Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ǹjẹ́ Bíbélì Lè Ràn Mí Lọ́wọ́ Tí Mo Bá Ní Ìrẹ̀wẹ̀sì Ọkàn?

Ǹjẹ́ Bíbélì Lè Ràn Mí Lọ́wọ́ Tí Mo Bá Ní Ìrẹ̀wẹ̀sì Ọkàn?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Bẹ́ẹ̀ ni, ìdí ni pé a lè rí ojúlówó ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ “Ọlọ́run, ẹni tí ń tu àwọn tí a rẹ̀ sílẹ̀ nínú.”​—2 Kọ́ríńtì 7:6.

Ohun tí Ọlọ́run máa ń fún àwọn tó ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn

  •   Agbára. Ọlọ́run kò ní mú gbogbo ìṣòro tó o ní kúrò torí kó lè tù ẹ́ nínú, àmọ́ ńṣe ni yóò gbọ́ àdúrà rẹ tó o bá béèrè pé kó fún ẹ ní agbára tí wàá fi lè fara dà àwọn ìṣòro náà. (Fílípì 4:13) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run máa gbọ́ àdúrà rẹ torí Bíbélì sọ pé: “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; Ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.” (Sáàmù 34:18) Kódà tí o kò bá lè sọ bí ẹ̀dùn ọkàn tó o ní ṣe rí lára rẹ, Ọlọ́run lè gbọ́ àdúrà tó o bá gbà fún ìrànlọ́wọ́.​—Róòmù 8:26, 27.

  •   Àwọn àpẹẹrẹ rere. Ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Láti inú ibú ni mo ti ké pè ọ́.” Ẹni tó kọ sáàmù yìí lè fara da ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn tó ní nígbà tó rántí pé Ọlọ́run máa ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini. Ó sọ fún Ọlọ́run pé: “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ìṣìnà ni ìwọ ń ṣọ́, Jáà, Jèhófà, ta ni ì bá dúró? Nítorí ìdáríjì tòótọ́ ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ, Kí a lè máa bẹ̀rù rẹ.”​—Sáàmù 130:1, 3, 4.

  •   Ìrètí. Yàtọ̀ sí pé Ọlọ́run ń tù wá nínú nísinsìnyí, ó ti ṣèlérí pé òun máa mú àwọn ìṣòro tó ń fa ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn kúrò. “Àwọn ohun àtijọ́ [tó ní nínú ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn] ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà,” nígbà tí Ọlọ́run bá mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ​—Aísáyà 65:7.

 Àkíyèsí: Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà lóòtọ́ pé Ọlọ́run máa ń ràn wá lọ́wọ́, a sì máa ń tọ́jú ara wa ní ilé ìwòsàn tá a bá ń ṣàìsàn, irú bí ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn tó le gan-an. (Máàkù 2:17) Àmọ́ ṣá o, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò ní sọ irú ìtọ́jú kan pàtó tó yẹ kó o gbà lọ́dọ̀ àwọn dókítà fún ẹ; olúkálukú ni yóò pinnu irú ìtọ́jú tó fẹ́ fúnra rẹ̀.