Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Oríṣi Ohun Ọ̀gbìn Méje” Lára Ohun Ọ̀gbìn Ilẹ̀ Tí Ó Dára Náà

“Oríṣi Ohun Ọ̀gbìn Méje” Lára Ohun Ọ̀gbìn Ilẹ̀ Tí Ó Dára Náà

“Oríṣi Ohun Ọ̀gbìn Méje” Lára Ohun Ọ̀gbìn Ilẹ̀ Tí Ó Dára Náà

NÍGBÀ tí wọ́n ń kọ Bíbélì, wọ́n máa ń pe ilẹ̀ Ísírẹ́lì ní, ilẹ̀ olókè àti àfonífojì, ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀ etíkun àtàwọn òkè olórí pẹrẹsẹ, ilẹ̀ tó ní àwọn odò àtàwọn ìsun omi. Ilẹ̀ yìí máa ń so oríṣiríṣi èso tó dára gan-an, nítorí pé oríṣiríṣi erùpẹ̀ àti ojú ọjọ́ ló wà níbẹ̀, yàtọ̀ síyẹn, wọ́n ní aṣálẹ̀ ní gúúsù àti àwọn òkè tí yìnyín bò ní àríwá. Nígbà tí Mósè ń fojú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ́nà nípa ohun tí wọ́n máa rí ní “ilẹ̀ tí ó dára” náà, ó pè é ní “ilẹ̀ àlìkámà àti ọkà bálì àti àjàrà àti ọ̀pọ̀tọ́ àti pómégíránétì, ilẹ̀ ólífì olóròóró àti oyin,” ó dárúkọ ohun ọ̀gbìn méje.—Diutarónómì 8:7, 8.

Títí dòní, wọ́n ṣì ń lo ọ̀rọ̀ náà “oríṣi ohun ọ̀gbìn méje” láti ṣàlàyé àwọn ohun tí ilẹ̀ náà ń mú jáde. Ọ̀pọ̀ ìgbà tó yàtọ̀ síra ni wọ́n ti yàwòrán àwọn ohun ọ̀gbìn ilẹ̀ náà sára ẹyọ owó àtàwọn sítáǹbù láti fi ṣàpẹẹrẹ bí ilẹ̀ náà ṣe lọ́ràá tó. Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣọ̀gbìn àwọn nǹkan yìí lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì? Ipa wo ló ń ní lórí ìgbésí ayé àwọn èèyàn lójoojúmọ́? Ẹ jẹ́ ká wò ó.

“Àlìkámà àti Ọkà Bálì” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, àkókò kan náà ni wọ́n máa ń gbin àlìkámà àti ọkà bálì, ìyẹn ní ìgbà ìwọ́wé, àmọ́ ọkà bálì máa ń fi oṣù kan gbó ṣáájú àlìkámà. Wọ́n máa ń mú ìtí ọkà báálì tó jẹ́ àkọ́so wá sí tẹ́ńpìlì ní oṣù March tàbí April láti fi rúbọ sí Jèhófà lákòókò tí wọ́n bá ń ṣe Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìní-ìwúkàrà. Àmọ́ wọ́n máa ń mú àlìkámà wá ní oṣù May láti fi rúbọ, ìyẹn nígbà tí wọ́n bá ń ṣe Àjọyọ̀ Àwọn Ọ̀sẹ̀ tàbí Pẹ́ńtíkọ́sì.—Léfítíkù 23:10, 11, 15-17.

Láti ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún títí di ẹnu àìpẹ́ yìí, inú aṣọ làwọn àgbẹ̀ ilẹ̀ Ísírẹ́lì máa ń kó àwọn nǹkan oníhóró tí wọ́n fẹ́ gbìn sí, wọ́n á sì máa fi ọwọ́ fọ́n-ọn kiri. Ńṣe ni wọ́n máa ń fọ́n ọkà bálì káàkiri orí ilẹ̀. Àmọ́ ní ti hóró àlìkámà, wọ́n máa ní láti fi erùpẹ̀ bò ó ni. Bí wọ́n ṣe máa ń gbìn ín ni pé, yálà kí àwọn ẹranko tó ń túlẹ̀ tú ilẹ̀ fi bò ó tàbí kí àwọn èèyàn da erùpẹ̀ bò ó.

