Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ Ọ̀RỌ̀ | ÀWỌN IRỌ́ TÍ KÒ JẸ́ KÁWỌN ÈÈYÀN NÍFẸ̀Ẹ́ ỌLỌ́RUN

Òtítọ́ Lè Dá Ẹ Sílẹ̀ Lómìnira

Òtítọ́ Lè Dá Ẹ Sílẹ̀ Lómìnira

Lọ́jọ́ kan, Jésù ń kọ́ àwọn èèyàn nípa Jèhófà Bàbá rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù ó sì ń tú àṣírí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ìgbà yẹn. (Jòhánù 8:12-30) Ohun tí Jésù sọ lọ́jọ́ náà kọ́ wa bí a ṣe lè ṣàyẹ̀wò ohun tí àwọn èèyàn gbà gbọ́ nípa Ọlọ́run lónìí. Jésù sọ pé: “Bí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, ọmọ ẹ̀yìn mi ni ẹ̀yin jẹ́ ní ti tòótọ́, ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.”—Jòhánù 8:31, 32.

Gbólóhùn tí Jésù sọ pé: “Dúró nínú ọ̀rọ̀ mi” jẹ́ ká mọ ìlànà tá a lè fi wádìí bóyá àwọn ẹ̀kọ́ tí ẹ̀sìn ń kọ́ni jẹ́ “òtítọ́.” Tó o bá gbọ́ nǹkan kan nípa Ọlọ́run, kọ́kọ́ bi ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ ẹ̀kọ́ yìí bá ohun tí Jésù sọ àti ohun tó wà nínú Bíbélì mu?’ Ìwọ náà lè tẹ̀lé àpẹẹrẹ àwọn kan tó jẹ́ pé lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ìwàásù àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, wọ́n “fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ ní ti pé bóyá bẹ́ẹ̀ ni nǹkan wọ̀nyí [àwọn ohun tí wọ́n ń kọ́] rí.”—Ìṣe 17:11.

Ṣé o rántí Marco, Rosa àti Raymonde tí a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́? Ẹ̀kọ́ Bíbélì tí wọ́n kọ́ lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló jẹ́ kí àwọn náà fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Báwo wá ni ohun tí wọ́n kọ́ yìí ṣe rí lára wọn?

Marco sọ pé: “Ẹni tó ń kọ́ èmi àti ìyàwó mi lẹ́kọ̀ọ́ fi Bíbélì dáhùn gbogbo ìbéèrè wa. Bí ìfẹ́ Jèhófà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í jinlẹ̀ nínú wa nìyẹn, àárín èmi àti ìyàwó mi sì túbọ̀ gún régé!”

Rosa sọ ní tiẹ̀ pé: “Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ìwé ìmọ̀ ọgbọ́n orí tó kàn ṣàlàyé ohun tí àwọn èèyàn rò nípa Ọlọ́run ni mo ka Bíbélì sí. Àmọ́, díẹ̀díẹ̀ ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè mi nínú Bíbélì. Ní báyìí, mo ti wá mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ gan-an. Mo ti rí i pé mo lè gbẹ́kẹ̀ lé e.”

Raymonde náà sọ pé: “Mo gbàdúrà sí Ọlọ́run pé mo fẹ́ mọ̀ ọ́n. Kò pẹ́ sí ìgbà yẹn tní èmi àti ọkọ mi fi bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, a kọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ nípa Jèhófà! Inú wa sì dùn láti mọ irú Ọlọ́run tó jẹ́.”

Yàtọ̀ sí pé Bíbélì tú àṣírí àwọn irọ́ tí àwọn èèyàn pa mọ́ Ọlọ́run, ó tún jẹ́ ká mọ òtítọ́ nípa àwọn ìwà dáadáa tí Ọlọ́run ní. Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí ni Bíbélì, ó sì jẹ́ ká “mọ àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ti fi fún wa pẹ̀lú inú rere.” (1 Kọ́ríńtì 2:12) Á dáa kí ìwọ fúnra rẹ mọ ìdáhùn Bíbélì sí àwọn ìbéèrè pàtàkì nípa Ọlọ́run, bí àwọn ohun tó ti pinnu láti ṣe àti ohun tó fẹ́ ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú. Ka ìdáhùn nípa díẹ̀ lára àwọn ìbéèrè yìí lórí ìkànnì Wo abẹ́ “Ẹ̀kọ́ Bíbélì > Ohun Tí Bíbélì Sọ.” O tiẹ̀ lè béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lórí ìkànnì wa tàbí kí o sọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé kí wọ́n wá kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó dá wa lójú pé tí o bá kọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì, wàá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ju bí o ṣe rò lọ.