Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 KÓKÓ Ọ̀RỌ̀ | ÀWỌN IRỌ́ TÍ KÒ JẸ́ KÁWỌN ÈÈYÀN NÍFẸ̀Ẹ́ ỌLỌ́RUN

Wọ́n parọ́ pé Ìkà ni Ọlọ́run

Wọ́n parọ́ pé Ìkà ni Ọlọ́run

OHUN TÍ Ọ̀PỌ̀ ÈÈYÀN GBÀ GBỌ́

Ìwé ẹ̀kọ́ ìsìn Kátólíìkì tó ń jẹ́ Catechism of the Catholic Church sọ pé: “Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni ọkàn àwọn tó bá kú sínú ẹ̀ṣẹ̀ máa ń lọ sí ọ̀run àpáàdì níbi tí wọ́n á ti máa jìyà nínú ‘iná ayérayé.’” Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn kan sọ pé gbogbo ẹni tó wà nínú ọ̀run àpáàdì kò lè sún mọ́ Ọlọ́run, wọ́n ti jìnnà pátápátá sí Ọlọ́run.

ÒTÍTỌ́ TÍ BÍBÉLÌ JẸ́ KÁ MỌ̀

“Ọkàn tí ń dẹ́ṣẹ̀-òun gan-an ni yóò .” (Ìsíkíẹ́lì 18:4) Àwọn òkú “kò mọ nǹkan kan rárá.” (Oníwàásù 9:5) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọkàn máa ń kú, tí ẹni tó kú kò sì mọ nǹkan kan, ṣé ó wá ṣeé ṣe kí ẹni yẹn tún máa joró nínú “iná ayérayé” tàbí kó jìnnà pátápátá sí Ọlọ́run?

Nínú Bíbélì, àwọn ọ̀rọ̀ Hébérù àti ti Gíríìkì tí wọ́n sábà máa ń tú sí “ọ̀run àpáàdì” dúró fún ipò òkú. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jóòbù ń ṣàìsàn tó le koko, ó gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Ìwọ ìbá fi mi pamọ́ ní ipò òkú.” (Jóòbù 14:13, Bíbélì Mímọ́) Ibi ìsinmi ni Jóòbù ń wá, kì í ṣe ibi tí yóò ti máa joró tàbí ibi tí á ti jìnnà pátápátá sí Ọlọ́run, inú sàréè ló ń sọ.

ÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ NÁÀ FI ṢE PÀTÀKÌ

Àwọn tó ń sọ pé ìkà ni Ọlọ́run kò fẹ́ kí á sún mọ́ ọn, ńṣe ni wọ́n fẹ́ ká jìnnà sí i. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Rocío, tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò sọ pé: “Láti ìgbà tí mo ti wà lọ́mọ ọwọ́ ni wọ́n ti fi ẹ̀kọ́ ọ̀run àpáàdì kọ́ mi. Ẹ̀rù bà mí débi pé mi ò tiẹ̀ rò pé Ọlọ́run ní ìwà rere kankan. Mo rò pé ó máa ń bínú gan-an, kò sì ní àmúmọ́ra.”

Àlàyé tó ṣe kedere tí Bíbélì ṣe nípa ìdájọ́ Ọlọ́run àti ipò tí àwọn òkú wà yí èrò tí Rocío ní nípa Ọlọ́run pa dà. Ó sọ pé: “Ará tù mí, àfi bíi pé wọ́n sọ ẹrù tó wúwo kalẹ̀ lórí mi. Ní báyìí, mo ti wá gbà pé lóòótọ́ ni Ọlọ́run fẹ́ ohun tó dára fún wa, ó nífẹ̀ẹ́ wa, èmi náà sì lè nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Mo wá rí i pé Ọlọ́run dà bí bàbá tó bìkítà nípa àwọn ọmọ rẹ̀, tó sì fẹ́ ire fún wọn.”—Aísáyà 41:13.

Ọ̀pọ̀ ló ń sin Ọlọ́run torí pé wọ́n ń bẹ̀rù iná ọ̀run àpáàdì, àmọ́ Ọlọ́run kò fẹ́ ká sin òun nítorí pé à ń bẹ̀rù òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù sọ pé: “Kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.” (Máàkù 12:29, 30) Yàtọ̀ síyẹn, tí a bá gbà pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúṣàájú, àá lè gbára lé ìdájọ́ tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú. Àwa náà á sì lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú bíi ti ọ̀rẹ́ Jóòbù náà, Élíhù tó sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe burúkú, Olódùmarè kì í sì í yí ìdájọ́ po.”—Jóòbù 34:12.