Bíbélì sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa fífún irúgbìn, kíkórè, pípakà, fífẹ́ ọkà àti lílọ ọkà. Iṣẹ́ kékeré kọ́ ni wọ́n máa ń ṣe ní ìpele iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan. Lójoojúmọ́, nínú ilé àwọn èèyàn, wọ́n máa ń lọ àwọn hóró tí wọ́n kórè náà, á sì di ìyẹ̀fun, lẹ́yìn náà, wọ́n máa ń fi ṣe búrẹ́dì tí ìdílé máa jẹ. Èyí mú ká túbọ̀ lóye ìtọ́ni tí Jésù fún wá pé ká máa gbàdúrà fún “onjẹ ojọ wa.” (Mátíù 6:11, Bibeli Mimọ) Búrẹ́dì tí wọ́n fi ìyẹ̀fun àlìkámà tàbí ọkà bálì ṣe wọ́pọ̀ gan-an lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì.—Aísáyà 55:10.

“Àjàrà àti Ọ̀pọ̀tọ́ àti Pómégíránétì” Lẹ́yìn tí Mósè ti ṣe aṣáájú àwọn èèyàn rẹ̀ nínú aginjù fún ogójì [40] ọdún, ó mú wọn dé bèbè ibi tí wọ́n ti máa gbádùn ohun tí wọ́n ń retí, ìyẹn jíjẹ lára èso Ilẹ̀ Ìlérí. Àbí, ẹ̀rí wo làwọn amí tó rán lọ ṣe amí Ilẹ̀ Ìlérí náà lógójì ọdún sẹ́yìn mú wá sí àgọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní aginjù láti fi hàn pé ilẹ̀ náà lọ́ràá gan-an? Ohun náà ni, “ọ̀mùnú kan tí ó ní òṣùṣù èso àjàrà,” èyí tí ó wúwo débi pé, “ọ̀pá gbọọrọ” ni “méjì lára àwọn ọkùnrin náà” fi gbé e. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún mú èso ọ̀pọ̀tọ́ àti pómégíránétì bọ̀. Ẹ ò rí i pé, oúnjẹ àjẹpọ́nnulá ni èyí jẹ́ fún àwọn tó ń rìn kiri ní aginjù yìí! Ìyẹn wulẹ̀ jẹ́ ìtọ́wò ráńpẹ́ nípa àwọn ohun rere tí wọ́n ṣì máa gbádùn!—Númérì 13:20, 23.

Ọgbà àjàrà nílò àbójútó déédéé, ìyẹn kí wọ́n máa gé e, kí wọ́n máa bomi rin ín, kí wọ́n sì máa kórè rẹ̀, nípa báyìí yóò lè máa méso jáde dáadáa. Oko àjàrà tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè máa ń ní ojú ilẹ̀ tí wọ́n ṣe ní ìpele-ìpele, ó tún máa ń ní ọgbà tó yí i ká láti dáàbò bò ó, wọ́n sì máa ń ṣe àtíbàbà olùṣọ́ sínú rẹ̀. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe nínú ọgbà àjàrà, wọ́n sì mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ tí èèyàn kò bá ṣe àwọn nǹkan náà.—Aísáyà 5:1-7.

Àkókò tí wọ́n bá ń kórè èso àjàrà, ni wọ́n máa ń bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe wáìnì. Wọ́n máa ń kó èso àjàrà púpọ̀ jọ, wọ́n á sì tẹ̀ ẹ́ nínú agbada ńlá tàbí kí wọ́n fún un nínú ìfúntí. Nígbà míì, wọ́n máa ń se omi tí wọ́n bá rí látara èso àjàrà kí wọ́n lè yọ ṣúgà tó wà nínú rẹ̀ tàbí kí wọ́n fi í sílẹ̀ kó lè kan, kó sì di wáìnì. Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní àwọn ilẹ̀ tó dáa fún gbíngbin èso àjàrà tí wọ́n lè fi ṣe wáìnì. *

Ó lè jẹ́ pé èso ọ̀pọ̀tọ́ gbígbẹ àti omi èso ọ̀pọ̀tọ́ tí wọ́n fún nìkan làwọn èèyàn tó ń gbé níbi tó jìnnà sí ibi tí wọ́n ti ń gbin igi ọ̀pọ̀tọ́ máa ń rí. Èso ọ̀pọ̀tọ́ tí kò tíì gbẹ́ máa ń yàtọ̀ gan-an, nítorí pé ó máa ń dùn gan-an, ó sì máa ń lómi. Téèyàn bá fẹ́ tọ́jú èso ọ̀pọ̀tọ́ kó lè pẹ́ kọjá ìgbà kúkúrú tí wọ́n fi ń kórè rẹ̀, èèyàn ní láti sá a gbẹ kó sì kó o pa mọ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n sọ̀rọ̀ nípa “ìṣù èso ọ̀pọ̀tọ́” nínú Bíbélì.—1 Sámúẹ́lì 25:18.

