:14, 15.

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ nínú àwọn ìlànà ìwà rere tó wà nínú Bíbélì. Àmọ́, a kì í fipá mú ẹnikẹ́ni láti fara mọ́ èrò wa, a ò sì ń gbìyànjú láti ṣe àyípadà òfin tó dáàbò bo ẹ̀tọ́ àwọn tí ọ̀nà ìgbésí ayé wọn yàtọ̀ sí tiwa. Ohun tó máa ṣe àwọn èèyàn láǹfààní là ń wàásù rẹ̀ fún àwọn tó bá fẹ́ gbọ́.—Ìṣe 20:20.

^ 1. Róòmù 12:18: “Ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.”

^ 2. Aísáyà 48:17: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní.”

^ 3. 1 Kọ́ríńtì 6:18: “Ẹ máa sá fún àgbèrè!”

^ 4. 1 Pétérù 2:17: “Ẹ máa bọlá fún onírúurú ènìyàn gbogbo.”

^ 5. Kólósè 3:5: “Nítorí náà, ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo.”

^ 6. Jákọ́bù 1:14, 15: “Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ni a ń dán wò nípa fífà á jáde àti ríré e lọ nípasẹ̀ ìfẹ́-ọkàn òun fúnra rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ìfẹ́-ọkàn náà, nígbà tí ó bá lóyún, a bí ẹ̀ṣẹ̀.”