Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà

Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà

BÁWO ni ọkùnrin kan tí ojú rẹ̀ rí màbo láti kékeré ṣe di ọkọ àti bàbá tó ń láyọ̀, tó sì ń bójú tó ìdílé rẹ̀ dáadáa? Kí ló mú kí obìnrin kan tó ya ìyàkuyà yí pa dà di èèyàn dáadáa? Gbọ́ ohun tí wọ́n sọ.

“Mo wo ara mi bí ẹni tí kò wúlò fún nǹkan kan.”—VÍCTOR HUGO HERRERA

  • ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1974

  • ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: CHILE

  • IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: Ọ̀MÙTÍ PARA

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ:

Ìlú Angol ni wọ́n bí mi sí, ní apá gúúsù orílẹ̀-èdè Chile tó jẹ́ ibi tó lẹ́wà gan-an. Mi ò mọ bàbá tó bí mi. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́ta, ìyá mi kó lọ sí ìlú Santiago tó jẹ́ olú ìlú ilẹ̀ Chile, ó mú èmi àti àbúrò mi ọkùnrin dání. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ a ṣáà rí ibi kólóbó kan há ara wa mọ́ nínú àgọ́ hẹ́gẹhẹ̀gẹ ti àwọn aláìrí-ilé-gbé. Ilé ìyàgbẹ́ tó wà fún gbogbo èèyàn là ń lò, ibi ẹ̀rọ omi tí wọ́n ṣe fún àwọn panápaná la sì ti ń pọnmi.

Lẹ́yìn ọdún méjì, ìjọba fún wa ní ilé kékeré kan. Àmọ́ àwọn ọ̀mùtí, ọ̀daràn, aṣẹ́wó àti àwọn tó máa ń lo oògùn olóró ló kún àdúgbò náà fọ́fọ́.

Lọ́jọ́ kan ìyá mi pàdé ọkùnrin kan, wọ́n sì fẹ́ra nígbà tó yá. Òkú ọ̀mùtí ni ọkọ màmá mi yìí, ó sì máa ń lu èmi àti ìyá mi. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń dá sunkún níkọ̀kọ̀ torí pé mi ò ní bàbá tó lè gbà mí lọ́wọ́ ìyà yìí.

Ìyá mi ń ṣiṣẹ́ kára lójú méjèèjì kó lè tọ́jú wa, àmọ́ a ṣì jẹ́ akúùṣẹ́. Nígbà míì tí ebi bá ń pa wá, a kì í rí nǹkan míì jẹ ju mílíìkì gbẹrẹfu àti ṣúgà lọ. Tí èmi àti àbúrò mi bá fẹ́ najú, ṣe ni a máa ń jí tẹlifíṣọ̀n wò láti ojú fèrèsé obìnrin kan tó wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀dọ̀ wa. Àmọ́ ọjọ́ tó ká wa mọ́ ibẹ̀ nìyẹn dópin!

Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tí ọkọ màmá mi kò bá mutí yó, ó máa ń ra oúnjẹ fún èmi àti àbúrò mi. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tó ra tẹlifíṣọ̀n kékeré kan fún wa. Ìyẹn sì jẹ́ ọ̀kan lára ìgbà mélòó kan tí mo rántí pé mo láyọ̀.

Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méjìlá, mo kọ́ bí wọ́n ṣe ń kàwé. Ní ọdún kan lẹ́yìn náà, mo kúrò nílé ìwé mo lọ ń ṣiṣẹ́. Tí iṣẹ́ bá ti parí, èmi àti àwọn tó dàgbà jù mí tí a jọ ń ṣiṣẹ́ jọ máa ń lọ sí agbo àríyá, a ó mutí yó, a ó sì tún lo oògùn olóró níbẹ̀. Kò sì pẹ́ tí mo fi sọ nǹkan wọ̀nyẹn di bárakú.