Tí páádi èso pómégíránétì tó ti pọ́n bá fọ́, ó lè ṣàkóbá fún èso inú rẹ̀, èyí lè mú kó bà jẹ́, ó sì lè má ṣe ara lóore. Bí wọ́n ṣe fi nǹkan ṣe èso pómégíránétì sí eteetí ọ̀kan lára aṣọ àlùfáà àgbà nígbà yẹn lọ́hùn ún àti bí wọ́n ṣe ṣe é sára òpó tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì fi hàn pé àwọn èèyàn mọyì èso yìí gan-an ni.—Ẹ́kísódù 39:24; 1 Àwọn Ọba 7:20.

“Ólífì àti Oyin” Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ibi ọgọ́ta [60] tí Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa ólífì, ó jẹ́ ohun tí wọ́n máa ń fi se oúnjẹ, wọ́n sì tún máa ń lo òróró rẹ̀ fún nǹkan míì. Oko ólífì ṣì wà láwọn ibi tó pọ̀ nílẹ̀ Ísírẹ́lì. (Diutarónómì 28:40) Láwọn àgbègbè kan títí dòní, ńṣe làwọn ìdílé máa ń pawọ́ pọ̀ kórè rẹ̀ lóṣù October. Àwọn tó ń kórè máa lu igi láti gbọn èso ólífì bọ́, lẹ́yìn náà, wọ́n á wá ṣa àwọn èso tó já bọ́ sílẹ̀. Wọ́n máa ń tọ́jú èso ólífì pa mọ́, òun sì ní àwọn ìdílé máa ń jẹ jálẹ̀ ọdún tàbí kí wọ́n kó o lọ síbi tí wọ́n ti ń ṣe òróró fún àwọn ará àdúgbò. Kódà, ọgọ́rọ̀ọ̀rún onírúurú ibi tí wọ́n ti ń ṣe òróró ólífì làwọn awalẹ̀pìtàn ti wà jáde. Lóde òní, ó máa ń fani mọ́ra téèyàn bá ń wo òróró aláwọ̀ ewé tí wọ́n ń dà sínú ohun ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ sí fún ìlò àwọn ìdílé lọ́dún kan tàbí tí wọ́n fẹ́ lọ tà lọ́jà. Yàtọ̀ sí pé wọ́n máa ń fi òróró ólífì se oúnjẹ, wọ́n tún ń lò ó fún ìpara àti epo àtùpà.

Ó ṣeé ṣe kí oyin tí Mósè sọ jẹ́ èyí tó wá látara kòkòrò oyin tàbí kó jẹ́ èyí tó wá látara èso déètì àti èso àjàrà. Wọ́n ṣì máa ń lo oyin tó wá látara àwọn èso yìí láti mú nǹkan dùn. Àmọ́ oyin tí Bíbélì sọ nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa Sámúsìnì àti Jónátánì jẹ́ oyin tó wá látinú afárá oyin. (Àwọn Onídàájọ́ 14:8, 9; 1 Sámúẹ́lì 14:27) Ilé oyin tó lé ní ọgbọ̀n tí wọ́n ṣàwárí rẹ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí ní Tel Rehov, ìyẹn àríwá ilẹ̀ Ísírẹ́lì fi hàn pé, àwọn èèyàn máa ń sin oyin láti ayé ìgbà Sólómọ́nì.

Lóde òní, ẹnikẹ́ni tó bá rìn gba inú ọjà Ísírẹ́lì kọjá máa rí “oríṣi ohun ọ̀gbìn méje” ni onírúurú ọ̀nà, ní àwọn ilé tí wọ́n ti ń ṣe búrẹ́dì àtàwọn ìsọ̀ tí wọ́n ń kó èso àti ewébẹ̀ sí. Díẹ̀ ni àwọn ohun ọ̀gbìn méje yìí jẹ́ lára ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ohun jíjẹ tí wọ́n ń gbìn níbẹ̀. Ọ̀nà ìgbàlódé tí wọ́n gbà ń ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀ báyìí ti jẹ́ kó ṣeé ṣe láti lè máa gbin àwọn ohun ọ̀gbìn ilẹ̀ kan ní ilẹ̀ ibòmíì. Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn àmújáde yìí fi hàn pé orúkọ ilẹ̀ kékeré yìí ń rò ó, pé lóòótọ́ ló jẹ́ “ilẹ̀ tí ó dára.”—Númérì 14:7.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Wọ́n tún máa ń sá èso àjàrà lóòrùn kí wọ́n lè fi ṣe èso àjàrà gbígbẹ.—2 Sámúẹ́lì 6:19.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Àlìkámà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Ọkà bálì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Àjàrà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12, 13]

Ọ̀pọ̀tọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Pómégíránétì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Oyin

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ólífì