ILÉ ÌṢỌ́ October 2012 | Báwo Ni Ìwà Ìbàjẹ́ Ṣe Gbilẹ̀ Tó?

Kí ló ń fa ìwà ìbàjẹ́? Àwọn àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé ohun tó ń fà á àti ohun tá a lè ṣe sí i?

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Báwo Ni Ìwà Ìbàjẹ́ Ṣe Gbilẹ̀ Tó?

Ìwà ìbàjẹ́ ti gbòde kan kárí ayé, àtunbọ̀tán rẹ̀ kìi síì dáa nígbà míì.

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Ǹjẹ́ Èèyàn Lè Jẹ́ Olóòótọ́ Nínú Ayé Oníwà Ìbàjẹ́ Yìí?

Wo bí àwọn méjì ṣe kọ́ nípa àǹfààní tó wà nínú kéèyàn jẹ́ olóòótọ́.

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Ìwà Ìbàjẹ́ Yóò Dópin!

Ọlọ́run máa to mú gbogbo ìwà ìbàjẹ́ kúró láyé. Báwo ló ṣe máa ṣe é?

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ran Agbo Ilé Kan Tó Ń ṣe Ẹ̀sìn Híńdù Lọ́wọ́

Kí nìdí tí agbo ilé kan tó ń ṣe ẹ̀sìn Hindu ṣe rí àlááfíà àti ìrètí torí bí wọ́n ṣe kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

ÌJÍRÒRÒ LÁÀÁRÍN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ ÀTI ẸNÌ KAN

Ṣé Ọlọ́run Máa Ń Dá Àwọn Èèyàn Lóró Nínú Iná Ọ̀run Àpáàdì?

Ẹ̀rí wà pé olódodo ni Ọlọ́run bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó máa fìyà jẹ àwọn èèyàn burúkú.

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ àwọn Kristẹni sá kúrò ní Jùdíà kí Jerúsálẹ́mù tó pa run lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni? Àwọn wo ni “àwọn ọmọ àwọn wòlíì”?

KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁTINÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ǹjẹ́ O Lè Wà Láàyè Títí Láé?

Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tó fún wa ní ẹ̀mí, lè fún èèyàn níu ìyè àìnípẹ̀kun ó sì ti ṣèlérí láti ṣe bẹ́ẹ̀.

SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN

“Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé sì Jókòó”

Ta ni “Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé”, kí sì ni ìran tí Dáníẹ́lì rú túmọ̀ sí?

TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÌGBÀGBỌ́ WỌN

“Obìnrin Títayọ Lọ́lá”

Ọmọ ilẹ̀ Móábù ni Rúùtù, àjèjì ni ní Ísírẹ́lì, tálákà sì tún ni. Kí nìdí tí wọ́n fi pè é ní “obìnrin títayọ lọ́lá”?

ÀWỌN ÒǸKÀWÉ WA BÉÈRÈ PÉ

Ṣé Ó Dìgbà Téèyàn Bá Lọ́kọ Tàbí Téèyàn Bá Láya Kó Tó Lè Láyọ̀?

Ṣé àwọn Kristẹni tí kò ṣègbeyàwó lè láyọ̀ ṣá? Bíbélì jẹ́ ká mọ ojú tó yẹ ká fi wo ìgbeyàwó àti àpẹẹrẹ àwọn tí kò gbéyàwó, síbẹ̀ tí wọ́n láyọ̀.

Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà

Báwo ni àwọn méjì, tí ìwà burúkú bí ọtí àmujù àti lílo òògùn olóró kún ọwọ́ wọn, ṣe jáwọ́ tí wọ́n sì wá di ẹni tó ń láyọ̀?

ERÉ ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ

Má Ṣe Máa Wá Ipò Ńlá!

Ábúsálómù, tó jẹ́ ọmọkùnrin kẹta tí Dáfídì bí fẹ́ fipá gbàjọba, àmọ́ ohun ńlá tó ń wá máa ná a ní ohun tó pọ̀.