Nígbà tí mo wà ní ọmọ ogún ọdún, mo pàdé ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Cati, a sì fẹ́ra wa nígbà tó yá. Nǹkan kọ́kọ́ ń lọ dáadáa fún wa o, àmọ́ nígbà tó yá mo tún pa dà sínú gbogbo ìṣe mi ti tẹ́lẹ̀. Mo kúkú wá ya ìyàkuyà pátápátá. Níkẹyìn mo rí i pé bí mo bá ń bá a lọ báyìí, ẹ̀wọ̀n tàbí ikú ni ọ̀rọ̀ mi máa já sí. Èyí tó tiẹ̀ dùn mí jù ni pé irú ìyà tó jẹ mí nígbà tí mo wà ní kékeré ni mo tún ń jẹ́ kó máa jẹ ọmọ mi Víctor báyìí. Ìbànújẹ́ bá mi, inú bí mi sí ara mi, mo wo ara mi bí ẹni tí kò wúlò fún nǹkan kan.

Ní nǹkan bí ọdún 2001, Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì wá sí ilé wa, Cati sì gbà kí wọ́n máa kọ́ òun ní ẹ̀kọ́ Bíbélì. Ó wá sọ ohun tó ń kọ́ fún mi. Èmi náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí n kàn tiẹ̀ fi mọ nǹkan tó ń kọ́. Lọ́dún 2003, Cati ṣe ìrìbọmi, ó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ:

Lọ́jọ́ kan, mo ka Rúùtù 2:1, tó sọ pé Jèhófà máa ń san ẹ̀san fún àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ tí wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti fi í ṣe ibi ìsádi, ìyẹn ibi ààbò wọn. Mo wá rí i pé tí mo bá yí ìwà mi pa dà, inú Ọlọ́run lè dùn sí mi, kó sì san mí lẹ́san. Mo sì kíyè sí i pé Bíbélì sọ ọ́ lemọ́lemọ́ pé ọtí àmupara kò dára. Ọ̀rọ̀ inú 2 Kọ́ríńtì 7:1 wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. Ẹsẹ Bíbélì yẹn gbà wá níyànjú pé kí á “wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin.” Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í jáwọ́ nínú àwọn ìwà àìdáa tí mo ń hù nìyẹn. Lákọ̀ọ́kọ́, ìbínú mi túbọ̀ pọ̀ sí i, àmọ́ Cati dúró tì mí digbí, kò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi sú òun.

Mo ní láti fi iṣẹ́ mi sílẹ̀ nígbà tó yá torí pé kò rọrùn fún mi láti wà níbẹ̀ láìmu ọtí àti sìgá. Lóòótọ́ láàárín ìgbà díẹ̀ tí mi ò fi ṣiṣẹ́, a ò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́, ṣùgbọ́n mo túbọ̀ ráyè tẹra mọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mò ń kọ́. Ìgbà yẹn ni mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ síwájú gan-an nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Aya mi Cati kì í béèrè nǹkan tó kọjá ohun tí agbára mi lè gbé, kì í sì í ráhùn pé a ò fi bẹ́ẹ̀ ní ọ̀pọ̀ nǹkan. Mo dúpẹ́ gan-an ni pé ó ń fìfẹ́ tì mí lẹ́yìn.

Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, mo túbọ̀ ń bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rìn pọ̀ dáadáa. Wọ́n jẹ́ kó yé mi pé bí mi ò tiẹ̀ ṣe kàwé yìí, Jèhófà mọyì bó ṣe ń wù mí láti sin òun tọkàntọkàn. Ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan tó wà nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ní ipa tó dára gan-an lórí ìdílé wa. A ò tún rí ibòmíì tí irú àlàáfíà bẹ́ẹ̀ wà láyé yìí. Ní December ọdún 2004, èmi náà wá ṣèrìbọmi.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ:

Ohun tí Jèhófà sọ nínú Aísáyà 48:17 ti ṣẹ sí mi lára. Ó ní: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní.” Ìgbé ayé mi tó yí pa dà wú ìyá mi àti àbúrò mi ọkùnrin lórí gan-an débi pé àwọn náà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kódà inú àwọn aládùúgbò wa ń dùn pé ìwà mi ti yí pa dà sí rere, àti pé ìdílé wa ti tòrò gan-an.

