Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Má Ṣe Jẹ́ Káyé Sú Ẹ

Má Ṣe Jẹ́ Káyé Sú Ẹ

TÓ O bá mọ ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Diana, a wàá rí i pé ó jáfáfá, ó lọ́yàyà, ó sì kóni mọ́ra. Àmọ́ bí ọ̀dọ́bìnrin yìí ṣe dára tó yìí, ìbànújẹ́ tó ń bá a fínra kọjá àfẹnusọ. Tí nǹkan ọ̀hún bá dé sí i báyìí, ńṣe ló máa ń rí ara rẹ̀ bí ẹni tí kò wúlò fún nǹkan kan, ó sì lè máa ṣe é bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, ọ̀sẹ̀ tàbí oṣù. Ó sọ pé: “Ọjọ́ kan ò ní lọ kí n má ronú pé ó sàn kí n kú. Ó dá mi lójú pé bí mo tiẹ̀ wà láàyè, mi ò ṣe ẹnì kankan láǹfààní.”

“Àwọn ìwádìí kan fi hàn pé gbogbo ìgbà tá a bá rí èèyàn kan tó gbẹ̀mí ara ẹ̀, ọgọ́rùn-ún méjì míì ló ti gbìyànjú láti gbẹ̀mí ara wọn, nígbà tó jẹ́ pé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [mìíràn] ń ronú láti gbẹ̀mí ara wọn.”​—THE GAZETTE, MONTREAL, CANADA.

Diana sọ pé òun ò ní pa ara òun láé. Àmọ́, nígbà míì kò rí ìdí pàtàkì kan tó fi yẹ kó ṣì wà láyé. Ó sọ pé: “Ohun tó máa ń wù mí jù lọ ni pé kí n kú sínú jàǹbá kan. Mo ti wá rí ikú gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ mi, kì í ṣe ọ̀tá mi.”

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé ọ̀rọ̀ wọn náà jọ ti Diana. Àwọn kan tiẹ̀ ti ronú láti gbẹ̀mí ara wọn, nígbà tó jẹ́ pé àwọn míì ti gbìyànjú ẹ̀. Ṣùgbọ́n ohun táwọn ọ̀mọ̀ràn sọ ni pé, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn tó ti gbìyànjú láti gbẹ̀mí ara wọn ló jẹ́ pé kì í kúkú ṣe pé ó wu àwọn náà láti kú, àmọ́ ńṣe ni wọ́n ń wá bí wọ́n ṣe máa fòpin sí ìyà tó ń jẹ wọ́n. Ní kúkúrú, ayé ti sú wọn; àmọ́ wọ́n fẹ́ mọ ìdí tó fi yẹ káwọn ṣì wà láàyè.

Má ṣe jẹ́ káyé sú ẹ. Jẹ́ ká wo ìdí mẹ́ta tó fi yẹ kó o ṣì wà láàyè.

a A ti yí orúkọ rẹ̀ pa dà.