Ìyàwó mi jẹ́ ẹni tó fẹ́ràn Ọlọ́run gan-an, kòríkòsùn la sì jọ jẹ́, ó sì fọkàn tán mi dáadáa. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò mọ bàbá mi rárá, Bíbélì ti kọ́ mi bí màá ṣe tọ́ ọmọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí mo bí. Wọ́n sì máa ń bọ̀wọ̀ fún mi dáadáa. Ní pàtàkì, wọ́n mọ Jèhófà gan-an, wọ́n sì fẹ́ràn rẹ̀ gidigidi.

“Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò mọ bàbá mi rárá, Bíbélì ti kọ́ mi bí màá ṣe tọ́ ọmọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí mo bí”

Mo dúpẹ́ gan-an ni pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé ojú mi rí màbo nígbà èwe mi, Jèhófà ti mú kí n dẹni tó ń láyọ̀ ní báyìí tí mo ti dàgbà.

“Mo wá ya ọmọbìnrin onínú fùfù àti ìpáǹle.”—NABIHALA ZAROVA

  • ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1974

  • ORÍLẸ̀-ÈDÈ MI: BULGARIA

  • IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: MO Ń GBÉ OÒGÙN OLÓRÓ LỌ SÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ MÍÌ

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ:

Ìlú Sofia ní orílẹ̀-èdè Bulgaria ni wọ́n ti bí mi, ìdílé wa sì rí já jẹ. Ṣùgbọ́n bàbá mi fi ìdílé wa sílẹ̀ lọ nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mẹ́fà. Ìbànújẹ́ ńlá ló jẹ́ fún mi, ẹ̀dùn ọkàn mi sì pọ̀ gan-an. Mo wá ka ara mi sí ẹni tí wọ́n pa tì, àti ẹni tí àwọn èèyàn ò lè fẹ́ràn. Bí mo ṣe ń dàgbà, èrò yìí mú kí n di ọmọ aláìgbọràn. Mo wá ya ọmọbìnrin onínú fùfù àti ìpáǹle.

Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá ni mí nígbà tí mo kọ́kọ́ sá kúrò nílé. Mo sábà máa ń jí owó màmá mi àti ti àwọn òbí ìyá mi. Nílé ìwé, ìgbà gbogbo ni mo máa ń wọ ìjàngbọ̀n torí inú fùfù mi. Torí náà láàárín ọdún díẹ̀ péré, ilé ìwé márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n mú mi lọ. Ọdún mẹ́ta ló kù kí n jáde ilé ìwé nígbà tí mo pa ilé ìwé tì. Mo wá ń ṣe ìṣekúṣe kiri. Mo máa ń fa sìgá gan-an, mo sì jẹ́ amugbó. Mo tún jẹ́ ọ̀mùtí, mi kì í wọ́n lóde àríyá, mo sì máa ń gbé oògùn olóró lọ sí orílẹ̀-èdè míì. Ayé tí èèyàn ò ti nírètí kankan, tí àwọn èèyàn ti ń jìyà tí wọ́n sì ń kú yìí wá sú mi pátápátá. Torí náà, gbogbo ohun tí mo máa ń rò kò ju bí màá ṣe gbádùn ara mi ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan láì ronú ọ̀la.

Lọ́dún 1998, nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlélógún, wọ́n mú mi ní pápákọ̀ òfuurufú ìlú São Paulo, lórílẹ̀-èdè Brazil nígbà tí mo gbé oògùn olóró. Wọ́n sì jù mí sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rin.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ:

Ní ọdún 2000, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí ọgbà ẹ̀wọ̀n tí mo wà lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí náà, tó ń jẹ́ Marines, mú mi bí ọ̀rẹ́. Ó sì mú kó wù mí láti túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì. Mo wá béèrè nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́ àwọn tí a jọ wà lẹ́wọ̀n, torí pé mi ò gbọ́ nípa wọn rí. Ó yà mí lẹ́nu pé ohun tí èyí tó pọ̀ jù nínú wọn sọ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò dáa rárá. Obìnrin kan tí a jọ wà lẹ́wọ̀n sọ fún mi pé mo lè ṣe ẹ̀sìn èyíkéyìí o, àmọ́ kí n má ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ohun tó sọ wá mú kí n túbọ̀ fẹ́ mọ̀ sí i; mo fẹ́ mọ ìdí tí àwọn èèyàn fi kórìíra àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó bẹ́ẹ̀. Nígbà tó yá, mo gbà pé ìsìn tòótọ́ tí wọ́n ń ṣe ni àwọn èèyàn fi kórìíra wọn. Bíbélì ṣáà sọ pé gbogbo ẹni tó bá ti ń gbìyànjú láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù ni wọ́n máa ṣe inúnibíni sí.—2 Tímótì 3:12.

Láàárín ìgbà yẹn, ilé tí wọ́n fi ṣe ọ́fíìsì àwọn tó ń bójú tó ọgbà ẹ̀wọ̀n wa ni wọ́n ní kí n ti máa ṣiṣẹ́. Lọ́jọ́ kan mo wá rí àwọn àpótí kan tí wọ́n kó àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! * tó ti pẹ́ gan-an sí ní yàrá ìkó-nǹkan-sí. Ni mo bá kó àwọn ìwé ìròyìn náà lọ sínú yàrá tí mo wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í kà wọ́n. Bí mo ṣe ń kà wọ́n sí í, bẹ́ẹ̀ ló ń dùn mọ́ mi bí ìgbà tí ẹni tó ti ń rìn nínú aṣálẹ̀ gbígbẹ táútáú dé ibi ìsun omi tútù. Kò kúkú fi bẹ́ẹ̀ sí nǹkan tí mo ń ṣe, torí náà ọ̀pọ̀ wákàtí ni mo fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lójoojúmọ́.

Lọ́jọ́ kan, wọ́n ní kí n wá sí ọ́fíìsì ọgbà ẹ̀wọ̀n wa. Èrò mi ni pé wọ́n ti fẹ́ tú mi sílẹ̀, ni mo bá sáré di àwọn nǹkan mélòó kan ti mo ní pa pọ̀, mo kí àwọn ẹlẹ́wọ̀n yòókù pé ó dìgbóṣe, mo sì sáré lọ sí ọ́fíìsì náà. Ṣùgbọ́n nígbà tí mo débẹ̀, ṣe ni wọ́n sọ fún mi pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ bá mi ṣe ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn àwọn ayédèrú ìwé tí wọ́n ká mọ́ mi lọ́wọ́. Bí wọ́n ṣe tún fi ọdún méjì kún ẹ̀wọ̀n mi nìyẹn.

Inú mi kọ́kọ́ bà jẹ́ gan-an. Àmọ́ lọ́jọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í rí i pé ire ńlá ni ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn máa já sí fún mi. Ìdí ni pé, bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo ti kọ́ ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ nínú Bíbélì, ó ṣì wù mí kí n máa bá ìgbé ayé mi àtẹ̀yìnwá nìṣó tí mo bá ti kúrò lẹ́wọ̀n. Ìyẹn fi hàn pé ó ṣì yẹ kí n lo àkókò díẹ̀ sí i kí n lè yí pa dà pátápátá.

Láwọn ìgbà kan, ṣe ni ó ń ṣe mí bíi pé Ọlọ́run kò ní gbà kí n jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó ń sìn ín. Ṣùgbọ́n mo ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ẹsẹ Bíbélì bíi 1 Kọ́ríńtì 6:9-11. Àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn fi hàn pé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni, àwọn Kristẹni kan jẹ́ olè tàbí ọ̀mùtí tàbí alọ́nilọ́wọ́gbà kó tó di pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sin Jèhófà. Síbẹ̀, Jèhófà ràn wọ́n lọ́wọ́, wọ́n yí pa dà. Ìṣírí ńlá ni àpẹẹrẹ wọn jẹ́ fún mi.

Kò ṣòro fún mi láti jáwọ́ nínú àwọn kan lára ìwàkiwà mi. Bí àpẹẹrẹ, kò fi bẹ́ẹ̀ nira fún mi láti jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró. Sìgá mímu ni mi ò tètè rí fi sílẹ̀ bọ̀rọ̀. Ó lé ní ọdún kan gbáko tí mo fi sapá gidigidi kí n tó lè jáwọ́ ńbẹ̀. Ohun kan tó ràn mí lọ́wọ́ ni pé mo ṣèwádìí nípa àwọn ìpalára tí sìgá mímu ń ṣe fún ìlera èèyàn. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, olórí ohun tó jẹ́ kí n lè jáwọ́ ni pé mo ń gbàdúrà sí Jèhófà láìsinmi.

“Mo ti rí Bàbá tó ju bàbá lọ, ìyẹn bàbá tí kò ní kọ̀ mí sílẹ̀ láéláé!”

Bí mo ṣe túbọ̀ ń sún mọ́ Jèhófà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í borí èrò pé mo jẹ́ ẹni tí wọ́n pa tì, èyí tó ti ń bá mi fínra láti ìgbà tí bàbá mi ti fi wá sílẹ̀ lọ. Ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 27:10 wọ̀ mí lọ́kàn gan-an ni. Ẹsẹ yẹn sọ pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé baba mi àti ìyá mi fi mí sílẹ̀, àní Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gbà mí.” Mo rí i pé mo ti rí Bàbá tó ju bàbá lọ, ìyẹn bàbá tí kò ní kọ̀ mí sílẹ̀ láéláé! Ìgbésí ayé mi ṣẹ̀ṣẹ̀ wá lójú wàyí. Ní oṣù April ọdún 2004, ìyẹn oṣù mẹ́fà lẹ́yìn tí mo jáde ní ọgbà ẹ̀wọ̀n, mo ṣe ìrìbọmi mo sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ:

Mo jẹ́ ẹni tó ń láyọ̀ báyìí. Mo bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìwàkiwà tó ń ṣe ìpalára fún mi, mo sì ní àlàáfíà ara àti ìfọ̀kànbalẹ̀ ju èyí tí mo ní látẹ̀yìn wá kí n tó dàgbà tó báyìí. Ìdílé mi tòrò, èmi àti Jèhófà Baba mi ọ̀run sì jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Mo sì tún ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ arákùnrin àti àwọn arábìnrin àti ìyá àti baba láàárín àwọn olùjọsìn rẹ̀. (Máàkù 10:29, 30) Mo dúpẹ́ gan-an pé wọ́n kà mí sí ẹni tó máa wúlò, àní kí èmi pàápàá tó rò bẹ́ẹ̀.

Nígbà míì, ìrònú máa ń bá mi nítorí irú ìgbé ayé tí mo ti gbé tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n ohun tó máa ń tù mí nínú ni pé, nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí, gbogbo àròkàn àti àròdùn yóò di ohun tí “a kì yóò sì mú wá sí ìrántí” mọ́. (Aísáyà 65:17) Ṣùgbọ́n ní báyìí ná, ìrírí mi ti jẹ́ kí n lè máa gba ti àwọn tó bá ní irú àwọn ìṣòro bíi tèmi rò. Ìrírí tí mo ní yìí wúlò fún mi gan-an. Bí àpẹẹrẹ, tí mo bá wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ó máa ń rọ̀ mí lọ́rùn láti wàásù fún àwọn tí wọ́n ti sọ oògùn olóró di bárakú, àwọn ọ̀mùtípara tàbí àwọn ọ̀daràn, láìsí pé mo kọ́kọ́ ń sára fún wọn. Ó dá mi lójú pé níwọ̀n bí mo ti lè yí pa dà kí n lè rí ojú rere Jèhófà, kò sí ẹnì kankan tí kò lè yí pa dà!

^ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.